Document Body Page Navigation Panel
1
CHANGE
ATOKA Akoko Oju Ewe
Idagbasoke
IPOLONGO
Ona Titun Lati Fi Polongo Abajade Iwadi 2mins. 1sec. Iroyin titun
kan soro lori iyeneji ti awon
amoye nipa idagbasoke ni lori awon ona
atijo fun ipolongo awon abajade iwadi
EKO
Orile-Ede Naijiria Ati Awon Miran Je Anfani Lara Eto Agbaye Lori Iwe 1min.
51secs.
O ju milionu marun iwe lo ti a ti fun awon
orile-ede Afirika laarin ogbon odun
ILERA
Awon Ogun Laisi Awon Ohun-Ose Agbenule-Bugbanmu Ti Npaniyan 2mins. 1sec
Ipolongo kariaye lati tako awon ohun ose
agbemule-bugbamu ti npaniyan ti nyorisi rere.
ORO AWON OBIRIN
Orile-Ede Ghana Se Agbedide Ilana-Eto Fun Ifiagbara Fun Awon Obirin 1min.
5secs
Orile-ede Ghana nseto lati wo inu orundun titun
pelu eto to peye lori oro idamo nipa eya ara
Iwa-Ipa Si Awon Omode Wopo Ni Orile-Ede Uganda 1min. 41secs Awon
iwa-ibaje buruku ti ko se fenuso ni o dabi enipe
won nhu si awon omode ni orile-ede Uganda.
Awon Opo Ja Fun Eto Ipeja Ni Orile-Ede South Africa 2min. 58secs. Awon
obirin opo to ti dagba ni ilu awon apeja kan ni
orile-ede South Africa jijadu fun eto to dogba pelu awo
okunrin
Ise Fun Eto Awon Obirin Lori Ijogun 1min. 13secs Awon obirin iwo-oorun
ile Afirika
njijadu fun eto lati jogun awon ohun
ini
Ayika
ISE OGBIN
Kokoro Alajerun Mu Irokeke Ewu Deba Ipese Ounje Ni Orile-Ede Ghana 1min. 39secs
O seese ki ekun ologbele ti iha ariwa
orile-ede Ghana padanu bi idaji ninu
Ire-oko won ni odun yi 1
1 Page 2 3
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
2
CHANGE
Owo Igbawease Le Mu Irewesi Ba Awon Agbe Ti Ki Ilo Ajile Onikemkali
1min. 39secs
Isoro lati kun oju iwon afilele idarasi fun awon
ounje ti a ko fi ajile kemikali gbin le mu ki awon
orile-ede to sese ndagbasoke padanu ipin to joju ninu
oja to ngboro si.
IYIPADA AFEFE ILE
Ojo Omiro Ajenilara Tabi Imorusi Aye? 2mins. 9secs Ojutu si isoro
iyipada ninu afefe ile le ma
lo taara gegebi awon afenifere ayika ti lero
ETO IMULO FUN ITOJU
Oro ti Enikan so lori Iseda ati Emi Eda Eniyan 33secs. Awon eniyan
gbodo se iwontunwonsi larin igbe-aye
ode oni ati iseda aye
Orile-Ede Zambia Se Ayewo Ayika Re 1min. 45secs Awon ajo lori
ayika ni agbaye ati ijoba
orile-ede Zambia se agbeyewo ipinsi-yeleyele
eweko ati eranko orile-ede na.
ISE IKOLE
Awon Onimo ijinle sayensi gbejako Eto Agbese Ajo oloko-owo Mitsubishi 1min.
24secs
Eto lati ko ile ise iyo sori Ibudo Ajogunba
Agbaye kan ni o ti ru ibinu awon gbajumo
onimo ijinle sayensi soke.
AWON IGBO
Awon Igbo Orile-Ede Ghana 26secs. Oro die nipa oro gedu orile-ede
Ghana
ETO OUNJE
Odunkun Iyanu 45secs. Odunkun ti yio ma mu ire pupo jade ni won
ti se agbedide re ni orile-ede Amerika.
AWON AJALU IDOTI
Egbin Melo Ni Oko Ayokele Re Ngbe Jade? 31secs. Imo titun si itujade
lati inu oko irinna
Opo Lo Nsa Fun Ajalu Ayika Ju Ti Ogun Lo Nisisiyi 43secs. Iroyin
titun fihan wipe awon ajalu ayika ti so eniyan
pupo di alainibugbe ju ogun lo
A Nilo Awon Ohun Ipana To Je Ore Ayika 1min. 13secs. Awon ifofo
ti a fi npa ina ngbe egbin wo inu
awon omi abe ile 2
2 Page 3 4
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
3
CHANGE
IMO IJINLE SAYENSI
Oko Inu Ofurufu Fe Kolu Aye 52 Secs. Awon amoye irawo gbagbo wipe
awon
ohun nla lati inu orun le kolu ile aye
EDA ABEMI EGAN
Beari: A Nri Won Ninu Obe Ju Ninu Igbo 1min. 40 Secs. Akojopo awon
eranko beari ni agbaye ni
o ni idojuko irokeke iparun
Awon Ijapa Okun Nse Agbero Awon Agbegbe
Ibisi Won 2min. 9secs. Eri wipe idabobo awon eranko egan dara fun
ayika
Eto Fun Awon Omode Ijapa Ati Ekuro 5mins. 24secs.
Bi aisooto ati ojukokoro ijapa se
mu ijanba ba idile re.
Egun Ti O Sonu 3mins. 21secs. Itan Ndebele kan lati iha guusu
Afirika se alaye idi re ti Agbanrere
fi ntan igbe re ka.
Nje Ibunije Ojola Le Dababo Eni To Buje Kuro
Lowo Ibunije Awon Ejo Miran? 1min. 7secs. Ibunije ojola ko funmi ni ajesara
kuro lowo ibunije
awon ejo oloro pupo.
Nje Awon Alangba Ma Nge Iru Won Lati Jajabo Lowo Awon To Fe Pa Won? 50secs.
Ri aridaju idi re ti awon alangba fi nge iru won – Ijanba
ni tabi amomose? 3
3 Page 4 5
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
4
CHANGE
Iroyin Orile-Ede Naijiria Ati Awon Miran Je Anfani Lara
Eto Agbaye Lori Iwe 1min. 51secs Awon orile-ede Afirika meje, lara awon
ti a ti ri orile-ede Naijiria, ni won gba eyi to poju ninu awon iwe ti ajo
orile-ede Amerika kan ti ko lowo ijoba ninu ti nse ipese re fun awon orile-ede
to sese ndagbasoke lati odun 1962. Awon orile-ede yoku ni Zimbabwe, Zambia,
Uganda, Liberia, Ghana ati Etopia.
Laipe yi ni a fi orile-ede South Africa kun awon olujanfani na, o si wo inu
iwe itan mgbati o gba iwe to mu gbogbo iwe na di ogoji milionu.
Ajo ti ko lowo ijoba ninu na ti a mo si Ajo amulu dun Arakunrin awon Arakunrin
(Brothers Brother Foundation
(BBF) a ma se ipese awon iwe si awon orile-ede to sese ndagbasoke lati mu won'
dagba ninu eko giga ki won si se aseyori imo to ga' iyen gegebi oro lati enu
ogbeni Luke Hingson to je Aare ajo BBF.
Ajo na a ma se ipinfunni awon iwe bi milionu meta lododun fun awon orile-ede
to sese ndagbasoke. O ju milionu marun iwe ti won ti se ipese re si ile Afirika.
Gegebi oro lati enu Hingson ti Ajo orile-ede Amerika fun Ifitonileti (United
States Information Agency (USIA) gbe jade: "Bi milionu meji ni o lo si Zimbabwe,
milionu kan lo si Liberia ati egbegberun lona egbeta si Ghana.
Awon to tun ti gba ipin to ga ni Zambia, Uganda, Naijiria ati Etopia."
Hingson so wipe awon pupo lo ti lowosi aseyorisirere eto ipese iwe ti BBF. O
ju awon agbewejade adota lo ti won ko awon iwe won sile lara awon ti a ti ri
ajo Lippincott-Raven, McGraw-Hill, Simon & Shuster, Awon
koko pataki ti Scott-Foreman fun awon Omode, Zanep Bloser ati John Wiley and
Sons. Igbeowo-sile wa lati odo Ajo Orile-ede Amerika fun Idagbasoke kariaye
(United States Agency for International Development
(USAID), Ile-ise ijoba orile-ede Amerika fun Ise-ogbin (U. S. Department of
Agriculture).
USIA, ati Eto Ijoba orile-ede Amerika fun idapada owo oko ori okun (U. S. Government's
Ocean Freight Reimbursement Programme).
Awon orile-ede to ngba awon iwe na ni ipa ti won nko. Akosile awon iwe ti
awon agbewejade se ipese re ni
won ma nfi han won ki won le yan ninu re, nipa bayi ohun ti won nilo nikan ni
won yio gba. Newslink Africa.
Awon Eranko Beari: A Nri Won Ninu Obe Ju Ninu Igbo Lo 1min. 40secs
Beari, eranko nla ajeran kan onirun sakisaki to ni awon eekanna woroko to
loro pupo, ni irokeke iparun ti wa lori re nibi gbogbo nitori won wulo fun ounje
ati egbogi. Eyi ni ifohunsi agbeyewo agbaye akoko lori ipo ti
awon eranko beari wa, eyi ti ajo agbaye fun itoju iseda aye-Ajo Akojo Owo
ni Agbaye fun Iseda Aye (World Wide Fund for Nature (WWF) – se.
Iwadi na toka si ise gedu, ise ogbin, ode sise, ija pelu eda eniyan ati owo
kariaye gegebi awon afikun irokeke ewu si awon eranko na.
Ode sise ti mu isofo nla ba awon eya meta ti ile Asia ti a mo si sloth, sun
ati beari dudu. Ijaya wa wipe eya sun ti parun patapata ni orile-ede India.
Ise ogbin ati owo ninu egbogi ti jeki beari alawo oloye na parun patapata 4
4 Page 5 6
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
5
CHANGE
ni orile-ede Mexico. Ni ile alawo funfun Europe and iha ariwa ile Amerika,
irokeke ewu wa fun won lati inu ija laarin eniyan ati eranko ati owo sise.
Eranko beari ki ise ohun ti a mo pupo ni ile Afirika. Owo kariaye ninu awon
eya ara beari mi o wa ni ile Asia, Europe, Ariwa ati Gusu ile Amerika, a si
nlo won ninu egbogi ibile ti orile-ede China fun itoju awon arun okan,
edo ati iyodi. Akojade WWF na ti won gbe jade ni ojo ketadunlogbon osu keje
odun yi tun so wipe won ma nje awon owo beari bi adidun.
Gegebi oro Elizabeth Kempf to je Alakoso Ifitonileti nipa awon Eya fun ajo
WWF ati alajoko abajade iwadi na ti a pe ni: A fe won laaye! Awon Beari inu
Egan: "Awon eyaara beari wa ninu awon oja ile Asia. Bi iye
awon beari ti nlo sile, awon eranko ti awon ile Amerika ni awon onisowo tun
nfojusi." WWF.
Awon Onimo Ijinle Sayensi Gbejako Ise Agbese Ajo Oloko-Owo Mitsubishi 1min.
23secs.
Igbero ajo oloko-owo kariaye kan ti a mo si Mitsubishi lati ko ile ise ula
ti iyo kan ni orile-ede Mexico laipe yi ni o ti mu awon ogbontarigi onimo ijinle
sayensi ni agbaye to ju ogbon lo papo lati tako ise agbese na.
Ise agbese na ni a pero re fun ibikan ti a npe ni Laguna San Ignacio eyiti
Ajo UNESCO ti so di Ile Ajogunba Aye ni odun 1993. Omi osa na ni o je ibi ibisi
ti ko le ri idaamu kansoso ti o ku fun Eja Abuibutan alawo oye
ti pacific to wa labe ewu iparun.
Ajo Mitsubishi ngbero lati gbon egberun mefa galonu omi ni ida ogota iseju kokan
kuro ninu osa na ki o si da eyi sori ile to to ibuso merindinlogofa ni igun
mererin re. Awon onimo ijiule na so wipe ise agbese na je ewu si
ayika ti ko se faramo. Won ti se ipolongo bi ipolowo oja ninu awon iwe iroyin
olojojumo gegebi New York Times ti New York, Guardian ti San Francisco Bay ni
orile-ede Amerika at iwe iroyin La Reforma ni orile-ede
Mexico lati tako ise agbese na.
Gegebi asiwaju awon elegbe re, gbajumo onimo ijinke nipa idagbasoke eda eniyan
ati eranko, Dokita Roger Payne to jumo se awari wipe awon eja abuibutan abuke
ima ukorin, ni o ko akojade awon onimo ijinle na.
Apakan re so bayi: "Ajo Mitsubishi ni lati mo bi iwuwo imo ijinle sayensi se
to ni atako si igbero won lati so ile ibisi kansoso to ku fun eja abuibutan
di California ti ile ise iyo."
Agitrop
Orile-Ede Zambia Se Ayewo Ayika Re 1min. 45secs Orile-ede Zambia
ni awon eya eweko ati eranko to to egberun mejo laarin ile re. Iwadi kan to
ulo lowo lori
ipinsiyeleyele eweko ati eranko tun ri wipe orile-ede na ni orisi ibugbe awon
eda abemi merindinlogun, bi igbo ati agbegbe iyasoto eweko bi edegbeta ati opolopo
awon ibi aabo to jasi ara won lara eyiti a ti ri awon ogba
egan orile-ede, ibi aabo awon eye and awon agbegbe isakoso eran-ode. Awon agbegbe
ti a dabobo fere to idaji gbogbo ile orile-ede ila-oorun Afirika na to to aradotaleledegberin
egberun ibuso kilomita ni igun mererin
re.
Awon itosona fun iwadi na ni o wa lati odo Ajo Adehun Kariaye lori Ipinsiyeleyele
Eweko ati Eranko (Con-vention on Biodiversity (CBD). Adehun na kan nipa fun
awon orile-ede to je omo egbe lati ka awon eya won 5
5 Page 6 7
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
6
CHANGE
ki won si soro jade lori ohun to wanibe ati bi a se nlo won, boya ilo
yi nmu i rokeke ewu ba iwalaaye awon eya kan ati ohun ti a ni lati se lati se
itoju won.
Iwadi na ri ifarakorawon to po larin awon eweko ati awon eda abemi inu egan
ni orile-ede Zambia. Akojade na so bayi: "Awon eweko npese ibi aabo fun awon
eranko nigbati awon eranko nse iranwo nipa imunibisi,
itankale ati irudi." Awon ibugbe eda abemi na wulo fun atunlo awon oraile ati
omi mimo, idena ijele ogbara, imu afefe ile wa ni deede at imuyade ohun ogbin.
Iwadi ti orile-ede Zambia na ni a se ipolongo re lati owo gbajumo onimo ijinle
nipa ilolupo awon eda abemi ati agbegbe won, ojogbon Emmanual Chidumayo ninu
akojade kan ti ape ni: "Iye melo iru wo? Ajo Agbaye fun
Ipese Ayika (Global Environment Facility (GEF) lati ipase Ajo Apapo awon orile-ede
Agbaye fun Eto Idagbasoke (United Nations Development Programme (UNDP) ni o
gbe owo sile fun iwadi na. A lero wipe
abajade iwadi na ni a o lo lati se agbekale ogbon imulo ati ilana ise lori ipinsiyeleyele
eweko ati eranko fun
orile-ede Zambia. Kobus
Owo Igbaweeri Le Mu Irewesi Ba Awon Agbe Ti Ki Ilo Kemikali 1min. 52secs.
Ibere to nga si lo wa ni ile alawo funfun Europe ati Amerika fun awon ounje
ati ire oko ti ko ni egbogi ipakokoropaeku. Opolopo awon agbe ni awon orile-ede
to sese ndagbasoke ni o ti nwona fun akoko ola bi
won se nsise lati pese fun ibere na. Sugbon awon ofin ikoojawole eyiti Ajo
isokan ile alawo funfun Europe (European Union) (EU) fi lele le mu irewesi ba
ise ogbin to je ore iseda (eyiti a tun mo si ise ogbin eleroja iseda
aye) ni awon iha aye to sese ndagbasoke. Ni bayi won ti fa ifiesun "Ijegabalorieni
lori oro eda abemi." kan ile
alawo funfun Europe.
Awon ofin to se agbekale idiwon fun ifunniniweeri lati wo oja EU ni a ti se
apej uwe re bi eyiti ko kobiara si bi nkan se wa ni iha aye to sese ndagbasoke
ati awon agbe alanoje. Apere kan ni ofin wipe awon agbe ti ki ilo
kemikali gbodo paala si awon oko won pelu ibu ile toro ti a ko se ogbin si.
Ofin yi ni a ti ko gegebi ohun
owongogo ti awon agbe talaka ko lagbara re.
Idena pataki miran ni ibere wipe awon agbe to fe iwe eri gbodo sanwo awon
olugbaninimoran to je wipe ile Europe ni won wa, lati jerisi oko won bi eyiti
o je ti eleroja iseda aye.
Gegebi oro Nick Robins ti Ajo kariaye fun Iwadi lori Ayika ati Idagbasoke
(International Institute for Environ-ment and Development (IIED) eyiti o wa
ni ihu London, ti o si tun je ajumoko akojade ti a pe mi Iyipada ninu
Igbejade atiIlo: Sisi lekun awon Anfani oko-owo: "Gbigba iwe eri fun wiwo
awon oja ile Europe le mu inani lowo ati wahala wa fun awon agbe kekeke iha
gusu."
Biotilejepe anfani owo ninu ire oko to ba iseda aye mu si ngberusi ni o ti
to bi bilionu (milionu lona milionu) owo dola Amerika misisiyi. O dabi enipe
awon orile-ede ile Afirika ko mo nipa oja yi. Sugbon awon oro aje ti iha
gusu ile Amerika ti nse atunse awon ilana ise ogbin won lati koju re. Orile-ede
Chile nikan se ifiranse egberun meji tonnu awon ire-oko ti iseda aye ni odun
1998, o si pa owo bi egberun meta owo dola Amerika.
PANOS. 6
6 Page 7 8
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
7
CHANGE
A Nilo Awon Ohun Ipana To Je Ore Ayika 1min. 13secs. Iwadi ti
fihan wipe ifofo ti a fi npa ina to ba sele lati inu ijabo oko ofurufu le mu
egbin wonu awon omi abe ile.
Ina lati inu awon ijabo oko ofurufu ni o ma nje ti ijona epo eyiti omi ko le
kapa re. Nitorina awon ifofo olomi
to ma ndi tanna iboju ti a mo si AFFF ni won pile se agbejade re lati sise ni
kiakia lati pa ina nipa nina iboju omi felefele sori epo to njona.
Awon AFFF ni a mo wipe o ni awon efun oloro olorisi pupo ati efin oloro-dapo-mo-omi
ninu. Awon eroja kemikali yi mi o mu ki a ma fura si awon ifunjade oloorun,
eedu ati epo robi nipa oro idoti ayika.
Dokita Jennifer Field ti ile-eko giga Yunifasiti ti ipinle Oregon ni orile-ede
Amerika pinnu lati se aridaju ohun to nselesi awon AFFF ti a ntu sinu ayika.
O se ayewo omi abe ile ni ibudo awon ologun ati ni ibudo igbeko awon
panapana ti a ko lo mo, o si wa se awari to daniniji wipe awon AFFF ki ituka
sinu ayika. Ninu awon ibikan o tile ri wipe awon omi abe-ile se ifofo. Iwadi
si nlo lowo lati mo ewu pato ti egbin AFFF le ni fun ilera eda
eniyan. Environmental News Network.
Awon Apileko Ono Ona Titun Lati Fi Polongo Awon Abajade Iwadi
2mins. 1sec.
Iroyin kan ti o ndaba awon ona titun lati fi di alafo to wa laarin awon
oluwadi, awon alase ati awon osise idagbasoke ni a ti gbejade. Iroyin na eyiti
Darren Saywell ati A. P. Cotton ko, ni o lero lati ri wipe abajade to
wulo ninu iwadi lori idagbaseke de odo awon talaka ati awon ajo to so wipe awon
nse oju fun won.
Iroyin na ni o da lori iwadi kan ti Yunifasiti ti ilu Loughborough se eyiti
o se ayewo awon ona ti a ngba ni lowolowo lati fi jijo se amulo awon abajade
iwadi. O se itopase awon ogbon imulo to wa tele fun ipolongo
awon abajade, awon idilowoko won ati awon ohun to nse igbonwo fun ipolongo to
munadoko.
Awon oluwadi na ri wipe opo ninu iwadi idagbasoke ni ko de odo awon talaka ati
awon ajo ti ko ni owo ijoba
ninu nitori nigbati iwadi na ba ti pari patapata ni a sese jijo nse amulo ifitonileti.
Gegebi iroyin na ti so: "alagbase iwadi, ni akoko yi, yio fokansi lati te
ajo agbowo kale lorun nipa gbigbe iroyin ti yio ba owo ti a gbe kale mu jade
dipo ki o fojusi inilo awon ti yio lo o."
Ojutu ni lati se ajopun ifitonileti lati ibere de opin ise agbese iwadi na.
"Ajopin ifitonileti gbodo sele ki iwadi to bere, nigbati iwadi ba nlo lowo ati
paapa nigbati a bati pari iwadi na." Gegebi iroyin na ti so: "Ona yi yio fi
aaye
sile fun ifesipada ati ikeko nigbati iwadi na ba nlo lowo."
Awon imoran fun ipolongo to munadoko ni sise agbekale to ja gaara lori awon
ti iwadi na wulo fun ki won si se
aridaju wipe agbejade awon iwadi wa ni arowoto, o faniwora o si rorun lati lo.
Bakanna a gbodo lo orisirisi ona ipolongo lati se akojopo ati igbejade ifitonileti
gegebi akopo kukuru kukuru. Awon oluko iroyin na gbagbo
wipe ajopin awon abajade iwadi ati awon ifenuko je ilana to ntesiwaju, o si
sekoko fun gbogbo ilana igbekale ati igbese ise idagbasoke.
id21 Report. 7
7 Page 8 9
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
8
CHANGE
Awon Opo Ja Fun Eto Ipeja Ni Orile-Ede South Africa 2mins. 58secs.
Awon opo awon apeja bi merinla ni ilu Cape Town ni orile-ede South Africa
ni o njijadu fun eto ipeja to dogba
pelu ti awon okunrin. Eto ipeja won dawo duro nigbati awon oko won ti ku,
a si wa fi won sile lati se itoju awon ebi won lori owona ti ko to nkankan ni
ilu ipeja kekere kan ti a mo si Kalk Bay.
Awon opo na, lara eyiti Sybil Edwards to je mo odun metaleladorin ati awon
ore re metala ti ojo ori won lo lati odun merindinlogota si mejidinladorun wa
nfe nkankan pada lati ilu abinibi won. Nwon njijadu fun eto ipeja
tiwon eyiti a mo tele si "ibufuni ipin." Nwon gbero lati gba awon apeja ni Kalk
Bay lati bawon peja ti won ba se aseyori.
Awon opo na ti nfi iwe ibere fun ipun tiwon na lele lododun lati odun 1994,
sugbon ni igbagbogbo ni won ti njawon kule.
Gegebi Mrs. Edwards, eniti oko re je apeja fun odun to ju ogoji lo se so: "A
ko mo idi ti won ko fi gba fun wa.
Ireti nikan lo gbe wa ro."
Ibere ni won ma nse nipase Ajo Atunse Ipeja, eyiti agbe kale lati mu awon
oju titun wo inu ise ti a jegabale tele. Ajo Alakoso omu ati Ebute ni o nse
ayewo awon iwe ibere na ti Alase Ijoba (Minisita) fun oro Ayika ati Irin-ajo
Afe si nfi ase si.
Melody Kingma to je agbemuso fun awon opo na so wipe won gbero lati fi owo ti
o ba wole lati inu awon eto ipeja na se agbekale eto iwosan ati itoju fun awon
opo ati alaaboara larin awon apeja Kalk Bay.
Okan ninu awon opo na, Mrs. Gairssa Fortune so wipe egbe na ko ti i gba ekunrere
alaye lori idi ti won fi ko
ibere won. O ni: "Mo ro wipe won ko kan fe pin owo pelu wa ni."
Opo ninu awon opo na lo ngbe lori owo ifehinti bi ogorun dola owo Amerika
lososu Die ninu won lo leri owo fi pamo. Monica Collison, omo odun mejidunladorin,
to nikan to omo meje leyin ti oko re ku ni ogun odun
seyin, so wipe awon nkan bi ile itaja orisirisi ohun elo ko si ni Kalk Bay,
eyi si nso di dandan fun awon obirin na
lati rin irin-ajo lo si ibomiran fun awon ohun ti won nilo. Eru nba won wipe
awon le saisan ki won ma le ri itoju gba ni agbegbe won.
Wilhelm Kroon, igbakeji oludari iseto oro ti Ajo alakoso Omi ati Ebute ko
le soro lori idi re ti won fi ko ibere awon opo na.
O ni: "Won gbodo kunojuwon ilana ki won si ma reti fun eyiti o dara. Akara na
ko ju bi o se wa lo besi ni opolopo eniyan lo nfe wo ninu ise na."
African News Online
Awon Ogun Laisi Awon Ohun Ose Agbenule-Bugbanu Ti Npaniyan 2mins. 1sec.
O ju adotalerugba milionu ohun ose agbanule-bugbamu apaniyan ti a mo ede
geesi si (Anti-Personnel Landmines (APL's) ti a se akojopo re. Beni, leyin opo
odun ipolongo fun imukuro won, milionu mejila pere ni a tii baje.
Sugbon awon apolongo fun imukuro ohun ose yi gbagbo wipe ko si igba ti aye tiiwa
ni ailewu lati owo ibugbanu 8
8 Page 9 10
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
9
CHANGE
apanirun awon ohun ose wonyi ni akoko ti ko si ogun ju akoko yi lo.
O to idamewa awon olugbe aye to ni abo ara lona kan tabi omiran. Opo ninu won
lo je alafaragba lati owo ohun ose agbenule-bugbamu apaniyan yi.
Fun apeere, o fere je wipe gbogbo orile-ede ni o ti fowosi Adehun odun 1997
lori Igbesele ilo, akojo, sise ati
ikokiri ohun-ose agbenule-bugbamu apaniyan. Bi orile-ede mejidinlogoji to nse
awon ohun ose na tele ni o ti gbesele isejade. Opo ninu awon merindinlogun to
ku ti ko tii jeje lati ma see mo ni ko tiise ohun ose na fun opo
odun. Besi ni ninu awon olufiranse ohun ose na si ile okeere pataki metalelegbon,
orile-ede Iraq nikan ni ko tiigba lati dawo ifiranse duro.
Ju gbogbo re lo, awon orile-ede to mba ara won ja ki ilo ohun ose inu ile
yi mo lakoko ogun.
Iroyin pataki eyiti o se agbeyewo itiraka kariaye lati mu APL kuro patapata
laipe yi ni o fihan wipe egbegberun lona egbegberun ohun ose ile na ti a kojo
ni a ti baje, sise re nlo sile beni owo kariaye minu re ti dopin. Iroyin
na ti a pe ni. Iroyin Itopase Ohun Agbenule-bugbamu fun odun 1999 – Si Aye
ti ko si Ohun-Ose inu ile
mo, ni a gbejade lati owo Akojopo awon Atopase ohun ose Agbenule-bugbamu
(Landmine Monitor Core Group) to je apapo awon egbegbe aladani to nsise gegebi
Ipolongo Kariaye lati gbesele ohun-ose Agbenule-bugbamu
(International Campaign to Ban Landmines).
O ju awon ogorin oluwadi ni ogorun orile-ede ati ifowosowopo awon ajo to ko
ni owo ijoba ninu bi edegbeje
to lowo si agbejade iwe eledegbefa oju-ewe na.
A se ifilole iwe na laipe yi ninu ipade awon egbe to faramo Adehun lori ohun
Ose Agbenule-bugbamu to waye ni ilu Maputo ni orile-ede Mozambique, awon onko
re si seleri lati ma se imubaakoko-dogba re ki won si ma
gbekale lododun gegebi ohun elo ipolongo. Newslink Africa.
Ojo Omiro Ajenilara Tabi Imorusi Aye? 2mins. 9secs. Ere ije lati se
idinku iye oludoti lati imu awon ile ise ninu afefe ayika le ni ikose laipe
yi, ti idani-niji ti ojogbon ile-eko
Yunifasiti kan gbe dide ba je otito. Michael Schlesinger, ojogbon lori imo ijinle
nipa afefe ayika ni Yunifasiti ti ilu Illinois ni orile-ede U. S. A kilo wipe
itiraka lati din ojo omiro ajenilara ku le yorisi imorusi aye.
Efin oloro imi-ojo ati efin oloro CO 2 awon kemikali meji ti a ntu sinu afefe
ayika lati inu awon ile ise ati oko irinna, ni o nfa ojo omiro ajenilara ati
imorusi aye. Ninu afefe, efin oloro iimi-ojo na ma ndapo mo ategun alafia
ati omi lati di awon ohun to nrosile pada si ile aye pelu ojo bi ojo omiro ajenilara.
Lati da ojo omiro ajenilara duro, awon ile-ise ti ndin ipa to je efin oloro
imi-ojo ku ninu awon itujade ile-ise won, o wa ku efun oloro CO 2 .
Eyi si wa ni ikolu ti a ko pinnu re lori afefe ayika eyiti a mo si imorusi aye.
Bi o se jepe efin oloro CO 2 ma nko itansan-oorun jo ti o si ma mu ki igbanatutu
lo soke ti eyi si ma nfa i morusi
aye, efin oloro imi-ojo ni idapo pelu omi ati ategun alafia ninu afefe ayika
a ma da itansan-orun pada si oke, eyi a si ma fa itura wa.
Ni awon idunadura kariaye, awon ijoba to je omo egbe Ajo onijobasijoba lori
Iyipada Afefe Ile (Intergovern-mental Panel on Climate Change (IPCC) faramo
iyasoto kemikali mejeji kuro lara ara won lati da ojo omiro
ajenilara duro. Schlesinger ni: "O je ohun to gbeburuyo wipe ninu sise ise lati
wa ojutu si isoro ayika kan, wa mu isoro miran buru si." 9
9 Page 10 11
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
10
CHANGE
O te siwaju wipe: Nitori na o dabi enipe idinku isoro ojo omiro ajenilara
nipa idinku ninu itujade efin oloro imi-ojo nmu imorusi aye buru si nipa sise
atileyin imorusi ninu ati nitosi awon ekun nibiti a ti din awon itujade efin
oloro imi-ojo ku." Environmental News Network.
Awon Ijapa Okun Se Agbero Agbegbe Ibisi Won 2mins. 9secs. Eri ti wa
wipe iwalaaye awon eranko egan and ti ibugbe won da lori ekini si ekeji. Fun
apere, ijapa okun to
walabe ewu iparun nilo eti-kun to gbelege lati le wa laaye. Iwadi titun fihan
wipe o seese ki awon etikun na nilo awon ijapa okun jube lo fun iwalaaye ilana
ilolupo eda abeni ibe.
Awon ijapa okun olori-nla ti orile-ede Amerika ma nri irin-ajo to fere to
egbawa ibuso kilomita lati ye eyin won lori iyanrin etikun kanna ti a ti pa
awon na. Awon afenifere ayika si ti ja gidigidi lati toju awon etikun na fun
won
. Sugbon iwadi lati owo omo ileeko giga Yunifasiti ti Florida (University of
Florida (UF) kan lori etikun ti Melbourne ni Florida fihan wipe awon eyin ti
awon ijapa okun na ye ni awon eroja kosemani ti o le mu eweko
ni etikun na lagbara si, ti yio se itoju ilana ebe etikun ki o si je ounje fun
awon orisi eda abemi egan miran ninu ilana ilolupo eda abemi ati agbegbe ibe.
Sarah Bouchard, omo ile-eko giga UF ri wipe eroja to wa ninu awon eyin ijapa
nse agbero fun orisirisi eda abemi etikun. Bouchard ri wipe "Awon akan, eye
ati eranko kan to dabi okere ti a mo si racoon ma nje eyin
ijapa okun, won a si ma tan won kakiri inu awon ebe erupe etikun. Awon itakun
eweko a ma hu lo si ibiti awon eyin na wa won a si ma fo won lati de odo eroja
to wa ninu won. Nigbati awon ijapa okun kekeke ba si yo
jade kuro ninu awon eyin to ku, oje inu awon eyin na yio wa lori ile lati fi
mudunmudun fun ilana ilolupo eda
abemi inu iyanrin etikun na."
O ju egberun marundinladorin ite lo ti won ma nfi lele ni itopa awon etikun
Florida. Awon ijapa okun na ma nrin irin-ajo lati ibi ijeun won ni awon orile-ede
Bahamas, Cuba, Dominican Republic, Florida Keys ati awon
agbegbe miran ni iha ila-oorun gusu ati ile Carribbean wa si etikun ibisi won.
Awon iwadi ojo iwaju yio wo kini yio sele si ilana agbero emi ni etikun na ti
awon ijapa okun na ko ba ye eyin si agbegbe na no.
Environmental News Network
Kokoro Alajerun Mu Irokeke Ewu Deba Ipese Ounje Ni Orile-Ede Ghana 1min.
39secs.
Awon kokoro alajerun ti yabo ekun ogbele meta ni iha ariwa orile-ede Ghana,
won si ti ba awon oka je lara eyiti a ti ri oka baba, agbado, jero ati iresi.
Awon eran ajeko to je awon ewe ti awon kokoro na wa lara won
papa ku.
Nibayi, kokoro buruku na ti je sare hektari ohun ogbin to ju egberun mejileladorin
lo ni lekun iha oke ila-oorun.
Sare hektari oka egberun mewa miran ni won tun ti parun ni ekun iha oke iwo-oorun.
Awon agbegbe bi mefa ni iha ariwa ni oro na si kan gbongbon.
Pelu ikominu lori wipe o seese ko ju idaji gbogbo ire oko oka ti odun yi lo
ti a o padanu latari ayabo kokoru alajerun yi, Alhaji Amidu Sulemana, Alase
Ijoba fun ekun oke ila-oorun se ikilo wipe." Irula won ni ekun ariwa
yi wa labe ewu." Alase na ti bere ni pajawiri fun awon oogun ipakokoro ati awon
ohun elo ifunnka lati owo
ijoba apapo ni ilu Accra. 10
10 Page 11 12
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
11
CHANGE
Ibaje ayika ati airo ojo lo nfa ayabo kokoro alajerun na Awon osise
ile-ise ijoba fun ise-ogbin so wipe ojo nla kan to ba ro yio dekun ayabo na.
Igbakeji Aare, Ojogbon John Mills, to se ibewo si agbegbe na, se ileri iranlowo
ijoba gegebi irugbin fun atungbin ati ajile fun awon agbe ti a ti le awon kokoro
na kuro lori ile won.
Ni bayi, Ajo orile-ede Ghana fun Isakoso Ajalu (National Disaster Management
Organisation) ati Ile-ise ijoba fun Eto Ounje ati Ise Ogbin (Ministry of Food
and Agriculture) lo siwaju ogun si awon kokoro na nigbati adura
nlo ni awon ile ijosin fun ojo. Edward Ameyibor.
Orile-Ede Ghana: Ipinnu To Le Lati
Dekun Ipagborun? 2mins. 41secs. Orile-ede Ghana to padanu iko meji ninu
meta igbo re ninu orundun yi, ti gbe igbese lati dekun ipagborun ki o
si se iwuri fun itoju. Orile-ede na ti se ifiropo ofin to fi aaye gba gedu
gige ninu awon igbo ni odun medogun medogun pelu eyi ti o fi iyipo ogoji odun
lele.
Lara awon igbese miran ni igbesele ifiranse si ile okeere awon gedu ti a ko
la lati eya gedu merinla lara eyiti a ti ri mahogani. Ayewo ilana to nlo lowo
fihan wipe eleyi ko dena awon to nge gedu lona ti ko bofin mu.
Ibori igbo orile-ede Ghana to dinku lati sare hektari milionu metalelogun ni
odun 1901 si sare hektari milionu mejo o le odunrun egberun loni. Ijoba ati
awon afenifere ayika ntiraka lati se idinku ipadanu nla yi lati se itoju
ilana ilolupo igbo orile-ede na.
Ogbeni Walter Gyabaah – Atuoni, Osise Igbo fun agbegbe Offinso ni ekun Ashanti
se alaye bayi: "A gba akoko ogoji odun lori iwontunwonsi akoko odun merinla
ti o ngba awon igi oloko-owo ti o dara ju lati dagba
to fun gige. A se agbero eleyi finnifinni biotilejepe ija ma nwa lorekore lenu
ojo meta yi pelu awon ajigeduge ti
won ma ndihamora nigbamiran, ti won si ma nsise ni oru."
Laipe yi, ile ejo kan ni ki awon ajigeduge meta san owo itanran irinwo egberun
owo cedi (bi ogojo owo dola), won si gba awon ayun won latari wipe won se fayawo
gedu metaleladofa ti won ji ge. Awon osise igbo benu
ate lu owo itanran na, won si so wipe awon onifayawo na le ri ilopo mewa owo
na lori awon gedu na. Ile ise
ijoba fun Oro Ile ati Igbo siro wipe orile-ede na npadanu owo to ju milionu
mewa dola lo latari fayawo gedu. Ofin miran lori igbo ti o ni ijiya to le gan
ni o ti wa niwaju ile asofin orile-ede Ghana.
Pelu bi ojo nro perewu ni awon ekun igbo, ipolongo ti bere lekan si fun igi
gbingbin. Opo agbegbe lo ti gbe idije kale larin awon ile-eko lori igi gbigbin
nigbati awon ajo ti ko lowo ijoba ninu na nse akitiyan lati kede
idabobo fun ayika nipa imugbooro si awon igbo orile-ede na. Awon kanlekanle
kekeke ati awon egbe osise ise ogbin ti Ajo Apapo awon Osise (Trade Union Congress
(TUC) jo nkepe fun igbesele ifi gedu ranse si ile
okeere. Sugbon ko dabi enipe ijoba yio da won lohun niwon-gba to je wipe ifiranse
gedu si ile okeere ni ona kerin ti owo ile okeere to poju fi nwole.
Eyi ni idaanu orile-ede Ghana. Bi ijoba ti nfe lati se itoju ayika ki won
si se igbelarunge ipinsi-yeleye eweko ati eranko, o nilo owo dola Amerika lati
fi sanwo awon oja to nti ile okeere wa.
Edward Ameyibor. 11
11 Page 12 13
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
12
CHANGE
Akanse Eto Oro Ti Enikan So Lori Iseda Ati Emi Eda Eniyan 33secs.
"Okan ninu awon ipenija itoju iseda ni lati se agbedide iwontunwonsi to
peye lori awon kosemani ode iwoyi-inilo fun ati ri owo pa ki eniyan titori be
ma gbe nibiti anfani oro aje wa, lati gbadun awon anfani igbe aye larin
ilu ati ti anfani ati lo isinmi ni aroko, lati ni odo to mo gaara ati awon afonifoji
to jinna si arin ilu ati lati se aridaju wipe awon ifo eye inu egan yio tesiwaju
lati mu okan eda eniyan funye."
Oro lori Itoju/ George B. Hertzog, Oludari Ajo Alabojuto Awon Ogba Orile-ede
ti Orile-ed Amerika.
Eto Fun Awon Omode Ijapa Ati Ekuro 5mins. 24secs.
Nigba aye atijo, iyan nla kan mu ni ile awon eranko. Ounje sowon pupo, beni
ebi si npa gbogbo eranko, eye ati kokoro. Nitori eyi ohun jije gbogbo lo niye
lori pupo. Ohun to si je gbogbo eda alaaye ninu ile-oba awon
eranko logun ni irula nipa isode ati wiwa ounje kiri.
Ni ojo kan, ijapa wa ounje lo o siri ekuro kan. Bi o ti mu, o bo lowo re o si
yi wo inu iho kan legbe igi ope na, Pelu ipinnu lati mu ekuro re pada, o wo
inu iho na o si lo titi ti o fi ri iwin kan, o si bere nipa ekuro re. Iwin na
so fun ijapa wipe omo oun ti je ekuro na.
Ijapa beresi sokun. O pariwo, o nmi soke sodo, o si ndaba wipe on o pa ara on
bi on ko ba ri ekuro on gba
pada. Ni idakeji o bere wipe ki won fi omo iwin na fun on ni pasi-paro fun ekuro
na. Leyin ti gbogbo ebe ti kuna lati tu ijapa ninu iwin na fun ni 'ilu ounje'
kan gegebi itunu. Nigbakugba ti a ba lu ilu na ounje yio jade lati
abe re. Sugbon iwin na kilo wipe won ko gbodo fo ilu na pelu omi. Ti won ba
fo ilu na, agbara re yio lo, ko si ni mu ounje wa mo.
Ijapa dupe lowo iwin na o si lo pelu ilu ounje na. Nigbati o de ile, o pe
awon iyawo ati omo re, o si ti won mo inu yara kan.
O lu ilu na. Ounje orisirisi si kun inu yara na, won si je ounje to te okan
won lorun. Leyin ounje na, ijapa kilo fun won wipe ki won pa enu won mo nitori
on o nife lati pin orire na pelu awon eranko ati eye to ku. O si tun
kilo fun won ki won ma fo ilu na fun idikidi kan biotiwukiori.
Nitori idi eyi, bi awon eranko ati eye to ku ti ngbe si, ijapa ati ebi re nsanra
si. Nigbati awon eranko toku bi leere, o ni iya on to ti ku lo nbo on ati ebi
on, o si wa so fun awon to fe ma jeun be ki won pa awon iya won.
Nitoripe awon eranko to ku ko fokantan ijapa, won ko pa awon iya won, sugbon
won fi ijapa sile won ko si
bi leere lati mo orisun ounje aladun re mo.
Sugbon sa, leyin igbadie, ijapa lo si irin-ajo jijin, nigbati o si ti lo,
awon iyawo re woye wipe ilu ounje na ti doti pupo. Nitorina won foo lati jeki
o tun mo lekan si. Lehun fifo na won sa sinu oorun, won si nki ara won wipe
awon ti se ise to dara. Sugbon nigbati ebi pa won, won lu ilu na sugbon ohunkohun
ko jade lati inu re. Nwon
ranse si ijapa, o pada ni kiakia o si wa gbera lati lo gba ilu niran.
O lo si idi ope kanna, o si se orire wipe o tun ri ekuro miran ti o moomo
ju sinu iho to wa nidi igi ope na. Ekuro na yi si egbe kan ninu iho na o si
ha sibe. Lesekese ijapa telee. Nigbati o si ri iwin na o fi esun kan omo re
wipe
o ti je ekuro on. Iwin na so pe eyi ko ri be, o si mu ekuro na nibiti o wa.
Ijapa so wipe ekuro on ko niyen o
si fi ake kori wipe on o pa ara on tabi ki won fun on ni ilu miran. Sugbon sa,
o se asise kan ko so fun iwin na 12
12 Page 13 14
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
13
CHANGE
ko lu ilu na ki o to ju si ejika re ti o si sare lo sile pelu ayo.
Bi o ti de ile, o pe gbogbo ebi re sinu yara re, o ti ilekun o si beresi lu
ilu na. Gbogbo won duro fun ounje sugbon ohun iyalenu lo je fun won nigbati
o je pe awon kokoro to lewu bi oyin ati agbon lo jade lati inu ilu na
ti o si ta won laisi anu. Nitori pe awon lekun wa ni titi, ko si ona ati salo
fun ijapa ati ebi re. Nitori na awon kokoro na ta won titi ti won fi daku, won
si di ero ile iwosan.
Eko ti itan yi ko wa ni wipe a gbodo tiraka lati je olotito ninu gbogbo ise
wa ki a ma si lowo ninu gbigba tabi mimu ohun ti ki ise tiwa.
Character Moulding for Better Citizenship.
Egun To Sonu 3mins. 21secs. Nigbakanri ni aye atijo, Erin ati Agbanrere
ni ariyanjiyan kekere kan to yorisi ija nla. Awon mejeji je oninu fufu
eranko. Agbanrere ja pelu igboya o si se Erin lese nigba pupo pelu iwo mimu
ori re, sugbon inu fufu ati ibinu re mu ki o ja bi afoju.
Sugbon Erin teri inufufu re ba, ati nitori pe o tobi, o si lagbara ju agbanrere
lo, o si le lo owo ija re to lagbara, owo re bere si le ju ti Agbanrere lo.
Nigbeyin, Agbanrere juwo sile. Pelu ipalara ati ogbe pupopupo kakiri
awo ara re to nipon, o se yenkuyenku lo.
Agbanrere wa ninu irora pupo, ara re si nseje gan an. O wa Oore lo eniti o lero
wipe o le ran on lowo. O be wipe ko fun on ni okan ninu egun ara re to ba gun
to si mu julo ki on le lo bi abere lati ran awon ogbe to jinkoto
ninu awo ora on.
Oore, eniti inu re ko dun nipa jiji ti o ji kuro ninu oorun re olosansan, tete
fe pada lo sori ibusun. Nitorina, lati le jeki Agbanrere tete ma lo, o gbalati
ya ni egun re to dara julo lori adehun wipe Agbanrere yio da egun na
pada ti o ba ti lo tan. Anu si tun se e fun Agbanrere.
O han soro wipe: "Awon egun mi ni ohun ti mo ni lati fi dabobo ara mi kuro lowo
ota mi, Kiniun. Nitorina mo gbokan le o lati da egun yen pada." Agbanrere fi
ara mo eyi o si seleri wipe on yio da egun na pada ni ojo keji.
Agbanrere lo awon fonran lati ara igi afon lati fi ran awo ara re (Titi di
oni ni eniyan le ri awon oju ogbe na to ga soke to si ri wurururu lori awo ara
re). Inu re dun si ise to se. O si dubule lori awon koriko to ro lati sun orun
iwosan ti ara re nilo. O rora fi egun oore segbe re ki O ma ba sonu.
Ni irole ojo kan, leyin ojo bi melo kan leyin eyi, Agbanrere pade Oorre. Lojiji
o ranti ileri re, sugbon bi o ti gbiyanju to ko kan le ranti ibiti on fi egun
na si tabi ohun ti o sele si i. Gbogbo nkan to ranti ni wipe on ran ara
on pelu egun na ti on fi enu dimu. "Oluwa o!" ni ironu to wa sokan re. "Abi
mo ti gbemi laimo?".
Leyin opolopo ironu, Agbanrere pinnu wipe bi on ba tile ti gbe egun na mi, nigbana,
o ya tabi o pe ni, ohun to nsele si ohun gbogbo nkan ti on ba gbemi lojojumo
ni yio sele si i. O se alaye eyi fun Oore, o tuba, o si seleri
lati da egun na pada laipe. Idi niyi ti Agbanrere fi ma nfese gba iyagbe re
kiri. Lati igba na ni o ti nwa egun Oore to sonu laarin awon iyagbe re.
When Hippo was Hairy. 13
13 Page 14 15
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
14
CHANGE
Nje Ibunije Ojola Le Dabobo Enito Buje Kuro Lowo Ibunije Awon Ejo
Miran? 1min. 7secs.
Beko ki ise otito. Ko si eri imo ijinle sayensi to fihan wipe ibunije ojola
le fun o ni ajesara fun ibunije gbogbo
ejo, gegebi awon asa ibile iha ila-oorun Afirika kan se so. Biotilejepe awon
ojola ma nbu eniyan je, won je ara awon ejo ti a npe ni 'akamonifunnipa' ti
ko loro. Lati pa ohun ode won, won yio we ara won yi ohun ode won
ka, won o si fun un pa.
Ibunije lati odo gbogbo eranko le fa kokoro ati arun. Ojola yio bunije ti a
ba ja won laya. Awon eniyan ti ojola
buje le ku ti kokoro ba wo oju ogbe na, sugbon ki ise nitori oro. Awon eniyan
ti ku lati inu ibuje ojola nitori 'eru ba won doju iku?. Nitori na a o wi fun
o wipe ki o jowo ejo gbogbo sile jeje. Bikobasepe o ni imo pupo nipa
ejo ati bawo ni a se le da won mo, o le kabamo. Chongololo
Nje Awon Alangba Ma Nge Iru Won Lati Jajabo Lowo Awon To Fepa Won? 50secs.
Eyi je otito. Opolopo alangba lo kere, won si ni awon ota to po. Nwon a
ma lo iyara, iboju, ati iju-iru-sile lati jajabo kuro lowo apanije bi awon ologbo,
ejo ati eye. Awon onimo ijinle sayensi se iwadi awon alangba, won
si ri wipe iru won ni awon apakan to ro ti isan iru to le le se. Apakan iru
ti o ba ge a si ma ju sihin sohun nitori awon akanse isan wa ninu re. Bi apanije
ba ti nwo iru to nju kiri, alangba na le salo. O ju egbedogun eya
alangba lo to wa laye. Afayafa niwon, won si je ebi awon Ooni ati Ejo. Opolopo
won lo ngbe ni agbegbe afefe ile to mooru, won a si ma je awon kokoro ati alantakun.
Chongololo.
Oro Awon Obirin Ise Fun Eto Ijogun Fun Awon Obirin 1min.
13secs.
Akojopo ti ko le daindain kan ti awon ajo ajafuneto awon obirin lati awon
orile-ede iwo-oorun. Afirika mejo se ayeye Ojo Ise fun Eto Ijogun fun awon obirin
akoko. Ojo na, ojo kokandin-logbon osu keje odun yi, ni
won se ayeye re ni orile-ede Burkina Faso, Cameroon, Gambia, Ghana, Liberia,
Nigeria, Senegal ati Togo, pelu atileyin lati odo Egbe fun Ofin Eto Eda Eniyan
ni Kariaye (International Human Rights Law Group) ti o wa
ni ilu Washington D. C.
Ojo ise fun awon eto ijogun fun awon obirin je ara ipolongo olojo-gbooro lati
mu ifojusi si awon asa ibile ti awon ekun ati orile-ede to du awon obirin ni
eto won lati jogun ile ati ohun ini miran. Eto na bere ninu ipade kan
ti Egbe fun Ofin Eto Eda Eniyan ni kariaye pe ni orile-ede Ghana ni osu kokanla
odun 1998. Ninu ipade na,
awon obirin na fenuko lati se eto awon ise kan, lara eyiti ojo ise fun awon
Eto Ijogun awon obirin, eyiti o ni ero lati bori awon isoro wonyi, wa. Ninu
iwe kan to nkepe fun ipolongo na, Marie-Elena John Smith, Alakoso ile
Afirika fun Egbe fun Ofin Eto Eda Eniyan ni kariaye, bebe fun itiraka si,
lati ru imoye soke lori 'isoro to dikoko' na ni kariaye.
"Awon asa yi ntesiwaju biotilejepe awon ofin wa ni opolopo orile-ede to pese
idabobo die fun eto awon obirin lati jogun, eyi si nyori si isoditalaka egbegberun
awon egbegberun awon obirin ati omode."
Nibayi, egbe na npin awon iwe kan ti won ko si Ajo Apapo orile-ede Agbaye (United
Nations( UN) ati Ajo Isokan Ile Afirika (Oranisation of African Unity (OAU)
eyiti o fi Imoran lele awon ona ti won le fi dekun iwa-ipa
si awon obirin to da lori eya won. International Human Rights Law Group.
14
14 Page 15 16
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
15
CHANGE
Orile-Ede Ghana Se Agbedide Ilana-Eto Fun
Ifiagbara Fun Awon Obirin 1min.. 5secs. Ajo Alakoso nipa ti iye eniyan ilu
ti orile-ede Ghana (National Population Council) ngbero lati dari ifojusi sori
awon obirin ati odomobirin ninu orundun titun ti nbo na. Nigbati o nsoro ni
i lu Accra laipe yi, Akowe Alase ti Ajo na, Richard Turkson, so wipe ifiagbara-fun
awon obirin, eko odomobirin ati iboyunje to lewu ni yio je
koko eto ajo na.
Turkson so wipe Ajo na yio sise pekipeki pelu awon ile-ise, awon eka ile ise
ati awon ajo ti ijoba ati awon ajo ti ko lowo ijoba ninu lati tera mo idanileko
fun awon ara ilu lori oro to jemo idamo nipa eya ara. O fikun wipe
ifowosowopo be ti mu awon igbedide eto inulo fun idari iye eniyan ilu wa seyin.
Lara awon aseyori ajo na lateyinwa ni ati ri awon eto imulo wonyi: ogbon imulo
ti onigba ti ko gun pupo lori ilera, eto imulo ti orile-ede lori ilera ti ibisi,
aseseko eto imulo ti orile-ede lori ilera ibisi awon odo; ogbon imulo
ti orile-ede lori ifitonileti ati ofin awon omode ti ile asofin fowosi laipe
yi. Awon aktiyan ajo na tun ti mu idinku wa ninu isabiyamo lati eyito ju omo
mefa lo fun obirin kan si eyito din si omo marun.
Africanews.
Iwa-Ipa Si Awon Omode Wopo Ni Orile-Ede Uganda 1min. 41secs. Awon
omode orile-ede Uganda ni awon obi ati awon alejo ma nna, fi agbara balo ti
won si nfiyaje ni alasegbe,
o si dabi enipe ko si ohun kan ti a nse nipa re. Eyi ni gegebi agbejade iwe
iroyin olojojumo kan ti orile-ede
Uganda ti a npe ni Monitor ni ojo ketala osu keje odunyi. Iwe iroyin
na ro o wipe a ma nlu awon omode titi won o fi daku ni ile ati ni ile-eko. Awon
niran ninu awon obi to buru npa tabi so awon omode di alaabo-ara fun
awon ese bi jiji awon ohun kekeke tabi ikuna lati ri ago orun-owo fun baba
to nkanju lo si ibi ise.
Iwe iroyin na so bayi: "Iru ijiya to wopo ni siso owo omode pelu okun, ki won
fi eepo igi ogede tabi takada bo
won, ki won si wa sana si i."
Monitor bu enu ate lu isele ifiipa ba awon odo lo po ati ti awon omobirun
ti ojo ori won ko ju odun meta lo to wopo. Laipe yi, ijoba orile-ede Uganda
fikun ojo ori ti omobirin le gba fun okunrin lati odun merinla si
mejidinlogun lati dabobo awon omobirin. Awon omo orile-ede ti oro na ta lara
nkepe fun ikobiarasi to lagbara
si lati odo ijoba lati dekun iwa-ipa si awon omoobirin.
Ninu oro re, Monitor sope: "Isoro kan pelu iwa-ipa si omode ni wipe
a ko ti koju re bi oro to kan orile-ede gbongbon. Yato si awon ajo ti ko lowo
ijoba ninu, ijoba ko iti na owo kokan lati se iwadi lori oro na, tabi apero
ti orile-ede lati no ohun ti o nlo ati lati se iwuri fun ojutu ti orile-ede
si isoro na." Africanews.
Awon Otito To Wulo Ni Arowoto Odunkun Iyanu 45 secs.
Ni ikan bi osu meji seyin a royin nipa eya odumkun kan to nni ire pupo ti
o si ti se ayipada si aye awon eniyan abule bi melo kan ni iha gusu iwo-oorun
Cameroon, ati pe iyanu na ni won ti nmu wa si oko-osin maalu ti
Obudu ni iha gusu ila-oorun orile-ede Naijiria. Nisisiyi, a le so fun o wipe
odunkun to ni awon idara to farajo
eyi ni won ti se agbedide re ni orile-ede Amerika. 15
15 Page 16 17
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
16
CHANGE
Awon eya odunkun ti orile-ede Amerika ti a pe ni eyito-dara-niilo tabi
eyito-wulo-ni-ona-meji ni a so wipe o le se afikun owo to nwole fun agbe to
bi igba owo dola Amerika lori saari ile kan. A si le lo fun ounje ati fun sise
eya oti ethanol ti a nlo ninu sise awon egbegi. Environmental News Network.
Oko Inu Ofurufu Fe Kolu Aye 52secs. Sa ro wo! Nigbati o nsun ni ale
yi, nkan nla kan lati inu ofurufu ti o tobi to apata nla kan iru eyiti a ma
nri ni ipinle
Plateau, le ya kuro loju ona re ki o si kolu aye.
O le ro wipe ko dabi enipe eleyi le sele, sugbon awon eniyan wa to gbagbo wipe
o seese, won si pade ni osu keje odun yi ni ile-eko giga Yunifasiti ti Cornell
ni agbegbe Ithaca ni New York ni orile-ede Amerika ninu apero
kariaye kan lori awon irawo inu orun ti a mo si Asteroids, Comets ati Meteors.
Awon aworawo ro wipe bi idamewa pere ninu awon nkan to nyi kiri leba aye ni
a ti i damo ati pe o seese ki okan ninu won wa kolu aye ni ojo kan.
National Geographic News
Awon Igbo Orile-Ede Ghana 26secs. Awon Egan Iyasoto okoodinlodunrun
ni o wa ni orile-ede Ghana ti won si ni awon eya igi gedu bi igba-o-din-mewa,
sugbon adota pere ni won ti nlo lona ti oloko-owo. Ofin gbani laaye lati se
ikore gedu to to milionu kan o le irinwo egberun iwon mita onigun mefa (cubic
metre) – lododun. Awon omo orile-ede Ghana kokan si nlo
bi iwon mita onigun-mefa meji lodun nigbati awon omo orile-ede Naijiria kokan
nlo eyo mita onigun-mefa kan ati abo lododun.
George Ameyibor/ Obasi Ogbonnaya.
Egbin Melo Ni Oko Ayokele Re Ngbe Jade? 31secs. Nje o mo iye efin
oloro CO2 ti oko ayokele re ngbejade? Jeki a fun o ni oye. Ti o ba nwa oko ayokele
ti ile
alawo funfun Europe ti o nje iwon lita epo kan fun iwon ibuso kilomita metala,
nigbati o ba ti rin egberun merindinlogun ibuso, iwuwo efin oloro CO2 ti oko
ayokele re ti gbejade yio to ti oko re ni ilopo meta! Ro eyi
wo. WWF.
Opo Lo Nsa Fun Ajalu Ayika Ju Ti Ogun Lo Nisisi Yi 43secs. Awon asasala
ti ayika to nsa fun ogbele, omiyale, ipagborun ati ibaje ile to milionu medogbon
lodun to koja, eyi
si je bi iko mejileladota ninu ogorun gbogbo awon asasala laye – o ju awon ti
ogun si nipo pada lo fun igba akoko.
Gegebi akojade lori awon ajalu agbaye fun odun 1999 ti Ajo Alasepo kariaye
ti Alagbelebu Pupa (Interna-tional Federation of the Red Cross) se so: "Gbogbo
eniyan lo mo nipa awon isoro ayika ti imorusi aye ati
ipagborun ni ona kan, ati ti isoro awujo ti ilosoke osi ati iposi awon ilu talaka
ni ona keji. Sugbon nigbati awon nkan meji yi ba fori so ara won, ajalu titun
to ga ti sele niyen.
WWF. 16
16 Page 17
Radio
Vol II No 9 August 1999 [Yoruba]
17
CHANGE
Awori Ageso Oruko
AFFF -Ifofo to ndi iboju olomi felefele
APL -Ohun-ose agbenule-bugbamu apaniyan.
BBF -Ajo Amuluedun Arakunrin awon Arakunrin
CBD -Adehun Kariaye lori Ipinsiyeleyele Eweko ati Eranko
EU -Ajo Isokan Ile Alawo funfun Europe
GEF -Ajo Agbaye fun Ipese Ayika
IPCC -Ajo Onijobasijoba lori Iyipada Afefe Ile.
NASA -Ajo orile-ede Amerika fun Isakoso Imo Ijinle nipa Irin-Ajo Inu
ati Oju ofurufu.
NGO -Ajo ti ko lowo ijoba ninu
OAU -Ajo fun Isokan Ile Afirika
UN -Ajo Apapo Awon orile-ede Agbaye
UNDP -Ajo Apapo awon orile-ede Agbaye fun Eto Idagbasoke. 17
© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw