Go Back
Communicating for Change

Document Body Page Navigation Panel

Pages 1--15


Page 1 2
Vol II No. 11
Deceember, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

1
Idagbasoke IBARAENISORO
Omo Orile-Ede Ethiopia Se Ifilole Ero Asoromagbesi Redio Olohun Ketekete Ni Ile Afirika Ati Aringbungbun Ila-Oorun 3mins. 9secs. 8
Igbohunsafefe redio to ndun ketekete bi awon awo rekodu CD ti wa ni ile
Afirika nisisiyi.

Ona Si Orisun Iroyin : Itankale Internet Ori Komputa Se Atunse Awon Ofin 1min. 34secs 7

Ile ise asoromagbesi akoko ti ara ilu ti bere ise
ORO AJE
O Seese Ki Awon Oko Inu Ofurufu Pa Owo Toto Adota Bilionu
(Milionu Lona Egberun) Owo Dola Amerika Wole Ni Odun 2000 1 min 38secs 6
Iwakiri inu ofurufu ti beresi mu awon ere owo ti a ti nreti wa

EKO
Ajo UNESCO Pari Itan Ile Afirika 3min 37secs. 10 Ise odun marundinlogoji lati se awari ati akosile ipa ti ile Afrika ko ni

aye ti pari
Iwadi Titun Se Afihan Ohun Na Gangan To N Fa 'Awon Isoro Lati Kawe' 2 mins. 22 Secs. 4

O seese ki awon omode to ni isoro lati kawe ni ireti itetemo ati itoju
ILERA
Fifi Obe Ba Abe Obinrin Je Si Wopo Ni Orile-Ede Naijiria 3 mins 48secs. 3 Iwadi titun se ifesemule otito wipe abe dida fun awon obinrin si nlo lowolowo

ni ibi pupo ni orile-ede Naijiria
Ajo Orile-Ede Naijiria Kan Gba Eye Ti Kariaye Lori Idanileko Lori Ibalopo Laarin Okunrin Ati Obinrin 1 min 34 secs. 5

Ise opolopo odun lorin ipolongo eko lori ibalopo laarin okunrin ati
obinrin mu ere wa.

Arun Kogboogun Eedi Si Je Isoro Bi Ojo Eedi Ni Agbaye Se Nsunmotosi 2 mins 36 secs. 4

Biotilejepe isoro gbogbo agbaye ni arun kogboogun Eedi, sibe, o fere je wipe
meta ninu merin awon alarun na lo wa ni ile Afirika.

ISETO ILU
Imudarasi Ilu Khartoum So Egbegberun Di Alainilelori 2 mins 47 secs. 9 Awon eniyan bu enu ate lu awon alase ilu Khartoum latari siso opolopo

ebi di alainilelori.
AWON OBIRIN
Ajo Ibanisoro Fun Iyipada se Agbejade Aworan Fiimu Lori Awon Opo 2 min 15 sec. 6

Afihan isoro awon opo ni orile-ede Naijiria 1
1 Page 2 3
Vol II No. 12
December, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

2
Ayika ITOJU
Awon Igi Elegberun Odun Ninu Iwe Kan 1min. 33 secs. 5 A gbe awon igi ti ojo won pe ju Laye jade ni orisirisi awo

EKO
Agbegbe Niger Delta: Imo Nipa Ayika Lo Soke 2 mins. 50 secs. 7 Ajo Amuludun Ile Aye to wa Laaye Nsise lati se alekun imo awon eniyan

agbegbe Lori ayika agbegbe Niger Delta.
EGBIN
Ona Titun Fun Isakoso Egbin Arin-Ilu Bere Ni Orile-Ede
Argentina 2 mins. 7 secs. 3
Ilu kekere kan ni orile-ede Argentina Se agbekale eto daradara kan

fun isakoso egbin arin ilu
EDA ABEMI EGAN
Awari Titun Se Igbelaruge Imo Lori Itoju Ni Orile-Ede Ghana 2 mins. 14 secs. 9 Eya Etu kan ti a ti ro pe o Ti parun patapata ni a seesi ri.

Adajo Orile-Ede Amerika Kan Da Gedu Gige Duro Lati Dabobo Eja 51 secs. 14
Idajo ile ejo kan ti ijoba apapo ni Orile-ede Amerika buyi kun ofin lorin
Awon Eya to wa labe ewu iparun.

IMO IJINLE SAYENSI
Awon Aworan Titun Fihan Wipe Ko Si Okun Kariaye
Kokan Nibiti a Ti Ro Pe O Wa Tele 1 min. 5 secs. 15
O Seese ko je wipe ko si okun kokan ninu aye ti a mo si Mars

ISOWO
Ifowosowopo Titun Lati Gbejako Itusile Isowo 1 min 5 secs. 15 Awon ota aye atorun teletele ti ri Ota miran lati jo jumo dojuko

ETO AWON OMODE
Idi Ti Aami Omije Fi Wa Ni Ereke Amotekun Ti A Mo Si Cheetah 4 mins 49 secs. 11

Itan ibile Zulu kan se alaye awon aami Omije to wa ni awon ereke
amotekun Cheetah

Iseju Melo Ni O Si Le Fi Wa Laaye Ti Ejo Oka Ba Bu O Je? 1 min. 50 secs. 11 Bawo ni ibuje ejo oka ti loro to fun eda eniyan?

Iho Omi 10 mins. 55 secs. 12 Ehoro ro wipe on le je meji ni aba Alade, sugbon ijapa ni iro lo pa.
Emelo Ni Awon Kokoro Oyin Ma Nse Oyin Jade Laarin Odun Kan 1 min 28 secs. 14

Akoko itana eweko melo ni o wa laarin odun kan?
Oro Ti Enikan So Lori Itoju 51 secs. 14 Nibo ni eda eniyan yio lo ti a ba le ara wa kuro laye 2
2 Page 3 4
Vol II No. 11
Deceember, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

3
Iroyin Fifi Abe Ba Abe Obinrin Je Si Wopo Ni Orile-Ede Naijiria 3 mins. 48 secs.
Dida abe fun obinrin ni won si nse ni ibi pupo ni orile-ede Naijiria. Eyi jade ninu iwadi jakejado orile-ede na laipe yi ni akoko ti Redio ti orile-ede Naijiria royin ni ibere osu kokanla wipe ijoba ipinle Ogun ti fi ofin
de iwa na. Okan ninu meta awon omo orile-ede Naijiria to ti le ni omo odun mejidinlogun lo jewo wipe awon yio da abe fun omo won obinrin. Iye na ga ju eyi lo ni iha iwo oorun Naijiria nibiti awon to ju idaji
awon to dahun ninu iwadi na ti so wipe awon yio da abe omo won obinrin. Iwadi ti alabasisepo ajo oluwadi
Gallop to wa ni Ilu Eko, iyen ajo RMS Media Services se fihan wipe o seese ki asa yi san de odo awon iran omo obinrin to mbo, paapa ni iha iwo-oorun orile-ede na.

Ajo oluwadi na, RMS Media Services, fi oro wa edegbeta eniyan ti ojo ori won ju odun mejidinlogun lo lenu wo lati inu eya mejila pataki jakejado awon ipinle merindinlogoji to wa ni orile-ede na. A pin awon
eniyan ni dogbadogba laarin awon olugbe aarin ilu ati awon olugbe igberiko, bena si ni iye okunrin ati obinrin na je dogbadogba. Abajade na fihan wipe eniyan meje ninu mewa awon to kopa ninu iwadi na ni iha iwo
oorun Naijiria lo mo nipa abe dida fun obinrin laarin awon eniyan won. Ipinle Eko lo tele pelu eniyan marun ninu mewa. Ila-oorun ati Ariwa ni eniyan merin ninu mewa ati eniyan meji ninu mewa.

Awon abajade na jo ni loju pupo ti aba fi ti ipinle ati eya wo nitoripe o fere to eniyan mesan nimu mewa to mo nipa asa na ni ipinle Edo, Ondo ati Bayelsa ati bi eniyan mejo ninu mewa laarin awon Urhobo, Ijaw ati
Edo. Bi idamerin awon ti won foro wa lenu wo jakejado orile-ede lo so wipe won da abe fun awon. Sugbon ti a ba mu lorin ipinle, eniyan bi meta ninu merin awon to dahun ni iha iwo-oorun lo so wipe won
da abe fun awon. Iha ila-oorun ati Eko ni eniyan kan ninu meta nigbati ti ariwa je eniyan kan ninu mewa.
Nigbati a n soro ninu ifiorowanilenuwo na, Arabinrin Margit Cleveland ti ajo RMS Media Services so wipe awon idi ti won ka fun asa na po, sugbon o fere je wipe gbogbo awon to dahun lo so wipe asa ni lati da abe
fun omo okunrin ati obinrin ni orile-ede Naijiria. Awon idi miran ni wipe ki ije ki omo obinrin ya onisekuse, ki ije ki ido gun ju bose ye lo, o nje ki ibimo rorun, o je ara eto imuwoegbe wipe o nteri obinrin ba fun oko
re. Gegebi oro Cleveland  ' Iro patapata gba ni wipe abe dida ndena isekuse. Ti a ba se iwadi laarin awon asewo, opolopo ninu won lo da abe. '

Ajo RMS Media Services ko bere lowo awon oludahun won kini ero won lori asa fifi abe ba abe obinrin je ni orile-ede Naijiria. Biotilejepe iwadi na eyiti o si munadoko julo ni orile-ede Naijiria, Cleveland so wipe
on yio fe latio tun se itopinpin awon ohun miran to ro mo abe dida fun obinrin ni ojo iwaju. Lara awon ohun na ni sise iwadi laarin awon eya kekeke ti ko si ninu iwadi yi, sise iwadi iru re laarin awon obinrin nikan, ati
ni awon orile-ede to wa nitosi bi Cameroon ati Ghana, mimo imo ijinle si nipa ohun to nfa abe didia fun obinrin ati sise agbekale ipolongo to munadoko lati koju re. Ni ipari oro re, Cleveland so wipe : Ti a ko
ba koju asa na ni ona kan tabi omiran, asa na yio tesiwaju fun iran be melo kan sii. Ko si ni dawo duro
nitori ki ise asa to le ku. ' RMS

Ona Titun fun Isakoko Egbin Ilu Bere Ni Orile-Ede Argentina 2 mins 7 secs. Ilu Salta ni Orile-ede Argentina, to ni awon olugbe bi oke medogbon, ni o ti darapo mo awon ilu agbaye ti
won ti se agbekale ona lati fi se akoso egbin lati awon inu ile gbigbe. Laipe yi ni ilu na, lati inu eyiti egbin to le jera iwon tonnu ogorun meji ati abo ti njade lojojumo, se agbekale eto fun isakoso egbin aloku nkan re
fun odun mewa to mbo. 3
3 Page 4 5
Vol II No. 12
December, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

4
Koko eto na ni fifa ise kikejopo, yiyasoto ati didanu awon egbin aloku nkan le awon aladani lowo. Eto na ni a o se agbekale re ni ipele marun ni sisentele bere pelu ipolongo odun kan fun awon ara ilu lati jeki won
mo nipa eto isakoso egbin ilu tuntun na. Pele kokan yio lo fun bi odun kan si meta. Lara awon ipele miran
ni odun meji laarin eyiti ile-ise aladani kan yio tewogba akojopo egbin olojojumo leyin ise asewo kan lati fi se iyasoto awon egbin lati orisun won. Odun meji to tele yio wa fun imuduro awon aseyori to ti wa ki won

si se aridaju wipe, o kere tan, idaji awon olugbe ilu na nya awon egbin won sototo lati ile. Awon olugbe yio tun ko lati se iyasoto awon egbin ti ko le jera bi gilasi, irin, takanda, ike ati irin aluminium fun atunlo.

Odun marun to gbeyin to je ipele kerin ati ikarun ni won o lo lati fi se aseyege iyasoto akojopo ati atunlo gbogbo orisirisi egbin patapata. Ogbeni Lucas Seghezzo, amoye lori oro egbin aloku nkan lati Salta to
seese ki on na wa lara awon to se agbekale eto iskoso egbin ilu na ni o so wipe ilu na ti pinnu lati se aseyori imulo eto na. Gegebi oro to Seghezzo so 'Gbogbo ona ati fi se eto na, ibojuto akojopo, igbapada awon
ohun ilo, inawo ati bebelo ni a o se itopinpin re lori iwulo ati idarasi nipa ilo awon nkan bi atoka melo kan. ' UWEP

Iwadi Titun Se Afihan Ohun To N Fa 'Awon Isoro Lati Kawe' Gan 2min. 22 secs.
Iwadi titun ti fihan wipe aisedeede ninu eto akoso ara lati owo opolo ni o n fa isoro ati kawe fun awon to nfe kawe ti won si ni anfani lati se be. Gegebi oro ti iwe iroyin Economist so:  ' Bi abajade yi ba kesejari….. yio
jeki o seese lati le so daju wipe eniyan kan wa ninu ewu arun ailekawe nigbati ifura nipa re ba ti sele. ' Titi di enu ojo meta yi, awon amoye wipe isise opolo ti ro wipe ailera yi ti a mo ni ede geesi si 'dyslexia' ni o je
isoro to ndanikan sele. Won gbagbo nipa awon ti o ni ikolu na ko ni oye lati mo ohun ti won fe ka tabi ko. Ero ti ki ise otito yi ni o gba atileyin nipa wipe awon alarun ailekawe ki ini isoro lati ba eniyan soro. Ona
titun lati fi mo arun na fihan wipe ailera na ma nwaye latari aisedeede ninu awon seeli ero ori ni apakan
opolo. Aisedeede yi ma nfa ilosile ninu bi opolo se le tete gba ki o si se amulo imoran lati oju ati eti. Ogbeni John Gabrieli ati Torkel Klirberg ti ileeko giga Yunifasiti ti Standford ni orile-ede Amerika ni o se

agbekale ona titun yi eyi ti a pe ni Idojuru eroja inu opolo to nse ifamora-igbesoke iyaworan nkan inu opolo (diffusion tensor magnetic-resonance imaging (DTI).

Aseyorisirere ninu imo lori arun yi wa leyin ti won ri wipe awon eniyan to ni arun na nni wahala diedie lati gboran. Won ri wipe won ki ile moye awon gbolohun to ba ni awon oro to ndun bakanna, paapa ti won ba
sare tele are won. Awari yi mu ki Dokita Gabrieli ati Klingberg fura wipe o seese ki arun na ni nkan se pelu bi awon aami se nyara lo kakiri awon isan eto akoso lati owo opolo. DTI je ona lati fi se idiwon awon omi
kekeke to wa ninu awon ohun alaaye inu ago ara. Nipa wiwoye bi awon omi kekeke yi se ayara lo ninu
awon isan eto akoso ara lati owo opolo, awon onimo ijinle sayensi na ri wipe won ri ona to ja gere fun ilokiri na ninu awon eniyan ti ko ni arun na ati ona to ko ja gere ninu awon to ni arun na.

The Economist
Aarun Kogboogun Eedi Si Je Isoro Bi Ojo Eedi Ni Agbaye Se Nsunmotosi 2 mins 36 secs.

Ile Afrika lo si ni awon eniyan to po ju to ti ikolu kokoro – HIV, iyen kokoro arun to nfa aikunojuiwon
ajesara ninu ago ara eniyan, tabi to tile ti ngbe pelu arun-kogbogun Eedi gangan. Eyi ni a ri gbo lati inu iroyin ti ajo United Nations gbe jade laipe yi. Ninu gbogbo awon eniyan bi milionu (egberun lona egberun)

merinlelogbon to ni kokoro HIV tabi arun Eedi ni agbabye, o fere to milionu metalelogun ninu won to wa ni iha isale asale Sahara. 4
4 Page 5 6
Vol II No. 11
Deceember, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

5
Ninu iwe pelebe kan ti ajo United Nations gbe jade saaju ojo Arun Eedi ni agbaye eyiti yio waye ni ojo kini osu kejila odun yi, ile Afirika lo je asiwaju ninu ajakale arun Eedi. O fere je wipe gbogbo eniyan to ku
lati owo awon arun ibalopo ni odun 1998 lo je omo ile Afirika. Lara awon ogbon oke omode ti abi pelu
arun na awon to je omo ile Afirika ninu won ju oke medogbon lo ile Afirika. Na ni ati fere ri gbogbo ikolu tabi iku lati owo arun na lara awon omode ati iko ogorin ninu ogorun gbogbo ikolu kokoro – HIV ati iku titi

di oni yi. Gegebi oro inu iwe pelebe na eyiti akole re je kokoro – HIV ati Arun Eedi – Idahun Ajo United Nations, ile Afirika na lo ni awon obirin to poju to ni arun na. O fere to idaji awon to ni arun na ni ile Afirika
to je obirin!
Biotilejepe ile Afrika lo ni ikolu arun na to poju, arun na ko duro si ile, tabi sodo eya tabi iru awon eniyan kan. Nibayi egbegberun lona egbegberun ikolu arun na lo wa ni iha gbogbo ni agbaye. Ninu eyi ni a ti ri bi
milionu meje ni ile Asia, milionu meji ni ile Latin Amerika, milionu kan ni iha ariwa Amerika ati awon egbegberun lona ogorun ni ile Carribbean, ile alawo funfun Europe, aringbungbun ila-oorun, awon orile ede
Australia, New Zealand ati awon erekusu Pacific. Gegebi Akowe-Agba ajo United Nations, Kofi Anan se so laipe yi nigbati o tun nran gbogbo aye leti nipa itesiwaju ikolu ajakale arun na; "  A gbodo jeki awon
eniyan nibi gbogbo mo wipe nkan na ko iti dopin ati eyi ki ise oro nipa orile-ede bi melo kan ni ile okeere to jina rere; wipe irokeke ewu niyi lori gbogbo eda eniyan patapata. Ajo United Nations ni ireti wipe aye
yio tun ipinnu re se lati gbejako arun na ni ayajo ojo Arun Eedi ti odun yi. Lara awon ona ti a ti la sile lati fi
koju arun na ni ilowosi awon oloselu to ga julo, ifowosowopo laarin gbogbo eniyan ni awujo ati mimukuro idakejeje ati abuku to ro mo kokoro HIV ati Arun Eedi ati ti opolopo owo ati ohun miran to n lo si ati se

idena ati itoju kokoro HIV. Awon miran ni imuyarasi iwadi lori abere ajesara fun arun Eedi ati inawo to po si lori eto fun awon odo.
HIV/ AIDS more than a Health Crisis
Awon Igi Elegberun Edun Ninu Iwe Kan 1 min 33secs.
Ni ojo kerinlelogun osu kokanla odun yi, ni ilu London, Ipolongo Igbo fun Emi ti Ajo WWF yio se agbejade atejade to dayato kan fun gbogbo aye. Iwe na ti a pe akole re ni Awon Igi Aye Atijo – Awon Igi to gbe aye

fun Egberun odun ni o je igbelaruge awon eya igi to leni medogbon to le gbe laye fun egberun odun, o kere tan. Ninu iwe na ni a tun ti ri awon awari tuntun nipa awon eweko ni agbaye. Iwe na, eyiti awon eniyan ti npe
ni Iwe Egberun odun, ni a se akojopo re lati owo ayaworan Edward Parker ati Anna Lewington. Parker rin
kakiri aye fun opolopo odun to nya awon aworan igbo to yanilenu. Iwe 'Awon Igi Aye Atijo' na se akosile opolopo awon eya igi kakiri aye, o si se afihan ipataki won lona esin, asa ibile, itan ati ayika, ati imenuba ojo

ori ati titobi awon igi to dagba ju ni aye. Lara won ni a ti ri akojopo lati awon igbo olojo ti ile Amazon titi de awon ogbele ti Asale Namib. Nigbati nsapejuwe iwe na gegebi iwe to joniloju to si dara, alariwisi kan so wipe
'o se akojo die lara awon aworan Parker to dara ju' A le ri iwe na ra lati odo Sonia Pugh ni Collins and
Brown Publishers ni ile Geesi (Ero Ibanisoro : +441719242575). WWF

Ajo Orile-Ede Naijiria Kan Gba Aami Eye Ti Kariaye Lori Idanileko Lori Ibalopo Laarin Okunrin Ati Obinrin 1 min. 34 secs.
Ajo Ise lori Ilera (AHI), ajo orile-ede Naijiria kan ti ko lowo ijoba ninu eyiti o dojuko idanileko lori ibalopo laarin okunrin ati obinrin ni o gba Aami Eye ti Idanileko lori Ibalopo ti ajo WAS. Aami Eye na, eyiti Egbe
Agbaye fun oro lori Ibalopo laarin okunrin ati obinrin (World Association of Sexology (WAS) se onigbowo re, ni a fun Ajo AHI ni ilu Hong Kong ninu Apero Agbaye nla kerinla lori Ibalopo okunrin ati obinrin to
waye ni osu kejo odun yi. 5
5 Page 6 7
Vol II No. 12
December, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

6
Ajo AHI ni Igbimo Olugbaninimoran ti ajo WAS yan lati inu awon asayan ajo bi ogun awon ti a ti foruko won sile fun aami eye na. Nigbati o nfun won ni aami eye na Dokita Eli Coleman to je Aare Egbe Agbaye
fun oro lori Ibalopo laarin okunrin ati obinrin se alaye lori isepataki re. 'A ma n fi ami eye na fun ajo to
dara julo to ti ipolongo idanileko lori ibalopo laarin okunrin ati obinrin ni orile-ede re nipa awon eto to mu ogbon titun jade. Nitorina o wa fun sise iwuri fun awon ajo to npolongo idanileko lori ibalopo pelu ireti

wipe awon ajo miran yio ni iwuri lati se be gege'
Aami Eye na wa gegebi ohun airotele fun Ajo Ise lori Ilera eyiti o ko ipa pataki ninu agbejade Awon
Itosona fun Idanileko lori Ibalopo to munadoko ni orile-ede Naijiria.
Gegebi Dokita Uwen Esiet to je okan ninu awon olutoju ajo na se so pelu idunnu nigbati o ngba aami eye na gba. « A ko fojusona wipe a o

ri aami eye na gba.» O so wipe aami eye na yio se iwuri fun ajo na lati tesiwaju ninu ikepe fun imudarasi ninu bi o se rorun si fun awon odo ni orile-ede Naijiria lati gba idanileko to peye lori ibalopo okunrin ati
obinrin. Growing up.

Ajo Ibanisoro Fun Iyipada Se Agbejade Aworan Fiimu Lori Awon Opo 2 min 15 secs.
Aworan fiimu kan ologbon iseju, eyiti o n se afihan otito ti wa nipa igbesi aye awon opo ni orile-ede Naijiria ni a o se ifilole re ni ibi meta otooto ni orile-ede Naijiria ni osu yi. Aworan fiimu ni ti a pe akole re ni Titi ti
Iku yio fi ya
wa ni a ya ni iha ila orun Naijiria nibiti awon isoro awon opo ti buruju ti a ti se ayipada re si
soro pupo. A o se afilole re ni ilu Eko, Enugu ati Port-Harcout laarin ojo kokandinlogbon osu kokanla ati ojo kejo osu kejila odun yi. Ajo Ibanisoro fun Iyipada (Communicating for Change CFC) se aworan fiimu

na ni odun to koja lati fi se ifojusi oro to ti fere duro si ipo eewo. Aworan na se afihan ifiorowanilenuwo pelu awon opo, awon egbe awon opo ati awon eniyan miran to nse iranlowo lati petu si isoro won.
Opolopo awon opo lo ni anfani lati tu okan won jade nipa ipo ti won wa, ti won si so awon iriri ti won ti
farada fun opolopo odun. O je afihan awon ala ohun rere to ti wo danu, ife danu rere to ti duro ati iwa-ipa nipa ti ara ati ti emi.

Titi ti iku yio fi ya wa tan imole sori awon asa ibile to n fi awon opo sinu isoro ti ko se fenuso. Lara eyi ni a ti ri itimole fun awon ojo pipe, ibaje ara gegebi ori fifa, isofo olojo gbooro ninu eyiti o gbodo ma sunkun ki o
si baraje lati yo ara re kuro ninu ifurasi wipe on lo pa oko re, ati eto ibile iwenumo lati ge gbogbo asopo
laarin on ati oko re oloogbe. CFC gbe aworna na jade pelu iranlowo lati owo ajo Igbekele Ero Amohunmaworan fun Ayika (Television Trust for the Environment) (TVE) ti ile-ise won wa ni ile Geesi, ti

awon na gba owo lati owo Ajo Apapo Ile alawo funfun Europe. Obasi Ogbonnaya

O Seese Ki Awon Oko Inu Ofurufu Pa Owo To To Adota Bilionu (Milionu Lona Egberun) Owo Dola Amerika
Ni Odun 2000 1 min 38 secs.
Iwakiri inu ofurufu to ti nlo fun bi ewadun merin ti bere si mu ere owo ati ti imo ero to joju wa fun awon orile-ede
Europe ati Amerika to je olubere akitiyan na. Iye owo ti a siro si bilionu merindinlogoji owo dola Amerika ni owo itaja to wole lati inu awon ibudo inu ofurufu ti awon eniyan wa ninu re ati awon oko inu ofurufu agbelero
ni odun to koja. Bakana, alekun ninu ilo imo ero to mu awon ogbon titun jade ni a lero wipe yio ran awon
orile-ede to sese ndagbasoke lowo. Awon akosile yi jade lati inu Apero keta ti Ajo gbogbo orile-ede Agbaye lori Iwakiri ati Ilo Inu ofurufu fun Alafia (United Nations Conference on the Exploration and Peaceful Uses of 6
6 Page 7 8
Vol II No. 11
Deceember, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

7
Outer Space (UNISPACE III) eyiti o waye ni ilu Vienna ni osu keje odun yi.
Gegebi o ti jade lati inu UNISPACE III owo ti a siro si adota bilionu owo dola Amerika ni a lero wipe yio
wole fun odun 2000. Alekun isepataki ilo inu ofurufu fun ise aje yi lo je koko ifikunlukun ninu apero Vienna na lori awon ona ti awon eniyan fi le lo inu ofurufu. Ikede Vienna ati Ilana Ise (Vienna Declaration and

Action Plan) eyiti a fowosi ni UNISPACE III ni eto kan fun idabobo inu ofurufu ati isakoso awon oro re fun anfani aabo ati ire eda eniyan. Eto na ni a royin re wipe o je imudarasi UNISPACE I lati II eyiti o waye
ni odun 1968 and 1982.
Lara awon eto to waye ni Vienna ni a ti ri awon ona lati fi se ipese iranlowo imo ero ati eko lati le jeki awon orile-ede to sese ndagbasoke na je anfani ninu awon imo ero to jemo inu ofurufu. Lara awon wonyi ni
ibojuto awon ipo ti oju ojo, ayika ati ise ogbin wa. Ikilo kiakia nipa awon ajalu ti iseda to nrodede, awon isopomo itankale Internet lati inu oko inu ofurufu fun awon ibiti ko si waya ero ibanisoro, awon ilana imona
ati agbekale awon ona ati ohun elo titun fun sise awon ohun elo. Jade. Development Update

Ona Si Orisun Iroyin: Itankale Internet Ori Komputa Se Atunse Awon Ofin 1 min 34 secs.
Nisisiyi o le beresi gbo eto lori ero asoromagbesi ti ara ilu lati ibikibi ni agbaye ti o ba ti te ohun elo afowote lori ero komputa re. Asiwaju kan ninu ipese itankale internet ati Ilo fun Igberoyinsaye ni orile-ede Amerika,
ajo Bizness On line Com., lo jeki eyi seese nipa ifilole ile-ise asororomagbesi ti ara ilu lori ero Komputa, akoko iru re ni agbaye ni osu to koja ni ilu New York, orile-ede Amerika. Ile-ise na wa nisisiyi lori (htttp://
www. thepublicradiostation. com) o si nse ipese orisirisi eto lati jakejado Amerika ati gbogbo aye. Lara won ni a ti ri orin jazz, ifitonileti lori oja rira ati tita, ori ibile, oro awon obinrin, ayika, iroyin ati awon apilese eto.
Ibudo iroyin na ni a se agbekale, eto ati igbejade re lati owo ajo Bizness On line Com. to se eto na pataki
fun awon oko-owo ti ko tobi pupo ati awon agboole ni orile-ede Amerika.

Gegebi oro Alase agba ajo Bizness Online Com. Mark E. Munro, '  Pelu bi ilo itankale Internet se npo si, awon ofin ti nyipada fun orisirise ile igberoyinjade. A nsise lowolowo pelu opolopo ile-ise asoromagbesi,
amohun maworan ati ajo oniweroyin, lati ran won lowo lati lo itankale Intrnet gegebi afikun ohun elo won. '
Munro tun so wipe a se awon eto na ni ona ti awon yio fi mo igbati eto ti won ba feran ba wa lori afefe. Ohun iwuri miran tun wa. Bi olugbo kan ba kuna lati gbo eto to feran, o kan le te eto na pada ki o si gbo

lati olugbo inu eto ti a ti fi sinu ibi ipamo.
O fere jepe gbogbo ona Igberoyin jade meteta ti ati mo tele. (iwe iroyin, ero asoromagbesi ati ero amohunmaworan) lo nlo itankanle Internet nisisiyi gegebi afikun ona won . Bi o ba ti te ohun elo alafowote, o

le wo eto ori ero amohunmaworan to feran, o le ka awon iwe iroyin ati apileko oro tabi ki o gbo eto ori ero
asoromagbesi to feran. Ile-ise Public Radio Station. com ni o je ero asoromagbesi alakoko yio wa lori afefe.

Awon Apileko Oro
Agbegbe Niger Delta: Imo Nipa ayika Lo Soke 2 mins. 50 secs Ajo orile-ede Naijiria ti ko lowo ijo ba ninu kan ti a mo si Ajo Amuludun Ile Aye to wa Laaye (Living Earth
Nigeria Foundation (LENF) ni o ti fi igba akoko pese anfani fun awon eniyan agbegbe ni Niger Delta lati soro enu won jade nipa ise agbese to mu ogbon titun wa. 7
7 Page 8 9
Vol II No. 12
December, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

8
Lara awon ise agbese na ni a ti ri ero asoromagbesi ti ayika kan lori eyiti won ti ma nfi ede geese amulumala wa awon eniyan agbegbe lenu wo, ati awon iwe alemogiri eyiti o nse afihan ona alagbero ti awon eniyan yio ma
fi se asepo pelu ayika won. Awon ti n je anfani eto na lowolowo ni Akipelai, Oloibiri, ati Biseni – akopo awon
agbegbe mejo.

Awon ise agbese yi to bere ni odun 1998 ti jo awon eniyan loju pupo. Inu oloye abule Akipelai dun pupo leyin ti o ti wo 'Owuro Titun'  to je ere ori itage akoko ti won se ni abule re. Leyin ere na, o pariwo 'mo sese
ri abule mi ninu awojiji tan ni' Ajo Ile aye to walaaye ti se ohun miran leyin eleyi nipa riran awon agbegbe na lowo lati da egbe ere ori itage tiwon na sile eyiti won pe ni 'Egbe Elere Odioniobebh ti Akpelai. O fere je wipe
gbogbo awon abule to wani agbegbe meta na lo ti ni egbe elere ori itage tiwon. Eto ori ero asoromagbesi meji, alapa metala metala ti a pe akole won ni Akoko ti de ati Kilo Nsele ni ati gbe sori afefe ni ori ero asoromagbesi
radio pataki meta ni ipinle Bayelsa, Cross River ati Delta. Nigbati o nsoro lori awon eto ori redio na, Oloye Amakine Ogu to je Amananowei ti Egbebiri ni Biseni so bayi. 'Eyi ni ohun to daraju to si sele si wa. Eto na ti
gbe wa saye, o si ti fi awon isoro agbegbe wa han fun awon ara ita. 'Edith Ikeni, omobinrin kan ni Akipelai
woye wipe oro ifiwanilenuwo ori redio na 'lo je igba akoko ti awon obinrin abule igberiko ni ipinle Bayelsa yio ni anfani lati soro inu won jade sita. '

Ogbeni Aureol D. Vianana to je Alaga Alase ti Ajo Ipinle Bayelsa fun Iseto Ayika ati Idagbasoke fihan wipe ajo on mo riri ilo ero asoromagbesi lati fi ru imo awon eniayn agbegbe soke niapa yika won. 'Nipase awon
eto ori redio na, ajo Ile Aye to wa laaye yio ni ipa pataki lara ibalopo awon awon agbegbe pelu ayika won gegebi a ba ti nse ayipada nipa iwa ati ise wa. ' O wa seleri wipe Redio Bayelsa yio gba eto na wole to ba ti
bere lori afefe. Biotilejepe ohun elo mejeji lati fi ru imo nipa itoju soke lara eyiti awon iwe alemegiri ni ti Ile
Aye to Wa Laaye ni awon ti oro na kan ti tewo gba tayotayo, ipa ti won o ni fun ojo pipe ni a ko ti mo. Living Earth Nigeria Foundation

Omo Orile-Ede Ethiopia Se Ifilole Ero Asoromagbesi Redio Olohun Ketekete Ni Ile Afirika Ati Aringbungbun Ila Oorun 3mins. 9 secs.
Awon omo iha iwo-oorun ile Afirika yio beresi gba igbohunsafefe redio olohun ketekete nibi gbogbo jakejado ekun na ki o to di odun 2000 nipa liloawon ero redio ti a pile se lati gba ati lati lo awon agbejade lati inu oko
inu ofurufu. Awon to jeki eyi seese ni Ajo Worldspace Corporation to je ilana igbohunsafefe oniketekete to tobi julo ni agbaye eyiti da sile lati kari gbogbo ile Afirika fun igba akoko Igbohunsafefe Worldspace eyiti o
bere ni osu to koja ni o je akoko iru re igbohunsafefe redio lati inu oko ofurufu to nlo imo ero igbalode lati ri wipe ohun awon redio han ketekete titi de awon agbegbe to jinna pupo nibiti igbohun safefe redio ko ti lr fr
teletele. Redio yi yio se igbesafefe orisirisi eto radio eledepupo jakejado ile Afirika bere lati orile-ede Naijiria,
Ghana, Senegal, South, Africa, Kenya, Cote d'Ivoire, Egypt ati Morocco.

Igbohunsafefe na lo nwa lati awon ibudo igbohunsafefe to wa ni ilu London ati Washington si ile Afirika lati inu oko inu ofurufu ti nlo agbara lati inu oorun ti a mo si Afri -star ti ajo Worldspace ti a gbelo sinu ofurufu ni ibere
odun yi. Afristar' yio pese eka to ju medogbon lo ti eto iroyin, orin, idaraya ati idanileko si agbegbe to gbale to
milionu (egberun lona egberun) mejilelogoji ibuso kilomita ni igun mererin ni ile Afirika ati Aringbungbun iha ila-oorun. Gegebi oro Noah A. Samara to je Alaga ati Oga Agba fun Worldspace nibi ifilole ilana na 'Lotito oni

je ojo itan ninu igbohunsafefe. Fun odun mewa ni a ti fi sise fun ojo oni. Fun igba akoko, eto eri redio to han ketekete ni won ngbo ni awon agbegbe tio o je wipe titi di isisiyi, kogba ekunrere ise lati awon orisun igbahunsafefe
ti a ti mo tele. Inu wa dun lati mu igba otun waye pelu ise redio olohun ketekete wa. ' 8
8 Page 9 10
Vol II No. 11
Deceember, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

9
Ilana Igbohun safefe Worlsspace siro lati de odo awon bilionu (milionu lona egberun) kan olugbo jakejado aye. Sugbon sa ero redio apilese to ni ohun elo igba agbara latinuafefe lati inu oko ofurufu ni won nilo lati fi
gba igbesafefe lati odo Afristar. O to bi oke kan ati abo awon ero redio yi ti a ti se jade lati owo awon
asiwaju oluse awon ohun elo ina tonlo agbara awon eroja kekeke ti a kojopo ti a mo si electronics Lara won ni Hitachi, JVC, Panasonic, ati Sanyo. Nigbati yio ba fi di osu kejila odun yi, yio fere to oke mefa abo

iru ero radio yi ti a ti se ti a o si ta si ile Afirika. Sugbon opolopo milionu awon ero na ni won yio ni lati se ki won si ta ni owo pooku ti agbara ka jakejado igberiko ile Afirika lati le jeki Worldspace je ohun elo
idagbasoke to munadoko.
Lara awon ise ti Worldspace nse ni a ti ri asayan awon eto iroyin lati awon ile-ise ero asoromagbesi ati amohunmaworan ti agbaye ati ti orile-ede miran, igbohunsafefe ni opolopo ede lara eyiti ati ri ede Geesi,
Faranse, Larubawa at Afrikaan. Eto nlo lowlowo lati se igbesi ofurufu awon oko inu ofurufu Asiastar ati Ameristar gegebi ara igbero Worldspace lati se igbohunsafefe si gbogbo awon oja to sese nyoju ti a ko ti te
lorun. Ni odun 1990 ni Samara da Worldspace sile. O se agbekale awon erongba re ni odun kanna si awon eniyan ni Eko nibi ifilole ise agbese Awon omo ile Afirika eyiti oludokoowo omo orile-ede Naijiria
kan se kokari re lati jeki gbogbo aye mo nipa isoro awon omode ile Afirika. PR NEWSwire/ NEWSdesk

Awari Titun Se Igbelaruge Imo Lori Itoju Ni Orile-Ede Ghana 2 mins. 14 secs.
Awari Sitatunga ni orile-ede Ghana ni aipe yi ti mu agbara titun wonu ipolongo lori imo nipa itoju ni orile-ede na. Sitatunga je lara ebi etu ti won ma nri ni awon ile ira ati ile olomi ni iha ila –oorun ati gusu Afirika ati

orile-ede Naijiria. O ti parun patapata ni awon orile-ede iha iwo-oorun Afirika yoku bi Cote d'Ivoire, Sierra Leone, Liberia, Senegal ati Gambia, latari ode sise. Titi di enu ojo meta yi, won ro wipe eranko na ti
parun patapata ni orile-ede Ghana sugbon awon itiraka lati paala si awon agbegbe irin ajo afe to je mo ilolupo awon eda abemi ni awon ile ayika odo Volta ni ekun ila oorun Ghana ni o jeki won seesi ri eranko na
ni agbegbe osa Avu. Eni to ri ni Ogbeni Frank Kofigah to je Alakoso irin-ajo afe fun ekun Volta.
Eka ile-ise fun awon eda abami egan, Ibudo Iwadi lori Itoju Iseda Aye (Nature Consevation Research Centre (NCRC), ati I se Agbese ti Ile Olomi ni Ghana ti fi ife won ninu awari na han. Nigbakanri, Sitatunga
lo je eran-ode ti awon ode osa Avu feran sugbon nisisiyi oloye won ti pase wipe won ko gbodo sode re mo. Gegebi oro Mr. Kofigah:  ' niwongbati a ba le se agbero awon agbegbe ti a dabobo iru awon eranko to
dara bayi yio ma fa awon aririn ajo afe wa, won yio si mu owo wole. ' Awon akitiyan miran ni won nse lati dabobo eranko na ni ibugbe re. Ogbeni David Kpelle to je oludari ise agbese ti Ile Olomi ni Ghana ti soro
nipa eto fun ipolongo ayika lati jeki awon eniyan mo wipe ohun pupo ni won leri lati inu irin ajo afe ti ilolupo awon eda abami to je mo eranko na ju lati pa fun ounje lo. Ni afikun, eka ile-ise to wa fun awon Eda
Abami Egan ngbero lati gba ilowo si awon ajo kariaye fun itoju iseda aye fun iwadi agbegbe lati mo iye,
titobi ati ipinkiri eranko na ninu ipolongo fun itoju re. Edward Ameyibo

Imudarasi Ilu Khartoun So Egbegberun Di Alainilelori 2 mins. 47 secs.
Eto nla kan lati mu olu-ilu orile-ede Sudan ti oorun npa buruku-buruku, iyen Khartoun dara si ni o ti si egbegberun awon olugbe nipo. Opolopo ninu won lo je talaka. Okan ninu awon asiwaju egbe Ajafitafita

fun Eto Eniyan ni orile-ede Sudan to je ajo ti ko lowo ijoba ninu ti awon oniroyin, agbejoro ati oluko n se akoso re, so wipe eto lati ko awon talaka kuro ni olu-ilu na lati si awon oju ona nlanla, awon titi arin ilu to fe
si ati awon ogba igbafe fun awon ara ilu titun ni o ti si awon olugbe bi egberun mokanlelogoji nipo. 9
9 Page 10 11
Vol II No. 12
December, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

10
Awon ti ko nile yi ni o ti darapo mo awon eniyan bi milionu meta to ngbe ni awon ile bi buka ni awon ilu awon talaka to yi olu ilu na ka nibiti won de duro si leyin ti won sa kuro fun ogun abele olodun
merindinlogun towa ni iha gusu orile-ede na. Ilejade na ni ijoba ipinle Khartoun nse lati igba ti ise na si ti
bere ni odun 1998, o ti yori si iwopale ile bi oke mewa ti gbogbo won je ti awon ti ko ni agbara ni awujo. Alaga awon egbe Ajafitafita fun Eto Eniyan ni orile-ede Sudan, Ghazi Suleman ti se aroye wipe awon ebi ti

won fatu kuro ni olu-ilu na ni won nha mo awon ibiti o jinna si ilu, to jinna si ise sise ati awon anfani ilu bi ile-eko ati si ibi ijosin ati awon ibudo itoju ilera.

Sugbon ijoba nwi awijare wipe awon ebi ti won si nipo pada na ni won fun ni ile tiwon ti won si ngbadun aye to dara ju ti tele lo. Gegebi oro osise ijoba ipinle Khartoun kan, 'imudarasi ati atunto Khartoun ko so
wipe ki won ma fi agbara mu awon eniyan kuro. ' Gomina ipinle Khartoun, Mazoub Al Khalifa kede laipe yi wipe ijoba oun ngbero lati se atunto olu ilu na lati so di awokose fun awon ojele olu-ilu ile Afirika.
Khartoum yio je okan ninu 'awon olu-ilu to dara julo ni ile Afirika ti eto latise atunto na ba ri owona. '
Gegebi Gomina na se so, ilu Khartoum ti a da sile ni o le ni ogorun odun seyin, ni a se fun milionu meji awon olugbe sugbon nisisiyi awon olugbe inu re ti ju milionu mefa lo, lara eyiti ati ri awon bi milionu meta ti ija to wa
ni gusu Sudan si nipo pada. Al Khalifa so wipe egbegberun awon ebi ni a o ko lo si awon ibomiran lati lana fun awon titi nla, ogba itura ati oju ona nlanla. Ni odun to koja, ijoba apapo da ajo kan sile ti a pe ni Ajo fun
idagbasoke Aarin Ilu Khartoum (Khartoum Centre Development Authority (KCDA) lati se abojuto imudarasi olu-ilu na ki o si se eto itunu fun awon ebi ti akitiyan na ba si nipo.
IPS

Ajo Unesco Pari Itan Ile Afirika 3 mins 37 secs.
Apa to kehin ninu Itan gbogbo Ile Afirika ni won ti te jade, eyi si fi opin si ise agbese ti o bere ni odun 1964 lati owo Ajo Apapo orile-ede Aye fun Eko Imo Sayensi ati Asa ibile (United Nations Educational,

Scientific and Cultura Organisation (UNESCO) lati se akosile itan ile Afirika lati igba ti oju ko iti la titi de oniyi. Ise agbese na ni won se latise atunse ero awon eniyan wipe awon awujo ile Afirika ko ni itan, won
ko si le ni idagbasoke ayafi ti itanidi lati ode wa bi ayabo ogun, igbe aye ati asa ba de ba won. Okokan ninu awon apa mejejo na ni o soro lori awon ilowosi ile Afirika sakosako si ogun gbogbo eda eniyan, lara eyiti a
ti ri asejade irin, imu ise ogbin wa si etile ati otito wipe ile Egipti aye atijo je awujo olaju ti ile alawo dudu
Afirika. Ise agbese na tun fidi otito mule wipe ogoji milionu omoile Afirika ni won gbe lo ninu owo eru sugbon okansoso ninu merinmerin won lo la awon irin ajo buruku gigun na rekoja okun ja. Apa kejo awon

iwe na ni a se agbejade re ninu aseye kan ni ilu Tripoli ni osu karun odun yi lati saami ipari ise agbese olodun marundinlogoji na.

Ipade gbogbogbo ti Ajo UNESCO ni odun 1964 fi ise agbese na lole ni ilu Paris ni akoko ti o gbero lati gbe asoyepo dide laarin awujo orisirisi ni aye ki awon eniyan orisirisi le jijo gbe po ninu igboraeniye. O se
pataki fun awon orile-ede Afirika ati Asia to sese di ominira lati se afihan awujo won fun aye ki won si se imupadabosipo fun won lati jeki won mo won daradara. Gegebi ero ise agbese na, o di dandan 'lati se
atunse awon oro ti ki ise otito to ti gbale latari wiwo ti won ti n wo ile Afirika pelu oju awon amunisin ti ko
jagara. ' Ise agbese na dagba soke ni awon ipele bi melo kan, odun marun to saaju 1965 si 1970 ni won lo fun iwadi si awon orisun itan ile Afirika. Won gba awon eleyi lati inu oro enu, akosile ti a toju, iwadi ijinle si

igbe aye awon eniyan aye atijo paapa lati inu iwujade awon ilu aye atijo, ati awon akosile nipa ede. Ni ipele keji, 1970 si 1980, won se agbekale ogbon imulo fun kiko itan na. Lara eyi ni agbekale igbimo kariaye
eleni mokandinlgoji kan lati se abojuto gbogbo ise na. Idameta won je awon ti ki ise omo ile Afirika lati 10
10 Page 11 12
Vol II No. 11
Deceember, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

11
orile-ede Amerika, Geesi, Brazil ati Caribbean. Won se ilana bi itopo awon iwe na yio se ri, won pin ise to je mo ti awon aworan ati awon ise ona, won si wa awon onkowe fun awon orisirisi apileko, won si yan
oludari kansoso fun apa kokan. Ipele itejade bere ni odun 1980. Ipari ipele yi ni ifaseyin lati inu idaamu
owo to tele ifaseyin orile-ede Amerika ati awon omo egbe miran kuro ninu ajo UNESCO ni odun 1990. Apa kejo loda lori ile Afirika lode oni oludari re ni gbajugbaja ni, Ali Mazrui, Olukotan Oluselu lati orile-ede

Kenya to n gbe ni Amerika.
Gegebi oro Christopher Wondji, ti o jijo je oludari apa na ati eniti o se kokari gbogbo ise na ni UNESCO. 'Ni
pataki ohun to je ni itupale awon egbe fun ijijagbara, idasile kuro labe imunisin, atunto ile na, awon isoro idagbasoke ati ibaraenilopo ni kariaye. ' Ohun kansoso to ba won ninu je ni wipe awon iwe na ko le fojusi

awon odun to bere lati 1990
The Courier

Eto Awon Omode

Iseju Melo Lo Si Le Fi Wa Laaye Ti Ejo Oka Ba Bu O Je? 1 min 50 secs. Ibere yi soro lati dahun nitoripe o seese ki o ma ku rara ti ejo oka ba bu o je. Oka je ejo oloro, ti o ba si
bu eniyan je yio po oro sinu eni to bu je. Ohun ode oka ma nsaba je omo eye tabi awon eranko kekeke, bi eku ati ekute. Eniyan ki ise ohun-ode re, iyen ni wipe a ki ise ara ounje to n je. Oka ma nbu eniyan je ti
eru ba baa ti o si fe dabobo ara re. O le po oro die si o lara tabi ko ma po oro rara. Bi o ba po oro si o
lara o seese ki ara re ma ya ki o si ni lati gba itoju ni ile iwosan. Bi ko ba tile po oro si o lara, o seese ki idoti wo inu ogbe na lati ara eyin ejo na. Awon onimo Sayensi to nwoye awon ejo so wipe opolopo eniyan

ti ejo buje ma n ku nitori ijaya ki ise nitori iye oro ti ejo na po jade.
Orisirisi oka lo wa, okan ninu won ni oka ti Egipti. O feran lati ma gbe nitosi ogan ikan. Ti o ba wa ninu ewu yio gbe ori re soke yio si na jojo re, iyen ni ibiti o ma n fe labe ori re. Ti ewu na ba ti lo yio yara sa wo inu iho

lo. Nigbamiran ejo na tile le dibon bi eyiti o ti ku. Sugbon awon to mo iwa ejo daradara so wipe ohun to dara
ni ki eniyan ma sunmo ejo, yala o ti ku ni tabi o wa laaye.
Chongololo

Idi Ti Aami Omije Fi Wa Ni Ereke Amotekun Ti a
Mo Si Cheetah 4min. 49secs.
Nigba pipe seyin ode buruku to tun ya ole kan joko sabe igi o si n wo orere ile gbalasa kan nibiti awon agbo igala to sanra ti njeko ni alafia. Ode na n ro ninu ara re wipe oorun ti mu ju fun oun lati se wahala lati

rin la igbo ja, lati lo sode nigbati o woye wipe nkankan rugbo ni apa otun oun. Abo amotekun kan ti a mo si
Cheetah lo ti pinnu lati se ode awon igala na, o si n see daada. Lojiji o pa ese re po labe re, o si fo siwaju bi ofa. Pelu iyara to ga o sare si awon igala na o si mu okan ninu won bi o ti fe ma salo.

Bi o ti nmi helehele nitori ise to se amotekun na wo ohun-ode re lo si abe iboji kan ni egbe ile gbalasa na. Ode na wo ohun to sele tiyanutiyanu lori iyara ati ijafafa ti o ri. Sugbon bi o si nwo, iyalenu to je fun lati ri wipe awon
omo amotekun meta lo dara ni iwo nwo ohun to sele labe iboji ti won duro si. Ilara wa kun inu okan ode na fun
awon omo amotekun na, o si nro wipe bawo ni iba se dun to ti on na ba ni eru to le ma se ode fun oun. Eyi wa mu ero buruku kan wa sokan re. O mo wipe awon amotekun ki igbejako eniyan, nitorina o pinnu wipe yio

rorun fun oun lati mu okan ninu awon omo amotekun ki oun si ko lati ma sode fun oun. 11
11 Page 12 13
Vol II No. 12
December, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

12
Bi o se nro ninu ara re o simi sara lati duro (ojo eniyan ni, ko si fe lati ri boya iya amotekun yio ja lati dabobo awon omo re) Bi orun se nwo lo, iya amotekun na fi awon re pamo sinu igbo kan o si lo sibi iho
omi lati mumi. Ni kiakia ode na mu oko re o si yara lo sibi igbo ti awon omo amotekun na wa. Nibe o ri
awon ikoko amotekun ti ko ti le salo. Ko mo eyiti iba mu ninu won, nitorina o ji gbogbo won pelu ero wipe amotekun meta yio dara ju okansoso lo.

Nigbati iya won pada ni bi ogbon iseju lehina ti ko si ri awon omo re, okan re baje. Iya na sunkun titi ti omije fi fi aami dudu si ereke re mejeji. O sunkun ni gbogbo oru na ati ni gbogbo ojo keji. O sunkun oelu
ariwo nla, okunin agbalagba kan to gbo si wa lati wo kini fa ariwo na. Okunrin arugbo yi ti ni opolopo iriri ati ogbon ni aye o si ni imo to ga ati owo fun awon eranko. Nigbati o mo ohun ti o sele inu bii, nitoripe yato
si wipe ode ole na ti di ole, o tun ti se lodi si asa ibile eya na. Gbogbo eniyan lo mo wipe ode na gbodo lo agbara ati imo ti re. Ona isede miran jasi abuku.

Okunrin arugbo na pada si abule o si so ohun ti o sele fun awon agbaagba. Inu bi awon ara abule na won si le ole ode na kuo ni abule won titi lai. Okunrin arugbo na ko awon omo amotekun metata o si da won pada
fun iya won, eniti inu re dun. Sugbon ekun asundabo iya amotekun na ti fi aami ti ko le pare soju re. Nitorina titi di oni ni awon eniyan Zulu ni orile-ede South Africa ma n so wipe amotekun ngbe aami ekun oju
re kiri gegebi iranti fun awon ode wipe ohun abuku ni lati se ode ni ona to ba yato si ti ibile. When Hippo was Hairy.

Iho Omi Na 10 mins 55 secs. Ogbele na buru pupo. Ogbe to be ti awon eranko fi n duro wo bi awon iho omi won ti ngbe lokankan.
Nigbati won riwipe awon yio nilati duro fun igba pipe leyin ti iho omi to kehin ba ti gbe ki ojo to tun ro, won pinnu lati wa nkan se si oro na. Nitorina won pe ipade ninu eyiti asoju eya eranko kokan gbodo pese ki
gbogbo orisirisi eranko le mu imoran wa. Ni ojo ti won da, awon eranko na pejo, won si soro fun igba pipe.
Nigbati yio fi di osan won ti fenuko wipe gbogbo eranko gbode gbe kanga kan to jin to be to fi je wipe ko le gbe bi ogbele na tile wa fun odun bi melo kan. Eranko kokan lo gbodo sise bi agbara re ba ti to ki omi

na le je ti gbogbo won ni dogbadogba.
Oro na ka awon eranko lara to be ti gbogbo won fi gba ipinnu na wole… iyen ni wipe gbogbo won, yato si
ehoro. Emi! Gbele fun anfani elomiran? ' O kigbe, '  ki ise emi! Emi funrara mi ko nilo omi. Nitorina kini de

tingofigbele? ' 'Ehoro, o dara na'  awon agbaagba so fun. 'O o ni gbele, o o sini mumi. Ti o ba tile di igba
ti gbogbo adagun to ku ba ti gbe a o ni gba o laye lati mumi lati inu kanga wa. '  Eyi ba Ehoro lara mu. O dubule o si ya oorun. O yan, o na ponpon o si ntogbe nigbati awon eranko to ku nsise bi akura, Won gbele, won ko

yepe ati okuta kuro, aare si mu won sii bi iho na se njin lo diedie si isale. Opolopo ojo leyin eyi nigbati awon ti ye ko bere ile gbigbe ni owuro de, inu won dun rekoja lati ri wipe ni gbeyingbeyin awon ti kan omi, kanga na
si ti kun fun omi ni gbogbo oru na.
Leyin opolopo ise ati akitiyan, awon eranko gba kanga na gegebi ohun ini won, won si pinnu wipe Ehoro ko gbodo to omi won wo bena ni enikeni ko gbodo gba ju ipin tire lo. Nitorina won yan eso kan lati ma so omi
na tosantoru bere lati ori Amotekun eniti iwo lile oju re ati ailefokantan enia re yio le oluyojuran to ba fe yoju
pada. Ogbele na ko dawo duro bi Ehoro se ro Awon iho omi na ti gbe nikokan, ko si se se fun un mo lati tesiwaju laisi omi. O wa di dandan fun lati mu ninu omi kanga na. O lo si ibi kanga na o si ri wipe oun

gbodo koja lara eso. 'Iyen o le soro' Ehoro bara e so .  Iyen yio rorun ju ati ma gbele ninu oorun lo.  12
12 Page 13 14
Vol II No. 11
Deceember, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

13
Laipe Ehoro sare pada sinu igbo lati lo wa afaara oyin. Ori ikan o si ji oyin inu re o ko awon afara yen sinu ape kan. O pada si ibi iho omi na o si joko nibiti amotekun ti le rii. O ki owo re bo inu oyin na bi o se nba
amotekun soro. 'Uunun, kini yi dara, oju e dara, oorun e na dara. Wo awo re to fanimora! Oluwa o!
emi agbadun eyi yi o! ' Nigbana o pon owo re la o si fi enu re pariwo pelu igbadun. Ko seese fun amotekun lati gboju kuro o si beresi dato mi bi o si n ro bi oyin na ti dun to.

Ehoro ni: 'Nje o mo, amotekun, wipe oyin yi lo dun ju ninu gbogbo eyi ti mo ti la ri. O da mi loju wipe iwo na yio fe lati to die wo nibe. ' 'Jo, mo fe, 'amotekun dahun. Ehoro gbe owo soke, 'O ti o , ko le ya be,
oyin yi dara to be to fi je wipe to ba ti towo wa fe la gbogbo e tan. Lati le dabobo oyin mi, ma de owo re kan, ko le je wipe owo kansoso lo ma fi je e. ' Pelu ebi inu, amotekun gba o si duro pelu ikanju fun Ehoro
lati de owo on kan ki oun le ki ikeji bo inu oyin aladun na.
Boya oyin na lo dun to be ni o, tabi ifojusona amotekun lo jeki o ri be, ko si enito le so. Sugbon itowo
akoko na dun mo tobe to fi bebe fun omiran. 'So ri nisisiyi! So ri nisisiyi! Ehoro kigbe. 'Sebi mo so fun e be, Nisisiyi lati le ma fun e laaye lati je gbogbo e ma ni lati de owo e kan to ku kii nwa ma fi si e lenu funrara

mi. ' Amotekun gba. Ohunkohun, yiowu ko je, ko sa ti le ri oyin yen je si! Laipe ehoro ti de amotekun daindain. Ehoro sare lo si ibi kanga o si mu omi pupo, o wa we – ohun to je eewo – ninu omi na, gbogbo
eyi to ku fun mimu.
Nigbati awon eranko mo wipe Ehoro ti tan Amotekun je, oju ti amotekun o si salo pelu itiju. Eso ti won tun yan ni Akata. Laisianiani, o gbon pupo ju ki ehoro wuruwuru le tan je. Sugbon ni irole ojo na ohun kanna
tun sele, Akata na tun titori oyin gba ehoro laaye lati de owo on mejeji ti o si wa nwo bi agutan gbogbo bi ehoro se nmu omi to si nwe ninu kanga na. Itiju akata po gidigidi ni ojo keji, bena si ni itara awon eranko bi
won se nsoro lori bawoni won se le dena ehoro ole kuro nibi kanga won.
Lojiji ijapa rapala siwaju o si bere bi won ba le jeki on se eso. Awon eranko toku fi sefe. '  Iwo, Ijapa! Se o ro wipe iwo le se aseyori nibiti Amotekun ati Akata ti kuna? ' Kini o ro pe o le se? Sugbon Ijapa sa taku,
nikehin won gba fun. Ijapa rapala lo bi o se le yara to, o si pe iyawo re, fun iranlowo. Won lo sidi igi oro,
nibe ni iyawo re fi oje ara igi na yi gbogbo igba eyin ijapa. Pelu erin moonu loju re. Ijapa pada lo sidi kanga. O wa iho ti ko jin pupoo si joko sinu re to be ti eniyan ko fi le ri ori ati ese re. Gbogbo nkan ti

eniyan le ri ni igba eyin re lo dabi okuta rubutu.
Nigbati Ehoro yan lo sidi knaga, o ri wipe ko si eso, o rerin titi ti awon irun-imu re gbonriri. 'Mo mo be, ' o
rerin. 'mo mo pe n go lo omi won lofe. Won logbon ju emi ehoro ologbon ewe lo! '  Ehoro mu omi bi o se fe, o si tun we ni irorun. Nigbati o ti mo dada ti ara si ti tuu, o jade kuro ninu omi o nwa ibiti on ti le gbe ara on ninu

oorun. 'Ah! Ojo ire mi loni' Ehoro soro nigbati o ri igba eyin ijapa. Ijoko daradara kan niyi to nduro demi lati joko sori re.  Nitorina, Ehoro joko pelu irorun lori igba eyin ijapa o si simi ninu oorun irorun na pelu titi ti irun
ara re fi gbe, o si wa to akoko lati lo sile. Sugbon……. Ah! Ah! Kileleyi? O tigan mo ori ijoko re! O yi, ofa,
o jampata sugbon daindain lo le mo ijoko na.

Ijapa na mo eyi, o si rapala jade kuro ninu iho na, o wa ba eru re ti kayefi ti mu soro.  ' Owo mi ti te o Ehoro, wa nilati bami kalo' Ijapa so pelu erin idunnu nitori aseyori re. Ehoro kapa iyalenu re, o si fi igboya
wi fun Ijapa wipe 'Ijapa, mo gba e niyanju ki o jeki nma lo. O seese ko ma mo sugbon owo mi otun
lagbara pupo, bi o ko ba si jekin lo ngo fi fo igba eyin re yi. ' 13
13 Page 14 15
Vol II No. 12
December, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

14
Ijapa kan tun rerin die sii ni o si sope ''  O ya Ehoro, see. Nitorina, Ehoro gbe owo otun re soke o si gbele igba eyi na 'kum' sugbon owo na gan mole! 'Ijapa' Ehoro dahun 'mo kan nsanu e ni o. Owo osi mi
lagabra ju ti otun mi lo o, ma jeki nlo o, joo nitori yio fo igba eyin re di eruku'' ''Niso'' Ijapa dahun
''Gbaga'' beni owo osi Ehoro lu igba eyin ijapa o si gan mole. Ehoro ni  ' 'Ijapa mo fun o ni anfani kansoso yi . Awon ese eyin mi mejeji lagbaa ju apa mi lo, bi ngo ba si ta o nipa, mo ju o soke sinu kurukuru. ''

'Jo, se ohunkohun to ba wu o, ' Ijapa dahun. Nitorina, Ehoro gbe ese re mejeji soke o si fi won ta Ijapa nipa, won si duro si be won ti gan mo igba eyin ijapa. Ijapa wa rapala lo sodo awon agbagba eranko pelu
elewon na leyin re daindain, o fa Ehoro lewon lowo fun idajo to tosii Shangani Folk Tales

Oro ti Enikaan so Lori Itoju 51 secs
"A so fun wa wipe a le Adamu ati Efa kuro ninu Ogba Edemi sinu aye. Lati igbana ni a ti nrin ni idurogangan ti a si ngbaradi lati le ara wa kuro ninu Ogba Edeni tiwa -iyen ni ile Aye. Baya ilekuro ko ni oro to ye ka lo,

nitori iyen dabi enipe ibomiran wa ti a le le wa si. Sugbon ni tiwa yi, ti a ba ti ba Edni yi je ti a si lo tan, ko si iboniran, ko si aye miran to nro ni ofurufu ti a le lo be igba ti a ba paro ibugbe. Aye daradaara sugbon to wa

labe ewu iparun yi na nikan ni eyiti a ni."
Gerald Durrell, Afenifere Itoju ati Olukoure

Emelo Ni Awon Kokoro Oyin Ma N Se Oyin Laarin Odun Kan? 1 min 28 secs. Awon kokoro oyin ma nse oyin jade nigbati awon igi ati eweko miran ba ni itanna. .Fun apeere, ni awon
orile-ede Afirika kan, awon igi ma mu itana jade larin osu kejila odun kan si osu keji odun to tele, ati lati osu keta si ikarun, eyi si funni ni ''akoko oyin'' meji. Awon kokoro oyin ma nse oyin jade lati inu oje aladun,
iyen oun didun ti o ma nwa ninu awon itanna. Bi won se nko oje aladun, awon oyin ma nmu ibisi wa fun
awon itanna nipa gbigbe eruku alawo ofefe ti a ko itanna lati ara itanna kan si omiran. Awon itanna kan ma nmu oyin to dara lenu wa ju awon miran lo. Igi to dara fun oyin ju ni ila-oorun Afirika ni a npe ni

'Mutondo'. Igi na ti o ma n mu itanna jade lati osu keta si ikarun ni a tun n pe ni 'Muchesa'.
Ni orile-ede Zambia, opo ninu oyin won ni o nwa lati awon agbegbe Mwinilunga, Kambampo ati Zambesi ni
iha iwo-oorun ariwa. Awon wonyi ni awon agbegbe ti won gbajumo fun kokoro-oyin sisin, ti won si ti nsowo oyin ati gedegede oyin (to ma njade ninu oyin sise) fun bi adojo odun. Oyin je okan ninu awon ohun to dun julo

ti a leri ninu iseda aye. Nje o mo bi won ti nsee? Awon kokoro oyin nikan ni o le see. Won a mu ekan oje aladun kan sinu enu won pelu kemikali kan pataki, won a fe ategun sinu re lati mu omi inu re kuro, ohun ti yio

ku ni ekan oyin gidi. Chongololo
Awon Otito To Wulo Ni Arowoto
Adajo Orile-Ede Amerika Kan Da Gedu Gige Duro Lati Dabobo Eja 51 secs.
Adajo ile-ejo ijoba apapo kan se idajo kan ti yio mu inu eniti oro na kan dun ti o ba je wipe o le kawe ni.
Ni osu to koja ni ilu Seattle ni Washington, adajo na da gedu tita duro ninu igbo ijoba apapo kan ni ile odo Umpqua ni iha iwo-oorun ariwa latari wipe ijoba kuna lati se apero to dara to boya ise gedu yio se ipalara

fun awon eja ti a dabobo labe ofin Awon Eya to wa labe ewu iparun lara. 14
14 Page 15
Vol II No. 11
Deceember, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

15
Kini eleyi tumo si? Eyi tumo si wipe ijoba yio pada lati gbe igbese lati teriba fun ofin, o gbodo se Iwadi apilese lori ikolu fun Ayika (Environmental Impact Analysis) eyiti o le yori ni ikehin si wipe ko ye ki ijoba
gba ise gedu laaye ninu igbo na. ENN

Ifowosowopo Titun Lati Gbejako Itusile Isowo 1 min. 3 secs.
Ipaala ija ti wa nile nisisiyi lati dojuko awon adehun kariaye to tu isowo sile ti o si tipa be fi awon orile-ede to seese ndagbasoke sinu airowomu to ga si. Ajo fun Isowo ni Agbaye (World Trade Organisation), ti o je

adehun kariaye lori isowo to tobi ju to si lagbara ju, ni won ti bu enu ate lu ni opolopo igba fun siso awon orile-ede to sese ndagbasoke di talaka to si ntipa be mu won tubo gbarale awon oro adayeba won to ti
ntan lo fun owonna ati agbero. Nisisiyi o dabi eni wipe Ajo fun Isowo ni Agbaye ati itusile isowo ti se iwuri
fun idasile ajosepo awon ajeji parapo kan. Awon Egbe osise ati ajijagbara fun ayika ni orile ede Ameika ti kede idasile egbe alajosepo kan lati fi gbejako itusile isowo ohun to joniloju nipa isele yi ni wipe nigba pupo

ni awon egbe osise ati awon ajijagbara fun ayika ma n je ota aye atorun lori oro adayeba. ENN/ Worldwire

Awon Aworan Titun Fihan Wipe Ko Si Okun
Kariaye Kokan Nibiti A Ti Gbagbo Pe O Wa Tele 1 min 5 secs.
Fun opolopo odun, awon onimo ijinle sayensi ti gbagbo wipe awon etikun nla to si gun wa ninu aye ti a mo
si Mars. Lati le ri aridaju eyi ati awon igbagbo mira nipa Mars, Ajo orile-ede Amerika fun Isakoko Imo Ijinle nipa irin-ajo oju ati inu ofurufu (United States National Aeronautics and Space Administration

(NASA) ran awon oko inu ofurufu ti ko leniyan ninu ti won pe ni irin-ajo Viking si aye na ni laarin 1970 si 1979. Awon aworan Mars ti awon oko inu ofurufu wonyi fi ranse sile fihan bi enipe awon okun kariaye nla
figbakanri bo eyito poju ninu iha ariwa aye na, won si fi awon iriri to dabi eti'kun han.
Eri titun ti fihan wipe igbagbo yi ki ise otito. Gegebi iwadi ti won gbejade ninu atejade awon iwe iwadi ti Imo nipa oye ti ojo kini osun kewa odun yi ni orile-ede Amerika, awon aworan titun ti aye Mars ti a fi awon
imo ero igbalode fihan wipe ko si eri fun awon eti kun ti iba ti yi awon okun atijo ka lori aye pupa na. ENN 15

Page Navigation Panel

1 2 3 4 5 6 7 8 9
10 11 12 13 14 15

 

© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw