Go Back
Communicating for Change

Document Body Page Navigation Panel

Pages 1--15


Page 1 2
Radio
Vol II No 7 June 1999 [Yoruba]

1
CHANGE
ATOKA ORI ORO
AKOKO OJU EWE
Idagbasoke
ILERA
Ona Agbese tuntun fun Eto

Itoju-ilera ni Igberi ko 56 secs 5 Iranaraenilowo' owo iranwo lati ile-okeere

ati atileyin Ijoba nso ti eto rere fun itoju-ilera
ni Afirika
Egbogi tuntun le da iku lati inu ikolu ako iba duro 51 secs 4

Iwadi nlo lowo lati mu ki ikolu ako iba
sepere, ki o ma yorisi iku
Idaniloro Arun-kogboogun Aids ni ile Afirika 40 secs 13 Arun kogboogun Aids ntesiwaju lati gba eto

si emi kuro lowo egbegberun lona ogororun awon
omode ile Afirika

OUNJE
Ajo Agbaye fun Ounje ati Ise ogbin nkilo nipa Aije
ounje to darato 1 min. 58 secs
7 Ipejaju nse irokeke aijeounjetodarato si awon

orile-ede to sese ndagbasoke
Ajo Gbogbo Orile-ede Agbaye kepe fun Iranlowo Ounje fun orile-ede Angola 2mins. 10secs 8

Egbegberun lona ogororun awon omo orile-ede
Angola lo wa ninu ewu aijeounjetodarato ayafi

ti agbaye ba se ipese iranlowo ounje yanturu ni kiakia.
Spirulina: Ewedo Iyanu 2mins. 39secs 12 Irugbin gbogbonse ti awon ebi gbodo

mo nipa re

IMO IJINLE SAYENSI
Awon oluwadi nse ayewo awon ilana
monomono 2 mins. 36secs
9 Awon otito pupo tun yoju sita nipa

monomono
IGBE AYE
Itolesese Ijiya Eda Eniyan 27secs 14 Angola: Orile-ede to njiya lati owo ogun abele

olodun medogbon 1
1 Page 2 3
Radio
Vol II No7 June 1999 [Yoruba]

2
CHANGE
Awon obirin orile-ede Bangladesh nparowa lati 2 mins. 46secs 12 wa ni dogban dogba pelu awon okunrin
Awon obirin orile-ede Bangladesh nwa ofin ogun jije
to dunmoni

ORO AJE
Ajo Unicef nro awon orile-ede Ayanilowo lati fagileAwon gbese ile Afirika 1min. 46secs 11

Ajo Akojo owo pajawiri ti Apapo orile-ede Agbaye
fun Awon Omode (United Nations International
Children Emergency Fund) (UNICEF) so wipe gbese
ile Afirika ndu awon obirin ati omode ni eto won.

Ajo Kariaye fun Ifagile Gbese 26secs 14 Sise eto fun ominira kuro ninu isinru gbese

Oro Idagbasoke ti enikan so 33secs 10 Oke isoro pataki fun idagbasoke ni ile Afirika
Ajo Oro Aje fun ile Afirika nse eto fun Idagbasoke 1min. 18secs 7 Agbara isabiyanuo to dinku ati igberu iposi eniyan
to fasehin le mu ki idagbasoke alagbero tete waye
ni ile Afirika

Ayika
AFEFE ILE
Imorusi Agbaye: Ilosoke Oru ni Orile-ede India 27secs 14 O seese ki orile-ede India tun faragba akoko ooru

apaniyan lodun yi.
Iyipada Afefe Ile: Otito tabi Asodun? 36secs 6 O seese ki iyi ipada afefe ile ti ni awon afaragbota nla

re akoko

ITOJU ISEDA
Oro ti enikan so lori Itoju Iseda 18secs 9 Ihuwasi awon eniyan si itoju iseda

Diduro de Ijanba na lati sele 30secs 14 Ibudo Ajogunba Aye kan to wa labe irokeke ijanba

AWON IGBO
Iroyin to peye lori ijerisi Igbo 17secs 14 Iroyin to sese jade lori ijerisi awon igbo jakejado aye

Awon Kolekole ati awon Osise Igi faramo Ijerisi 54secs 4 Atileyin to sese jade fun ijerisi awon igbo wa lati odo
egbe agbaye kan fun awon osise igi.

IDOTI
Awon Oludoti Baraku 21secs 14 Awon osise oko oju omi agbepo ni awon

iwa ti ko dara 2
2 Page 3 4
Radio
Vol II No 7 June 1999 [Yoruba]

3
CHANGE
Banki Agbaye se iranlowo fun orile-ede Afirika merin lati doju ija ko idoti epo robi 56secs 6
Awon orile-ede okun kariaye ti India merin gba
iranlowo lati gbejako idoti awon ona oju omi

to gbelege.
Orile-ede Cote d'Ivoire fi Imurasile re fun Ijanba
Epo Robi han 1min .29secs
6 Leyin isele ojiji ina ni ibudo epo kan, orile-ede

Cote d'Ivoire fi awon ara ilu lokan bale wipe on
ti gbaradi lati koju awon ijanba ayika.

AWON ILE OLOMI
Iponlongo ti bere lati se igbala awon oro omi mimo 59secs. 5

A ti se ifitonileti ilana kan lati se igbala awon oro
Omini agbaye.

Orile-ede Cote d'Ivoire ri ojuutu si isoro Epo oju omi 55secs 4

Ogun ogun-odun lori awon epo oju omi ni aseyori.
EDA ABEMI EGAN
Eranko wo lo ni awon eya to poju? 36secs 13 Eranko yi ni eya to poju ti gbogbo apapo

eranko to ku lo.

ETO IMULO
Idanileko Oniiforoweoro ngbero lati se idilowo ki ija ma sele lori oro iseda aye 57secs 5

awon orile-ede ihe gusu Afirika meje pade
lori awon oro ayi ka to le faja

ETO AWON OMODE
Idi ti kiniun ki ise je eso 2mins. 30secs 10 Awon eranko kekeke gbodo jajafa lati le dabobo

awon orisun ounje won ninu egan
Bawo ni awon Labalaba se njeun? 22secs 11 Enu to te woroko mu ki awon labalaba leje awon orisi

ounje kan.
Igi wo lo tobi ju ni aye? 1min. 24secs 11 Mo igi ti iwuwo re ju ti apapo egberun awon erin

ile Afirika to ti dagba tan lo
Ojo Omode Ile Afirika 1min. 7secs 10 Ojo omode ile Afirika nran agbaye leti wipe osi je

iwa odaran si awon omode

Ayewo Awon Oro to S'ajeji 15 Awon Ageso Oruko 15 3
3 Page 4 5
Radio
Vol II No7 June 1999 [Yoruba]

4
CHANGE
Iroyin

Egbogi tuntun le da iku lati inu ikolu ako iba duro 51secs
Opin si ako-iba, arun to ti npani lati ojo pipe wa, ti fere de tan. Iwadi tuntun kan to nlo lowolowo ni orile-ede Geesi ti fe gbe egbogi jade ti yio mu ki awon ifarahan ako iba sepere, ko ma le paniyan. Biotilejepe iwadi nipa

egbogi na sese bere ni, ifarahan wa wipe a o ma lo gegebi abere ajesara fun awon omode.
Ako iba ma npa egbegberun lona egbegberun eniyan lododun ninu eyiti o je pe awon omode ile Afirika ni o
papoju. Iwadi na da lori eri wipe iwonba ifaragba die si ikolu ako iba ni igba ewe ni eniyan nilo lati ni ajesara. Nitorina, a ko se egbogi ajesara na lati dena ikolu sugbon lati ma jeki ikolu ni agbara lati pa eniti o kolu.

London Press Service.

Orile-ede Cote d'Ivoire ri ojuntu si isoro Epo oju-omi 55secs. Leyin igbiyanju ogun odun, orile-ede Cote d'Ivoire ti jagun molu lori awon eweko omi to nsare posi ni yanturu
to si ti gba awon adagun eja kan to si ti ngbe irokeke ba awon eda abemi omi ati awon akitiyan oro aje ti agbegbe. Lara awon eweko na ni a ti ri epo oju-omi, ewebe odo ati koriko odo.

Ona idilowo kan ti imo ijinle sayensi nipa eweko ti a mo ni ede Geesi si biology, eyiti won bere si lo ni odun 1997 ni o bori ogun na fun orile-ede Cote d'Ivoire. Ninu ise alajosepo kan pelu ajo Apapo awon orile-ede
Agbaye fun Idagbasoke (UNDP), eyiti Ajo Akojo Owo ni Agbaye fun Iseda Aye (World-wide Fund for Nature( WWF) gbe owo kale fun, Orile-ede Cote d'Ivoire se ibisi awon kokoro ti o da sinu awon adagun ti
awon eweko omi na ti yabo. Awon kokoro wonyi, ti a ko so oruko won, je awon eweko na, won si pawon run.

Awon ibudo ibisi kokoro merin ototo ni won gbekale jakejado orile-ede na fun igbejako to munadoko si awon eweko omi na.
Africa News on Line.
Awon kolekole ati awon osise igi faramo ijerisi 54secs
Atileyin fun awon igbo ti a nse akoso won lona to dara ti a mo si ijerisi igbo (forest certification) ni o ti wa lati odo Ajo Alasepo ti kariaye fun awon osise ikole ati igi (International Federation of Building and Weed

Workers (IFBWW). Eyi waye leyin adehum kan pelu Ajo WWF lati se igbelaruge itoju igbo ati awon itosona fun iwe-idamo-igbo lati ti mo awon ohun elo to wa lati inu igbo ti won se akoso won daada.

Gegebi oro Akowe-Agba ajo IFBWW, ogbeni Ulf Asp: "Awon osise igbo ati egbe osise won ni ife-inu ninu isakoso-igbo alagbero nitoripe bi ko ba si igbo ko si ise".
O ju egberun lona egberun mewa awon osise lo ni orile-ede mokanlelogofa to je omo egbe IFBWW. Egbe na yio lo awon imosese ati imo timotimo re lori igbo fun anfani itoju iseda. Ajo WWF ngbero lati fi saare hektari
igbo to to igba milionu sabe isakoso alagbero nigbati yio ba fi di odun 2005. WWF

Ona Agbese tuntun fun Eto Itoju-ilera ni Igberiko 56secs Itoju ilera agbegbe eyidi inawo re wa lati inu awon owo ti ile-ise ijoba fun oro ilera ma ngbe kale ni o dabi
awose fun eto itoju ilera ni ile Afirika. Eto kan ni orile-ede Ghana ti ni ifojusi lati odo awon amoye. Ise Agbese 4
4 Page 5 6
Radio
Vol II No 7 June 1999 [Yoruba]

5
CHANGE
Ifietosi Ebi ni agbegbe Navrongo (Navrongo Health and Family Planning Project (CHFP) ni won bere re ni iha ila-oorun ariwa orile-ede Ghana ni odun 1993 gegebi ise asewo lati se igbekale awon ise ilera ati iseto ebi ti

agbegebe to se regi. Ise agbese na ni a so wipe ki o dojuko awon koko isoro to ndojuko itoju ilera ni awon
igberiko orile-ede Ghana. Lara awon isoro na ni inawo to ga, ona jijin, ise ti ko dara, aimosese ati aisi ilowosi awon eniyan agbegbe. Awon amoye gbagbo wipe eto CHFP ti yeje lori oro na. Awon alase ilera lati awon

orile-ede miran ti nse ibewo si ise agbese na lati keko lara re.
Ise agbese Navrongo na wa fun awon eniyan to to egberun lona okandinlogoje. Awon to si se inawo re ni Ajo
orile-ede Amerika fun idagbasoke kariaye (USAID) Ajo Amuludun Rockefeller (Rockefeller Foundation), ile-ise ilera ati Ajo Alakoso nipa iye eniyan ilu (Population Council).

Newslink Africa.

Idanileko Oniiforoweoro ngbero lati se idilowo ki ija ma sele lori oro iseda aye 57secs
Imo nipa awon ija kariaye to le yori lati inu awon oro iseda aye to ndinku ni o ti gba igbelaruge ni iha gusu Afirika, leyin idanileko oniiforoweoro kan lori pinpin oro ni osu kefa odun yi ni orile-ede Mozambique lati owo
ajo orile-ede Finland kan ti ko lowo ijoba ninu ti a mo si KUTI.
Nigbati o nsoro nibi sisi ayeye na, olotu Ile-Ise orile-ede fun ifowosowopo ti Ayika kilo nipa awon edekoyede
to le sele ni iha gusu Afirika lori ilo oro.

O so bayi: "Awon eto imulo ti orile-ede lori isakoso ati ilo oro omi to mu ogbon wa ni a gbodo se kokari re larin awon orile-ede to nlo won."

Opo ninu awon odo ile Afirika lo koja awon aala orile-ede, ti o si je pe won ma nse agbami nla si awon oke odo won ni opo igba.
Ero idanileko oniiforoweoro na ni lati se idilowo awon edekoyede lori ilo ati isakoso awon oro iseda aye ni ile Afirika. A se agbekale re ni ifowosowopo pelu Ajo Amuludun Eduard Mondlane (Eduard Mondlane
Foundation). Awon to kopa ninu re si wa lati awon orile-ede Angola, Botswana, Kenya, Malawi, Namibia, Zambia, Zimbabwe ati Finland
PANA.
Ipolongo ti bere lati se igbala awon oro omi mimo 59secs
Ipolongo kan lati se ipamo omi mimo ni agbaye ni ajo WWF bere re ni Apejo ipade nla keje ti Ramsar fun awon egbegbe to ni asepo ti o waye ni Costa Rica. Ipade na je ti awon orile-ede to ti ni adelun labe ofin lati

dabobo awon oro omi mimo ni abele won. Ipolongo ti Omi to wa Laaye na ni o ni ero lati yera fun aito omi ni agbaye ati ipamo awon eda abemi inu awon
odo, adagun orisun omi, ile ira ati awon ile olomi miran.
Gegebi oro ti Oludari-Agba fun ajo WWF, Claude Martin so: "Eyi ni ara awon ilowosi wa si ifokansi nla ti itoju ati ilo alagbero ti awon oro iseda aye." Eto na ni won se ifilo re ni ojo ketala osu karun larin ipade nla na to
waye lati ojo kewa si ikejidinlogun osu karun. Ajo WWF tun se ifilo igbeowosile fun ipolongo na nigbati o lo anfani awon ariyanjiyan gigun to waye lori awon idiwo lori owona ni ipade nla ti Ramsar na.
WWF. 5
5 Page 6 7
Radio
Vol II No7 June 1999 [Yoruba]

6
CHANGE
Iyipada Afefe Ile: Otito tabi Asodun? 36secs Idi awati awon ogun eya opolo mi orile-ede Costa Rica ni a ti da lori iyipada afefe ile. Isele na ti a se apejuwe
re wipe o runiloju, ni a royin re laipe yi ninu iwe iroyin atigbadegba ti a npe ni 'Science'. A soo mo ile gbigbe
juti atijo lo ninu igbo Monteverde to wa ni awon ile oke giga ni Costa Rica. Eyi ni oju ojo ti a mo si 'El Nino' to waye lodun to koja tun mu buru si.

Osise ajo awojutu si nkan ti o wa ni orile Amerika ti a mo si Ajo Awojutu si Idinku Iye awon Eda Abemi Jomijoke (Declining Amphibian Population Task Force), Micheal Lannoo ti se apejuwe isele iyipada na
gegebi idinku akoko ti eranko to da lori afefe ile ode oni. WWF.

Banki Agbaye se iranlowo fun orile-ede Afirika merin lati 56secs doju ija ko Idoti Epo Robi
Orile-ede Africa merin to wa lori okun kariaye ti India to si nfe lati dojuko didoti ti epo robi ndoti awon oju ona ori omi won ni o ti gba iranlowo lati odo Banki Agbaye. Banki na daba lati gbe owona sile fun eto agbegbe kan
lati dojuko idasile awon adalu-efin oloro-po-mo-isan-bi-omi (hydrocarbons) eyiti yio na won to milionu marun owo dola Amerika.

Ifitonileti yi waye leyin idanileko oniiforoweoro kan to bere ni ilu orile-ede Mauritius kan ti a npe wi Quatre-Bornes ni ojo kokanlelogun osu kefa, eyiti a pe lati jiroro lori ise agbese na eyiti o kan awon orile-ede Mauritius,
Comoros, Madagascar ati Seychelles.
Gegebi awon iroyin ti ro, ise agbese na lo je akoko iru eyi ti Ajo Akojo Owo fun Ayika Agbaye (Global
Environment Fund (GEF), to je alabasisepo Banki Agbaye, yio se inawo re.

Idanileko ifiornoweoro na soro lori iwe adehun kariaye meta to je mo owo itunu fun itudanu epo robi. Idameta gbogbo ogota milionu agba epo robi ti a nse lojojumo ni a ngbe koja lori okun kariaye ti India.
PANA.

Awon Apileko Oro
Orile-ede Cote d'Ivoire fi Imurasile re fun Ijanba epo robi han 1min. 29secs Ogororun awon omo orile-ede Cote d'Ivoire, lara eyiti a ti ri awon akoroyin bi melo kan, lo wo bi Ajo
Alakoso Ibudoko Oju Omi ti orile-ede Cote d'Ivoire ti fi imurasile re han ni ojo keje osu kefa lati kapa itudanu epo robi lori omi osa ti olu ilu re, Abidjan.

Ifihan na waye leyin ina to jo laipe yi ni ibudo epo kan ni Abidjan eyiti o ba Ajo Alakoso Ibudoko Oju Omi ti orile-ede Cote d'Ivoire labo. Awon alase pinnu lori afihan imurasile won na lati le fi okan awon olugbe Abidjan
ti isele na ko lominu bale.
Idaraya na ti Ibudo Igbejako-Idoti ti orile-ede Cote d'Ivoire se kokari re ni won se bi igba ti won ba nkoju
itudanu epo to to egberun lona ogbon iwon tonnu ninu omi osa na. Ajo oloko-owo aladani kan ti a mo si Pollumar, eyiti o mo nipa idilowo idoti omi na lowo si idaraya na. 6
6 Page 7 8
Radio
Vol II No 7 June 1999 [Yoruba]

7
CHANGE
Idaraya na lowo awon egbegbe awon panapana marun ti a lo papo lati se aseyori awon afokansi kan bi isele ijanba ayika to buru to iru re ba waye ninu. Lara awon ifokansi na ni iko awon arinrinajo afe kuro leti awon
etikun, eti ebute ati ile ise, idalowoko ibesile ina, didaduro ati fifa itudanu epo kuro, sise akojo epo ni ibudo, fifo
etikun mo ati ipese iranwo alakoko fun awon to ni ikolu.

Awon panapana metadinlogoji, egberun lona egbeta lita ihokusu olomi ati oko idankan-olomikan-pomo-omiran meta ni a se akojo won fun idaraya na.
Africa News on Line.

Ajo Oro Aje fun Ile Afirika nse eto fun Idagbaseke 1min. 18secs. Apakan ninu Ajo Oro Aje fun ile Afirika (Economic Commission for Africa (ECA) ni a ti gbe ise le lowo lati mu
ki idagbasoke alagbero mu oro aje awon orile-ede ile Afirika tete de nipa sise iwuri fun iresile ninu piposi awon olugbe. Eka na ti a mo si Eka ti Ifokanbale nipa Ounje ati Idagbasoke Alagbero (Food Security and Sustainable
Development Division (FSSDD) yio sise pelu awon ijoba lati "mu ilosoke iye awon eniyan ilu wa ni ibamu pelu agbara ile lati mu ounje to to jade."

Awon aseyori ni orile-ede kokan ni a kosile, bena ni ona ti won gba ni won o se imulo re biotiye jakejado ile aye na.
Itenumo ise na lo da lori idinku ngbara isabiyamo ni ile Afirika si iko meji pere ninu ogorun ki awon ebi le ma ni bi omo meji-meji lati bi marun si meje to je nisissiyi. A ti nri oye wipe agbara isabiyamo ti bere si lo sile ni
awon orile-ede bi melo kan. Iroyin laipe yi lati owo ajo ECA ntokasi wipe emi awon omo ile Afirika ti ngun si bi igbe aye won ti ndara sii. Ajo ECA ngbero lati teramo awon eto ifuninimo ati iparowa-fun, ati ikojo agbara
lati se aseyori idagbasoke alagbero ni ile Afirika. Economic Commission for Africa.

Ajo Agbaye fun Ounje ati Ise Ogbin nkilo nipa Aije ounje-to-dara-to 1min. 58secs.
O ju idamefa ninu awon olugbe aye ti irokeke aije-ounje-to-dara-to wa fun bi awon oko ipeja nla ni awon okun kariaye ni agbaye se npa eja lododun ju bi eja se nbisi lo. O ju adofa milionu iwon tonnu eja ti won npa
lododun. Sugbon ire alagbero ti eja lododun lati inu awon okun kariaye wa larin milionu tonnu mejilelogorin ati ogorun.

Awon orile-ede to sese ndagba ni irokeke yi koju si ju. Eja lo je orisun okun-ara fun iye to ju edegberunleladota milionu awon eniyan won. Sugbon sa, ifitonileti tuntun lati odo ajo FAO fihan wipe awon orile-ede to sese
ndagbasoke na nkopa ni lemelemo ninu owo kariaye ninu eja ati awon ohun ti a nfi eja se.
Ajo FAO woye bayi: "Bi ifiojaranse si ile okeere se npa owo ile okeere to niye lori pupo fun won, kiko eja ati
awon ohun ti a nfi eja se lati awon agbegbe ati ipinle to sese ndagba le du awon eniyan alaini ati awon omode ni ounje ibile ti ko won sugbon ti o ni eroja rere pupo ninu".

Igara lori awon okun kariaye ga nitori eyiti o poju ninu eja ti a nje lo nwa lati inu awon okun. Die pere lo nwa lati inu awon odo ati orisun omi mimo miran. Yato si eyi, awon eniyan ma nje eja ju okun ara eranko miran lo.
Awon isiro ti ajo FAO gbejade laipe yi fihan wipe o fere to ogbon milionu eniyan ti owo to nwole fun won wa lati inu ipeja, bena si ni opolopo owon orile-ede to sese ndagbasoke to gbarale eja nikan gegebi orisun okun- 7
7 Page 8 9
Radio
Vol II No7 June 1999 [Yoruba]

8
CHANGE
ara won. Awon ajo afenifere ayika ti se agbekale orisirisi ona lati fi yera fun idamu loro okun ara to nrodede. Awon ona na nro awon ijoba lati mu owo iderun kuro fun awon ajo oloko-owo to npeja Won tun nkepe fun

idasile awon agbegbe ti gbesele ipeja nibe nibiti a o gbe dabobo awon eja ibe gegebi idojutofo lori ipejaju nibomiran.
FAO.
Ajo Gbogbo Orile-ede Agbaye kepe fun iranlowo Ounje fun orile-ede Angola 2min. 10secs.
Ajo gbogbo orile-ede agbaye kepe laipe yi fun iranlowo ounje pajawiri lati ile okeere to to ogosan tonnu awon
oka lati fi ranse si orile-ede Angola lati le yera fun aijeounjetodarato ni opolopo agbegbe eyi to nrodede ni orile-ede ti ogun ti ja si wewe na.

Gegebi iroyin kan lati odo ajo UN ni osu kefa odun yi, egbegberun lona ogororun awon omo orile-ede Angola ni o dojuko ewu airiounjetodarato latari airi ounje, ilera ti ko dara ati aito imototo. Akojade na, eyiti Ajo
Agbaye fun Ounje ati Ise Ogbin (FAO) jo gbe jade pelu Ajo Agbaye fun Eto Ounje (World Food Programme (WFP) so wipe ogosan egberun tonnu oka na ni won yio ni lo larin osu mewa siwaju lati yera fun idaamu to
nrodede. Awon kan ti seleri egberun lona merindinlogota, o wa seku egberun lona merinlelogofa tonnu.
Akojade na so bayi: "O fere je wipe gbogbo agbegbe ni ija ti sele, sugbon awon ibiti oro na kan ju ni awon
agbegbe aringungbun ti won ti ngbin agbado."

Irinajo anu kan si orile-ede na ti awon ajo FAO ati WTP se lati lo fun won ni Irugbin ati Ounje kilo wipe owon ounje ni awon agbegbe yi yio buru si ni awon osu to nbo.

Ija to wa ni orile-ede Angola to bere lati odun 1975 leyin ti Egbe to Gbajumo fun Idande Angola (Popular Movement for the Liberation of Angola( MPLA) to je egbe oloselu gbogbo-wa-lajo-ni ti se agbekale ijoba
akoko leyin Ominira. Egbe Orile-ede fun Ominira Patapata fun Angola (The National Union for the Total Independence of Angola (UNITA), eyiti o ni atileyin orile-ede South Africa to je eleyameya ati awon ijoba
alagbara iwo-oorun aye se atako fun ijoba MPLA. Won fowo siwe adehun kan ni odun 1994. Awon apa
mejeji ni a gbo pe ko tele awon ilana re.

Akojade so wipe aisialafia latari ogun abele na ti din ile to wa fun ise ogbin ku, o si tun di awon eniyan lowo lati ma ba ise ogbin ti teletele lo.
IPS.
Awon Apileko Oro Pataki

Oro ti enikan so lori Itoju Iseda 18secs
"Eniyan ode oni, eyiti a ma nfi igbagbogbo kopo si awon ona tooro tabi ti a fi mu lati fokansi ati wa ni ibamu pelu ogunlogo oko to nrun to si npariwo ko lemi ireti, laisi igbaradi to le ati idanileko, lati je ohun miran ju eni

abuku ati ibaje loju oore aginju……………………………." Max Nichelson, Oludasile WWF Ti Ile Geesi.

Awon oluwadi nse ayewo awon ilana monomono 2mins. 36secs O fere to egberun merin eniyan ti monomono pa ti egberun mewa miran tun sese larin odun 1959 ati 1994.
Monomono mi owo imole nla to njade lojiji lati oju orun ni akoko iji pelu aara ni igba ojo. Oju ojo to banileru 8
8 Page 9 10
Radio
Vol II No 7 June 1999 [Yoruba]

9
CHANGE
yi tun nfa ibaje ti iye owo re to egberun marundinlogoji owo dola Amerika lododun.

Awon eniyan ti gbiyanju fun opolopo orundun seyin lati moye monomono ki won si lo agbara re. Ninu sise eyi eniyan se awari ina monomono. Laipe yi awon onimo ijinle sayensi pade ninu apero kan ni ilu Guntersville ni
Alabama lati se agbekale awari tuntun lori awon ilana monomono ni agbaye, lati le se afikun imo won lori bawo, nibo ati nigbawo ni monomono ma nja. Ajo orile-ede Amerika fun isakoso imo ijinle nipa irin-ajo oju ati
inu ofurufu (The United States National Aeronautics and Space Administration( NASA) ni o se onigbonwoipade na.

Ohun ti o je koko agbeyewo ninu ipade na ni ifitonileti nipa ilana monomono ni agbaye eyiti won gba lati ara awon ohun elo to fun mi ni iwo monomono lati oke kurukuru.
Hugh Christian ti ibudo fun Imo nipa Ipinkiri Omi ati Afefe ile ni Agbaye (Global Hydrology and Climate Centre) to wa ni ilu Huntsville, Alabama so bayi: a O dabi euipe monomono ni imolara si iyipada apere oju ojo
to nwaye lati odun de odun."
Gegebi awari won, monomono ma npo ninu awon iji lori ile ju lori awon okun. Nitoto, iko mejidinlogorun ninu ogorun gbogbo monomono lo nsele lori ile. Won ma nsele pupoju ni osan, won si ma nyato lati akoko kan si
eyito tele. Won tun ri iyato pupo ninu awon ilana monomono lori ile. Iyato die lo wa lori okun.
Christian so siwaju bayi: "A gbagbo wipe eyi sele latari wipe ile ma ngba ooru sara (o si ma ntu jade sinu afefe ni kiakia). Ni ida keji, omi le gba opo ooru sinu sugbon diedie lo ma ntu sita."

Awon onimo ijinle sayensi na tun royin wipe o dabi enipe monomono ma ntele oorun. Monomono ma nlo
siwaju siwaju si iha ariwa ila to da aye si meji gegebi akoko ooru ba ti ntesiwaju ni awon agbegbe ti afefe ile won ko gbona ju ni iha ariwa. Iru ilana bayi ni won tun woye re ni agbegbe olooru ni iha gusu, sugbon

monomono ko po nitori ko si ile nikoja awon ile olooru na.
Awon onimo ijinle sayensi nse atupale ifitonileti to fihan wipe iyipada ninu oju ojo ma nni ikolu lara awon ilana
monomono. Nitorina a ni ireti wipe o seese ki awon ilana monomono je ona kan lati fi se idiwon itesi oju ojo aye.

Environmental News Network.

Oro ti enikan so lori Idagbasoke 33secs "Ninu lilo lati ise iriju ti ko peye si eyi to dara lori ayika, gbogbo akitiyan eda eniyan ti a ko ba ti se ni ibamu pelu
iseda aye ko le ni agbero gegebi apejuwe fun ojo pipe. Opolopo awon orile-ede Afirika loni ni o dojuko isoro ayika to le eyiti o ni ikolu lara idagbasoke awujo ati oro aje. Awon oro to se pataki ju ni ipagborun, ibaje ile,
ibaje awon oro omi, ilo ile ati ko b'ogbon mu ati ipadanu ipinyeleyele eda abemi." Economic Community of Africa.

Eto Fun Awon Omode Ojo Omode Ile Afirika 1min. 7secs
Ojo omode ile Afirika ti odun yi, eyiti a se iranti re ni osu to koja jakejado aye kepe fun ifojusi si iwa-ipa ti osi
nfikolu awon obirin ati omode ile Afirika. Ojo na, ojo kerindinlogun osu kefa ni a ya soto ni odun 1976 leyin ipa ika ti a pa awon omo ile-eko ni orile-ede South Africa eleyameya. Awon omode na dide lati se iwode ni 9
9 Page 10 11
Radio
Vol II No7 June 1999 [Yoruba]

10
CHANGE
ilodi si iwa aito to sele ni Soweto to je ilu awon alawo dudu to tobi ju ni orile-ede na, ati ti ilana oloselu ika to ha awon omo ile Afirika mo to si nje gaba lori won.

Leyin odun merin ti a ti tu eleyameya pale, awon omo ile Afirika tesiwaju lati ma se iranti ojo na lati se iwuri fun
awon ijoba lati tun eje won si awon omode je, lati se agbero eto won ati lati se ipin awon oro fun itoju won. Akori oro fun odun yi "Iwa-ipa si awon omode ati irokeke itankale arun kogboogun HIV ati AIDS" nkepe fun

ifojusi si awon ikolu osi lori awon obirin ati omode latari awon atunto lile ti oro aje ti ati mu ile Afirika la koja lati owo awon ayani lowo won.
UNICEF/ IPS.

Idi ti kiniun ki ise je eso 2mins. 30secs Ni ojo kan ijakuno ti oruko re nje Bwawa se awari eso didun kan ti igi udara. Sugbon bi o ti joko nibe to
ngbadun ounje re, lo ba gbo ti kiniun bu ramuranu ni okeere. O ro ninu ara re: "O dabi enipe ebi npa kiniun. Mo lero wipe ko ni wa si ona ibiyi ko wa ri awon eso mi daradara yi." O beresi kominu, nitoripe kinum, gegebi
gbogbo eniyan se mo, le jeun pupo, bi o si ti je oba awon eranko, o ni eto lati ji ounje enikeni.
Kiniun ko wa si itosi, sugbon ijakumo ologbon ewe ti ronu etan kan ti yio da kinium duro lati ma je eso udara re. Bi kinium se sunmo itosi, Bwawa beresi yara je eso na bi o ti le se to, o si ri wipe kinium nwo on bi on se
nhu iwa okanjuwa yi. Lojiji Bwawa subu lule o si beresi yira, o kerora, o wa duro rigidi bi eniti ku. Kiniun, nitori eyi, ro wipe eso na gbodo je majele, nitorina o ba ona tire lo, o si wa lo jinna. Nigbati Bwawa dide, o
ranti ibikan ti on ti ri oku ijakumo miran ti o wa nitosi. Nitorina o lo wa o si gbe si ibiti on ti dibon iku labe igi udara na. Inu re dun si etan re yi o si lo sile.

Ose bi melo kan leyin eyi kinium koja o ri igi udara ti eso po lori re. O rin lo si ibi igi na sugbon o duro nigbati o ri oku ije kumo kan to ti jera. Awon jokujoku ti tu egungun re ka. Kiniun ranti wipe on ri Bwawa to nje eso
igi udara na. O bura funrare wipe on ko ni fowokan eso mo lae.
Lati ojo na kiniun ko je eso igi udara na, tabi eso igi miran paapa. Eyi mu ki inu ijakumo ati awon eranko kekeke inu igbo dun pupo. Nisisiyi won le je iye eso ti won bafe lai pin pelu kininu to njeun repete.
When Hippo Was Hairy.
Bawo ni awon Labalaba se njeum? 22secs Awon labalaba ma nfa oje aladun mu lati inu itanna. Ounje won ni eyi. Won ni enu to s'ajeji bi pali gbooro

oniho ti a ma fi mu nkan, enu yi si ma nkajo labe ori won. Bi o ba rora wo labalaba kan finnifinni, wa ri i. Awon labalaba je erauko to rewa to ni apa nla to si ni awo orisirisi.
Chongololo

Igi wo lo tobi ju ni aye? 1min. 24secs. Igi ti o tobi ju ni aye na lo je ohun elemi to tobi ju laye. Igi nla sequoia kan ti a pe ni 'General Sherman', o si nhu
ni iha ariwa ile Amerika ati awon orile-ede Amerika ati Canada. O ga ni iwon 'metre' merinlelogun ni iyika. Wa a le fojuwo bi o se tobi to ti o ba le jeki awon omo ile-eko merindinlogun fowosowopo ninu iyika nla kan.
Iyika yen lo fihan bi o ti tobi to. Nje o le gbagbo?.
Ti o ba fe wo bi o ti ri lori igi na, wa nilati duro lori aja kokanlelogbon ile alajapupo ti a ba ko segbe re. Iwuwo re ni a ro wipe o to ogorun tonnu. Eyi wa ni ibamu pelu iwuwo egberun erin ile Afirika to ti dagba tan. tabi ti
iwuwo egbegberun lona edegbefa omo ile-eko. 10
10 Page 11 12
Radio
Vol II No 7 June 1999 [Yoruba]

11
CHANGE
Ti a ba ge General Sherman lule yio se to bilionu marun igi isana. Sugbon sa, nje o le gbagbo wipe General Sherman ko ni igi to ga ju laye? O ti o, on ko. Igi sequoia ti Amerika miran ga ju General Sherman lo. O ju
adofa 'metres' lo ni gigun. Chongololo.

Oro Nipa Awon Obirin
Ajo Unicef nro awon orile-ede ayanilowo lati fagile awon gbese ile Afirika 1min. 46secs
Iyaafin Parole Bellany to je Oludari Alase fun Ajo Akojo Owo Pajawiri ti Apapo Orile-ede Agbaye fun awon Omode (United Nations International Children Emergency Fund (UNICEF) ti ke si egbe awon orile-ede mejo
to ni awon ile ise to po ju lo ni agbaye ti a mo si G8 lati se atunyewo gbese awon orile-ede ile Afirika. O ni ajaga na ndu awon obirin ati omode ile Afirica ni eto abinibi won. Gegebi oro re nigba iranti ojo awon omode
ile Afirika l'osu to koja: "ki ise ohun ti a bojumu mo ni o ku die ki egberun odun miran tun wole de, wipe ogogorun milionu eniyan ni o wa ninu igbekun gbese si awon orile-ede olowo."

Iha isale asale Sahara nje owo to ju igba bilionu (milionu lona milionu) owo dola Amerika lo si awon ijoba ati awon ajo ni pupo awon orile-ede G8 wonyi Britain, Canada, France, Germany, Itali, Japan, Russia ati America.
Itiraka kariaye fun awon orile-ede ti o talaka ti o je gbese nlanla (The International Heavily Indebted Poor Country (HIP) Initiative) eyiti a dasile ni odun 1996 lati pese iderun fun awon orle-ede mokanlelogoji to kuuse
julo, lara eyiti orile-ede Naijiria wa, ni o ti fori sonpon, gegebi oro to iyaafin Bellamy so.
Abayade eyi buru fun ile Afirika. Iku awon omode fi idameta ga ju ti awon ekun miran ni aye lo, won si nlo ilopo mefa owo ti won fi npese eko fun awon omode ekun na to to odunrun milionu (egberun lona egberun) lati
fi san gbese, okan ninu meta awon omo na ni ko gba abere ajesara, idaji awon olugbe ni ko kawe rara, besi ni okan ninu omode mefa to nsise jakejado aye lo je omo ile Afirika.
Gegebi oro Bellamy: "Ko si orile-ede to le de ibi afokansi ninu idagbasoke re nigbati eyiti o papoju ninu awon eniyan re ba nyiya labe osi to ga eyiti o dojuko awon milionu milionu eniyan ninu aye loni"
LPS.
Spirulina: Ewedo Iyanu 2mins. 39secs
Idagbasoke ewedo ninu awon adagun kekeke, odo nla ati kekeke tabi adagun nla le je aami idoti, nigbapupo ni a si ma npa won. Sugbon ni opolopo agbegbe ni aye, eya ewedo kan ti a mo si Spirulina eyiti a ma ngbin ni

ehinkule eni, je iriri to bojumu fun awon eniyan ti ko ri ounje to dara to je.
A le se ni tutu ki a si je bi eran, tabi ki a sa gbe ki a si lo gegebi afikun ounje ninu obe, asaro tabi awon ohun
mimu. Spirulina ti o ti gbe a ma dabi iyefun, a si ma run bi eja gbigbe. Sugbon o ma npadanu oorun na migbati a ba fi kun ounje. O si tun ma nyi awo ounje pada si awo ewe.

Spirulina je ewedo alawo ewe ti a ngbin ti a si nje jakejado aye gegebi orisun okun-ara pipe. Gegebi atejade kan laipe yi ti iwe iroyin atigbadegba Intermediate Technology, spirulina je orisun okun-ara to po julo ti o han
si eda eniyan. O fere je gbogbo ara re ni okun-ara, o si tun ni opolopo awon eroja kosemani to a mo si amino acid. O tun kun fun awon eroja vitamin ati agbara inu eje lara eyiti ati ri awon vitamin ti a mo si A, B12 ati E, 11
11 Page 12 13
Radio
Vol II No7 June 1999 [Yoruba]

12
CHANGE
bena mi o si tun wulo gegebi egbogi, o si munadoko lati fi gbejako awon ikolu, awon arun awo ara, aito eje ninu ara ati awon arun okan ati ti ilana ironu ninu ara.

Iroyin to daraju fun awon iya ni wipe awon iwulo re gegebi ounje to peye ni a ti ri idaniloju re ninu awon eto
bibo awon omode ti ko ri ounje to dara to je ni ile India ati Afirika. Awon oko ogbin spirulina si wa ni awon orile-ede Democratic Republic of Congo, Benin Republic, Burkina Faso, ati Central African Republic.

Spirulina ki ise orisun ounje tuntun. O ti wa fun opolopo orundun, awon iran iran ni ile Afirika, Amerika ati Asia lo si ti loo. Biotilejepe awon onimo ijinle sayensi sese se awari re ni odun 1939 ni, a ti nlo o ni opolopo orile-ede
lara eyiti a ti ri Chad, India, China, Japan ati Mexico.
A le gbin spirulina lehinkule ninu adagun ti omi re ko le gbe ti o si ni iyo, ti o si fe to iwon nita mewa ni igun mererin reti o si jinle to iko meji ninu meta ese bata kan. Awon ilana to rorun lo wa fun rirolu adagun na
lorekore, bibo awon eroja inu re ati mimu wa ni igbonatutu to loworo, ati lile awon kokoro sa nigbati a ba jeki
o siju si oorun. Fun ifitomileti si, kowe si olotu, Change Radio, P. O. Box 56283, Falomo, Ikoyi, Lagos, Nigeria.

Intermediate Technology.

Awon obirin ni orile-ede Bangladesh nparowa lati wa ni dogbandoga pelu awon okunrin. 2mins. 46secs
Awon ajijagbara fun eto awon obirin nparowa fun ijoba won ni lemolemo fun ilana ofin to farajo ti orile-ede Naijiria nipa oro eto ijogun. Sugbon ijoba won nte jeje, won nsora lati ma se si igbagbo awon olugbe to poju
to je musulumi ati awon olugbe to je Hindu.
Awon egbe ogbirin nbere fun eto dogbandogba si ohun ini ati ofin imulo to dogba lati fun awon obirin ni eto
kanna si ohun ini, igbeyawo, ikosile ati itoju awon omode.

Orile-ede Bangladesh si nse agbero ofin esin lori ijogun eyiti o fun omo obirin ni idaji pere ipin ini to to si okunrun, tabi ko ma gba nkakan rara.

Sugbon amofin pataki kan Salma Khan, to je alaga igbimo ti Adehun ti gbogbo orile-ede agbaye lori imukuro gbogbo ifi-iyato-si awon obirin (United Nations Convention on the Elimination of all form of Discrimination
against Women (CEDAW) gbagbo wipe fifi oro ijogun sabe awon ile ejo ti gbogbo ara ilu le se ayipada asa na ni ibaramu fun awon obirin. O toka si apeere Naijiria, Egypt, ati Tunisia gegebi awon orile-ede ti ile ejo ti
gbogbo ara ilu ti se aridaju iwani-dogbandogba awon obirun pelu awon okunrin ninu oro ijogun. Awon ajafuneto
eniyan tun se itose awon orisi iyanisoto nipa eya ni orile-ede Bangladesh si esin, won si fi esun kan wipe iyanisoto ti di baraku ninu awujo.

Fun apere, awon olori esin ma nse adura ninu mosalasi nigbati won ba bi omo okunrin. nigbati awon ebi ma nsofo nigbati won ba bi omo obirin. Iya re si ma ntesiwaju titi ojo aye re leyin na. Iwadi fihan wipe obirun osise
ninu oko a ma gba owo to kere ju idaji ohun ti elegbe re lokunrin ngba. Awon obirin si ma nfi ogun wakati sise ju awon okunrin lo larin ose kan, gegebi iwadi ti Ajo iwadi ti orile-ede Bangladesh lori eko nipa Idagbasoke
(Bangladesh Institute of Development Studies (BIDS) se. 12
12 Page 13 14
Radio
Vol II No 7 June 1999 [Yoruba]

13
CHANGE
Unicef na ti ri wipe awon omokunrin ni orile-ede Bangladesh to kuro ni ile iwe laipari eko won ki ise ise ile ju fun bi iseju mejila lo lojumo nigbati elegbe won lobirin ma nsise ile fun wakati marun lojumo.

Awon obirin ajafuneto eniyan na gbagbo wipe o sese ki won tun ofin orile-ede Bangladesh se laise si imo awon
eniyan lori esin. Ni osu to koja, alase orile-ede na fun oro ofin, Abdul Matin Khasru gba, o si so wipe ijoba on ti duro lati gbe igbese lati se eto fun awon obirin.

O fikun oro re wipe: "sugbon ko sese fun ijoba oloselu lati gbe igbese to le pa igbagbo awon elesin lara." Ogbeni Khasru so wipe lakoko awon eniyan gbodo gbaradi lati gba iyipada ki a to le se ipinnu lori re.
LPS.
Awon Otito To Wulo Ni Arowoto Eranko wo ni o ni eya to poju? 36secs

Nje o mo wipe o ju eya milionu kan lo ti orisirisi kokoro ti o wa laye?. Eyi ju ti gbogbo eya awon eranko toku lo ni apapo won. Awon kokoro kan le se ohun to yanilenu. Fun apeere, eegbon le fo ni ilopo igba gigun ara
re. Efon le mu eje to wuwo to on funrare ninu ounje ekansoso. Eya esinsin kan tile wa ni California ni orile-ede Amerika to ngbe to si nbisi ninu epo robi.
Chongololo.

Idaniloro Arun Kogbogun AIDS ni ile Afirika 40secs Biiko merin ninu marun ibusun ni awon ile itoju alaisan ni awon to ni arun Igbasara awon Eroja nba Agbara
Igbogunti-arun inu ago ara je ti a mo si arun kogboogun AIDS (Acquired Immune Deficiency Syndrome (AIDS). Eyi ni a mo lati inu awon akojade kan lati owo UNICEF, eyiti o ya aworan to derubani lori isenilese
arun AIDS ni ile Afirika. Oro na buru ni iha ila-orun ile Afirika. Ni orile-ede Kenya nikan oju egberun lona
egbeta awon omode lo ti o ti di omo orukan latari itankale arun na ti o ti pa eniyan bi ojilerugba egberun laipe yi. Iye yi yio lo soke nigbati yio ba fi di opin odun yi bi a ba fiyesi asotele bi igba egberun iku agbalagba si i.

UNICEF/ LPS.

Iroyin to peye lori ijerisi Igbo 17secs. Oju iwon ile lektari egberun merindinlogun igbo lo jakejado aye ti a se ijerisi re lati owo Igbimo Ise Iriju Igbo
(Forest Stewardship Council) eyiti a o si ma se akoso re ni awon ona ti yio jeki o duro daada ninu owo aje ti yio jeki o ni anfani fun awujo ki o si se deede pelu ayika.
WWF.
Imorusi Agbaye: Ilosoke Ooru ni orile-ede India 27secs
O ju edegbeje eniyan lo to padanu emi won ni awon ibi pupo ni orile-ede India latari ilosoke ooru to buru pupo kan eyiti o ja jakejado orile-ede na. Awon awoju ojo tun ti nse akosile iru itesi kanna lodun yi gegebi igbonatutu

afefe tun ti nga lo soke. Awon amoye afefe ile ti kilo wipe awon wonyi ni ifarahan to tete nyoju ninu imorusi agbaye, sugbon ijoba orile-ede na nlu oro na nile.
Down to Earth.

Itolesese Ijiya Eda Eniyan 27secs Orile-ede iha gusu Afirika to i a mo si Angola wa lara okan ninu awon to wa lori akaso to lo sile julo lagbaye
ninu idagbasoke. O ju idaneta ninu awon olugbe re to fere to milionu mesan eniyan ti o ti ni isipopada tabi ikolu to buru lati inu ogun olodun medogbon re. O ju idaji lo ninu awon olugbe re ti ko mo igbe aye miran ju ogun lo!
LPS. 13
13 Page 14 15
Radio
Vol II No7 June 1999 [Yoruba]

14
CHANGE
Awon Oludoti Baraku 21secs Awon osise inu oko oju omi agbepo to ndi eru soko ni okun Mediterranean ti mu iwa ki won ma gba awon aye
ikerusi inu oko won lori okun. Iwadi fihan wipe won ma nda epo robi to wuwo to egbeta egberun si edegberin egberun tonnu sinu okun Mediterreanean lododun nitosi etikun ti okun kariaye ti Atlantic ni iwo – oorun ile
Afirika. WWF.

Egbe Agbaye fun Ifagile Gbese 26secs Lati odun 1996 ni orisirisi egbe ti dide to parowa fun ifagile gbese fun awon orile-ede to talaka ti o ba di odun
2000. Ajosepo Odun Idasile 2000 (Jubilee 2000 Coalition) lara eyiti a ti ri awon ajo elesin, awon ajo ti ko lowo ijoba ninu, awon egbe osise, awon ajo ati eniyan afenifere ni o gbajumo julo. Lara awon omo ile Afirika
to je omo egbe yi ni a ti ri Nelson Mandela, Archbishop Desmond Tutu, Aare Jerry Rawlings ti orile-ede
Ghana, ati afenifere ayika kan ni Kenya, Wangari Maathai. LPS.

Diduro de Ijanba lati sele 30secs. O ju edegbeta milionu tonnu epo robi to nlo si ile alawo funfun Europe, Asia ati iha ariwa Amerika ti a ngbe
koja lojojumo la aarin awon orile-ede Afirika kan to wa lori okun kariaye ti India. Igbokegbodo yi lo mu iye to ju edegbaata irinajo awon oko oju omi nla agbepo waye lododun ninu awon omi to wa leba awon orile-ede
Comoros ati Madagascar ati la arin awon erekusu Aldabra ni ekun na, ilana ilolupo eda abemi ti omi to gbelege ti a si ti so di Ibudo Ajogunba Aye.
PANA 14
14 Page 15
Radio
Vol II No 7 June 1999 [Yoruba]

15
CHANGE
Ayewo Oro To S'ajeji

SEQUIA -Akojopo igi kan ti a mo ni ede geesi si 'conifer' igi nla California tabi igi rapata ati igi pupa.

Awon Ageso Oruko
AIDS -Igbasara awon Eroja to nba Agbara Igbogunti-arun inu ago-ara je
ti a mo si Arun kogboogun AIDS. BIDS -Ajo Iwadi ti orile-ede Bangladesh lori eko nipa idagbasoke

CEDAW -Adehun ti gbogbo orile-ede Agbaye lori Imukuro gbogbo Ifi-iyato-si awon obirin.
CHFP -Ise Agbese lori Ilera ati Iseto Ebi ni Agbegbe.
ECA -Ajo Oro Aje fun ile Afirika FAO -Ajo Agbaye fun Ounje ati Ise Ogbin

FSSDD -Eka ti ifokanbale lori Ounje ati Idagbasoke Alagbero. G8 -Egbe awon orile-ede mejo to ni awon ile ise ise-nkan-jade to poju
Lo ni agbaye
GEF -Ajo Akojo Owo fun Ayika Agbaye HIP -Agbekale kariaye fun awon orile-ede to talaka to si je gbese nlanla.

IFBWW -Ajo alasepo ti kariaye fun awon osise Ikole ati igi. MPLA -Egbe to Gbajumo fun Idande Angola
NASA -Ajo orile-ede Amerika fun isakoso imo ijiule nipa irin-ajo oju ati
inu ofurufu UNDP -Ajo Apapo awon orile-ede Agbaye fun Idagbasoke

UNICEF -Ajo Akojo Owo pajawiri ti Apapo orile-ede Agbaye fun awon Omode
UNITA -Egbe Apapo orile-ede fun Ominira Patapata fun orile-ede Angola.
USAID -Ajo orile-ede Amerika fun Idagbasoke kariaye. USD -Owo Dola Amerika

WFP -Ajo Agbaye fun Eto Ounje WWF -Ajo Akojo Owo ni Agbaye fun Iseda Aye. 15

Page Navigation Panel

1 2 3 4 5 6 7 8 9
10 11 12 13 14 15

 

© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw