Go Back
Communicating for Change

Document Body Page Navigation Panel

Pages 1--15


Page 1 2
Vol II No. 11
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

1
Idagbasoke Akoko Oju Ewe
ORO AJE
Ohun ti a nfe: Eto Imulo Oro Aje to dara, ki ise Iraanlowo 1min 53 secs 5 Awon orile -ede to sese ndagbasoke to nwa owo iranlowo

le ri pe o soro pupo si i lati ri owo gba lati ile okeere fun idagbasoke.
Nje ohun to dara ni Inawo Ijoba 2 mins 8 secs 3 Inawo ijoba ni awon oro aje to sese ndagbasoke nmu iroyin buburu ba

Idagbasoke oro aje.
Ila-oorun gba Iranlowo ju Gusu lo laarin odun mewa to koja 2 mins 26secs 4 Ariyanjiyan lori talo gba iranlowo to poju ni ewadun yi ni a ti yanju

AWON OBIRIN
Odun marun leyin Beijing 1min 38secs 13 Awon obinrin tun ke gbajare si awon ijoba lati fi ifaramo won han si

Ifiopinsi iyasoto nipa ti eya.
Olu Ilu Ifiipabaobirin lopo ni Agbaye 1min 31 secs 14 Orile-ede South Africa lo gba oye abuku ti olu ilu ifiipabaobirin

lopo ni agbaye.
Iwa-ipa si awon obirin Kakiri aye 1min 26secs 14 Awon iroyin to banilokanje nipa iwa-ipa si awon obirin ni awon

orile-ede miran ni aye.
AWON OSISE
Awon osise ni orile-ede Mali gba Ekunwo owo oya 3mins 30secs 8 Awon osise ni orile ede Mali jade kuro ninu akoko idasesile pelu awon

eto rere lati odo Ijoba.
AWUJO EDA ENIYAN
Awon Ajo ti ko lowo Ijoba ninu nja fun iwalaye won ni
orile -ede Sri Lanka 2mins 17secs 13
Awon ajo ti lowo ijoba ninu tako itiraka ijoba lati fi won sinu ide

labe itanje wipe won nfe dena iwa ibaje.

Ayika ITOJU
Oro ti Enikan so lori Itoju 15secs 12 Ainiimo ati Aibikita nmu irokeke ewu ba aye adanida
Orile-ede Madgascar se ifilole ogba Egan orile-ede Titun 3mins 11 secs 9 Andringitra ni iha ila-oorun gusu Madagascar to wani imurasile fun
awon onirin-ajo afe.
Awon Aworan Iseda Aye to tayo lati inu tite ero afowote ti ori Ero Asisebi opolo Komputa 1 min 30 secs 3

Nisisiyi o le ri okan ninu awon akojopo awon aworan iseda aye to
wuni lori julo lori Itakanle Ero Asisebi opolo Komputa ti ori
eroibani soro ni Agbaye.
1
1 Page 2 3
Vol II No. 12
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

2
Gedu gige lona ti ko bofin mu nmu irokeke ewu ba awon igbo
orile-ede Tanzania 2mins 19secs 6
Sare hektari milionu metalelogbon ti igbo ayebaye ti orile ede Tanzania ni

o wa labe ewu to nga si
IDOTI ATI EGBIN
Orile-ede Phillipines nwa awon ona titun fun dida egbin nu 2mins 13secs 5 Nitipatikuku ni Ilu manila fi nwa awon ona titun lati fi se itojuegbin bi awon

Ibi idaegbinsi ti won nlo tele ti nkun lo.
EDA ABEMI EGAN
Idinku onrikiakia deba Ipeja ni orile-ede Ghana 4 mins 7 Ibaraenidije ati idarasi ninu awon ona ipeja ti nyara din akojopo

eja orile-ede Ghana ku.
Awon Epo lile nmu irokeke ewu ba awon Ile onikoriko ti ila
oorun Ile Afirika 2mins 12secs 7
Epo buburu kan ti ko tete fi ara han be ti di eemo ni ile onikoriko ti iha

ila-oorun ile Afirika.

Eto Awon Omode

Awon Igba Aye Isode Efon 5mins 10secs 10 Okanjuwa mu ki Efon gbe ade ori re bi Oba awon Eranko fun kiniun
Abe felefele ti Asa 2mins 7secs 12 Akuko ati Asa je ore timotimo tele sugbon abe felefele kan to sonu tu won ka
Idi ati bawo ni awon Akoko se ngbe iho sara igi gbigbe? 1min 2secs 11 Pade eye to ngbe iho sara oku igi fun ile gbigbe
Bawo ni Agbanrere se ndabobo ara re kuro lowo awon ota? 1min 11secs 12 Ota agbanrere to buruju ni eda eniyan 2
2 Page 3 4
Vol II No. 11
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

3
Iroyin
Nje ohun ti o dara ni Inawo Ijoba? 2mins 8 secs
O le je ohun iyanu fun opolopo omo ile Afirika lati mo wipe inawo ijoba ko dara fun idagbasoke oro aje. Iwadi

eyiti Ajo fun Iwadi nipa Idagbasoke (Development Studies Association-DSA) to ni ile ise re ni ile Geesi gbe
owo kale fun ti fihan wipe inawo ijoba fun awon ohun ti ko se nkan jade tabi fun nkan ilo "ni ikolu ti ko dara lori
idagbasoke oro aje" Eyi ri be paapa ni orile-ede bi Naijiria nibiti akitiyan oko-owo ti da lori ise ririgba lati odo
ijoba. Ise gbigba a ma mu iwuri wa fun kiko awon irin-ise, ohunelo imoye wole lati se awon ise na. Besi ni
awon oro aje na ko ni ipile ise-nkan-jade to ga.

Iwadi si ikolu inawo ijoba ni won se ni orile-ede Tanzania, to je awokose orile-ede to sese ndagba soke to nja fitafita laarin opolopo awon isoro nlanla bi ilosoke ireti awon ara ilu laarin oro ti ko to nkan. Lara awon
abajade ni wipe "i nawo ijoba ni awon orile-ede to sese ndagbasoke, ni opolopo igba, ma nyorisi inawo to ju iye owo to wole lo ati idagbasoke ti ko yara lo soke"

Iwadi na tun ri wipe idinku ninu inawo ijoba yio yorisi ilosoke idagbasoke oro aje.
Iwadi na ri wipe orisi inawo ijoba meta pataki lo wa ni orile-ede to sese ndagbasoke, awon ni inawo to mu nkan jade tabi inawo lori idoko-owo, inawo ti ko mu nkan jade tabi inawo jeujeun ati inawo lori idagbasoke
eda eniyan.
Inawo lori idoko-owo ni won ri wipe o ni ikolu ti ko dara lori awon oro aje to sese ndagbasoke ni gbogbo igba.
Eyi je iyalenu nitoripe iru inawo yi ye ko yorisi idagbasoke oro aje. Inawo jeunjeun tun nre idagbasoke oro aje sile sii. Sugbon sa, inawo lori idagbasoke eda eniyan lara eyiti inawo lori ilera ati eko wa yorisi idagbasoke oro

aje.
Lati se iwuri fun idagbasoke oro aje, won gba awon ijoba awon orile-ede to sese ndagbasoke niyanju lati se
afikun inawo won lori imudarasi eko ati ilera. Inawo lori idoko-owo awon aladani ati akitiyan ise aje ni won gbodo tun se iwuri fun. Leyin awon iyipada titun ninu eto imulo yi won gbodo se ipolongo fun ayika to dara lati

se okunfa iranlowo ati idoko-owo lati ile okeere. ID21/ Obasi Ogbonnaya

Awon Aworan Iseda Aye to tayo lati inu tite ero afowote ti ori
Ero Asisebiopolo Komputa 1min 30secs
O ju egberun mewa awon aworan iseda aye to tayo -o seese ko je akojopo to tobi to si tayo julo ni agbaye
-ti yio to wa fun gbogbo eniyan nibikibi ni agbaye loju tite botini. Awon to se agbodegba eto yi ni ajo WWF
-Ajo itoju iseda aye ni kariaye -ati ajo Canon, awon oluta awon ile-ise ati awon ohun elo iriran.

Ninu ayeye pataki kan ti won se ninu Ipate Iwe to waye ni Frankfurt ni ojo kedogun osu kewa awon ajo mejeji
se ifilole ohun ti won pe ni akanse akojopo aworan ayika ori-afefe. Awon akojopo na ni yio wa ni arowoto awon ara ilu lati ori Eto Itankale Ero Asisebiopolo komputa lori Ero Ibani soro ni agbaye ti a mo si' Internet'

nigbati yio bi fi di idaji odun 2000. 3
3 Page 4 5
Vol II No. 12
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

4
Sugbon itankale kakiri agbaye ti Ajo Itoju Iseda Aye na le lo itankale ibani soro ti abe-ile kan ti a mo si 'Intranet'lati fi gba awon aworan fun ise Idanileko ati ipolongo. Akojopo aworan na ni egbegberun awon
aworan iseda aye ti a ti ya lati odun 1964 lati owo awon edegbeta ayaworan kakiri aye. Akojade kan fun
awon oniroyin lori akojopo na so wipe eyi je tente ori apata yinyin. Nisisiyi won ti nse agbekale awon oro apileko alaworan lori awon ipolongo ati ise agbese lori itoju awon ekun ilolupo eda abemi ati awon eya to wa

ninu ewu iparun.
Gegebi akojade na se so: "Eyi yio se afikun ipa titun si awon ise ti ajo WWF ti nse nisisiyi fun awon osise ile-ise
igboraeniye kakiri aye." WWF

Ila oorun gba Iranlowo ju Gusu lo laarin odun mewa to koja Ifoiya wipe oro iranlowo si kuro ni ile Afirika ati awon orile-ede miran to sese ndagbasoke lo si iha ila-oorun
ile alawo funfun Europe leyin ti orile-ede Soviet Union ti wo pale ni ati mo gegebi otito. Ijerisi yi wa ni bi odun mewa leyin ti awon orile-ede Afirika ti ke gbajare lori oro na eyi ti awon orile-ede iwo-oorun to ti dagbasoke
so wipe ki ise otito.

Ijerisi na wa ninu akosile iwadi kan ti a gbejade ni ipade olododun ti odun 1999 ti Ajo fun Iwadi nipa Idagbasoke
ti orile-ede U. K (United Kingdom Development Studies Association -DSA). Akosile na se itupale awon
iyipada pataki ninu owo iranlowo fun idagbasoke ti awon orile-ede to je omo egbe Ajo fun Ifowosowopo ati
Idagbasoke lori oro aje (Organisation for Economic Co-operation and Development (OECD) pin lati odun
1990 di akoko yi. O so wipe idinku wa ninu iranlowo fun idagbasoke lati owo awon ijoba (Official Development
Aid-ODA) si iha gusu nigbati ifojusi si lo si iha ila oorun laarin akoko na, ati wipe OECD ko mo eyi nitori awon
iyipada to waye ninu itumo ti OECD fun iranlowo fun idagbasoke lati owo awon ijoba.

(Awon orile-ede aye to sese ndagbasoke ni won tokasi gegebi iha gusu nitoripe opolopo won lo wa labe ila to da aiye si meji ti a mo si equator.

"Awon akosile ti OECD funrarawon fun odun 1990 si 1994 faramo ero wipe ko si isikuro oro lo si iha ila -oorun Europe sugbon wipe afikun ni iranlowo si iha ila-oorun je, sugbon ayewo finnifinni fihan wipe iyipada
ninu ifitonileti ati ikosile ipinwo nse igbelaruge ofo si iye owo iranlowo, o si nfi itokasi isikuro iranlowo owo lati ile Afirika lo si ila-oorun Europe, ati idinku iye iranlowo to lo si ile Afirika pamo." Ajo fun iwadi nipa Idagbasoke
tanmo awon ojuutu be melo kan si isoro na, lara eyiti a ti ri.
? Iyasoto owo iranlowo ti won na lori wiwa ojuutu si "awon isoro agbaye to kari gbogbo eniyan kuro lara awon ti won na lori awon ifokansi idagbasoke orile-ede.

? Ni ida keji OECD le yi isapejuwe iranlowo fun idagbasoke pada ni ona ti yio fi mu owo ti won fun ni
lati wa ojuutu si awon isoro agbaye to kan gbogbo eniyan wa sinu re; ati

? Gbigba awon ayewe owo wo aladani lati ye iwe owo agbowosile ati awon orile-ede to gba owo wo dipo ti awon agbowosile fi nse funrarawon.
DSA 4
4 Page 5 6
Vol II No. 11
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

5
Orile -ede Phillipines nwa awon ona titun fun dida egbin nu 2mins 13 secs
Ilu-nla Manila to je olu-ilu orile-ede Phillipines ni ila oorun gusu ile Asia, ti gbe ofin kan jade lati wa ona to ba

ayika mu lati fi da egbin to nwa lati inu awon ojule ilu na nu.

Ofin na kan nipa fun gbogbo awon to nlo nkan egbin lati ya awon egbin won soto sinu awon apo olora merin
to ni awo otooto. Awo elewe fun awon egbin ti ko ni kemikali ninu, awo dudu fun awon egbin to le jera, awo pupa fun egbin to loro to si lewu ati alawo ofefe fun egbin to je mo egbogi to le ran eniyan.

Teletele, gbogbo awon egbin wonyi ni won nko pupo ti won si nda si awon ibudo idalenu ilu na. Igbese titun yi waye bi awon ibudo idalenu ilu Manila ti nkun lo ti yio si di titi pa. Awon ibudo idalenu miran ni won ko iti ri.
Awon osise ajo Idagbasoke fun Ilu Manila beresi lo ofin lati se akoso idaegbinnu lati le yera fun idaamu egbin to nfe bo won mole.

Awon alariwisi ti bu enu ate lu ofin titun na wipe o ti pe ju o si mu ifoiya ati isoretinu wa. Nwon so wipe won ko iti se afihan awon ona ti won o ma fi da awon orisirisi egbin na nu. Ilu Manila nlo jijonina ati dida si ibudo
idalenu lati fi se akoso awon egbin re sugbon won ngbero lati ma lo awon ile ijolenina re mo lati odun 2003, ki o si wa da awon ile ise isoegbindiajile sile fun awon egbin re ti ko ni kemikali ninu.

Awon isoro miran to le yoju ni iye ti awon onile yio ma fi ra awon apo alawo orisirisi na (bi owo dola Amerika kan fun ogun apo), aiki tete wa ko awon egbin ati ijiya to le fun kiko awon apo egbin jade ki oko ikoledanu to
de. Awon owo itanran lo lati owo dola Amerika medogbon si ewon osu mefa ati ise fun agbegbe.
Pelu gbogbo isoro yi, awon olugbe gbagbo wipe o ye ki ofin yi ti wa tipe. Won nireti wipe yio se iwuri fun ikopada, itunlo ati isodiajile opolopo awon egbin to wa ni ibudo idalenu. O sese ki awon orile-ede die ni ile
Afirika ma woye isele to waye ninu isakoso egbin ni ilu Manila yi fun awon oye titun to se mulo ni ile Afirika. UNEP

Ohun ti a nfe: Eto Imulo Oro Aje to dara, ki ise iranlowo 1min 53secs Awon orile-ede to sese ndagbasoke yio ni isoro lati ri owo iranlowo lati ile okeere lati fi se igbelaruge awon eto
idagbasoke agbegbe ati ti orile-ede lenu lowolowo yi. Ohun ti won le reti ni idinku ninu owo iranlowo ati opolopo eko nipa eto imulo oro aje to munadoko lati odo awon orile-ede ti won je lowo. Ohun to fa eyi ni
atejade kan ti aipe yi lati odo Banki Agbaye to nso wipe iranlowo owo le sise ti eto imulo oro aje to munadoko
ba wa pelu e. Opolopo awon orile-ede ati ajo agbowosile lo nwoju Banki Agbaye fun awon itosona lori eto imulo.

Iwadi aipe yi lati owo ile eko giga Yunifasiti ti Nottingham, eyiti Eka Ile Ise Ijoba, ile Geesi fun idagbasoke ni Kariaye (U. K Department for International Development( DFID) gbe oro Banki Agbaye lese. Iwadi na ri wipe
aiduro ni bikan owo iranlowo to nwole ga pupo fun awon orile-ede to ba ni tabitabi wipa oro aje.
Gegebi ikilo Oliver Morrisey to je okan ninu awon to ko akosile na "opo igba ni a ma nfe lo owo iranlowo fun idoko-owo sugbon awon oludoko-owo ma nso ireti nu ti owo iranlowo ko ba wa deede. Bi aidaniloju ba se
po si ni ikolu to ma nwa lori iyori si oro aje." Iwadi na se ayewo ifiara kora wo lo wa laarin ailodeede iranlowo
ati idagbasoke oro aje ninu awon apeere orile-ede meji-dinladojo. Gegebi iwadi nat ti fihan, ailodeede iranlowo le ni ikolu lori isisesi oro aje ni ona meji. Ni ona kini o le se afihan wipe o sese ki orile-ede kan ni idaamu nipa 5
5 Page 6 7
Vol II No. 12
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

6
oro aje, gegebi iyan, omiyaleyaona tabi ilosile to ga ninu iye owo ori awon ire oko. Ni ona keji aisedeede le se ijelese fun eto imulo ati idoko-owo.
Awon aridaju iwadi na miran fihan wipe aisedeede ma ndin iwulo iranlowo ati idagbasoke oro aje o ku. Lara awon igbese fun atunse ti a lana sile ni eto imulo oro aje to dara si ni awon orile-ede to ngba iranlowo,
ifiarakoraeni to fesemule laarin agbowo sile ati agbowo ati ki a fun awon orile-ede to le ni ifaragba awon ohun to nfa aisedeede oro aje ni ifojusi pataki
ID21Obasi Ogbonnaya
Gedu gige lona ti ko bofin mu nmu irokeke ewu ba awon Igbo
orile-ede Tanzania 2mins 19secs

Orile-ede Tanzania npadauu bi oke medogbon sarre hektari ninu awon igbo abalaye re lododum latari owo igi

gedu ti ko bofin mu Oro yi ni a ri ninu atejade titun kan ti akole re nje "Ge ki o si sare: Gegu gige ati owo igi
gedu ti ko bofin mu ni ile-olooru." Iwe na so wipe awon osise ijoba na lowo ninu iwa arufin yi to fi igbo orile-ede
na to je milionu (egberun lona egberun) metalelogbon ati abo sabe ewu. Ilo igbo lona ti ko bofin mu ati iwa
ibaje ninu ise akoso igbo ati owo ibode na wa lara awon ohun ti o farahan ni awon orile-ede Ile Afirika miran
lara eyiti a ti ri Kenya, Senegal, Ghana, Naijiria ati Cameroon. Iwe wa daba wipe orile-ede Tanzania ko ni ipa
lati fi se idabobo igbo to munadoko. Nigbati o nsoro lori iroyin na, olori ijoba orile-ede Tanzania, Fredrick
Sumaye ti bura lati se ohun to to si awon arufin onisowo gedu. Akowe Agba ni ile-ise ijoba fun Oro Adayeba
ati Irin-ajo Afe, Philemon Luhanjo, ti gba wipe awon osise igbo kan jebi i lowosi ninu isowo gedu ti ko bofin
mu. A tun fura si won paapa fun ipadiapopo ninu idinku awon eya eranko to wa labe ewu iparun. Sugbon o
se iroyin to so wipe o seese ki awon osise eka ile-ise ijoba fun Eda Abemi Egan ma se iranwo fun ijiodese
gegebi egbe awon ode ni orile-ede Tanzania se fi esun kan won. Awon miran ti a tun fura si ninu isowo gedu
lona ti ko bofin mu ni awon onisowo ninu awon nkan ti won nfi igi se, awon eniyan i lu, awon oni gedu ati awon
ajo oloko-owo gedu. Luhanjo ni o fere je jakejado orile-ede na ni ikore lona ti o bofin mu ti ntesi waju ninu
igbo iyasoto ati awon agbegbe ti a ko yasoto. Awon arufin na ma nlowo ninu ikore gedu, igi ati eedu lona ti ko
bofin mu.

Gegebi ona lati da ipagborun duro, awon alase ti beresi bere fun iranlowo awon eniyan agbegbe to ngbe ni eba awon igbo. Aisi awon orisun agbara ina miran to wa nikapa awon eniyan igberiko lo nmu ki won nawo sinu
awon igbo gegebi orisun to wa ni arowoto. Won ti nfun won ni idanileko lati le se iranlowo nipa awon ona lati
fi se itoju dipo ki awon na ma kore igbo fun awon ere igba die. Awon egbe-egbe olopa ni won ti fi si awon oju ona nlanla gegebi eso lati ma mu awon ti won ba fura si ki won si ma gba awon eru ikore igbo ti ko bofin mu

lowo won. Environmental News Network 6
6 Page 7 8
Vol II No. 11
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

7
Awon Epo lile nmu irokeke ewu ba awon Ile onikoriko ni Ila-oorun Ile Afirika 2 mins 12 secs
Awon ile oni koriko ila-orun Afirika, eyiti o je iyebiye pupo fun agbara won lati se agbero fun orisirisi awon eda
abemi egan ile onikoriko safana ni epo buburu kan ti fi sabe ewu. Epo na ti a mo ni ede awon onimo ijinle si Tarchonantus Camphoratus ni o je epo ti ile onikoriko ti a le mu ni dogbandogba pelu epo oju omi hyacinth

eyiti o ti ndaamu awon odo nla, odo kekeke, adagun ati osa ni opolopo orile-ede, iwo oorun ile Afirika fun opolopo ewadun.

Epo lile yi ti a tun mo ni ede awon eya Masaisi leleshwa ni won koko se akiyesi ro ni o le die ni ogbon odun seyin. Awon onimo ijinle nipa ilo lupo awon eda abemi ati gbegbe won so wipe epo na ni agbara to yanilenu
lati wa ni ibamu pelu ayika sugbon ko ni anfani ilo kokan rara. O wa nfun eweko to ku pa ni ile onikoriko na. Awon eranko, yala awon ti a nsin tabi tinu egan, ki ije e.

Iroyin kan laipe yi ninu iwe iroyin kan ni orile-ede Kenya ti a mo si East African so wipe. "Epo na ni ibaramu to ga si awon ile onikoriko ati awon ibi ti ko fibe bara mu bi ile ori oke apata nibiti on ti ma nni eka to po to wa
ndi itankale itakun alagbara eyiti o nso ile di sisa ki o ma si baramu fun awon eya miran paapa, awon koriko ati ewebe."

Awon onimo ijinle nipa ilolupo awon eda abemi ati agbegbe won so wipe ibiti epo na tan ka ti le ni ilopo merin laarin ogbon odun seyin o si gba ile to ju saare hektari oke mefa ati aabo lo ni orile-ede Kenya ni kan, papa ni
Afonifoji Rift. Ni Laikipia ni ekun aringbungbun ariwa orile-ede Kenya, itankale epo na le awon eda abemiegan won lo si egbegbe awon agbegbe ti a dabobo, eyi si nmu ija wa pelu awon to nsin ohun osin, bi awon eranko
ti njijadu fun ounje. Ni awon agbegbe ti epo leleshwa na ti fere gbatan patapata, awon eda abemi egan ti di
awati patapata.

Awon onimo ijinle nipa ilolupo awon eda abemi ati agbegbe won ti kilo wipe ti won ko ba da epo leleshwa na lekun, awon ile onikoriko safana ila oorun Afirika le di asale. Sugbon sa o dabi enipe epo na ni epo die ninu
re awon onimo ijinle sayensi si ti nse iwadi si iwulo re fun oro aje. Eyi mu ireti wa wipe o seese ki a se idiwon
epo na nipa isekore re ni ojo iwaju. AWF Wildlife News

Awon Apileko Oro
Idinku onikiakia deba Ipeja ni orile-ede Ghana 4mins
Ise eja pipa ni orile-ede Ghana ti wa ninu wahala nla latari ipejaju awon eniyan agbegbe etikun ati ona ipeja to
darasi pupo ti awon oloko ipeja nlanla ti inu okun nlo. Awon aami akoko pe wahala ti de ni o farahan ni awon odun ibile to da lori eja ninu eyiti awon eniyan agbegbe omi ma npese opolopo ounje eleja.

Gegebi oro akoroyin omo orile-ede Ghana kan "Yato si awon ategun to tutu, ko si eri wipe akoko ipeja ti wa o si ti lo. Gbogbo awon odun eja ni won ti se laisi eja pupo ninu awon ikoko obe. Ko tile si eja herring paapa."
Ni igba ti ko tii pe pupo seyin ikore eja herring po tobe gee ti awon apeja fi ma nda eyi ti won ko ba ri ta pada sinu okun. 7
7 Page 8 9
Vol II No. 12
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

8
Lati se alaye owongogo na, won ti yi si oran efe ile Afirika. Awon apeja to wa ni awon abule kan nitosi ilu Accra, olu-ilu orile-ede Ghana ti so wipe ifietosiomobibi laarin awon eja lo je ki won ni ikore eja ti ko dara.
Awon eniyan abule ko figba kokan feran ipolongo fun ifietosiomobibi, won si wa ri idaamu na gegebi aaye lati
soro odi si.

Ni bayi, ise osise kan laarin marun omo orile-ede Ghana ti wa labe ewu. Opo ninu won lo npeja, to nse itoju eja ti won ti pa ati tita won. Adele Oludari ise ipeja ni orile-ede Ghana, Ogbeni George Hutchful so wipe ojo
i waju won sokunkun.
Gegebi oro re "Iye ati iwon eja ntesiwaju ninu dindinku lona to derubani nitori won ki iti dagba tan ki a to se i kore won. Eyi si ti yori si idinku ninu iye eja to wa ati adanu owo fun ise ipeja. " Gbogbo ebi idaamu na lo da
le ori isakoso ti ko tona fun ipeja okun eyito je on lo fun won ni eyito poju ninu eja orile-ede Ghana.
Ogbeni Hutchful so wipe itiraka ijoba lati yera fun idaamu nipa fifi eto Iye Eja ti won gba awon apeja laaye lati pa.( Total Allowable Catch-TAC) lele lo kuna nitori ijijadu to le ati didarasi ninu ona ipeja. Iye eja ti won gba
awon apeja laaye lati pa fun gbogbo orisirisi eja ni orile-ede Ghana ni iwon toonu egberun lona igba o le mewa lodun. Ko si igba kokan ti won tii tele ase yi.

Gegebi oro Hutchful, "Laarin odun mewa to koja iye eja ti won npa lododun ni abele lo lati egberun lona irinwo toonu." Egberun lona adorin toonu miran ni won nko wole lododun lati le kun oju ibere abele.

Eja ni orisun pataki fun jije eroja amuaradagba lati ara eranko ni orile-ede Ghana paapa laarin awon ilu. Isoro na yio buru si ti a ba wo bi iye eniyan yio se po si ni orile-ede Ghana. Laarin ogun odun sii, yio ju idaji awon
olugbe Ghana to to milionu (egberun lona egberun) mejidin logun eniyan ti yio ma gbe ni awon aarin ilu. Eleyi, gegebi oro Hutchful, jasi wipe eja jije yio lo soke sii.

Awon egbe apeja abele ti di ori oro na mu. Won ti mu ki awon omo egbe won bura wipe won ko ni lo etu abugbamu lati fi peja. Gegebi olori awon apeja ti agbegbe Mumford to bura na fun won pelu igo oti ogogoro
se so, eniti o ba se lodi si ibura na yio ri ibinu olokun. O ju egberun mesan awon oko olopon lo, ti bi idaji ninu won ni ero agbeeko-rin, to nsise lati inu awon ogosan le mesan abule ipeja ni itopa etikun orile-ede Ghana to lo
fun edegbeta o le adota ibuso kilomita.
Niti ipa tire, nisisiyi, ijoba nse ayewo awon ipeja ti awon oko ipeja nla ti okun nlo. Awon ajo oloko-owo ipeja
lati orile-ede Korea ni a gbo wipe o ni eyi to poju ninu awon oko na. Ayewo yi ti mu iyorisirere die wa. Merin ninu marun awon oko ti won yewo ni ibudoko ipeja ti iluTema ni eka ile-ise fun ipeja ni lati gba awon won sile.

Edward Ameyibor

Awon Osise ni orile-ede Mali gba Ekunwo Owo Oya 3mins 30secs Awon osise ni orile-ede Mali ti gba ekunwo iko meje ninu ogorun leyin idasesile to munadoko lati owo Egbe
Awon Osise Orile-ede Mali. (National Workers Union of Mali (UNTM) to je okan ninu awon Egbe isokan awon osise pataki ni orile-ede Mali, ati idunadura pelu ijoba.

Idasesile na mu ohun toju ekunwo to bere lati osu kewa odun lo wa. Gbogbo ilana owo osu awon osise ijoba ni won yio se atunto re ti yio si di mimulo lati osu kini odun to nbo Atunto yi ni awon akojopo awon amoye ninu
oro aje ati awon asoju ijoba ati egbe osise eyiti olori ile ise ijoba fun oro ile ise ijoba ati igbanisise, Ousnane 8
8 Page 9 10
Vol II No. 11
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

9
Oumaron Sidibe, yio yan yio se.
Ni afikun, adehun ti won se pelu ijoba fojusi awon ohun iderun miran fun awon osise gegebi idiyele owo oja
awon ounje pataki, eyiti owo re ti losoke pelu idamewa lododun, ati idinku ninu iye ti won nta ina monamona fun awon osise orile-ede Mali. Opolopo ninu awon ori adehun na lo beresi sise lesekese, ti eyi si mu oro rere

jade.
Gegebi oro okan ninu awon omo egbe osise: "Ilana titun yi ninu eyiti awon ori adehun nbere ise lesekese mu
iwuri pupo wa."

Sugbon sa, awon osise kan nberu wipe owo awon oja yio lo soke bi ekunwo bati gori owo oya won.
Okan ninu awon omo egbe UNTM ti o si nsiyemeji biotilejepe awon oniroyin nso wipe adehun na je eyito o
je 'ohunitan' kilo wipe. "A o ma wo bi awon onisowo yio se kobiara si ekunwo na nitoripe ti won ba gbe owo oja lo soke a o pada sibi ti ati bere" O wa mu wa si iranti wipe bi o se sele ni odun 1994 ti ilosoke owo oja pelu

idamewa leyin idinku iye owo CFA franc se jasi pabo leyin ti iye owo oja lo soke ju ekunwo lo. Titi di isisiyi, awon owo oja si wa ni bo se wa ni oja.

Mamadou Bathily, okan ninu awon oludunadura UNTM, fidani loju wipe idiyele owo oja yio sise ati wipe awon yio gba ijoba nimoran lati gbe igbese lati fi rin mole ti o ba ye be.
Gegebi oro Bathily "Erongba awon ekunwo na ni lati mu anfani wa fun awon osise ijoba to wa labe igara to po niisisiyi. Ko si ni je ohun to se itewogba rara ti owo awon oja ojojumo bi iresi, jero, wara, ororo isebe ati epo
moto ba fo lo soke to wa pa gbogbo aseyori wa re."
Nitire, Sidibe ti jeje lati mu gbogbo adehun ti won se pelu awon olori egbe osise se.
Ekunwo na ni awon egbe osise miran ti tewogba, awon bi Agbajopo awon Egbe Osise orile-ede Mali.
(Confederation of Malian Workers' Union-CSTM), to ko lati kopa ninu idasesile gbogbogbo na. Amadou Amion Guindo to je aare CTSM so wipe "biotilejepe ekunwo na ni igbese kini, ko ti to, awon osise si gbodo

tesi-waju lati ja"
CSTM ngbaradi fun idasesile gbogbogbo tiwon lati bere fun opin si ina monomono pipa to ma nwaye ni orile-ede
na ni akoko eerun. Awon osise awon ile ise aladani na ngbaradi fun idasesile tiwon lati bere fun ekunwo eyiti won ti kuna lati ri gba nipa idunadura.

IPS

Orile-ede Madagascar se ifilole Ogba Egan Orile-ede Titun 3mins 11secs Ogba Egan orile-ede Andringitra ni orile-ede Madagascar ti wa ni imurasile fun awon aririnajo-afe. Ogba na
ni won fi lole ni osu kewa odun yi, o si ni irisi wipe yio yorisi rere, gegebi oro Ajo Akojo Owo ni Agbaye fun Iseda Aye (The Worldwide Fund for Nature-WWF) to ti nparowa fun idasile ogba na pelu awon olubasisepo
miran. Lara awon olubasisepo na ni Egbe orile-ede fun Isakoso awon Agbegbe ti a dabobo (National Association for the Management of Protected Areas-ANGAD), Ijoba orile-ede Madagascar ati Ajo fun
Iranlowo lati orile-ede West Germany-KFW 9
9 Page 10 11
Vol II No. 12
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

10
Titobi Andringitra je egberun lona mokanlenlogbo ati ogojo sare hektari, o si wa laarin awon agbegbe idabobo meji to ti wa tele-awon ni ogba Egan Orile-ede Rano Mafana ati Isalo.
Gegebi oro ti ajo WWF gbejade fun awon oniroyin ni ojo kejo osu kewa odun yi, "Agbegbe idabobo titun yi lo ni ohun ifanimora fun irinajo-afe to ga ni agbegbe na da lori igbalaye to funni fun iwadi, idanileko ati irin-ese."
Bi ogoji ibuso kilomita awon oju ona fun irin-ese ati ibudo ipago ototo merin ni won ti pese sile laarin ogba na.

Awon akitiyan to ti waye ni Andringitra lati odun 1963 ni o ni ifojusi lati se iwuri fun ona ifowosowopo fun itoju awon ibi idabobo. Awon eniyan agbegbe na wa lara awon to kopa ninu ifenuko to ye fun itoju ati idagbasoke
agbegbe na ni ona alagbero. Eto isakoso fun ogba Egan orile-ede na ni lati se agbekale irin-ajo afe ti yio dabobo oro adayeba ki o si se iranwo fun anfani awujo eniyan ati oro aje awon eniyan agbegbe bi o ba ti nse
igbelaruge anfani asa won.
Nigbati Lantosoa Ramarojaona to je Alakoso Ise Asemuwonuarawon ti Ise Idagbasoke Itoju ni ile ise WWF ni orile-ede Madagascar nse alaye, o so wipe: "Yato si awon igbo olegbele ti iha gusu ati iwo-oorun gusu
erekusu na, Andringitra dabi apere akojopo gbogbo oro adayeba ti orile-ede Madagascar ni lati fun awon eniyan. O ju egberun medogun eniyan to ngbe ni abule merindinlugba ni ayika ogba egan na, gbogbo won ni
won si kopa ninu ise agbese na.
Gegebi oro Joseph Ralaiarivony, Oludari ti Orile-ede fun ise agbese na "O seese ko je wipe agbara to po fun ise agbese na ni atileyin to tigba lati odo awon eniyan agbegbe Betsileo, Bara ati Tanala. Won ti tetisile si wa,
won si gbawa laaye lati sise laarin awon asa ibile awujo ati isedale won to kun pupo lati mojuto awon ohun to
je mo itoju gegebi yiye to ye lati dena awon ina igbo. Nitori emi ajosepo won to ga, ifaramo won le." WWF

Eto Awon Omode
Awon Igba Aye Isode Efon 5mins 10secs
(Ninu itan adayegba awon eya Bushman aye atijo ti iha gusu ile Afirika efon fi igbakanri je ajeran ati ogbojuode)

Nigba kan Efon kan wa, ako ti o tobi to si roro to ngbe leba ile olomi nla kan. O je ode to ni agbara ati imo isode nla, o si feran ounje pupo eyiti o jeki awon eranko beru re. O roro to be to fi je wipe erin alagbara ati
agbanrere nikan ni o bo lowo igbejako oloro re.
Ni ojo kan Efon ba Kiniun lojiji nibiti o ti nmu omi ni ibi koto omi kan. Efon ti gbaradi lati pa kiniun pelu ifigbani awon iwo nla re lekan soso Nigbati Kinium bebe fun aanu, Efon gba lati da emi re si lori adehun kansoso wipe
Kinium yio di eru on ko si ma sode fun. Laisi aniani, Kiniun gba. Abi kilo tun le se?
Nitorina, Efon pase fun kiniun lati pa igala nla kan to njeko ni odi keji koto omi na. Kiniun sebe, o si wo eran na wa sodo Efon, to gbadun ounje to dara ni irorun. Efon ro ninu ara re, "Aha! Eto to dara pupoju ni eleyi!
Nisisiyi ngo ni aye lati gbadun iyiramole ni ososan, ki nsi sun labe iboji nigbakgba ti nba fe!" 10
10 Page 11 12
Vol II No. 11
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

11
Ni ojo keji, Efon tun pe Kiniun o si pase fun wipe ki o pa keteketa abila to je odo fun on-nitoripe ebi owuro ti npaa. Laipe, kiniun pada pelu ohun ode na, beni Efon si fi okanjuwa je gbogbo ketekete abila na. Ko fi
nkankan ku sile fun Kiniun, egun to kere ju, ko fun gegebi ebun fun ise re.
Leyin eyi, Efon a pe Kiniun lojojumo a si pase fun lati pa eran opolopo si fun on lati le te okanjuwa re lorun. Ko fi igba kokan fi okele kansoso sile fun Kiniun.

Nibayi, nitoripe olori agbo won nlo gbogbo igba re, lati fi se ode fun Efon, awon iyawo ati omo Kiniun ti beresi
ni isoro lati sode, ebi si ti beresi pa lara awon omo. Bi agbo se ntirin ti won si ndi alailagbara sii, beni Efon se ntobi to si ndi okanjuwa sii. Leyin igba die, Efon beresi jeun emarun lojumo. Kiniun nfirare se wahala pupo lati

wa ounje fun Efon buruku na.
Ni ojo kan Efon ri Kiniun to dubule pelu aare sabe igi egun kan. O pase fun wipe ko dide ko si gbaradi fun
isode nla. Nitori igbe aye irorun re, Efon ti wa tobi o si sanra debi wipe o fee le ma le rin. O si ti wa ni ikundun fun ounje to yanilenu.

O so fun kiniun bayi: "Loni, Kiniun, wa lo wa si pa okan ninu gbogbo orisi eranko to wa ninu igbo! Lesekanna, Kiniun mo wipe eyiti wa poju -ise ti ko se se, paapa ti on funrarare ti fere gbo tan. O bebe. "Jowo, iwo
alagbara, saanu mi! Iru nkan yi ko seese fun mi" O si gbon gogo e dudu ni ibinu. "A bi o ko ri awon ebi nu? Ebi npa won nitori nki ri aye lati ran won lowo lati sode. Efon alagbara, tu mi sile kuro ninu ileri mi."

Sugbon okanjuwa Efon po, ko si ni aanu. "Mo da emi re sii" O bu jade. "Nisisiyi o gbodo se ohun ti mo pase ti o ba buyi fun owo ara re." O si fi ese nla re kile ti eruku si ku soke. Kiniun dide soke pelu aare. O mo wipe
ko si oro owo mo ninu oro na , o si pinnu lati se ohun to ye. "Efon o, "O dahun. "O se mi laanu wipe o di dandan fun mi lati mu ibere re se. Gegebi o si ti pase fun mi, nitori okanjuwa re, lati pa okan ninu gbogbo
eranko igbo, ngo se be. Ngo si bere pelu re."
Bi o se so be, Kiniun be si eyin Efon to tobi o si di ehin nla re mo lorun, o si pa lesekese. Nigbeyingbeyin,
Kiniun ati awon ebi re je ounje nla. Leyin na won feran eran efon, won si tesiwaju lati sode re nigbakugba ti o ba seese. Awon efon to ku ko eko ti Kiniun ti ko won, won si tun beresi je koriko. Wo si pinnu wipe yio dara

fun awon lati ma gbepo nitori ati le dabobo ara won kuro lowo oba awon Eranko. When Hippo Was Hairy

Idi ati bawo ni awon Akoko se ngbe iho sara igi gbigbe? 1min 2 secs
Awon akoko je eye to ni agogo to le eyiti o sopo mo egungun lile agbari won. Eyi ni ona ti Olorun gba lati fi jeki awon akoko le ma gbe daradara ninu ibugbe inu igi. Nigbati opo awon eye nse ite tiwon pelu koriko ati eka igi,

awon akoko a ma se ile ite won sinu ogbologbo ara igi to rorun lati gbe ju igi tutu lo. Won tun ma nlo agogo won lati ya epo igi kuro lati ri awon kokoro ati idin-di-kokoro lati je.

Orisi eya akoko pupo ni o wa ni ile Afirika, lara eyiti a ti ni ri Akoko Onirungbon ati Akoko oloosu-pupa. Akoko onirungbon ni a mo wipe o tun ma nfi agogo re se awon nkan miran. Lojojumo, o ma nlu ilu pariwo
nipa kikan agogo re mo igi gbigbe ni agbegbe re. Oro to fi nranse bayi ni: "Ibi yi ni ile ni, mo ngbe nihinyi." Chongololo 11
11 Page 12 13
Vol II No. 12
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

12
Bawo ni Agbanrere se ndabobo ara re kuro lowo awon ota? 1min 11secs Awon agbanrere ni oju kekeke ati iriran ti ko dara nitorina, bawo ni won se ndabobo ara won? Won ni igboran
to dara ati imo igboorun eyiti o se itunnu fun iriran won ti ko dara. Won si tun le lo awon iwo won lati dabobo
awon ikoko won kuro lowo awon aperanje bi kiniun.

Bi won se ndagba, awon agbanrere ma ntobi ju ohun ti won leni ota ninu egan lo. Sugbon, o senilanu wipe ko si eranko to le dabobo ara re kuro lowo ode to ni ibon tabi oko tabi pakute. Ni ona yi, awon orisi agbanrere
meji ti a mo ni ile Afirika ni won ti fere se ode re debi iparun patapata. Awon ni Agbanrere Dudu ati Agbanrere
Funfun. Awon ajiodese ti nsode Agbanrere Dudu lati opolopo odun, won si nta awon iwo re fun awon onisowo lati ile okeene, paapa lati

Arabia nibiti won ti nlo won fun egbogi ibile, oogun amaradide ati gegebi ori obe. Ayafi ti a ba sora gidigidi ki
a si bojuto iwonba die to ku, laipe Agbanrere Dudu yio parun patapata.
Chongololo

Abe felefele ti Asa 2 mins 7 secs
Nigba kan ri, abule kan wa nibiti Asa ati ore re Akuko jo ngbe. Ni ojo kan, Akuko lo si ahere Asa o si kesi : "E ku oni o, Asa. Nje o le jowo ya mi ni abe felefele re ki nle ge irun awon omo ni?" Asa mu abe felefele re

fun Akuko, Akuko si pada si ile re lati ge irun awon omo re. Nigbati o setan, o fi abe felefele na si ibi kan to pamo ni ireti wipe on yio da pada to ba ya. Sugbon sa, o sele wipe omo
e to kereju ri abe felfefe wa, o mu lo si ita, lo fi sere o si so nu.
Ojo melo kan leyin eyi, nigbati Asa fe ge irun awon omo tire na, o bi Akuko "nibo ni abe felefele ti mo ya o wa? Se mo legba pada nisisiyi? Akuko lo o si wo sugbon ko si nibi ti o fi si. Iyawo re pe awon omo won papo o
si bere: "Nibo ni abe felefele Asa wa? Sugbon awon oromodie na ko mo, eyiti o kereju ninu won to soonu siti gbagbe.

Asa ni: "Akuko mo fe abe felefele mi ti o ko ba mu pada fun mi, wahala yio sele. Gbogbo awon adie jadelo, won si waawaa, sugbon won ko ri abe felefele. Nigbana ni Asa ni: "Akuko ti o ba ti so abe felefele mi nu, ngo
je awon owo re."
Bi o se ri niyen ti o fi je wipe lode oni ko si ore laarin Asa ati Akuko. Idi si niyen to fi je wipe ti Asa ba wa nitosi ara Akuko ki ibale, iyawo re yio si dabobo awon omo re labe awon iye re. Leyinna ti Asa ba ti lo awon adie
yio sare, won o si ma wa ibi wa ohun ati ibi gbogbo fun abe felefele to sonu ti won ko si ti ri.
Shanghari Folktales

Apilese Eto
Oro Enikan Lori Itoju 15secs
"Ko si ohun to se pataki ju lati ko iran to nbo nipa bi aye ti Olorun da se se pataki yi wa ka aye ti ainimo ati aibikita eda eniyan ti fi sabe ewu to ga".

Sir Peter Scott (Ayaworan ati Olufe Ayika) 12
12 Page 13 14
Vol II No. 11
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

13
Awon Ajo ti ko lowo Ijoba ninu nja fun iwalaaye won mi Orile-ede Sri Lanka 2mins 17 secs
Awon Ajo ti lo lowo Ijoba ninu ni Orile-ede Sri Lanka ti dide ogun lati da ijoba lekun ki o ma lepa eto won si
ominira lati dapo moraeni lara. Laipe yi ijoba orile-ede na yan Igbimo Alakoso fun igba die lati bojuto oran Ajo Alagbelebu pupa ti orile-ede SriLanka (Sri Lankan Red Cross -SLRC) Eyi ni igbimo iru re keji ti ile Ise

Ijoba fun Ise Awujo ti yan lati se akoso Ajo Alagbelebupupa lati osu keta odun, leyin opolopo ifiesunkan lori iwa ibaje ati isakoso buruku laarin ajo na.

Won yan igbimo titun na leyin ti ijoba ti se atunse ni osu karun si Ofin awon Ajo Onise Afifeinuse laarin Awujo (Iforukosile ati Iseto) ti odun 1980 (Voluntary Social Service Organisations -SSO (Registration and Regulation
Act 1980) eyiti a mo si ofin awon Ajo ti ko lowo Ijoba ninu. Iwe 'Eyikotewalorun, to nkepe fun ifagile atunse na ni awon Ajo ti ko lowo Ijoba ninu bi edegbeta fowo si. Atunse ofin na ati yiyan Igbimo Alakoso fun Igba die
fun SLRC ni awon NGO na bu enu ate lu wipe o bere ise lo seyin koja igba ti o waye.
Awon ajijagbara awon NGO so wipe "Ohun ti won je ni ifenusi ti ko tona ninu ero abele awon ajo ti ko lowo ijoba ninu" Won toka si wipe awon ofin to wa tele to lati wadi awon ifiesunkan lori isakoso ti ko dara ati
ikowoje laarin awujo awon NGO ki won si fiya je awon to ba hu iru iwa be.
Akojade fun awon oniroyin lati owo MIRJE to je okan ninu awon ajo ti ko lowo ijoba ninu ni orile-ede Sri Lanka so bayi: "Yiyo awon eniyan to wa ni ipo ase ninu Ajo onise Afifeinuse laarin Awujo lori esun ki won si
fi awon eniyan ti olori eka ile ise awujo yan gegebi won ti se pelu SLRC nfi aye to po sile fun awon iwa isiagbaralo lati sele."

Nibayi, won ti fi esun kan awon omo igbimo akoko ti won yan si SLRC. Won fi esun kan won wipe won san owo idakonko nlanla fun ara won, won nlo oko ajo na fun irin-ajo tiwon, ati wipe awon ebi awon omo igbimo
na rin irin-ajo lo si oke okun lori eko ofe, awon anfani to ye ko lo sodo awon omo egbe SLRC olojo pipe. BAOBAB

Odun Marun Leyin Beijing 1min 38secs
Awon asoju awon ijoba yio pade ninu ipade pataki ti Ajo gbogbo Orile-ede Agbaye (United Nations General Assembly) ni osu kefa Odun 2000 lati se ayewo imuse Pepe fun Ise eyiti won gbawole ni Ipade Apero kerin

lori awon obirin eyiti o waye ni ilu Beijing ni Odun 1995. Sugbon sa, awon NGO to ndasi oro awon obirin ti beresi kepe awon ijoba lati lo sinu ipade na pelu eri wipe awon ti fagile gbogbo ofin to ya awon obirin soto.
Meji ninu awon NGO na ni Ibadogba Nisisiyi (Equality now) eyiti o fikale sile ilu Washington D. C ni orile-ede
Amerika, at Ipolongo lati fi Opinsi Ifi-iyato-si awon Obirin (Campaign to End Discrimination Against Women).

Ipe na wa nitori awon egbe ajijagbara fun awon obirin si ni idaniloju wipe iru awon ofin be si nsise lowolowo.
Ajo Ibadogba Nisisiyi so wipe: "Ipolongo wa yio kepe awon ijoba ki won fagile tabi se atunse awon ofin wonyi
laarin igba yi si odun to nbo ki Ipade pataki karun ti Beijing to waye. Ninu ipade pataki na a le se afihan awon atunse wonyi gegebi aami ifaranmo tooto( yato si aikobiarasi) si awon oro ati ifeinu ti Pepe fun ise eyiti o kepe

fun imukuro iru awon ofin be." 13
13 Page 14 15
Vol II No. 12
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

14
Brooke Ackerly to je obirin ajijagbara ati ojogbon olubewo ni ile-eko giga Yunifasititi California ni orile-ede Amerika gbagbo wipe oro nipa eto awon obinrin gbodo wo rekoja awon ofin to fi-iyato-si, ki o si fojusi awon
ohun to se okunfa ati bi awon ifi-iyato-si na ti ri ati iwa-ipa si awon obirin.
www. equalitynew. org

Iwa ipa si Awon Obirin Kakiri Aye 1min 26 secs ? Orile-ede India:
Omobirin olodun mewa kan ni osise inu oko baalu kan to woye wipe o nsokun gba sile. Osise na mo
leyin eyi wipe omobirin na nsokun nitoripe baba re ti ta fun okunrin omo orile-ede Saudi Arabia kan, eni ogota odun, to joko segbe re fun iye owo to siro si ojilerugba owo dola Amerika.

? Orile-ede Kenya Ni ile-eko kan ti awon akeko ngbe ibe, odunrun awon omokunrin si ogun lo si ibugbe awon obirin.
Awon omobinrin mokanleladorin ni won fi ipa balo po. Awon mokandinlogun ni won te pa ninu
idarudapo ati salo. Igbakeji olori ile-eko na wa so leyin eyi wipe: "Awon omokunrin na ko ni ife ati se awon omobirin na lese. Won kan fe fi ipa ba won lo po ni."

? Orile-ede Brazil Okunrin kan to jewo wipe on gun iyawo on ati olufe re pa ni igbimo olupari oran ni ile ejo ti gbogbo
won je okunrin so wipe ko jebi esun imomopaniyan. Idasile na da lori ariyanyiyan wipe okunrin na se
nkan na lati dabobo ola re ti a ti se si. ? Orile-ede Amerika

Obirin kan eni odun mokanle-ladota ni ore-okunrin re tele ri ti fi obe gun pa nigba mokanlelogun bo se duro sinu ile-ejo kan lati fa ase idabobo re gun si. Siwaju eyi, erinmeji ni won ti fi esun idunmohuru mo
ni kan okunrin na. Lemejeji ni won jawo ninu esun na. Equality Now

Olu-Ilu Ifipabaobirinlopo ni Agbaye 1min 31 secs Orile-ede South Africa ni won ti daruko bi olu-ilu ifiipabaobirinlopo ni agbaye. Eyi da lori awon akosile enu ojo
meta yi lati orile-ede na to fihan wipe o ju egberun lona adota ifipabobirinlopo to sele laarin odun to koja. Awon orisun olopa so wipe iye yi ko fi gbogbo otito isele ifiipa-baobirinlopo ni orile-ede na han. O ju iko
metaleladorim ninu ogorun awon isele na ti ko ni akosile, gegebi oro awon olopa, nitori itiju eniti oran na sele si.
Gegebi iroyin kan lori ero asoromagbesi redio ti orile-ede Amerika (Voice of Amerika -VOA), awon isele ifiipabaobirinlopo na ni o ma nwaye pelu iwa ika lati owo awon afipabanilo na. Isele to di mimo fun opolopo
eniyan ni ti obirin kan ti won fi aso di loju ti opolopo okunrin si fi ipa balopo fun ojo meji leyin eyiti won wa fi
sile ninu horo kan nibiti awon aladugbo ti ri. Won ti fi ina jo ati imu ati enu re danu. Bena ni apa ati ikanleegun wa kakiri ara re. Awon orisun ise isegun so wipe obirin na wa ninu ewu to ga ati wipe yio nilo ise abe itun

odearase ni opolopo igba.
Igbakeji Aare Orile-ede South Africa, Dokita Jacob Zuma, dabi enipe on ni alase ninu ijoba ti oro na ka lara
julo. Sugbon awon alariwisi ijoba so wipe ikalara re waye nitori won fi ipa ba iyawo re lo po ni ile won ni agbegbe Kwazulu Natal laipe yi.

VOA 14
14 Page 15
Vol II No. 11
November, 1999 (Yoruba) CHANGE Radio

15
Ageso Oruko
ANGAP -Egbe orile-ede fun Isakoso Awon Agbegbe ti a dabobo
CFDAW -Ipolongo lati fi opin si ifi-iyato-si Awon Obirin
CFA -Awujo Oro Isuna fun ile Afirika
CSTM -Agbajopo awon Egbe Osise Orile-ede Mali
D. C -Ekun Columbia
DFID -Eka Ile-ise fun Idagbasoke ni Kariaye
DSA -Ajo fun Iwadi nipa Idagbasoke
GMP -Akojopo Gbogbo Ise Orile-ede
KFW -Ajo fun Iranlowo lati Orile-ede West Germany
MCRC -Ibudo Iwadi lori Itoju Iseda Aye
NGO -Ajo Afenifere ti ko lowo Ijoba ninu
ODA -Iranlowo fun Idagbasoke lori oro Aje
OECD -Ajo fun Ifowosowopo ati Idagbasoke lori Oro Aje
TAC -Iye Eja ti won gba awon Apeja laaye lati pa.
UNTM -Egbe Awon osise Orile-ede Mali
U. K -Ile Geesi
USD -Owo Dola Amerika
UWEP -Eto Imose Nipa Egbin Arin-ilu
WWF -Ajo Akojo Owo ni Agbaye fun Iseda Aye. 15

Page Navigation Panel

1 2 3 4 5 6 7 8 9
10 11 12 13 14 15

 

© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw