Document Body Page Navigation Panel
1
ATOKA ORI ORO
Akoko Oju Ewe
Iha Gusu Ile Afirika dojuko Ewu Ajalu Ojiji lori Arun 1min 45secs 7 Kogbogun
AIDS
O to adota egberun omo iha gusu ile Afirika to nni arun
kogboogun AIDS lososu
Ile Afirika dojuko ewu airiounjeje 1min 37secs 4 Ogun abele ati
awon kokoro ajeireoko ti jeki o soro fun
opolopo omo ile Afirika lati bo ara won
ORO AJE ATI IGBE AYE
Isaretobisi awon ilu ntesiwaju ni ile Afirika 21secs 14 Awon ilu ile
Afirika nsare tobi ju iwontunwonsi fun
agbaye lo
Ile Afirika polongo anfani idoko-owo to wa ninu re 2mins 48secs 8 Ile
Afirika ngbaradi lati fa awon oludoko owo nlanla
ni agbaye mora
EKO
Alafo laarin iforukosile okunrin ati obinrin ni ile-eko ni ile Afirika 46secs
13
Opo awon omodekunrin ni a nfi oruko won sile ni ile
eko ni opolopo orile-ede ile Afirika ju awon omodebirin lo
ILERA
Egbogi titun ndabobo awon omo ikoko awon iya to ni arun kogboogun AIDS 1min
32secs 7
Egbogi titun ti awon omo orile-ede Uganda ati America
gbe dide ni o fi ireti fun iran ile Afirika to mbo
ORO AWON OBINRIN
Opo ninu awon obinrin orile ede Sudan lo wa logba ewon 1min. 53secs 6
Owo ninu oti lile nfi egbegberun awon obinrin iha gusu
orile-ede Sudan sinu ogba ewon lododun
AYIKA
ITOJU
Oro to enikan so lori Itoju: Ipadanu Ipinsiyeleyele awon eweko ati eranko
34secs 14
Iwa omugo iran yi ti yio soro fun awon iran wa ti
mbo lati fori re ji wa. 1
1 Page 2 3
Vol II No. 10
September 1999 CHANGE Radio
2
Ati se afihan ilana lati dabobo awon odo ile Europe 1min 11secs 5 Ajo
WWF gbe igbese lati dabobo awon odo adayeba
ti ile Europe
Orile-ede Canada se pataki si Ipinsiyeleyele awon
eweko ati eranko 26secs 14 Bi idamewa gbogbo igbo agbaye lo wa ni
orile-ede Canada
Idaamu lori Omi Mimo 14secs 13 Yio fere to okan ninu awon orile-ede
meta ti yio se
alaini omi mimo to laarin adota odun si
OUNJE
Opo Iresi sii pelu omi ti ko to ti tele 2min 34secs 9 Isaredinku omi
agbaye ti fi ogbin iresi sinu ewu.
Awon onimo ijinle sayensi nwa ona lati fi lo omi
to kere ju ti ateyinwalo
Erekusu Zanzibar gbesele eja lati inu adagun 1min 50secs 5 Ifurasi
wipe awon ogun ipakokoropaeku ti tu sinu awon
adagun nlanla ti iha ila oorun Afirika ti mu ki awon olura
keyin si awon eja awon odo na
AWON AGBEGBE TI A DABOBO
Orile-ede Naijiria polongo awon ogba egan
orile-ede titun 51secs 4 Awon ibudo aabo meji fun awon eda abemi egan
di
ogba orile-ede
IMO NIPA ISE ONA
Awon oko inu ofurufu ayiayepo le sotele lori ibesile iba oloro 2mins
7secs 10
Awon Akosile oko inu ofurufu ayiayepo le se iranwo lati
dabobo awon eran-osin kuro lowo arun apani
EDA ABEMI EGAN
Eye to nso agogo 59secs 14 Iseda Aye si aso loju iyanu kan ninu egan
orile-ede
Indonesia
ETO AWON OMODE
Kiniun at Eku 2mins 3secs 11 Eni ba dami siwaju yio tele tutu
Kini idi re ti awon Adan fi nfo lale? 1min 5secs 11 Awon adan le
riran daradara lale
(Yoruba) 2
2 Page 3 4
Vol II No. 10
September 1999 (Yoruba) CHANGE Radio
3
Iwa odaran to buru jai ti ehoro to nje Kadima hu 4min 10secs 12 Mo
idi ti awon abo amotekun se ndanikan se ode ati idi
ti ehoro ti aya e ba ja fi nsure laibojuweyin
Orile-ede Itali gboro nipa iwa odaran lori ayika 44secs 13 Orile
Itali fi ipinnu re han lati da didanasun awon ogba
egan orile ede duro 3
3 Page 4 5
Vol II No. 10
September 1999 CHANGE Radio
4
Iroyin
Ile Afirika dojuko ewu Airounjeje 1min. 37secs
Oju milionu (egberun lona egberun) mewa eniyan ni awon orile-ede ile Afirika
merindinlogun to nfe iranlowo
ounje ni kiakia lati le yera fun irokeke airiounjeje. A mo eyi lati inu ifitonileti
ti Ajo Agbaye fun oro Ounje ati Ise
Ogbin (UN Food and Agricultural Organization (FAO) to wa ni ilu Rome gbe jade
laipe yi.
Gegebi oro FAO ni ojo kerindinlogun osu kejo odun yi: "ogun abele, ogbele
ati awon kokoro ajeireoko ti se
idilowo fun ipese ounje ni iha isale asale Sahara ni ile Afirika nibiti irokeke
ewu airiounjeje ti wa fun ogororun
egberun eniyan.
Orile-ede Angola ni owongogo ounje na kan julo. Amoye agba lori oro aje fun
FAO, Mwita Rukandema, so
wipe ogun abele to be sile laipe yi ti jeki ikowole iranlowo ounje di ohun eti
ni Angola. Nse ni awon egbe ogun
Egbe Ajumose fun Ominira Patapata fun orile-ede Angola (Union for the Total
Independence of Angola
(UNITA) nfi pelepele le awon eniyan kuro ni ile won. Awon egbe ogun na nge titi,
won nda awon oko lona,
won si nyin agba lu awon ilu. Gegebi afikun Rukandema: "Bi eleyi ba tesiwaju
fun osu meji si, a o gbo awon
iroyin airounjeje to buru jai fun opolopo eniyan.
Rukandema so wipe ona kansoso ti a le fi yera fun ajalu yi ni lati parowa
fun awon omo ogun ijoba ati ti awon
olote lati fi aye sile ni oju ofurufu. Iwonba ibudo oko ofurufu die ni baalu
to ngbe iranlowo bo ti le bale nisisiyi,
ounje ati egbogi ti won si nle gbe wa ko to. Opo awon omo orile-ede Angola ati
omo ile-okeere osise aanu to
ntiraka lati gbe ounje wolu ni won ti padanu emi won ninu awon idana ti a gbo
pe awon olote se.
Africa News On Line.
Orile-ede Naijiria polongo awon ogba egan orile-ede titun 51secs
Ni ojo keta osu kejo odun yi, ijoba orile-ede Naijiria so Ibudo Aabo Eda
Abemi Egun ti Okomu ni iha gusu
Naijiria ati Egan Iyasoto Awon Eran-ode ti Kamiku (iha ariwa Naijiria) di awon
ogba egan orile-ede titun ni
orile-ede na.
Ibudo Aabo Eda Abemi Egan ti Okomu ni a da sile ni nkan bi odun medogun seyin
ni Igbo Iyasoto ti Okomu
to je akokose ise agbese ti Ajo Afenifere fun Itoju Ayika ati Iseda Aye ni orile-ede
Naijiria (Nigerian Conservation
Foundation (NCF) to je alabasisepo ajo kariaye fun itoju, iyen Ajo Akojo Owo
fun Iseda Aye (Worldwide
Fund for Nature (WWF). Ogba egan na ti o je ibuso kilomita mejileladofa ni igun
mererin re ni o je ibudo
isinmi fun awon eye to nsi kiri ati ile fun orisirisi eda abemi egan lara eyiti
a ti ri erin igbo ati obo olorunfunfun.
(Yoruba) 4
4 Page 5 6
Vol II No. 10
September 1999 (Yoruba) CHANGE Radio
5
Gegebi Alhaji Lawan Marguba to je oludari ajo olutoju awon ogba egan orile-ede
se so: "Eyi je idagbasoke to
dara fun orle-ede wa"
Paddy Ezeala/ WWF
Erekusu Zanzibar gbesele Eja lati inu adagun 1min 50 secs
Erekusu Zanzibar ti gbesele iko eja wole lati adagun Victoria ni osu meje
leyin ti apapo ile Europe na gbesele
iko eja wole lati ekun na latari opo iroyin nipa majele eja ninu adagun na.
Oro kan lati enu Alase Ile Ise Ijoba
fun Ise Ogbin, Idagbasoke Ohun Osin ati Oro Iseda Aye so wipe igbese na waye
lati fi dabobo awon olura,
pelu awon aririnajoafe, ati oro aje erekusu na.
Ogagun Adam Nwakajuki so wipe bi otileje pe won ko iti mo pato boya awon eja
adagun Victoria ti gboro lati
ara oogun ipakokoropaeku, erekusu Zanzibar ko le sora re di akitan fun awon
ounje ti won ti ko sile nibomiran.
Igbesele na ti o tun kan eja lati inu odo Nile waye leyin igasoke ninu ikowole
awon eja epiya ati eya miran.
Ijoba ti fi awon oluyewo si awon ebute, idiko baalu, ile itura ati ile itaja
nlanla ni erekusu na lati dena awon eja
odo lati inu Adagun Victoria ati Odo Nile.
Oga agba kan ninu Ajo Erekusu Zanzibar fun Irinajo Igbafe, so wipe ile itura
ti won ba ri ti o npese ounje ti won
ti gbesele wa ninu ewu ipadanu iwe ase re.
I joba Erekusu na so fun awon ile itura to ba si ni epiya ni ipamo ki won
ko won danu. Igbese lati dena ikowole
eja odo lati oke odo orile-ede Tanzania, Kenya ati Uganda waye leyin ose meta
pere ti Zanzibar gbesele tita
orisi omi aladun kan ti won npe ni "Masafi" eyiti won nse ni ilu Dar es Salam.
Ijoba erekusu na so wipe awon
ayewo ti ile ise Oga awon Apoogun ti Zanzibar se ti "fihan" wipe omi "Masafi"
ko dara fun mimu eniyan.
Africa News On Line
Nwon ti si aso loju eto lati dabobo awon odo Ile Europe 1min 11secs
Igbese akin kan lati dabobo awon odo 'adayeba' ti ile alawo funfun Europe
yio bere losu yi, osu kesan odun
1999. Igbese na ti a pe ni 'Awon Odo to wa Laaye' je ipolongo jakejado ile na
lati owo Ajo Akojo Owo fun
Iseda Aye (Worldwide Fund for Nature (WWF) ajo kariaye fun itoju iseda aye.
Ipolongo na ni a se lati se
irusoke imo lori iwulo ati ise awon ilana odo adayeba, ki won se afihan awon
irokeke ewu to ro mo ilokulo ati
isakoso ti ko dara, ki won si se afihan ipa ti olukuluku ati awon ajo gbogbo
ni ninu itoju omi mimo. 5
5 Page 6 7
Vol II No. 10
September 1999 CHANGE Radio
6
Gegebi WWF ti so, iponlongo na yio 'se agbekale ilana eto fun isakoso awon odo
ni ile Europe ati fun iyipada
ninu ofin'. Ipolongo na ni a o fi lole ni ilu Brussels ni ojo kokanlelogun osu
kesan odun yi. Ni bayi iwe alaye kan
oloju ewe ogun ni won o gbejade ni ipari osu kejo pelu akole 'Awon Odo Ile Europe
to wa Laaye – Eto Fun
Ise Sise'.
Gegebi WWF se so: "Eto fun Ise Sise" na yio ta Ajo Apapo ile Europe, awon
ijoba orile-ede ati ti ibile, oko
owo ati awon ile ise, awon to nse ipese omi ati awon egbe miran ti oro na kan
laya lati fi ipinnu won han ki won
si se awon ohun to baye"
WWF
Opo awon obirin orile-ede Sudan lo wa logba ewon 1min 53secs
O ju egberun lona ogbon awon obirin to wa lewon ni iha ariwa orile-ede Sudan
to wa labe esin imale nitori
awon ese kekeke. Eyi ju ida kan ninu ogorun gbogbo obinrin orile ede na lo.
Iko marundinlogorun ninu ogorun awon obirin na lo nsewon nitori pe won pon
won si nta oti lile, gbogbo won
lo si fere wa lati iha gusu Sudan nibiti pipon ati tita awon oti lile ki ise
ese.
Gegebi iroyin laipe yi, o ju idaji ninu awon obirin na lo ti won tun nmu ti
won si ndapada sewon leyin ti won ba
ti fi won sile.
Iroyin na so bayi: "Awon irin-ise ipon-oti na ni won nta ninu oja gbanjo ita
gbangba, eni mimo lo si nraa. Awon
obirin yio fi ewon sile, won a tun lo ra irin ise ti won fi nro ti won si fi
npon oti won a si tun beresi se owo
kansoso ti won mo"
Nwon le mu obinrin, ki won gbe si ile ejo ki won si ju sewon laarin wakati
mejidinladota, won a si ko irin ise re
won a taa. Igba pupo ni won ma nse ejo won laisi agbejoro fun won. Lara ijiya
won ni nina legba, owo itanran
ati gbigbejusewon ti ko din ni osu mefa.
Opolopo ninu awon obirin na lo loyun sinu tabi to nto omo lowo. O ju ogorun
omo lo ti won nbi ninu okan ninu
awon ogba ewon na. Ninu omiran ninu won o ju igba awon omode ti won ti sewon
pelu awon iya won nigba
kan. Biotilejepe eka ti ogba ewon ni orile-ede Sudan ni a so wipe o wa ninu
awon ti isakoso re dara julo ni ile
Afirika, ikepe ti nwa fun awon ayipada lati se atunse awon ifiyajeni to buru
to nsele si awon obinrin iha gusu ni
iha ariwa nitori owo won ninu oti lile.
Newslink Africa 6
6 Page 7 8
Vol II No. 10
September 1999 (Yoruba) CHANGE Radio
7
Egbogi titun ndabobo awon omo ikoko awon iya to
ni arun kogboogun AIDS 1min 32secs
O seese ki egbogi titun kan pese abo to daju to ko si nani lowo pupo fun
awon omo ikoko ti awon iya to ni
kokoro arun HIV to nyorisi arun kogboogun AIDS – Igbasara Isele Aikunojuwon
Ajesara (Acquired Immune
Deficiency Syndrome) gegebi iwadi alajosepo kan laarin orile-ede Uganda ati
Amerika ti gbe jade laipe yi ni ilu
Kampala ati Washington.
Awon abajade ti a koko mo lati inu asewo olodun-meji lori egbogi na fihan
wipe idena ifunnini kokoro arun
HIV sele nigbati won fun alaboyun to ni kokoro-arun HIV ni egbogi na ti a mo
si Nevirapine (NVP) ni akoko
to ba nrobi lowo, ti a si fun ikoko to bi ni egbogi na laarin ojo meta ti a
bi.
Ifunnini arun dinku si idaji nigbati a se afiwe pelu itoju iru re pelu egbogi
miran ti a mo si AZT eyi ti o le na eniyan
lowo ni ilopo adorin sii, gegebi Ile ise Ijoba orile-ede Amerika fun Itoju Eda
Eniyan ati Ilera se so.
Gegebi oro lati enu Dokita Anthony S. Fauci ti Ajo orile-ede fun Aibaramu
ati awon Arun to nran eniyan to se
onigbowo iwadi na: "Iwadi yi lo je eyiti o mu iwuri julo wa titi di isisiyi
lori ifokansi wiwa awon ogbon imulo ti
a le lo jakejado aye to dena itankale kokoro arun HIV lati odo awon iya si awon
omo ikoko won"
Awon abajade na ni won gbe oriyin fun ninu ikede kan ni ilu Kampala: "Iwadi
yi funni ni ireti gidi wipe o le seese
fun wa lati dabobo opo ninu iran omo ile Afirika to mbo kuro lowo ibaje arun
kogboogun AIDS" Eyi ni oro
Crispus Kiyonga to je Alakoso fun Oro Ilera ninu ijoba orile-ede Uganda.
Newslink Africa
Awon Apileko Oro
Iha gusu ile Afirika dojuko Ewu Ajalu Ojiji lori arun
kogboogun AIDS 1min 45secs
Arun kogboogun AIDS ti nbureke koja ohun ti apa le ka lo ni iha gusu ile
Afirika lori gbogbo itiraka awon
ijoba, awon ajo ti ko lowo ijoba ninu ati awon ajo ti agbegbe (community-based
organizations (CBO) lati ru
imo soke lori isoro kariaye na.
Awon akosile aipe yi fihan wipe awon orile-ede Botswana, Namibia, Swaziland
ati Zimbabwe ni arun na kolu
pupojulo ni iha gusu ile Afirika. O fere to idamerin awon olughe orile-ede wonyi
ti o ni kokoro-arun HIV tabi
arun kogboogun AIDS gangan. O fere to idamerin awon eniyan ti ojo ori won wa
laarin odun medogun si
mokandiladota to ni ikolu na. 7
7 Page 8 9
Vol II No. 10
September 1999 CHANGE Radio
8
Gegebi iwe iroyin olosose ti orile-ede Amerika ti a mo si TIME se so, Ile-ise
Ilera ti orile-ede South Africa siro
wipe kokoro arun na yio kolu o kere tan idamarun awon osise ni odun to nbo.
Laarin odun meta si, awon ti yio
ku yio to egbegberun lona adotalerugba ti won yio si fi awon omo orukan to to
ogbon oke sile. Ati siro wipe
arun na yio ge ogun odun kuro ninu iwontunwonsi igbe aye, yio si mu ilosiwaju
oro aje joro pelu iko meji ninu
ogorun.
Gegebi iroyin ajo UNDP lori idagbasoke eda eniyan fun odun 1998 se kilo: "Ajakale
arun na yio ni ipa to le lori
oro aje ayafi ti a ba se agbekale awon ilana ati eto lati koju awon ikolu re
lori ipese osise ati ise sise.
Gegebi Alakoso Ijoba fun Ilera ni orile-ede South Africa, Nkosama Zuma se
so, orile-ede na lo ni igasoke to
po ju lo ninu awon alaisan kokoro arun HIV ti awon ti o si to oke meji abo eniyan
ngba kokoro-arun na sara
lososu. Awon wonyi je isiro to lewu gidigidi. Won nfun wa ni ikilo pe ohun gbogbo
ko lo dede ninu ija orile-ede
na pelu ajakale arun AIDS na.
Newslink Africa
Ile Afirika polongo awon Anfani Idoko-owo to wa ninu re 2min 45secs
Gegebi ijoba oloselu ti nfesemule ni ile Afirika, awon oludoko-owo ni agbaye
ti beresi fi okan si awon anfani
idoko-owo to wa ni ile na. Besi ni fun ojo meji ninu osu kewa odun yi ni ilu
Dakar, orile-ede Senegal, ile Afirika
yio ni anfani lati gba gbogbo aye to ku lalejo ninu apero pataki kan lori idoko-owo
lati fa awon alase ijoba to
wa fun ifowosowopo lori idagbasoke lati ile alawo funfun Europe, awon logaloga
pataki ninu awon ajo oloko-owo
nlanla, awon olori ijoba ni Afirika ati awon alakoso ijoba fun oro isowo ati
isuna owo.
Gegebi iroyin aipe yi kan lati owo ajo oniroyin, Newslink Africa, lara awon
alejo lati awon orile-ede Europe ni
ati ri arabinrin Clare Short, Alase ijoba orile-ede Geesi fun Idagbasoke Kariaye
ati Ogbeni Paul Nielson,
Alakoso ijoba orile ede Denmark fun Idagbasoke ati Ifowosowopo. Awon miran ni
Ogbeni Kenzo Oshima,
Oludari agba fun Ajo orile-ede Japan fun Ifowosowopo lori Oro Aje ati arabinrin
Hilde F. Johnson, Alakoso
Ijoba orile-ede Norway fun Idagbasoke Kariaye ati Eto Eda Eniyan.
Arabinrin Evelyn Herfkens to je Alakoso Ijoba orile-ede Netherlands fun Ifowosowopo
lori Idagbasoke na
yio pese pelu awon osise ijoba agbaagba lati orile-ede Faranse, Germany, Finland
ati Itali.
Awon to jumo se agbekale apero nla na ni Ajo Apapo orile-ede Agbaye fun Idagbasoke
Oko-owo (United
Nations Industrial Development Organization (UNIDO), Ajo Alasepo fun Itesiwaju
Isowo ni ile Afirika (Alliance
for Africa's Industrialization), Ajo Oro Aje fun ile Afirika (Economic Commission
for Africa), Banki Idagbasoke
ile Afirika (African Development Bank (ADB) ati Ajo Isokan fun ile Afirika (Organization
for African Unity
(OAU).
(Yoruba) 8
8 Page 9 10
Vol II No. 10
September 1999 (Yoruba) CHANGE Radio
9
Lara awon oro ti won yio so ni a o ti ri ikolu ti ilujarawon aye ni lori idagbasoke
isowo ni ile Afirika, oju-ojo fun
idoko-owo ni ile na, imuwonuarawon nipa oro aje ni elekun-jekun, ifowosowopo
laarin ile Europe ati Afirika
ati idagbasoke agbara awon aladani. Ona igbeowosile fun awon ise kereje-kereje
na ni won o tun jiroro lori
re.
Ipade osu kewa na je abajade ipolongo OAU ni ilu Harare ni osu kefa odun 1997.
O fi ase fun akowe-agba
ti ECA lati seto ipade awon orile-ede ati ajo to ngbe-owo sile pelu ile Afirika
lati wa ona fun inawo fun ilana ise
fun idagbasoke ile Afirika.
Awon olugbowo ipade na lero wipe yio jeki eto idagbasoke isowo ni ile Afirika
yara si ki awon orile-ede
Afirika le ni awon alabasisepo titun laarin ile na ati ni agbaye. Iroyin lati
ajo Newslink Africa na so bayi:
"Ifowosowopo nipa ise ona se pataki fun imudarasi ayika fun idoko-owo aladani
ni opolopo orile ede, o tun
ma nse iranwo lati se agbedide awon onisowo omo ibile to lagbara to si le ni
ifowosowopo to lagbara pelu
awon oloko owo lati eyin odi won"
Newslink Africa
Opo Iresi sii pelu Omi ti ko to ti tele 2mins 34secs
O seese ki iwadi onikiakia fun awon ona titun lati fi gbin iresi pelu omi
ti ko to ti tele ri ti bere si mu eso rere jade.
Won ti se agbedide awon ona titun lati fi gbin iresi. Awon ona na ti a pe ni
irugbin ni tutu, ifomirin iresi
lorekore, imuleteju, isakoso epo to darasi ati isakoso awon ile to san, ni egbe
olujodamoran kan lori Iwadi Ise
Ogbin ni Kariaye ti a mo si CGIAR se agbedide re lati din ikolu nla lori ipese
omi ti ibere giga si fun iresi mu wa
ku.
Awon ona titun yi se igbelaruge idinku ninu omi lilo fun ire iresi to ga si
ni sare ile hektari kokan. Alaye lori bi
won se nsise ni a ko menuba ninu iroyin CGIAR na sugbon sa, Ismail Serageldin
to je alaga CGIAR ati Adele
Aaare Banki Agbaye to wa fun awon Eto Pataki so wipe iresi ma nnilo omi to to
ilopo meji ti irugbin oka miran
ati pe o ju egbaa kan iwon tonnu omi kan lo ti won nlo lati fi gbin iwon tonnu
iresi kan. Eyi ko ni seese mo bi
ipese omi mimo ni agbaye ba se nyara din ku ti ibere fun iresi ni agbaye si
npo si.
Ni ogbon odun sii, yio ju idaji awon olugbe aye lo ti yio gbarale iresi gegebi
ogunna gbongbo orisun ounje won.
Awon agbegbe ibile fun ogbin iresi ni iha ariwa ati gusu orile ede Naijiria
ni o wa labe irokeke ewu nla lati inu
kiko ibi iwojopo agbami nla, igasoke iyo inu ile ati igberu si awon ilu. Gegebi
oro Ronald Cautrell, Oludari
agba fun Ile Ise Kariaye fun Iwadi lori Iresi, to je ibudo CGIAR ni orile-ede
Philippines: "Pelu ipadanu ile to wa
fun ogbin iresi latari igberu awon ilu, ibaje ile ati igasoke iyo inu ile, isoro
na di ti igberusi ire ninu awon ipo to
nganilara si" 9
9 Page 10 11
Vol II No. 10
September 1999 CHANGE Radio
10
Awon ona titun na le se iranwo lati gbe awon oro aje awon orile-ede to sese
ndagbasoke ro. Opo ninu awon
orile-ede to nsogbin iresi julo wa lara awon orile-ede to sese ndagbasoke, eyiti
Banki Agbaye pe ni "awon oro
aje ti owo to nwole lo sile pupo" Ile Asia nikan ni metadinlogun ninu awon orile
ede medogbon to je ogbontarigi
ninu ogbin iresi. Awon ni won nse ogbin ninu iko adorun ninu ogorun gbogbo ile
ogbin iresi jakejado aye, awon
na ni won si nse ipese iko adorun ninu ogorun gbogbo ipese iresi ni agbaye.
Nitoto, idameta gbogbo ile ogbin
ni opo ninu awon orile ede ologbin iresi ni ile Asia ni o je wipe iresi ni won
ngbin sori ile won.
CGIAR
Awon oko inu ofurufu ayiayepo le sotele lori ibesile iba oloro 2mins 7secs
Ibesile buruku ti kokoro arun Iba Afonifoji Rift to pa opolopo maalu run
ni iha ila oorun Afirika ti o si ni abajade
to buru jai fun awon eniyan ni a le se idena re. Awon iwadi titun ti fihan wipe
ibesile iba na ni akoko ati igba tire.
Akoko isele yi ni a ti le motele fun bi osu mefa saaju nipa lilo awon oko inu
ofurufu ayiayepo ti iwo oju ojo ki
a si gbe igbese lati pa awon ohun to le fa run.
Eyi lo waye latari iwadi titun ni ibudo Ifo ninu Ofurufu ti NASA to wa ni
Goddard ati ti Eka Idabobo Ilana Arun
to nran ni ni Agbaye (Department of Defence Global Disease Infections System)
ni Ile Ise Iwadi Ologun ti
Walter Reed in ilu Washington D. C, orile-ede Amerika.
Awon oluwadi ri wipe ibesile arun na ma nsaba se pekireki pelu awon akoko
ojo pupo to tan ka agbegbe to po
ni ila oorun Afirika. Won se ayewo akosile nipa oju ojo fun adota odun won si
ri daju wipe ibesile arun na meji
lo sele laarin odun metadinlogun to koja to si se pekireki pelu akoko opo ojo.
Kokoro arun na di awati laarin
awon ibesile na.
Gegebi awon abajade iwadi, efon ti a mo si Aedes lo ngbe kokoro arun na wonu
eyin re, eyiti a npa ninu ile tutu
leyin ti ogbara bati ti wo lo. Awon efon kekeke na a ma je awon eran osin. Ilana
yi ma ntesiwaju laisi isele
kokan titi di igba ti awon efon ti a mo si Culex ba wole de. Awon efon Culex
lo nfa awon ibesile nla nigbati won
ba ti je awon eran osin to ti ni kokoro arun na lara. Efon Culex yi ke, akoko
opolopo ojo nikan ni won npo si.
Awon oluwadi so wipe awon akosile oko inu ofurufu ayiayepo le sotele nipa
ibesile Iba Afonofoji Rift nibi osu
mefa saaju akoko na ti yio sele. Gegebi oro Compton Tucker, amoye Goddard kan
lori imo nipa eya ara ati
idagbasoke eweko ati eranko to ti lo akosile oko inu ofurufu ayiayepo lati fi
woye eweko ni ile Afirika fun odun
to le ni ogun so wipe "Ohun ti o dunmo mi nibiyi ni wipe akosile oko inu ofurufu
le fun wa ni ikilo saaju nipa
awon ohun to sedede pelu ibesile Iba Afonifoji Rift ki o si wa se afihan agbegbe
ti oro na kan gan"
Environmental News Network
(Yoruba) 10
10 Page 11 12
Vol II No. 10
September 1999 (Yoruba) CHANGE Radio
11
Eto Awon Omode
Kiniun ati Eku 2min 3secs
Kiniun ni gbogbo eniyan mo si oba awon eranko nitori o lagbara pupo o si
le 'fiyaje' eranko keranko pelu
agbara nla re. Nitorina gbogbo eranko lo beru ti won si bowo fun kiniun. Won
a si ma se ohun gbogbo to wa
nipa won lati ma bo si owo ibinu re. Gbogbo eranko lo nsapa won lati ri ojurere
kiniun ki won si je ore re.
Ni ojo kan, kiniun wa loju orun nigbati eku sesi sare koja lori inu re. Kiniun
ti o ji pelu ibinu, mu eku o si fe pa
nigbati eku bebe 'Jowo ma pa mi. Boya ni ojo kan emi na le gba emi oba eranko
la' Erin pa kiniun nighati o
ronu lori wipe eku 'kekere' fe gba emi on, kiniun, oba ati eranko to lagbara
ju la.
Sugbon sa, kiniun fi eku sile pelu ikilo wipe ko mase di orun on lowo mo.
Eku dupe lowo kiniun o si lo sile. Ko
pe leyin eyi nigbati kiniun nri kiri inu igbo ti o bo sinu awon ti awon ode
de. Nigbati o kigbe fun iranlowo
gbogbo awon eranko to ku ko daa lohun nitori won beru wipe yio pa awon je ti
awon ba tu sile. Nigbatoya,
eku gbo igbe kiniun o si wa ranti wipe nigbakan ri, kiniun da emi on si. O pinnu
lati san ore na pada nipa dida
kiniun sile. Nigbati o nsunmo kiniun o ri wipe awon okun aso oniyoloyolo ti
won hun papo ni won fi se awon
na. Eku bere ise o si bere si fi ehin ge awon okun aso oniyoloyolo na titi ti
o fi se iho nla to gba kiniun lati jade.
Nigbati o ti da kiniun sile eku so wipe "nigbati o da emi mi si, o rerin nigbati
mo bebe wipe emi na le gba emi
oba awon eranko la"
Eni ba dami siwaju, yio tele tutu.
Character Moulding Stories for Better Citizenship.
Kini idi re ti awon Adan fi nfo lale? 1min 5secs.
Awon adan je eran oru ti ko ni ona lati fi dabobo ara won. Okunkun ni aabo
won. Ota won to buru julo ni eye
kan ti a npe ni asa adan, eyiti o ma nsode ni irole-mo-ale nigbati awon adan
ma nfi ibugbe won ninu iho ati ori
igi sile. Awon eya die ma nje awon kokoro oru bi afopina. Awon omiran, gegebi
adan eleso, a ma je eso igi
to ba pon ni ale nigbati enikeni ko le ri won. Nitorina awon adan ma nfo ni
ale nitoripe ko si ewu ati pe ounje
won rorun lati ri.
Ninu gbogbo eranko to wa laye, adan nikan ni eyi to le fo. Awon iye won ni
a se pelu tanna awo to na lati aarin
awon ika eegun owo won to gun si egbe won ati ese eyin won. Awon eniyan die
ro wipe afoju ni awon adan.
Eyi ko ri be. Gbogbo adan lo ni oju won si le riran daadaa lale.
Chongololo 11
11 Page 12 13
Vol II No. 10
September 1999 CHANGE Radio
12
Iwa odaran lo buru jai ti Ehoro to nje Kadima ni 4mins 10secs
Nigbakan ri, gegebi awon eniyan to je eya Hambakush ti iha gusu ile Afirika
se so, ehoro to nje Kadima ni
adehun pelu amotekun to nje Nthoo lati ma so awon ikoko amotekun na meta nigbati
o ba ti jade lo sode. A
si ma fun Kadima lara awon ohun ode re fun ounje ale. Eto irorun yi sise daada
titi di igbati ogbele lile kan de
si ile na. Gbogbo awon eranko egan ti Nthoo ma nsode re ti si lo lati wa omi
lo si awon ekun miran, nkan si wa
le fun amotekun na, awon omo re ati Kadima. Lojojumo ni Nthoo npada wale lairi
ounje mubo. Laipe, ebi
bere si pa won.
Ni ojo kan, Nthoo pada wale o si ba Kadima to njeun. Nigbati o si bi lere
bawo ni o se ri ounje nigbati on to
je ode to dara julo ni gbogbo ile na ko ri ohukohun, Kadima dahun wipe ekulu
kekere kan ni o koja lenu iho
na on dogbon mu on si paa. Sugbon otito oro na ni wipe eran ti Kadima nje je
okan ninu awon omo amotekun
na!
Ni ojo keji, Nthoo tun sode lo, Kadima ika si tun pa omiran ninu awon omo
re o si jee. Nigbati amotekun tun
pada lowo ofo ni irole ojo yen, o dubule taaretaare o si wa so fun Kadima ki
o gbe awon omo oun wa ki on
toju won. Kadima ologbon ewe gbe omo kansoso to ku wa lemeta sodo Nthoo o si
wa tan lati gbagbo wipe
awon omo re wa laaye ati lalafia.
Ni owuro ojo keji, leyin ti Nthoo ti lo, ebi pa Kadima tobe ti o tun fi pa
omo amotekun kansoso ti o ku to si jee.
Lati bo ese re mole o fi awon aami iro si ati wole ati ati jade kuro ni iho
na, o si wa tu ile ka, o se opolopo eka
igi lati jeki o dabi enipe ija nla sele nibe.
Leyin na o lo sibi iho omi to ti gbe o wa kun ara re ni pupa pelu efun pupa.
Nigbati Nthoo pada wale, Kadima
to ri bi alaisan lo ba, o nsunkun, o si so fun wipe awon eniyan ti pa awon omo
re won si ti gbe won lo je. On
gbiyanju lati dabobo won sugbon awon ode na lu on pupo on si ti fere ku latari
eje ti on padanu. O si wa toka
si awon epon to wa lori irun ara re. O ma se o fun Nthoo! Ninu ibinu nla o gberaso
lati lo si abule to sunmo
ibe pelu ipinu lati gbesan lara awon eniyan to pa awon omo oun je.
Sugbon sa, bi amotekun na ti fe be le awon egbe odomokunrin kan ni oko na,
ohun nla kan kigbe lati ori igi wa
"Nthoo!" ohun na nje ti olofofo igbo ti a mo si 'Eye ma lo'. 'Nthoo' o tun kigbe.
Kadima ni ika na to pa awon
omo re, kii se awon eniyan daradara abule naa!"
(Yoruba) 12
12 Page 13 14
Vol II No. 10
September 1999 (Yoruba) CHANGE Radio
13
Nthoo yipada ni ibinu lati lo wa Kadima sugbon Kadima ti gbo eye na, o si ti
salo pelu iberu nla. Amotekun na,
Nthoo, ko tii ri Kadima, ehoro, mu sugbon awon eniyan Hambakush wipe wiwa kiri
na si ntesiwaju sibe.
Nitori eyi ni amotekun se nrora ti o si ma ndanikan sode. Idi tun ni yi ti ehoro
fi ma nsalo lai bojuwehin ti
ohunkohun ba sesi deba lojiji.
When Hippo Was Hairy
Alafo laarin iforukosile okunrin ati obirin ni ile-eko
ni ile Afirika Awon otito to wulo ni arowoto 46secs
Opo awon omokunrin ni a nfi oruko won sile ju awon omobirin lo ni ile eko
akobere ati girama ni opolopo
orile-ede Afirika. Iyosirawon iforukosile je omokunrin meji si omobirin kan
ni awon orile ede mokanla lara
eyiti a ti ri Naijiria, Ghana, Cote d'Ivoire, Republic of Benin ati Democratic
Republic of Congo. Eyi ni gegebi
awon akosile ti Ajo Gbogbo Orile Ede Agbaye gbe jade laipe yi. O ju awon orile-ede
mejidinlogun lo to ni
alafo to mo niwon lara awon ti a ti ri orile ede Egypt, Zimbabwe, Uganda, Ethiopia,
Cameroun ati Algeria.
Awon orile ede meje ko ni alafo ti eyameya nigbati orile ede South Afirika ati
Lesotho ni alafo ti idakeji ti iye
awon obirin to ju awon okunrin lo die foruko sile ni ile eko akobere at girama
United Nations
Idaamu lori Omi Mimo 14secs
Awon orile ede mokanlelogbon lo wa jakejado aye nisisiyi ti won ni idojuko
owongogo omi. Nigbati yio ba fi
di odun 2025, iye won ni a fokansi wipe yio ti lesi di mejidinladota nigbati
yio de gongo ni marundinlogota ni
odun 2050.
CGIAR
Orile Itali gboro nipa iwa odaran lori ayika 44secs
Leyin ti a ti ni akosile ogogun idanasun lojojumo ninu awon ogba egan orile
ede re, orile ede Itali ti seleri owo
italore to fere to oke meta owo dola Amerika lori awon adanasugbo. Ebun na ni
a o fun oluranlowo nigbati a
ba mu odaran na de ile ejo.
Awon iroyin so wipe ina ti awon adanasungbo nda lododun nfa ibaje to ga ninu
awon igi ati igbo orile ede Itali.
Iroyin WWF – Ajo Akojo Owo ni Agbaye fun Iseda Aye (WorldWide Fund for Nature)
so wipe "o fere to ina
mejidinlogbon ti won nroyin re lojojumo ni akoko ooru ni odun marun to koja,
gbogbo ibiti won si dana sun je
oke metadinlogun sare hektari. Opolopo ninu won lo si je lati owo awon adanasungbo".
WWF 13
13 Page 14 15
Vol II No. 10
September 1999 CHANGE Radio
14
Isaretobisi awon ilu ntesiwaju ni ile Afirika 21secs
Opolopo eniyan ni ile Afirika lo nfi aroko sile lati lo tedo si arin ilu
ju ni awon ibomiran ni aye. Laarin odun
1995 ati 2025, a siro wipe iye awon olugbe ilu yio di ilopo meji jakejado aye.
Sugbon ni ile Afirika, awon
olugbe ilu yio di ilopo meta ni akoko kanna.
Boiling Reint
Eye to nso agogo 59secs
Nje o ti gbo eye to nso akoko ti ojo je fun o? Ni orile ede Indonesia awon
oluwadi to nse ayewo iwa eya eye
kan ti a pe ni Pitta Erythrogaster ti se awari ohun kan to yanilenu. Won ri
wipe eya alaya pupa na ni ona to yato
to ma fi nmo akoko lojojumo. Ni kutukutu, eye na o wa lori ile, yio ma korin
owuro re. Bi oorun ba se yo yio
gun igi titi yio fi de tente re nigbati ojo ba kanri. Nigbana, ti oorun ba ti
nlo sile, eye na yio sokale igi na lati eka
si eka, yio si pada si ile ati ite re bi oorun ba se nwo ni agogo mefa irole.
Ko tan sibe o. O le so wipe ojo yio
ro ni ojo yen ti eye na ba duro sori ile ni gbogbo ojo na
WWF
Oro ti enikan so lori: Itoju Ipadanu Ipinsiyeleyele
Eweko ati Eranko 34secs
"Ohun to buru julo to le sele… ki ise idinku nkan agbara, iwopale oro aje,
ija olun-ose apayerun nuclear die,
tabi imunileru. Bi awon ajalu yi yio ti buru to fun wa, a le se atunse won laarin
iran bi melo kan. Ilana kan to nlo
lati bi ogun odun seyin ti yio gba wa ni egberun odun lati tunse ni ipadanu
ipinsiyeleyele iru ati eya ati iparun
awon ibugbe adayeba. Eyi ni asise wa ti awon iran to nbo leyin wa ki yio le
dari re ji wa
Edward o. Wilson, Ojogbon ni Yunifasiti Harvard
Orile-ede Canada se pataki si ipinsiyeleye awon eweko
ati eranko 26secs
Orile-ede Canada lo ni idamewa ninu gbogbo igbo agbaye, agbegbe to to okolenirinwodinmeji
milionu sare
hekitari, to fere bo idaji orile ede na. Awon igbo lo nse iranwo lati se agbero
idamarun gbogbo omi mimo to
walaye ki o si pese ibugbe fun awon eya eda abemi egan to to oke meje. Orile
ede na ni o nfi ire igbo to poju
lagbaye gegebi igi gedu ranse si ile okeere
WWF
(Yoruba) 14
14 Page 15
Vol II No. 10
September 1999 (Yoruba) CHANGE Radio
15
Awon Ageso Oruko
AAI -Ajo Alasepo fun Itesiwaju Isowo ni Ile Afirika
ADB -Banki Ile Afirika fun Idagbasoke
AIDS -Igbasara Isele Aikunojuiwon Ajesara inu Ara
CGIAR -Egbe Olujodamoran Lori Iwadi Ise Ogbin ni Kariaye
ECA -Ajo Oro Aje fun Ile Afirika
FAO -Ajo Agbaye fun Oro Ounje ati Ise-Ogbin
HIV -Kokoro Arun to nfa Aikunojuiwon Ajesara ninu Eda Eniyan
NCF -Ajo Afenifere fun Itoju Ayika ati Iseda Aye ni Orile-ede Naijiria
NGO -Ajo ti ko ni owo Ijoba ninu
OAU -Ajo Isokan ile Afirika
UN -Ajo Apapo awon Orile ede Agbaye
UNDP -Ajo Apapo awon Orile ede Agbaye fun Eto Idagbasoke
UNIDO -Ajo Apapo awon Orile-ede Agbaye fun Idagbasoke Isowo
UNITA -Egbe Ajumose fun Ominira Patapata fun orile ede Angola 15
© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw