Go Back
Communicating for Change

Document Body Page Navigation Panel

Pages 1--15


Page 1 2
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio August , 2000
1
Time Page
Egbe IleAfirika kepe fUn Igbekale Ofill 10riAwoll Ajogunba Eya Eda Alaaye. 4 mins.. 35 secs. 3

Awon Asoju Ile Afirika ninu Apero karun ti awon Egbeegbe lori Ipinsiyeleyele Awon Eweko ati Eranko to waye ni ilu Nairobi
tenumo bi o se ye lati dabobo awon eto awon eniyan agbegbe ati agbe.
Ajo kan fun Ire ati Alafia Eranko bu enu ate Iu Isode awoll Eran-Omi Seal Ni orile-ede Namibia 4 mins. 30 secs. 3
Ipinnu orile-ede Namibia lati mu ise okoowo isekore awon eran-omi seal re ni Ajo Akojo Owo ni Kariaye fun Ire ati Alafia Eranko ti bu enu ate lu.

Ile-ise Simenti Ni a ti ro lati kobi ara sii si Ayika 2mins. 30 secs. 4 A ti se italaya kan ni orile-ede Kenya si awon ile-ise Simenti ni ile Afirika
lati se idokoowo ninu isakoso ati idabobo ayika.
Orile-ede Ghana: Fifi Opill si Idakejeje 7 mins. 4 Iroyin titun tan imole sori awon oro to je mo iwa-ipa si awon obirin
ni orile-ede Ghana.
Awon Ijoba pade lati se ayewo Idabobo awon
Eda Abemi Egall Ile Afirika. 4 mins. 15 secs. 5
Bi awon egbeegbe si Adehun pataki kan lati doju ija ko owo ti

ko bofin mu ninu awon eranko ati eweko ile Afirika se npade ni ilu Nairobi, aseitupale oro kan gba wipe eyi je igbese pataki kan
lati se atileyin fun awon agbekale ile Afirika lati dabobo eda abemi egan.
Opo awon obirin sii 10 kopa ninu awon idibo to waye laipe yi lli orile-ede Zimbabwe 6 mins. 6
Awon obirin orile-ede Zimbabwe gbiyanju lati se alekun iye won ninu awon idibo si ile asofin to pari laipe yi.

Awon oniroyin gegebi onilaja ni awon akoko rogbodiyan 3 mins. 8 secs. 7 Idanileko oni-ifioroweoro kan to waye laipe yi ni orile-ede Naijiria
kepe fun ayipada alawokose ninu awon ojuse awon onise iroyin ni awon akoko rogbodiyan.

Didabobo awon Eja yanyan to wa labe ewu iparun ni iwo-oorun ile Afirika. 10 mins. 6 secs. 7
Awon afenifere itoju kepe fun idabobo awon eja yanyan ati awon eya eja skate ni ekun iwo-oorun ile Afirika.

Aare Clinton fowo si Iwe Adehun lori Ilana Ise pataki meji 2 mins. 9 secs. 9 Orile-ede Amerika di okan lara awon orile-ede to koko fowo si awon iwe
adehun pataki meji lori Ilana Ise ti Ajo gbogbo orile-ede Agbaye to tubo fi agbara fun awon idiwon agbaye lori idabobo awon omode.

Iyara-diilu: Irokeke Ewu nla si Ilera ati Ayika 8 mins. 33 secs. 9 Iroyin Ajo Agbaye kan ti se itokasi isodiilu eyiti a ko se eto fun gegebi
irokeke ewu pataki kan si ilera ni orile-ede South Africa.
1
1 Page 2 3
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio
August, 2000

2
Ajo fun Iforiji ni Kariaye (Amnesty International) kepe fun opin si iwa-ipa lori ibalopo ni orile-ede Sierra Leone. 9 mins. 48 secs. 10
Ajo ajijagbara fun eto eda eniyan yi ti tokasi ijinigbelo, fjipabanisun ati owo eru to je mo ibalopo okunrin ati obirin gegebi awon isele to
koninirira julo ninu ogun olodun mesan to ti nja ni orile-ede Sierra Leone.
Beijing ati Marun: Inu awoll asoju ile Afirika ko dun lori Apero na. 9 mins. 11
Apero awon obirin na ti a ti nreti ti wa, o si ti lo, sugbon o dabi enipe ko doju aami ifokansi opolopo.

Ise-ogbin Alaroje ndin awoll igbo orile-ede Malawi ku. 1 mim. 9secs. 13 Orile-ede Malawi ni a ti tokasi wipe 0 ni iye ipagborun to ga julo ni ekun
idagbasoke ti iha gusu ile Afirika.

A ti gbo ... Ajo AENS gba Aam. Eye Ominira Oniweroyin ni kariaye. 1 min. 28secs. 13
Agbara awon akosile isiro. 3 mins. 29 secs. 13

Eto fun Awon Omode
Bi Nwapfundhala se nge igi 6 mins. 18 secs. 14 Ehoro to nje Nwapfundhala ko bi idore se se pataki to 2
2 Page 3 4
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio August , 2000
3
Oro Asokagba
Awon oro magnigbagbe lori ati idagbasoke Egbe Ile Afirika kepe fun igbekale ofin lori Ajogunba Eya Eda Alaaye 4mins. 35secs.
Awon asoju ile Afrika ninu Apero karun ti awon Egbeegbe Adehun lori Ipinsiyeleyele Eweko ati Eranko to waye laipe yi ni ilu Nairobi lati ojo keedogun si ikerindinlogun osu karun odun yi ti
tenumo bi o se ye lati dabobo eto awon agbegbe ati awon agbe kuro lowo ijilo-laigase nipa akitiyan alajose pelu awon ajo to nmojuto iru awon oran bee.

Ninu akojade oloju-ewe meji won, eyiti asoju kan lati orile-ede Egypt ka jade, Egbe Ile Afirika na tun kepe fun ifi ipo asiwaju fun awon agbegbe ninu itesiwaju itoju ati ilo alagbero ti ipinsiyeleyele
eweko at eranko ati ilowosi won ni kikun ipinnu sise. Egbe Ile Afirika na wa lara awon asoju bi egberun kan ati aabo to pese sinu Apero ilu Nairobi na lori Adehun lori Ipinsiyelelyele Eweko ati
Eranko eyiti a pe ni COP 5.
Egbe na tun kepe fun igbelaruge ise-ogbin alagbero ti awon agbegbe to nlo awon ibile ati ti ode oni lati se alekun ilo ipinsiyele eweko ati eranko dapo mo ise ogbin ati lati lo awon agbara imusise ti
ilolupo eda abemi ni agbegbe won lati se alekun si ati lati dabobo igbejade. Egbe na tun se iwuri fun igbekale awon ofin orile-ede to wa ni ibamu pelu Ofin Awokose ti ile Afirika fun Idabobo Eto Awon
Agbebe Ibile, Agbe ati Awon Olohun osin ati fun iselokari si awon oro eweko at eranko (ti Ajo OAU gbejade ni odun 1998).

Ninu akojase won, won woye: "Gegebi ohun to je oro ikanigbongbon, oro to je mo gbigbe awon oro ajogunba eya eda ti ile Afirika lo sile okeere, ona sii, ati pinpin awon anfani to jeyo ninu ilo awon
ajogun eya eda ti ile Afirika gegebi ilana Adehun lori Ipinsiyeleyele Eweko ati Eranko (Convention Biological Diversity CBD) ni a gbodo mojutol." Egbe ile Afirika na tako idabobo imo to je mo ti
awon orisi emi labe ofin pelu siso wipe o ye ki a teramo ati muwasaye lagbaye ipo to dara fun ipinsiyeleyele ewoko at eranko ninu igbo, itoju ati ilo alagbero ninu awon apero to tona. Awon asoju
ile Afirika na jirebe si gbobo awon ajo fun idagbasoke ati igbewosile ni itele emi Adehun ti a mo si
Oro Agbeso kokanlelogun (Agenda 21) lati se ipese atileyin imo-ise ati owo fun awon orile-ede Afirika ati awon ise agbese to je mo ikojopo agbara lati sise ni awon eka Adehun CBD to

kannigbonbon. All Africa News Agency

Ajo kan fun Ire ati Alafia Eranko bu enu ate lu isode 4mins. 30secs. awon Eran-omi Seal ni olrile-ede Namibia
Ajo Akojo Owon ni Kariaye fun Ire ati Alafia Eranko ti fi edun-okan re han lori ikede aipe yi lati odo ijoba orile-ede Namibia wipe yio se imugoorosi ninu ise-okowo isekore re ninu eran-omi seal. Igbimo
awon minista ti orile-ede Namibia fowo si aba kan ti minista fun ise ipeja gbekale lati se alekun awon
to ni iwe ase lori eran-omi Seal lati meji si merin. Iyamboa ti so tele ni odun yi na wipe "ijoba ngbero lati se alekun to ga pupo" ninu ipinfunni isekore eran-omi Seal ni odun 2000, nitori alekun to nyara

de si akojopo awon eran-omi Seal ninu awon omi orile-ede Namibia nmu irokeke ewu ba ise ipeja ati agbegbe. Akoko isode eran-omi Seal ni orile-ede na yio bere ni ojo kini osu kejo.

Sarah Scarth to je oludari ajo na fun iha gusu Afirika so wipe ajo na ti nfojusi idagbasoke ninu isode ododun na fun opolopo odun, ko si ti ri eri -lona imo ijinle sayensi tabi omiran -lati se atileyin 3
3 Page 4 5
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio
August, 2000

4
imugboorosi isekore eran-omi Seal ni orile-ede Namibia. O tun fikun wipe awon to le pupo wa agbero fun isekore awon agbalagba eran-omi na tabi lati mo alekun won ni ododun. Yio je ohun to
lodi loati se alekun ipin lati faramo imugboorosi oko-owo lori eran-omi seal laisi iru ifitonileti be.
Oni: "A ko si mo eri imo ijinle sayensi kokan to le se igbelese wipe isekore eran-omi seal ni orile-ede Namibia yio je anfani fun ise ipeja. Awon iwadi imo ijinle sayensi kakiri aye, paapa orile-ede Canada,
ti fihan wipe ipejaju lo nfa ilosile akojopo eja, ki ise pipa lati owo awon eran-omi sea. Ti a ba se alekun awon ipin, ifitonileti lori agbero isode be ni gbodo muwa fun ayewo awon elomiran".

Awon ipin isode ni orile-ede Namibia fun odun 1999 je fun oke kan ati abo omode eran-omi seal ati egberun marun awaon agbalagba eran-omi na. Gegebi akosile ajojopo ti a se gbeyin ni osu kejila
odun 1997, gbogbo akojopo awon omode eran-omi seal ni a siro si oke marun o din egberun marun. Ko si akosile iye awon agbalagba eran omi sea.
Panafrican News Agency

Ile ise Simenti ni a ti ro lati kobiara sii si Ayika 2mins. 30secs. Awon ile-ise simenti ni ile Afirika ni a ti talaya lati nawo sii ninu isakoso ati idabobo ayika lati te
dabobo awon eniyan to ngbe agbebe won ati ayika kuro lowo idoti to ga.
Minista orile-ede Kenya fun irin-ajo afe, isowo ati idoko-owo, Nicholas Biwott, so wipe awon ajo oloko-owo na gbodo jawo ninu fifokansi ere jije laibiita nipa ayika ati ilera eda eniyan. O so eyi ninu
apero lori imo asiwaju ninu imubosipo awon ayika ti awon ti lo. O ro awon oluse siment na lati tele awokose ile-ise simenti ti Bamburi to wa ni ilu Mombasa eyiti o gbajumo fun imubosipo ayika.

Minista na so nigbati o nro awon ajo oloko-owo na lati se ohun otun wipe "Yio dara fun awon ile ise simenti lati nawo sii lori idabobo ayika. Apero na, eyiti Ajo orile-ede Kenja fun awon Idiwon (Kenya
Bureau of Standards) se kokari re, ni o se akopo awon ti oro na kan gbongbon.
Nibayi, orile-ede Kenya no iwon tonnu metric simenti to ju oke medogbon milionu lo lododun, eyi si
tumo si iwon adota kilo fun enikokan lododun. Panafrica News Agency

Orile-ede Ghana: Fifi opin si Idakejeje 7mins. Iwa-ipa si awon obirin je otito, sugbon awon obirin die lo setan lati soro nipa iriri won. Ni opolopo
igba, awon obirin ma nni opolopo idena eyiti o nmu irewesi ba won lati soro. l
Nigbati won ba yan lati soro nipa iriri won paapa, won ki i iso o fun awon ajo ijoba, sugbon won ma nyan lati royin na fun ebi, awon ore tabi awon eniyan agbegbe.

Eyi ni awon awari iroyin titun kan lori iwa-ipa si awon obirin ati omode. Iroyin na ti a pe akole re ni "Fi fi opin si Idakeje ati Italaya awon Aheso lori Iwa-ipa si awon Obirin ati Omode ni orile-ede
Ghana." je ise ajumose lati owo Ibudo Ikosile fun awon Iwadi lori eya ati Eto Eda Eniyan (Gender Studies and Human Rights Documentation Centre (GSHDRC), Ajo Apapo Egbe Osise, Ibudo fun
Idagbasoke awon Eniyan, Ajo Iranlowo Ise, Ajo Awon obirin fun Idagbasoke ni Ila-oorun Bawku,
Ajo Awon Aladugbo Agbaye, Ibudo fun Awon Igbese fun Idagbasoke Alagbero ati Ajo Olusisepo ninu Idagbasoke. 4
4 Page 5 6
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio August , 2000
5
Iroyin na kari awon ogun agbegbe ninu gbogbo ekun mewewa orile-ede na. Lara awon ona igbaseiwadi na ni a ti ri oro ajoso legbeegbe, iwe iforwanilenuwo ati awon iwadi ojukoroju lenu awon afunni ni
ifitonileti pataki.
Iroyin na tenumo ise pataki ebi ati awon ore gegebi ona iranlowo nigbati awon obirin ba ni iriri iwa
ipa ni gbogbo ona. Fun awon obirin to royin iwa-ipa nipa ti ara mesan ninu mewa ro o ni ipele ti ko lowo ijoba ninu (ebi, awon olori elesin ati ore) nigbati okan ninu mewa roo fun awon ajo ijoba (olopa

ati ile ejo).
Iroyin na so awon idi bi melo kan ti awon obirin fi nlora lati royin tabi soro nipa iwa-ipa, lara eyiti ati
ri egan, itiju tabi aijafafa olufaragba, iwa awulo lati so iriri awon obirin lori-iwa ipa di yepere, ati aini igbekele awon obirin ninu awon ninu awon ajo ijoba.

Awon idi miran ti won so ni isedale ati awon ihuwasi aujo, awon ohun ti a ti se tele si awon to hu iwa-ipa, owo to nna eniyan, iberu ati iparowa fun lati odo ebi. Fun apeere, bi meji ninu mewa ni ko fi
awon okunrin won to ti huwa ipa sile latari iparowa fun lati odo ebi ati awon ore nigbati bi idaji ninu awon obirin ti won fi oro wa lenu wo ni ko fi awon okunrin won eleke-ebu sile nitori awon omo.

Gegebi iroyin na, iwa-ipa lori ibalopo bi ifipabanilo, iba-ibatan-eni-lopo ati idunmohurumo ni a ka si eewo. Awon isele wonyi ni iroyin ko to nkan lori won beni a ki ile soro lori won.
Awon idi kanna ni won tokasi nigbati o tile debi ati royin ifiabara-bani-lo-po. Lori owo ti a nna, iroyin na woye wipe iko mejidinlogun ninu ogorun awon obirin to farapa ninu ikolu nipa ti ara ni ko
lo fun itoju nitori won ko ni owo ti ara won.
Iroyin na pari nipa siso wipe o ye ki a se alekun ninu agbara awon ajo ati olukuluku lati le dide si awon iroyin nipa iwa-ipa si awon obirin ati omode. Lati le jeki eleyi seese, o tanmo igbekale awon
eto imulo ati ona lati dide si ati awon ilana fun akojo ati isakoso ifitonileti lori iwa-ipa si awon obirin ati omode.

Gegebi Ojogbon Akua Kuenyelua ti Eko Ofin ti ile-eko giga Yunifasiti Ghana se so: "Iwadi na yio fun awon ti oro na kangbongbon ni mio ti won nilo lati le mojuto oro iwa-ipa ati anfani lati sise lati
wa awon ojuutu gidi."
Awon Ijoba pade lat se ayewo Idabobo awon Eda Abemi Egan Ile Afirika 4mins. 15secs.
Awon egbeegbe si adehun pataki kan to doju-ija-ko owo ti ko bofun mu ninu eranko ati eweko agbegbe ni ile Afirika ti si ipade kan ni ilu Nairobi, orile ede Kenya ni ojo karun osu keje lati se

ayewo iroyin Ajo Agbaye ati awon miran lori ipo ti awon akitiyan won wa. Igbimo Alase ti "Adehun Lusaka" eyiti apeja re nje Adehun Lusaka lori Ise Igbofinro Alajumose ti a dojureko owo ti ko bofin
mu ninu Eranko ati Eweko Egan (Lusaka Agreement on Cooperative Enforecement Operations
Directed at Illegal Trade in Wild Fauna and Flora) pade ni olu ile-ise Ajo Agbofinro re ti o wa ni ibudo Ajo orile-ede Kenya fun Ise lori Eda Abemi Egan.

Gegebi Jim Sniffen to je Osise Ifitonileti to wa pelu Ajo Agbaye fun Eto Ayika (United Nations
Environment Programme (UNEP) se so:

"Eyi je igbese pataki miran siwaju ninu awon akitiyan wa to nlo lowowo lati gbaruku ti awon igbese awon ijoba ile Afirika lati dojuko owo ti ko borin mu ninu awon eranko ati weko agbegbe "A gbe 5
5 Page 6 7
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio
August, 2000

6
Adehun Lusaka kale labe Asia Ajo UNEP, Igbimo Alase na si njiroro lori awon iroyin lati owo Oludari Alase ti ajo na ati iroyin kan lati owo Oludari Ajo Agbofinro ti Lusaka.
Awon Agbonfinro na, eyiti opolopo notasi bi "Olopa kariaye ti Ile Afirika fun Eda Abemi Egan" ni
a dasile labe Adehun na lati gbejako iwa odaran lori eda abemi egan ni ile Afirika nipa ajumose iwadi ati ajopin ifitonileti ati itankale iroyin. Awon Omo Igbimo Alase na to je awon egbegbe mefa to

fowosi Adehun na ni 0 tun nmu iroyin wa lori awon akitiyan won lati se atileyin fun ise Ajo Agbofinro na. Gegebi UNEP se so, awon osise Ajo Agbofinro na ni ifowosowopo pelu awon ajo orile-ede ti a
nyan ti se aseyori 10ri awon ise abele ati asewonu-aala awon orile-ede to ti yorisi gbigba ogogorun
iwon tonnu ehin erin ati ibon ati mimu opolopo awon ajiodese. Awon egbe si Adehun na ni orile-ede Republic of Congo, Kenya, Lesotho, Tanzania, Uganda ati Zambia. Ethiopia, South Africa ati

Swaziland na ti fowo si adehun na eyiti 0 bere ise ni ojo kewa osu kejila odun 1996. United Nations.

Opo awon obirin sii lo kopa ninu awon idibo to waye laipe yi ni orile-ede Zimbabwe 6mins. Awon obirin orile-ede Zimbabwe gbiyanju lati se alekun iye won ninu awon idibo sile asofm to waye
ni ojo kerinlelogun ati ikeedogbon osu kefa pelu marundinlogota ninu won lati inu awon egbe oselu ijoba ati alatako to nfe ijoko, eyi si je iye awon obirin oludije to si poju ninu itan ogun odun orile-ede
na.
Ile Igbimo Asofin to koja, eyiti a tukani ojo kokan1a osukerin, ni omo Igbimo to je obirin mokan1elogun, okan ninu won sije lati odo awon alatako. Egbe to nse ijoba, iyen Zimbabwe African
National Union Patriotic Front (ZANU-PF) to mu awon oludije obirin to poju sile ninu idibo yi pelu ogun to ndije. Egbe The Movement for Democratic Change (MDC) ti a da sile ni osu mesan seyin,
mu obirin mokan1a siwaju ninu awon oludije ogofa re.
Sugbon awon egbe ajafitafita fun awon obirin ko ni iwuri kokan pelu iye awon obirin yi biotilejepe ohun pataki kan ninu awon atejade ohun agbese awon egbegbe oselu ni awon ilana fun ifiagbara fun
awon obirin to wa ni ipilese awujofun apeere, egbe MDC seleri lati se igbelaruge ilana ipilese awujo
kan lati mu dogbadogba wa ninu igbe aye oro aje, awujo ati ti oloselu nigbati o so wipe on yio ri wipe awon obirin ko So eto won nu laiye latari ise won lori ibimoati ibisi ninu awon anfani ti igbanisise

tabi oro aje. Egbe ZANU-PF pinnu wipe, o kere tan, adota ijoko ni a o ya soto fun awon obirin ninu Igbimo Alase re. Ni ipade nla ti egbe na ti won se lopin odun to koja, won tun gba aba kan wole wipe
fun ipo meteta, obirin gbodo wa ninu okan. Sugbon gbogbo awon ipinnu na ni a ko iti muse.
Pelu bi obirin seko iko mejileladota ninu ogorun gbogbo eniyan ilu ti awon to nse asojU ninu won nse ko tii koja idaji ifokansi ajo SADC, awon egbe obirin nja fun igbese gidi. Orile-ede na ko iti wa
ni dogbandogba pelu awon olori iha gusu Afirika yoku ninu iwuntunwosi eya. Orile-ede South Africa ati Mozambique, awon mejeeji to ti Sunmo ati doju aami ipin iko ogbon ninu ogorun ti a wa
ninu adehun ti awon olori awon orile-ede to wa ninu Ajo Iha Gusu Afirika fun ldagbasoke (South African Development Community (SADC) fi owo si ni odun 1997, eyiti okokan llinu awon orile-ede
merinla to je omo egbe gbodo muse ti yio ba fi di odun 2005.
Orile-ede South Africa lo ni awon asoju obirin to ga julo ninu ile igbimo asofin ati igbimo awon
minisita ni ekun na. ne Igbimo asofin won onirinwo eniyan, lo ni obirin mokandinlogofa tabi iko ogbon 0 din die ninu ogorun, iye to sunrno iye ti won fi sinu adehun 1997 na gegebi iye to kere julo.

Orile-ede Mozambique lo wa ni ipo keji ninu won je obirin, sugbon igbimo awon minista re eleni 6
6 Page 7 8
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio August , 2000
7
metadinlogoji ni obirin kansoso. Egbe AfricanNational Congress lo je egbe to nse ijoba ni orile-ede South Africa ati egbe FRELIMO to nse ijoba ni orile-ede Mozambique ni ilana ipin iko ogbon ninu
ogorun fun awon obirin ninu awon ipeleipele egbeoselu won, eyiti o se iranwo lati se alekun ilowosi
won ninu awon ipo to lowo si ipinnu sise. Orile-ede Malawi, Swazilandati Lesotho lo reyin julo ninu oro isoju awon obirin ninu ile igbimo asofin ni ekun SADC, pelu bi gbogbo won se wa labe iko

mokanla pere ninu ogorun. Southern African Research and Documentation Centre.

Awon Oniroyin gegebi onilaja ni akoko rogbodiyan 3mins. 8secs. Idanileko oniifioroweoro kan ti ajo ti ko lowo ijoba ninu kan, iyen Egbe fun Iduriadura ati
IsakosoRogbodiyan (Negotiation and Conflict Management Group) seto re, ti Ile-ise ti Igbese Itesiwaju ti Ajo ori1e-ede Amerika fun Idagbasoke (United States Agency for International
Development. office ofTransition Initiatives (USAID-OTI) se kokari re ti pinnu ninu akojade re
wipe iyipada alawokose gbodo wa kuro ni ona awon oniroyin teletele fun ifitonileti ati idanilaraya nigbati oro ba je rogbodiyan, ki o si se eto fun ojuutu. Idanileko ti orile-ede na eyiti a doju re ko

iwojutusi awon rogbodiyan ti oro esin ati agbegbe ni o fa awon olori lati agbegbe ati ajo elesin ati awon eniyan kokan lati awujo awon omowe. Lara awon olukopa na ni ati ri awon oniseiroyin lati
awon ajo to je olori ninu itewejade, ero asoromagbesi redio ati ero amohunmaworan telifison.
Ninu akojade fun awon oniroyin onipele mokan1a awon olukopa ninu idanileko na fohun sokan wipe ki awon orisun iroyin ninu riroyin awon rogbodiyan fojusi awon ohun to le mu ojuutu wa ninu
rogbodiyan na dipo eyiti ko dara nibe bi o se ri nisisiyi ni orile-ede Naijiria: Nwon tunro awon oniroyin lati se atileyin fun awon ajo ti ko lowo ijoba ninu to ba nwa ojuutu si awon rogbodiyan.
Idanileko na ri wipe ipa ti isedale awon orisun iroyin nko ninu riroyin rogbodiyan gbodo yi pada. Gegebi oro won, awon onise iroyin ma nterarno ati pariwo rogbodiyan dipo ki won wa ojuutu sii.

Okan ninu awon to soro, Joan Mbagwu so wipeo di dandan ki awononise iroyin se iranlowo ninu isakoso rogbodiyan ni ona todara to fi je wipe iyorisi re yiodi idagbasoke, iyipada, igboraeniye,
iyanjuoro, ibaraenidore, ibaraenisepo, ibaraenisoro, ilosiwaju, alafia ife ati alekun imo. O pari oro re bayi: "o se pataki lati si okan wa paya lati mo wipe o seese ki rogbodiyan gbogbo mu anfani wa fun
ayipada ati idagbasoke tia ba se akoso rogbodiyan na lona to dara ki a si yera fun sisalo kuro ninu re tati fifi sily lati yori si iwa-ipa."
Post Express.

Didabobo awon Eja Yanyan to wa labe ewu iparun ni Iwo-oorun ileAfirika. 10mins. 6secs. O ju adota orisi eya yanyan ati o le ni ogbon awon eya eja Skate ati iru re miran lo to ngbe ninu ewu
ni ekun iwo-oorunAfirika lati orile-ede Mauritania de Guinea, pelu Cape Verde.
Latari ipaju awon eja Skate ati yanyan, ati ewu ipadanu ipisiyeleyele eweko ati eranko, awon ajo bi Ajo Isokan Agbaye fun Idabobo Iseda Aye (World Union for the Protection ofNature (IUCN) ati
Ajo Akojo Owo niAgbaye fun Iseda Aye (World-Wide Fund for Nature (WWF) ti se agbekale awon ise agbese ifoyeyeni ati iwadi pelu awon miran ti yio se aridaju awon imuse ni awon ibiti nkan na ti
nsele. Niti kariaye, lati odun 1999 ni Ajo Agbaye fun oro ounje ati Ise ogbin ti se agbekale ilana ise
sise lori isakoso ati Idabobo awon eja yanyan kariaye, eyiti o tanmo awon iwadi ati ofin kan fun imulo awon ori1e-ede to je omo egbe. Ajo Foundation Internationale Banc d' Aguin (FIBA), ni

ifowoso-wopo pelu ajo IUCN ati awon ajo orile-ede ti beresi se ise iwadi kan lori awon eja yanyan ni ekun won lati odun 19971ati le se akosile ki won si se abojuto bi nkan se nlo ni iha owo-oorunAfirika. 7
7 Page 8 9
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio
August, 2000

8
Awon eja ti won pa ni awon ibi ipeja agbegbe ni itopa awon etikun lati Mauritanai si Guinea ni wonyewo, ti won si ye awon akosile wo lori idagbasoke akojopo awon eja Skate ati yanyan. Iwadi
na fihan wipe ipejaju to buru pupo ti wa.
Iwadi na fihan wipe awon eya die, bi straw. fish ko si ni ekun na mo rara nigbati awon miran bi eja straw-fish ti ile Afirika, awon eya yanyan ti npe ni tiger, lemon ati hamerhead wo ninu ewu to ga.

Ohun to fa eleyi ni wipe nipa iseda won, won ma nni emi gigun, won kii isi tete balaga ( awon eya die ninu won ma nto odun medogun), ibimo bi ti eranko ninu gbogbo eya (wonki iye eyin sugbon won a
ma bimo odidi-odidi) akoko iloyun wonma npe ( awon eya miran ma nju odun kan lo) ati isabiyamo ti ko ga rara ( opo ninu won ki ini ju ikoko mewa lo). Ju gbogbo eyi lo, ilana idapada akojopo won
ko yara rara to fi je wipe akojopo won a ma tuka ti won ba ni isisile si ipeja pupo.
Sibe eja yanyan nko ipa pataki gegebi eleto larin awon eya eda abemi inu okun, idinku re to npo si si le yorisi apoju awon eya ti ko dara, tabi ko yori si ihuwasi to yato ninu awon eya ti won npa je. Ipaju

ati iparun awon eja yanyan le yorisi idojuru iwontunwonsi laarin gbogbo ilana ilolupo eda aberni inu
okun.

Oro na tun buru si ni pelu bi ibere fun awonnkan ti anfi eja yanyan se se npo si. Loni, iye ti wonnra awon nkan na ti lo soke pupo. Iwon kilo kan irun imu re to gbe daada ma nna ni ni owo bi ogorun

owo dola Amerika ni orile-ede Hongkong nigbati won nraa lowo awon apeja awon orile-ede Iwo-oorun Afirika ni nkan bi adota si adorin owo dola Amerika. Nitori awon anfani ti iru oja bayi funni,
eyi ti o si wa je ewu to ga julo fun iruula awon eya na, opolopo apeja lo ti dojuko pipa eja yanyan nikan.

Latari ewu ona meji, ti ilolupo eda abemi ati ti oro aje-dapo-mo-awujo eda eniyan, awon ajo fun itoju ni ifowosowopo pelu Ajo fun Oro Ipeja (Fisheries Comrnission (CRSP) ti ekunna se eto idanileko
oniifioroweoro fun igbaninimoran lori ipeja yanyan ati ti isakoso alagbero fun awon eya orisirisi. ldanileko na ko gbogbo awon olukopa ninu oran na papo ( awon apeja, awon alarobo ati awon
onisowo )mo awon oluwadi imo ijinle sayensi ati asoju awon ile-ise ijoba fun ipeja ti awon orile-ede ekun na.

Awon imoran ti won gbe kale se itokasi bi o se se pataki to lati wa ojuutu ti agbegbe fun awon eya na
ati fun awon apeja to nlo kakiri nipase ilana ise ti ajo CRSP yio si kokari re. Nwon tun tenumo bi o se ye lati teramo iwadi lori ayika ati isedale awon eya ati isapejuwe okun irin alasopo imulo lati leni

ifitonileti to se gbokanle lati fi se atunse awon ofm ati ilana to wa nisisiyi. Ipade na fohun sokan wipe o ye ki awon igbese fun itoju waye nipa didabobo awon agbegbe ati akoko ibisi ati nipa didin akitiyan
ipeja ku ni gbogbo ona. Won tun fohun sokan lori bi o se ye lati se iranlowo fun awon apeja agbegbe
toti dara le yanyan nikan ninu akitiyan iyipada ti yio jeki won le koju akitiyan won si awon orisi eja miran ki won si le yera fun idi-olosi. Awon olukopa miran bi awon alarobo ati onisowo na ni won

gbodo fi si ero. Awon olugbeowosile ni won ro lati se atileyin fun awon eniyan agbegbe ati orile-ede to ba gbaradi lati kopa ninu awon akitiyan orisirisi na. Lakotan, gbogbo awon olukopa lo tenumo
wipe a gbodo fi oye ye awon ara ilu, ki a se imudagbasoke agbara ifitonileti fun awon olukopa ati
alakoso ki a si fun awon eniyan ni imo i1ipase awon eto orisun iroyin ati igbeko.

Gbogbo awon aba wonyi ni won yio fi si ero nigbati won ba nse agbekale eto ajo fun oran Ipeja agbegbe na fun ise sise ni agbegbe na ati fun itoju ati isakoso akojopo eja yanyan. Imunadoko igbese

yi yio da lori ifaramo awon alase ati atileyin awon olugbowosile. Panafrjcan News Agency. 8
8 Page 9 10
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio August , 2000
9
\ Aare Clinton fowo si Jwe Adehun pataki meji lori Ilana Ise 2 mins. 9 secs.
Ni ojo keji osu keje odun 2000, orile-ede Amerika di okan lara awon orile-ede to koko fowo si awon
iwe adehun lori ilaria ise ti Ajo gbogbo orile-ede Agbaye to tubo fi agbara fun awon idiwon agbaye lori idabobo awon omode leyin ti Aare Clinton fi aami otuko re sori awon iwe adehun na ninu ayeye

kanto waye niolu ile-ise ajo agbaye ni ilu New York.
Nigbati o ntewogba ipo asiwaju orile-ede Amerika nipa fifowo si awon iwe adehun lori ilana ise
mejeji ti ko kan dandan yi ni aftkun si Adehun lori Eto Omode lori idabobo awon omode kuro ninu ise asewo ati ilowosi ninu ogun, Igbakeji Akowe-Agba furi Ajo Agbaye, Lonuse Frechette so wipe

igbese na "laiseaniani, yio se iwuri fun awon orile-ede miran lati fi otuko won kuniwe-ise na."
Bi Aare Clinton ti nseleri lati fi iwe mejeji ranse si Ile Igbimo Asofin Agba ti orile-ede Amerika, o so
wipe: Iwe-ise mejeji yi lo se af1han "emi idajo ododo ni kariaye" ati igbagbo gbogbo eniyan wipe "awon omode ye fun ife ati idabobo". O si tun so wipe on ni ireti wipe o seese ki won fase si ni odun

yi. Orile-ede Amerika mo wipe a ti fun on ni aaye lati ko ipa asiwaju ninu idunadura awon adehun na, o si wa lara awon orile-ede akoko lati fowo sii. O se ileri lati sa ipa re lati ri wipe orile-ede Amerika
tun mu ipo asiwaju ninu imulo awon iwe ise na, ki awon omode agbaye le ni "ojoiwaju to dara ju ti
eyin lo." Addis Tribune

Iyaradi-ilu: Irokeke Ewu nla si Ilera ati Ayika. 8 mins. 33 secs. Iyaradi-ilu ti a ko seto re ni ati tokasi gegebi ewu ilera ni iha gusu Afirika ti o si yorisi awon ipo to
ntan awon arun buruku kale. Awon arun wonyi jeyo lati inu awon isoro ayika bi omi to ti doti, imototo ti ko darato, ategun inu-ile ti eefin ti doti and isirasile si efon pelu awon apeere miran bi ti ki
opo eniyan ma gbepo ni ihamo. Gegebi iroyinAjo Agbaye fun Eto Ayika (United Nations Environment Programme (UNEP) kan ti a pe ni "Bi Ayika se ri ni Agbaye niodun 2000" se so awon !isoro ilera ti
ayika yi ni awon orile-ede to ndagbasoke ni o nburu si latari awon isoro idoti oloko-owo ati ti ise
ogbin tosese nyoju. Awon kernikali ti won nlo ni awon iha mejeji yi lo je awon okunfa pataki ninu fifa ati mimu buru si iko egbe, otutu aya, anm okan, idibaje ara ati iko amunifigarami. Alekun isisile si

ewu ilera to je mo kemikali ni awon aarin ilu ni o buru pupofun awon omode ati aboyun.
Opolopo ninu awon ilu nlanla ile Afirika ni a tedo gegebi ibudo isejoba ati isowo fun awon oyinbo
amunisin yato si ibudo fun ile-ise nlanla ati oko-owo eyiti yio ti nigbogbo eroja ise lati fi se itoju akojopo eniyan repete. Nitori idi eyi, awon aarin-ilu to ni gbogbo eroja amayederun to won gogo ni

awon itedo pupo ti ko ni eroja amayederun to nibiti eyiti o poju ninu awon enliyan ngbe ma nrogba yi ka. Idarasi ibugbe ati ohun amayederun ti wa nyato pupo, kotii sese fun awon alase ilu lati wa ni
igbese kanna pelu igberu to buyaari ninu awon agbegbe awon atipo atiilu wuruwuru. Gegebi iroyin
Ile-ise kariaye fun Iwadi lori Ayika ati Idagbasoke (Intemational Institute for Environment and Development (llED) se so. "Nigbati pupo awon talika a ma hamora nibiti ibugbe ko gbe to ni itopa

awon ile perese olomi tabi awon agbegbe miran ti o tete ni ifaragba idoti nitori ibi kansoso na niyen ti won le ri ile ya tabi kole si ni olowopooku ninu aarin ilu awon orile-ede Malawi, South Africa,
Zambia ati Zimbabwe.
Jsogbin seteti odo ti bureke ni ayika awon ilu nlanla ati ilu kekeke ile Afirika bi awon eniyan se nwa lati koju ikolu osi, eyi si nyorisi idoti orisun omi pelu awon ajile ati kemikali ipakokoro paeku ti a nlo
lori awon oko ogbin keekeke ti a ko seto won yi. 9
9 Page 10 11
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio
August, 2000

10
Gegebi iroyin ajo UNEP na se so, yio fere to id. aji gbogbo olugbe aye ti yio ma gbe ni arin ilu nigbati yio ba fi di opin ogun onihdun,. Nibayi, iko ogbon si ogota ninu ogorun gbogbo olugbe aye to wa ni
aarin ilu lo wa ni awon orile-ede nibiti owo to nwole ti kere, ti ko si si ibugbe to to pelu awon ohun-elo fun imototo ilana idominugere ati omi ero mimo. Ako iba ati iba wogunwogun ni die lara awon
arun to wopo to ntankale latari isodi-ilu tia ko seto fun. Awon efon mejeji to nfa awon arun yi ni o ti yirapada lati inu ayika abalaye won ninu igbo olojo nibiti won ti nbisi ninu iho igi to ni omi ojo, si
ayika aarin ilu nibiti won ti nbisi ninu awon koto idominugere, agolo olomi, taya ti a ko lo mo, ape ati igo.

Idarasi afefe na ni o ni ikolu lati owo ise awon ohun elojade ti o ma nwaye pelu isodi-ilu. Ko si eniti o nse abojuto tabi idiwon bi idoti se po to ninu afefe laarin opolopo ninu awon ilu nlanla ile Afirika,
sugbon bi otilejepe idoti afefe si lo sile ni iwontunwonsi pelu awon agbegbe miran, o ti ndi isoro ni awon agbegbe kan paapa ni awon ilu nlanla pataki. Idarasi ofo ma nje afihan bi idoti ayika se wa ni
ekun na. Okan ninu awon abajade idoti ayika ni ojo omiro .eyiti imi-ojo ma ntu jade ninu afefe ayika
nibiti o ti nyo ninu oorun lati di omiro imi-ojo. Ojo omiro ma nba ile, ewe eweko ati omi je, eyi si nyorisi ikolu ti ko dara lori ilera eda eniyan.

Nitori opolopo awon eroja ayika yi, awon agbegbe ti awon talika inu ilu ma ngbe nio ma nsaba gbelege, beni akojopo awon eniyan ma nlowosi ibaje na. Nitoripe isodi-ilu ma nni ikolu ti ko dara lori
ayika ti a ti dena re ko si seese, dindin iye bi awon eniyan se nya lo lati igberiko si ilu ku, nipa sise atunse si awon igberiko le se alekun agbara won fun ise-oojo. Iru igbese be ni a gbodo gbelese pelu
awon eto imulo oro-aje to munadoko eyiti yio din iwuri fun isilo lati igberiko si ilu ku. Eyi yio si din igara lori awon ohun elo ati agbekale amayederun to wa ni aarin-ilu yio si din ibaje ayika ku.
Southern African Research and Documentation Centre.

Ajo fun Iforiji Jakejado Aye (Amnesty International) kepe fun
opin si iwa-ipa lori ibalopo ni orile-ede Sierra Leone 9 mins. 48 secs.
Ijinigbelo, ifipabanisun ati ifi awon odobirin ati obirin se eru lori ibalopo ni orile-ede Sierra Leone ni

a gbodo da duro. Eyi ni oro ti Ajo fun ldariji Jakejado Aye so ninu iroyin re titun kan ti a gbejade ni ojo keji osu keje odun 2000. Awon iwa yi lo ti wa lara awon isele to koninirira to si banilokanje julo
ninu ogun abele orile-ede Sierra Leone. Gegebi ajo fun eto eda eniyan yi to ti ngbe aba kale fun
gbogbo awon ti oro na kan ni awujo kariaye se so. "Ifipabanisun, ifise-eru lori ibalopo ati awon orisi iwa-ipa to jemo ibalopo lati owo awon omo-ogun olote ni o gbile.

Egbegberun awon obirinti ojoori won yato sira won ni wonni won ti fi ipa basun ti won s. iji gbelo. Nigbati .pupo won ni a fi ipa mu lati di alabalopo tabi iyawo' awon omo ogun. Yato si iroro ati
ibalokanje ifipabanisun funrare, ifi-ipa bani se po le yorisi ipalara, iloyuntipatipa, arun tabi iku paapa. Lara awonipaya ti omo ogun olote nfun awon eniyan ilu ni lati fi agbara mu awon okunrin lati fi ipa
ba molebi won sun pelu ideruba wipe won yio ge owo tabi apa won kuro.
Biotilejepe ijoba orile-ede Sierra Leone ati Agbajopo AwonAjijagbara (Revolutionary United Front
(RUF) fowo si adehun alafia ni ilu Lome, orile-ede Togo ni osu keje odun 1999, ifietoeniduni si awon eniyan ilu, lara eyiti ati ri ifiipabanisun ati awon orisi iwa ipa ibalopo miran ni o si tesiwaju.

Ibesile ija ati ewu to sele lati osu karun tun ti tubo mu isele ifiipabanisun buru sii. Ni aarin osu karun, awon omo ogun olote ti RUF fi ipa ba awon omo obirin ati obirin sun, won si ji won gbe 10 ni
agbegbe Masiaka to wa ni bi ogoji ibuso kilomita si olu-ilu Freetown. Lara awon afaragba ni obirin
kan ti ojo ori re ko ti to ogbon odun pelu ikoko re olosu-marun, eyiti won jigbelo leyin ti awon olote ti gba ilu Masiaka. Ki won to jigbelo awon omo-ogun meje lo bo gbobo aso re ti won si fi ipa basun. 10
10 Page 11 12
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio August , 2000
11
Nigbati won mulo si ibudo awon olote, won. tun fipa basun ni opolopo igba, won si fi agbara mu lati ma ru eru, se ounje ati ge igi.
Awon omo ogunAjo Agbaye ni orile-ede Sierra Leone ti a mo si United Nations Mission in Sierra
Leone (UNAMSIL) ni o ni ase lati dabobo awon eniyan ilu to ba wa labe ewu iwa-ipa. Lati mu ase yi se doju aami, UMASMIL gbodo gba ona to dangajiya si pelu ipinnu lati dabobo awon eniyan ilu

pelu awon omobirin ati obirin to wa labe ewu ijigbelo, ifiipabasuh ati orisi iwa-ipa ibalopo miran. Lara ohun ti won gbodo se ni lati mu awon ibiti egbe UNASMIL yio ti sise gbooro si, paapa ni
gbogbo awon agbegbe ekun ariwa nibiti iwa-ipa si awon eniyan ilu ntesiwaju, ki o si sa gbogbo ipa
lati dabobo awon eniyan kuro lowo ikolu awon omo ogun olote.

Bi Ajo Amnesty International se so, bi otilejepe awon ajo ti ko lowo ijobaninu nse iranlowo fun awon olufaragba ifipabanisun ati iwa ipa ibalopo ni ilu Freetown, ise si po lati se, paapa ni ehin odi
Freetown nibiti iranlowo ko to nkan tabi ti ko si rara.
Labe ofm ibile ni kariaye, iwa ifiipabanisun lati owo awon osise ijoba tabi awon to dihamora lakoko rogbodiyan je iwa idaniloro.

lfipabanisun lati owo awon ti di ihamora ninu rogbodiyan ologun ni ati damo nisinsiyi gegebi iwa
odaran loju ogun, ti a ba si se leralera tabi ni opo yanturu o ti di iwa odaran si gbogbo eda eniyan. Nitori be o ti di ohun ti a le se idajo re nibikibi.

Ni orile-ede Sierra Leone, ona ifinufinido ti won fi gba lo ifipabasun ati iwa-ipa ibalopo ti won si se lo repete lai bikita, nso ti imoomo lo ifipabanisun ati iwa-ipa ibalopo si awon obirin ati omoge gegebi
ohun-ija ogun lati fi da ipaiya sile. Adehun Alafia ti osu keje odun 1999 funni ni iforiji patapata fun gbogbo iwa, ati iduni-ni eto eda eniyan, eyiti a ba se ninu ija na. Ajo Amnesty International gbagbo
wipe iforiji to wa ninu adehun alafia na te awon ilana eto eda eniyan loju, ko si ni ohun idena kokan si iteloju siwaju ati siwaju. Ajo Agbaye se afikun "oro ko ri be" si adehun alafia na eyiti o tokasi wipe
iforiji ko si fun iwa odaran si gbogbo eda eniyan, iwa odaran loju ogun ati awon iteloju lile miran fun
eto eda eniyan ati ofin omoluwabi.

Ajo Amnesty International so wipe: "ko le si iforiji fun ifinufindo fi ipa banisun ati iwa ipa ibalopo si awon obirin ati omoge ni oril-ede Sierra Leone eyiti o jasi iwa odaran oju ogun ati iwa odaran si
gbogbo eda eniyan. Gbogbo awon to seni o gbodo wa si idapo." Amnesty International.

Beiing ati marun: Inu awon asoju ile Afirika ko dun lori Apero na. 9 mins. Bi apero Beijing ati marun se nkase nile ni Ojobo, ojo kejo osu kefa gbogbo eniyan lo gba wipe
abayori taara ko waye. Apero na bere pelu ireti to ga wipe yato si wipe awon ijoba yio tun tun
ifaramo won se si awon ileri ti won se ni Apero Agbaye kerin lori oran Awon Obirin to waye ni ilu Beijing, orile-ede China ni odun marun seyin, won yio tun tewogba awon igbese miran lati se aridaju

dogba ndogba awon eya. Sugbon bi apero na se npari lo awon asoju ti okan won sipaya ati awon ajo ti ko lowo ijoba ninu ri wipe awon beresi jijakadi lati dabobo Itage Beijing fun Ise ti odun 1995, iyen
akosile ti gbogbo won pejo lati se ayewo imulo re. Ni gbogbo ose na ni idunadura to lekoko fi waye
fun iwe apero ti yio se itewogba fun gbogbo ijoba. Ohun to ye ko je ayewo bawo ni awon orile-ede ti tesiwaju ninu ilosiwaju eya ki won si tun gbese siwaju di apero fun asotunso awuyewuye atijo lori

awon eto ibalopo ati ibisi. Si ariwo iyinlatiodo awon egbe ajo ti ko 10wo ijoba ninu lati ile Afirika kan, oludunadura ajo G77 Timi Kuripamo-Agary so wipe: " A ti seohun gbogbo lati mu Itage 11
11 Page 12 13
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio
August, 2000

12
Beijing fun Ise wa bi o se wa. A tiraka pupo lati ma se adalu re." O so wipe awon orile-ede ajo G77 ati paapa awon egbe orile-ede Afirika ti fenuko 10ri awon adehun kan to ba won lara mu. Ninu eyi
ni a ti ri ifarako gbese lori eya ati ilujarawon aye ati eje lati odo awon orile-ede alagbara wipe won yio gba wipe o kere tan iko meje ninu mewa iko kan ninu ogorun gbogbo owo to nwole fun won
labele ni won gbodo ma yasoto fun nina lori iranlowo.
Sugbon awon eto to je koko ni won se adalu won ninu apero na. Lara awon wonyi ni awon eto ibalopo ati ibisi, ati idamo eto awon obirin gegebi eto eda eniyan. Gegebi ajo Iforiji Jakejado Aye
(Amnesty International) se so: " Awon ijoba bi melo kan si ntiraka lati fa sehin kuro ninu Itage Beijing fun Ise ki won si din agbara ohun ti won fohun si ni odun Marun seyin ku. Beijing ati Marun
10ye ko je ki ise Beijing o din Marun."
Idunadura lori abajade apero na mu edekoyede wa pelu ipinya to farahan laarin awon orile-ede ajo G77 ati awon orile-ede agbaye to ti dagbasoke lori awon oran bi ilujara won aye osi ati gbese.

Ipinya tun wa laarin awon iha aye awon musulumi ati omoleyin Kristi ati awon orile-ede to faye gba obirin pupo lori awon eto ibalopo ati ibisi. Oludunadara kan so wipe: "O soro lati ranti igba ti
idunadura ti soro ju eleyi lo. Gbogbo re lo lo tisan mole"
Nibayi awon ajo ile Afirika ti ko lowo ijoba ninu gbe iroyin kan jade to bu enu ate lu Ajo Agbaye fun
ihuwasi ti o sele si won ni ose yi. Gegebi asoju ajo ati ko lowo ijoba ninu lati orile-ede Zambia kan, Gldays Mutukwa se so: "Inu wa ko dun rara wipe won jeki a dabi ayojuran ninu ilana na. O dabi

enipe ti a fa seyin kuro ninu ilowosi gbogbo eniyan."
O pe ki awon ijoba ile Af1rika to wa si ayeye na nitori eto ti ko munadoko ati aisi owo. Nigbati awon
orile-ede alagbara ti beresi gbaradi fun ipade na fun opolopo osu, laarin ose apero gangan ni Egbe ne Afirika sese pade. Biotilejepe awon die, paapa awon orile-de Ajo Idagbasoke Iha Gusu Afirika ja ija

to dara ninu awon idunadura na, ile Afirika ko yori soke rara. Bi eniyan ba wo akosile abajade apero na gaara, yio ri wipe ko si ajabori kokan lori awon oro eya ti a tokasi wipe o se koko fun awon obirin
ile Afirika.
Awon ikuna to waye ni apero Beijing ati Marun ti gbe imi-edun soke wipe won ti fe so egbe awon obirin na di eyiti yio ma fale bi ise ijoba '. nosiwaju eyani kariaye dabi eyiti o ti di ilana ijoba lori imo
ijin1e ati ti ero eyiti o lojupo to si sooro mo, ti ko si tipa be fi aye sile ninu awon gbogan agbara fun ilosiwaju iselu ati ijajagbara. Gbogbo okun ati ifojusi apero Ajo Agbaye lo da lori "akosile na",
"ihamo lotunlosi" ati "ede".
Gegebi asoju kan lati orile-ede South Africa Pregs Govender se so: "egbe obirin jakejado aye gbodo gba ara re sile." O ni, eko to tobi ju lati inu Beijing ati Marun ni wipe "egbe awon obirin ni won ti
gbawole. A ti di eyiti o da lori imo ijinle. ati ero dipo ki aje eyiti yio ma se atunse. nosiwaju awon
obirinje orooloselu to ga, sibe apero na funrare ko ba ti oselu lo. Ijajagbara paapa ni won kan fi sile J1i eteti."

Ni ale ojo ti oku ola ki Apero awon Obirin na pari, awon obirin ti won ikuna duro si ode gbogan idunadura ni ile-ise Ajo Agbaye pelu awon buba to fi ibinu won han pelu akole "ko si ipada seyin."
Nitori won ko gba won laaye ninu apero na, won nfi ehonu won han lode. Ki ise iruopin ti a fi okan si ni. Ni ibere orundun kokanlelogun, o dabi enipe, fun awon obirin, akoko ti duro soju kan.
InterPress Service Africa 12
12 Page 13 14
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio August , 2000
13
Ise-Ogbin Alaroje ndin awon igbo orile-ede Malawi ku Imin. 9secs. Orile-ede Malawi ni o ni iye ipagborun to ga julo ninu ekun Idagbasoke Agbegbe Gusu Ile Afirika
(South African Development Community (SADC) eleni-merinla. Ohun Iyalenu ni wipe orile-ede Angola ti ogun ti baje ni o ni iye to lo sile julo.

Igbakeji Oludari fun oran Igbo ni orile-ede Malawi, Paulos Mwale, ti so fun ajo PANA wipe iye ipagborun orile-ede na fere toiko meji ninu ogorun nigbati iwontunwonsi niopolopo omo egbe ajo
SADC ko ju idamewa eleyi lo. Mwale to je omo-egbe eka ise ti ajo SADC to mbojuto oro igbo so wipe ohun to fa ti iye ipagborun ni Malawi fi ga pupo ni igbarale-popuju lori ise-ogbin alaroje nipa
eyiti o jepe opolopo ile gbalasa ni won mo fun ise ogbin. Ni atubotan iwa yi ndin ilora ile ku. O se aftkun wipe: " Alekun to ga ninu iye awon olugbe orile-ede na tun nko ipa tire ninu iye ipagborun to
ga ni Malawi".
O kere tan saare hektari oke meji ati abo ni won ma mo lodoodun, awon osise igbo si so wipeeyi
yorisi iye ilo oro adayeba to ga pupo. Panafrican News Agency

A ti gbo Ajo AENS gba AamiEye Ominira Oniroyin ni kariaye 1min. 28secs. Ajo Iroyin Oju Ile Afirika (African Eye News Service-AENS) ni won kede re gegebi eniti o gba Ami
Eye Knight ti ominira oniroyin ni kariaye (Knight's International Press FreedomAward) ni orile-ede Amerika ni ojo, ojobo. Ami eye to lola pupo na ni won ma nfun eniyan kokan tabi ajo to ba tayo to
si ti ni ilowosi to wunilori si ise iroyin ni ekun won ni aye. Awon oludije ni awon to je omo egbe Ajo Knight ni kariaye tiwon si je akoroyin omo orile-ede Amerika to nlo si ile okeere lati lo jijo lo
ikosemose won pelu awon elegbe won kariaye ma nfi oruko won sile. Awon aami eye na ni won o
fun won ninu Ase Ale olododun ti ltayo ninu Ise Iroyin ti Ibudo kariaye fun Awon Akoroyin ma nse kokari re eyiti yio waye ni ojo kokanla osu kewa odun 2000 ni ilu Washington D. C.

African Eye News Service (South Africa)

Agbara awon akosile isiro 3mins. 29secs.
Fi awon isiro bi meji han oniyemeji, ohun to fere daju ni wipe wa soo di oirigbagbo. Bi agbara akosl1eisiro se ri niyen. Ko si si eniti o mo eleyi ju awon oniroyin lo. Ni igba pupo ni a ti gbarale isiro

lati fi otito oran kan han, lati fi gbe oran kale ati lati fi ti awon ife inu wa ta a ti ni a ti eyi ti a gba siwaju.

Nitori idi eyi ni a fi gbodo fi oju sunnunkun wo bi awon oniroyin iha iwo-oorun aye fi ngbe awon akosileisiro jade lori ile Afirika. Ko si eniti o jebi oran yi ju awon ajo oniroyin iha iwo-oorun aye. Lati
igbati ajakale-arun Eedi ti bere ni ile na, opolopo ninu awon oniroyin yi ti se agbekale ogunlogo iroyin eyiti o ti mu ki gbogbo eniyan ni imo lori bi nkan se ri ni ile na. Okiki awon ajo oniroyin wonyi
na tun se iranwo lati so opolopo ero okan di otito. Die to je otito. Die ti ki ise gbogbo re lo je otito.
Die ti ki itilese otito rara. Fun apeere, ninu apakan iroyin ajo CNN lori ero Internet ti won pe ni itupale denudenu ti akole re je " Arun Kogboogun Eedi: Ile Afirika wa labe ewu iparun " woye wipe.

"Iha iwo-oorun Afirika ko ni ikolu to buru to ti iha ila-oorun, Afirika sugbon okan ninu ogun awon agbalagba ni orile-ede Naijiria -orile-ede to ni eniyan to poju ni ile Afirika -lo ni kokoro-arun HIV
La8rin iseju kokan omo orile-ede N aijiria miran yio tun ni ikolu. " Pelu bi gbogbo eniyan se mo pe
orile-ede Naijiria ko ni akosile to be, besi ni kosi awon ohun elo fun iwadi, eniyan le bere wipe "Nibo ni ajo CNN ti ri awon isiro won?"

CFC 13
13 Page 14 15
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio
August, 2000

14
Eto fun Awon Omode
Bi Nwapfundhala se nge igi 6 mins. 18 secs. Nwapfundhala, ehoro, ati Nwafene, ilaburu, nwa aya ni abule kanna. Nwapfundhala lo si koko ri

orebirin kan fun ara re. Nwafene jowu aseyori ore re, eyi si fa ikunsinu laarin awon ore mejeeji. Nigbeyingbeyin, Nwapfimhala so fun Nwafeme "Makominu, ore, ma ba e wa orebirin kan."

Nwapfundhala gbon pupo. O yan omoge kan ti ko iti ri Nwafene ri, o wa salaye fun wipe irisieniyan ko ni gbogbo nkan -iwa to wa labenu lo se pataki. Nigbati Nwapfunhala fi ma pari apejuwe iwa
Nwafene pelu awon oro didun fun odomobirin na, o soro fun lati so pe on ko gba, nitori na Nwafene na ni orebirin tire.

Pelu eyi na ore won ko si danmoran.
Ni owuro ojo kan Nwapfundhala pinnu lati ko Nwafene leko kan. "Bami kalo lati lo ge igi", o sofun orebirin re. Omobirin na mu aake, awon mejeji sijumo yan wo inu igbo lo. Nibe, Nwapfundhala yan

igi kan ti won ge lule, won la si meji won si wa inu re jade. Lehinna won pa eyin mejeji po o si tun dabi igi daradara. Won wa gbe duro si ibi to ti hu si tele won si lo sile.

Ni ojo keji, Nwapfundhala sofun Nwafene "Jeki a mu awon omobirin wa ki a lo ge igi die" Awon omobirin mejeeji si mu aake won si tele won wonu igbo lo. Nwapfundhala nrin lo niwaju, o si mu
won lo sibi igi oniho ninu ana. Nigbati won rii, o toka re si orebirin re osi so ni ohun oke ti awon toku na ko le sai gbo wipe: "Igi ti mo fe niyen ma si fi ori rni ge lu1e! Nigbana, Nwapfundhala kekere, pelu
idaniloju ninu ara re, yan lo sidi igi na o si rora fi ori re tii. Igi oniho na wo lule ni okiti igi lila.
Orebirin Nwafene woo pelu iyalenu, Nwafene yara dahun: "Beeni, emi ni mo ko bo se lese be. Bi erni na se nge niyen, bo ba femo". Nigbana o wo yika fun igi kan o si yan okan to tobi die ju ti Nwapfundhala

lo. Sebi on kuku tobi o si lagbara ju ehoro lasanlasan lo. Laimo, igi to yan, igi lile gbaa ni.," Igi, ti mo fe niyen!" o so fun won. "E wo rni bi ngo H ge lu1e pelu ori rni." Nwafere sunmo igi na pelu ibale
okan si bi inase die. Nigbana, o gbe ori lo sile o si kolu igi na pelu ere nla -GBAM. Lailai Nwafene ko ni daba lati fi ara re han ni eni to lagbara ju Nwapfundhala lo.
Shangani folk tales.
Ketekete Abila Akoko 8 mins. 9 secs. Ni atetekose nigbati ohungbogbo je otun lori ile aye, gbogbo eranko lo ri bakanna ko si eyi to ni iwo

to dayato tabi aso alarabara. Nigbati Eleda nse asepari ise nla re, o se awon iwo orisirisi ni nitobi ati iriri ati aso wiwo oniruru. Nigbati o se won tan, o ko won sinu iho apata kan to sunmo eti bebe
adagun nla kan. Leyin eyi gbogbo eranko to ngbe ni awon geregere onikoriko gbalasa ni Eleda ranse si pe ki won lo si iho apata na ni owuro ojo keji lati lo yan awon iwo ati aso wiwo ti won ro wipe yio
daraju fun won. Eyi fa irusoke ariwo ati ifojusona, gbogbo awon eranko lo si ni itara lati ri iru awon aso ati iwo to wa fun won.

Gbogbo won lo ni ifojusona yi, yato si Ketekete Abila, eyitioje wipe on kansoso to je logun laiye e ni ounje. Lotito gbogbo eranko yoku lo mo wipe alajebanu ni ketekete Abila. Nigbati gbogbo eranko
gbera lati lo si ibi adagun na bi ile ojo keji ti nmo, Ketekete Abila ko darapo mo won. Bi yio ba rin irin
to jin to yen, o gbodo koko je koriko tutu daradara fun ounje owuro, ko si le ri idi ti gbogbo eranko toku fi nkan oun loju lati wa sibi iho apata na. Ketekete Abila fimu soro wipe on yio tele won laipe,

leyin ti on ba ti pari ounje aro oun. Pelu ekunnu koriko lo fi soro jade, nitorina gbogbo awon eranko yoku fi Ketekete Abila oniwa abuku yii sile ni ibinu.

Leyin wakati die leyin eyi, Ketekete Abila pinnu wipe on ti jeun to to, o wa rora nyan lo si ibi adagun na ni itopase ona fife ti awon eranko yoku ti la sile. Bi Ketekete Abila ti sunmo adagun na, die llinu 14
14 Page 15
Vol. II No. 19 (Yoruba) CHANGE Radio August , 2000
15
awon eranko na ti npada lo si papa, enu si ya Ketekete Abila lati ri iyipada to wa ninu iriri won. Erin ti yan aso alawo resuresu kan ti ko wuyi loju sugbon o wa buyi kun eleyi pelu ehin nlanla meji. Kiniun
ti yan aso didan alawo eruku pelu iru nlato ni irundudu to gun. Eranko kan ti a npe ni Sable niaso
dudu to ndan pelu awon iwo tite to buru ni wiwo.

LokokanKetekete Abila koja lara gbogbo awon eranko ninu awon ohun eso won titun. Nigbeyin-gbeyin, bi o ti fe wo iho apata na, Ketekete Abila koja lara Agbanrere. Ohun to seni lanu ni wipe
Agbanrere ko riran daada nitorina aso to yan tobi pupo ju fun o wa ri gburugburu lara e. Bakanna o
ti yan iwo meji ti ko tobi bakanna o si le won mo imu re. Ju gbogbo re lo, iriri Agbanhere ko dara sugbon o dabi enipe inu re dun.

Nigbati Ketekete Abila wonu iho apata na, aso kansoso to ku ni okan to ni ila dudu ati funfun nlan1a, ko si ri iwo kokan rara. Leyin to ti rin irin-ajo gigun na, ebi tun ti npa Ketekete Abila o si yara dan aso
kansoso to ku wo. Aso ajeji onidudu ati funfun na ba mu daradara, sugbon nitoripe inu re ti npariwo ko bikita wipe won ko fi iwo kokan sile fun on. Nibayi awon eranko yoku to ti pada de ori papa ti
beresi ye ara won won pelu idunnu ninu awon ohun oso won titun. Nigbati Ketekete Abila pada de
papa ko tile bikita fun awon eranko yioku, nse lo gbori lo sile to si beresi njeun osan re lo. Awon eranko yoku ri aso onidudu ati funfun re to dayato, won si beresi rerin eleya. "Wo KeteketeAbila

okanjuwa ninu aso e titun to panilerin ti ko si ni iwo kokan," Gidigidi pariwo pelu efe. Laipe gbogbo eranko to ku beresi gbe oro na so.

Ketekete Abila ko bikita. Kini eniyan nfi iwo se nigbati o je wipe on to kanpa ni opolopo koriko ojele lati je nigbakugba ti eniyan ba fe? Titi di oni yi, Ketekete Abila ko nilo iwo sugbon nigbagbogbo lo
ma nsanra ti aso re onidudu ati funfun to dayato si ma ndan. When Hippo Was Hairy.

Oro Asokagba
Awon Oro manigbage lori itoju ati idagbasoke. "Opo igba ni iseda ma nfarasin, igbamiran a le bori e, sugbon laelae ko le parun."

Francis Bacon Onkowe ati Ojogbon 1561 -1626.
"E bowo fun ile awon baba wa."
Thomas Bullfinch, 1794-1867. "Oorun, osupa ati awon irawo iba ti di awati lati ojo to ti pe to ba je pe WOl\ wa ni arowoto eda

eniyan apankanrun' ,
Havelock Ellis Onkowe ati Amoye, 1859 -1939

"Olorun ti ya wa ni aye fun emi wa. Adehun nla ni lori ijogun. O je ti awon to tele wa bi o se je tiwa, a ko si ni eto kokan, nipa ohunkohun ti a le se tabi ti a kW1a lati se, lati ko won sinu ijiya ti ko nidi,
tabi 1ati du won ni anfani to wa ni ipa wa lati fi sile fun won.
JohnRuskin. "Eniyan ko le ja itanna kan laiko darnu irawo kan."

Francis Thompson Akewi 1859-1907. 15

Page Navigation Panel

1 2 3 4 5 6 7 8 9
10 11 12 13 14 15

 

© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw