Go Back
Communicating for Change

Document Body Page Navigation Panel

Pages 1--16


Page 1 2
Vol II No. 15 February 2000 CHANGE Radio (Yoruba)
1
IWA ODARAN
A nfe Ogba Ewon ti ko ganilara 1min. 8secs. 15 A ko se agbekale ogba ewon orile-ede Naijiria lati se atunse awon elewon

Idanileko Oniifiorowero si aso loju awon ofin orileede Naijiria
to se atileyin fun lilu Iyawo 3mins. 12secs 9
Olopa Naijiria ko le dekun iwa ipa abe ile si awon obirin ati omode

EKO
Orile-ede Niger Republic wa ona lati
se imupadabo awon ti ko ka iwe won yori 3mins. 18secs. 8
Orile-ede iha iwo-oorun Afirika gbe igbese

kiakia lati se idena akojo awon eniyan ti ko ba awujo mu.
Opo Ibugbe sii fun Awon Omokunrin ati Omobinrin Agbaye to je alaini 26secs. 15

Pupo ninu awon orile-ede aye lo ni Ibugbe fun awon omo ti a ko sile

OHUN AGBARA
Awon Ile Gbigbe lo nlo ohun agbara ina ju ni orile-ede Naijiria 1min. 53secs. 3 Pupo ninu awon ohun idana ti a nlo ni Naijiria ni a lo fun sise

ounje ati gbigbe omi kana.

OUNJE
Rogbodiyan mu ki Isoro Ipese ounje lo soke sii ni iha ila-oorun Afirika 4mins. 17secs. 5

Orile-ede Afirika medogun lo wo odun 2000
pelu ogunlogo awon eniyan won ti ko ni idaniloju ounje miran.

ILERA
O seese ki Odun 2000 mu opin ba Arun Roparose awon Omode 2mins. 42secs. 3 O seese ki ipolongo Ajo Agbaye Olodun-mejila fun iparun arun roparose awon

omode kesejari.
Awon Ayewo Tuntun se afihan Opo Ewu Taba lilo 3mins. 38secs. 10 Iku lati inu siga mimu ni a fokansi wipe yio lo soke ninu awon odun to mbo.

Ajo Agbaye so wipe Arun Kogbogun Eedi nmu irokeke ewu ba alafia ni ile Afrika 4mins. 30secs. 11
Arun kogboogun Eedi ti di isoro iwalalafia fun awon ijoba ile Afrika.
IBARAENISORO
Awon Aworan fiimu meji ti Ile Afirika lati owo Ajo Amuludun ti Ero Amohunmaworan fun Ayika gba Aami Eye. 2mins 7secs 5

Awon ajalu isoro idagbasoke ni ile Afirika ni a se afihan won ninu awon aworan
fiimu to gba aani eye.

Ayika ISE OGBIN
Abule kan ni orile-ede Ghana tewogba ise ogbin to ba ayika mu 5mins 34secs 6 Abule kan to ti dawo igbo sisun lododun duro ni o le fonnu ire oko to po to
si daraju ti awon aladugbo re lo.
1
1 Page 2 3
Vol II No. 15 February 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
2
ITOJU
Orile-ede United Kingdom se isuna Milionu merinlelogbon
owo dola Amerika fun okoowo Ipeja ni Ile Afirika 2mins 27secs 4
Orile ede geesi gbe igbese akoko lati se atunse lori idinku awon eja ile Afirika.

Okun ti ile rogba yika to tobi ju laye 24secs. 16 Ile aye meta lo paala yika okun ti ile rogba yika to tobi ju laye

IPAGBORUN
Ipa ti taba nko ninu ipagborun 1min 7secs. 15 Awon to nse siga tun dojuko esun wipe won nfa ipagborun ni afikun awon arun

to npaniyan.
Orile-ede China gbesele ise gedu sugbon o se alekun ninu ikogedu wole lati ile okeere. 25secs. 15

Igbo awon orile-ede to mulegbe China ni won nparun lati fun China ni
iye gedu to nilo.

Asale to tobi ju laye 22secs 14 O ju orile-ede mejo lo ti okokan won tobi to Naijiria ti a le ri ninu asale

to tobi ju laye

ISE GEDU
Olujodasile ajo afeinifere itoju ayika ti a mo si Greenpeace ti di agbenuso fun awon Onise Gedu 1min 1sec. 15

Olujodesile ajo Greenpeace to ti fi ajo na sile le ma ri owo to po si sugbon ko
rerin lo si ile ifowopamo.

IRIN-AJO AFE
Okoowo wiwo awon Eye 1min 47secs 14 Kini awon ohun to dara ju lati fi se agbekale okoowo Eye?

Eto fun Awon Omode Ketekete ati Erinmi 4min 14secs. 12
Okanjuwa Keteketa ati Esan Erinmi
Idi re ti Emo Apata Ko fi ni Iru 3min. 55secs 13 Iwa ole ati aigboran mu ki Emo Apata padanu ebun ti oba fun un.

Oro itoju ayika ti enikan so lori awon Ajalu Iseda Aye 47secs. 13 Nje gbogbo ebi agbaye le gbeni ibamu pelu gbogbo iseda aye?
Eranko wo lo buru julo? 1min. 35secs. 14 Se asobade meta ki o to ka akosile na. 2
2 Page 3 4
Vol II No. 15 February 2000 CHANGE Radio (Yoruba)
3
Iroyin
Awon Ile Gbigbe lo nlo ohun agbara ina ju ni orile-ede Naijiria 1min. 53secs Eka ile gbigbe ni aarin-ilu lo nlo eyito poju ninu agbara ina ti won ngbe jade ni orile-ede Naijiria. Eka na lo nlo
gbogbo ohun idana abalaye bi igi idana ati idamerin gbogbo awon ohun idana ode oni. On lo nlo iko meta ninu merin gbogbo epo oyinbo kerosini ni orile-ede na. Gegebi awon imo ti a ri kojo ninu iwadi ati awon
atejade lati odun 1992, 1995 ati 1997, on na lo nlo eyiti o ju idamewa lo ninu ina ilentriki ati eyiti o poju ninu
eefin alagba fun idana. Iwadi fihan wipe awon agbara ina yi ni a nlo fun sise onje ati mimu omi gbona.

Nitorina awon idojuru to nsele loorekoore ninu sise epo robi jade tabi ilana iye owo tita won lo nkan awon ile gbigbe ni aarin-ilu orile-ede na ju awon onimooto tabi ero to nwoko li Eyi yato si ohun ti a ro tete. Eyi to poju
ninu agbara ina ti a ngbe jade ni orile-ede na lo nwa lati ara awon ohun idana lati i nu ile, eyi ti epo robi je apere
to dara kan.

Bena ni, ilo ohun idana lati inu ile ti lo soke ni ilopo mewa lati odun 1970, ilo awon ile-gbigbe ni aarin-ilu lo si fa eyito poju ninu ilosoke na.

Iye awon olugbe ilu to nyara po si, titobi si awon ilu ati iyara ninu idagbasoke oro aje ati okoowo ati imogirisi idagbasoke awon igberiko ni o wa lara awon ohun to fa ilosoke ninu ilo agbara ina.
Gegebi awon oluwadi ni ile eko giga Yunifasiti Imo Ero ti Ladoke Akintola ni Naijiria se so, ilosoke ninu ilo ohun idana inu ile ninu awon ile gbigbe je afihan rere fun idagbasoke oro aje. Sugbon ko iti yori si idinku ninu
ilo igi idana, paapa ni aarin ilu. Ohun to fa eyi ni wipe ipese awon ohun idana bi epo oyinbo, eefin alagbara fun idana ati eedu ko iti lo deede tabi se gbekele.
Boiling point
O seese ki odun 2000 mu opin ba Arun Roparose awon Omode 2mins. 42secs.
Igbonara ayo to po lo wa ni Ajo Agbaye ni odun yi bi o se ngbaradi fun isegun pataki ti eto ilera awujo lori arun buruku, roparose awon omode. Ipolongo na, eyiti o bere ni odun 1988 lati pa roparose awon omode

run ni odun 2000, ni o ti nlo sopin bayi ti aseyege si wa ni arowoto. Iye arun roparose omode ti lo sile pupopupo lati oke metadinlogun ati abo ni odun 1988 si egbaa meji o le egbefa ti a royin re jakejado aye ni
odun 1999.
Gegebi oro Gro Harlem Brundtland, Oludari Agba fun Ajo Agbaye fun Oro Ilera (World Health Organisation (WHO) ni osu kini odun yi: "A wa ni bebe isegun ilera awujo kan ti yio wonu iwe itan, iyen ni iparun roparose
awon omode, arun to ti fa iya ti ko se fenuso fun ogunlogo awon omode."
Arabirin Bruntland ati Carol Bellamy to je Oludari Alase fun Ajo Akojo Owo ni Agbaye fun Awon Omode (United Nations Children's Fund (UNICEF), ti kowe si awon olori awon ogbon orile ede ni ile Afrika ati Asia
nibiti a si ti ri arun na. Won ro awon olori na lati se iwuri fun alekun akitiyan ifun nini abere ajesara, ki won se ipese awon ohun elo fun awon ojo ifunnini abere ajesara ni awon orile-ede na ki kan won si petu si awon ohun
to le fa rogbodiyan.
Gegebe bi Arabirin Bellamy se so ni ilu New York laipe yi "Niwongba ti a ba si ri ikolu arun na titun lara omode kan, gbogbo omode nibi gbogbo lo si wa labe ewu arun yi". 3
3 Page 4 5
Vol II No. 15 February 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
4
Ise agbese agbaye na lati pa arun roparose omode run nigbati yio ba fi di opin odun 2000 ni awon ajo WHO, UNICEF ati Rotary Kariaye nse asaju fun. Ni orile-ede India ni ti ri iko adorin ninu ogorun ikolu arun na to
si wa ni agbaye. Igbese lati pa arun na run ni odun 2000 da lori akitiyan to nlo lowolowo lati paa run ni orile-ede India.

Gegebi Dokita Brundtland se so nibi agbekale "Itisonu to Gbeyin fun Roparose Omode" ni olu ilu India nibi ti awon odunrun asoju pejo si lara awon ti a ti ri awon asoju orile-ede lati ile Afirika ati Asia: "Ni odun 2000 -odun
ifokansi fun iparun roparose omode -a ni aye bi oju ferese lati bori arun na titi laelae".
Lati igbati a ti se agbekale igbese fun iparun roparose omode ni odun 1985, ikolu arun na ti lo sile patapata. Iye awon omode ni agbaye to ngbe ni agbegbe ti ropanese omode si wa ti dinku lati iko adorun ninu ogorun
si bi idaji, a si ti pa arun na run ni ile Amerika, ile alawo funfun Europe ati Iwo-oorun okun Pacific, eyito poju
ninu Aringbungbun Ila oorun ati iha ariwa ati gusu Afirika. United Nations

Orile-ede United Kingdom se isuna miloonu merinlelogbon owo dola Amerika fun oko-owo Eja ni ile Afirika 2mins. 27secs.
O seese ki orile-ede United Kingdom se agbekale ona titun lati fi dekun abajade ti ko dara lori oro aje lati inu iyara dinku awon eja ni awon ibi ipeja ile Afirika to wa laarin okun. Laipe yi ni o se ifilo eto oni milionu
merinlelogbon lati se iranlowo fun awon talika apeja bi milionu marun ni awon orile-ede Afirika merinlelogun ti oro na kan julo. Eto na ko doju iwon ipolongo ti awon ajo afenifere itoju ayika to se aridaju itundunadura
laarin awon orile-ede Afirika ati ti ile alawo funfun Europe lori awon adehun kariaye lori ipeja eyiti o ti yorisi
ipejaju ati idinku onikiakia ninu akopo eja okun ile Afirika lati owo awon oyinbo ile Europe fe.

Awon afenifere itoju ayika ti bere fun adehun titun labe Ipade ti Lome eyi ti yio ge owo iderun si eka ipeja kuro, ti yi din titobi awon oko ipeja inu okun ku ti yio si se atunse si awon imo ipeja eyiti o fi aye gba awon lati
ko ohun gbogbo kuro ninu okun kariaye ti Atlantic. Awon adehun titun na yio tun se agbekale abojuto to dara
si lati se aridaju imulo ati sisan owo to boju mu fun awon ijoba ile Afirika fun pipeja ninu awon omi won.

Eto Ise Ojoo Ipeja Alagbero (Sustainable Fisheries Livelihoods Programme (SFL) ti oni milionu merinlelogbon owo dola Amerika ti ile Geesi na ni yio se iranlowo fun awon talika eniyan to ju milionu marun lo ti won nsise
ninu ise ipeja akosemose ni awon orile-ede to nkopa ninu eto na. Eto na yio se kokari fun ilo agbero fun awon
oro eja ati ti isepataki ipeja fun awon talika apeja na, awon to nlo eja ati awon onisowo. Yio tun ran awon orile-ede to nkopa lowo lati koju awon isoro ti won ti damo eyiti o jemo ipeja akosemose. Lara awon wonyi

ni a ti ri ipejaju, ona ipeja to npa eja run, ibaje awon ibugbe adayeba, ipadanu to nsele leyin ikore, ija laarin awon apeja, idoti, egbin, ikodanu awon ohun ti won ko mo eja ati pipa awon eya eja ti a ko fokansi.

Awon orile-ede wonyi lo je ifokansi fun eto SFL -Anglola, Benin, Burkina Fasso, Cameroon, Cape Verde, Congo, Cote d'Ivoire, Democratic Republic of Congo, Equatorial Guinea, Gabon, Gambia, Ghana, Guinea,
Guinea-Bissau, Liberia, Mali, Mauritania, Niger, Nigeria, Sao Tome ati Principe, Senegal ati Togo. Ajo FAO ni yio se akoso eto na, Eka Ile Geesi fun Idagbasoke Kariaye (United kingdom's Department for International
Development (DFID) ati awon orile-ede Afirika na yio lowosi eto na. FAO/ Obasi Ogbonnaya 4
4 Page 5 6
Vol II No. 15 February 2000 CHANGE Radio (Yoruba)
5
Awon Aworan Fiimu Meji ti Ile Afirika ti Ajo Amuludun
ti Ero Amohunmaworan fun Ayika se gba Aami Eye 2mins 7secs.
Malu na fo koja lori osupa Na ati Nigbati awon Okunrin Rere ko ba se Nkankan, aworan fiimu meji
nipa awon ajalu pataki ni Ile Afirika ni ogun orundun eyiti Ajo Amuludun ti Ero Amohunmaworan fun Ayika (Television Trust for the Environment (TVE) se, ni o ti gba aami eye ni ateriwo egberun odun titun.

Okan ninu won, Maalu na fo koja lori Osupa na, ni a fun ni aami eye ti 'Prix de l'Innovation' ni Ayeye
Kariaye ti Odun Awon Fiimu ti okun ati Iwakiri, to waye ni Toulon. Aworan na, eyiti Chris Walker ya, tele awon eya Fulani asikiri ti Iwo-oorun Afirika ninu irin-ajo isikiri won gegebi won ti nkoju gbogbo ikolu ati ibaje

iseda aye, lati wa awon ibuje koriko to dara fun awon maalu won. Aworan na fihan bi itiraka lati wa awon
papa ibuje to ti ndinku lo se se apejuwe itiraka lati funka mo igbe aye ibile to nti npare lo. Iranlowo wa nigbeyingbeyin lati orisun ti a ko lero, eyiti o fihan bi imo ero ti inu ofurufu ti le se iranwo lati se itoju igbe aye

ibile ati ayika.

Maalu na fo Koja lori Osupa Na ni won koko se afihan re ni Ayeye odun Aworan Fiimu ati Fidio ti
Margaret Mead ni ilu New York. Won ti yan fun Ayeye Odun Aworan Fiimu lori Ayika ti ilu Washington DC ti yo waye ni March 2000.

Aworan Fiimu Keji ti akole re je Nigbati Awon Okunrin Rere ko ba se Nkankan ni o gba Aami Eye ti odun
1999 fun Iroyin Oniwadi ti o dayato ni Kariaye. Ajo awon Akoroyin Oniwadi ni Kariaye (The International Consortium of Investigative Journalists (ICU) lo fun won ni aami eye na ni ile Europe. Steve Bradshaw ati

Mike Robinson lo ya aworan na, won si dojureko ajalu iparun awon bi milionu kan eya Tutsi ni orile-ede Rwanda ni ewadun to keyin orundun ogun. Aworan na bere idi ti awon erile-ede Iwo-oorun ko fi le se
nkokan lati dena iwa were yi biotilejepe won ti ni imotele nipa re? Awon adajo to fun won ni aami eye na ro
won wipe ki won fi aworan na han awon omo ile-eko jakejado aye "lati se afihan bi iwa ojo ti oselu se fi aye gba ipaeyarun pada sinu awujo agbaye."

oneworldoerg
APILEKO ORO
Rogbodiyan mu ki i soro Ipese Ounje lo soke si i ni iha Ila-oorun Afirika 4mins. 17secs. Bi orile-ede Afirika meedogun ni yio wo inu odun tuntun pelu idojuko idagiri ounje to ga. Awon orile-ede

Angola, Burundi, Democratic Republic of Congo, Republic of Congo, Eritrea, Ethiopia, Guinea-Bissau, Kenya, Liberia, Rwanda, Sierra-Leone, Somalia, Sudan, Tanzania, ati Uganda lo njiya lowolowo latari
rogbodiyan to ti sele laipe tabi to nlo lowolowo. Apapo ogun abele olojo gbooro ati ogbele ti ni ikolu lara
ogbin ati ikore irugbin ni gbogbo awon orile-ede na.

Nigbati o nkilo nipa bi nkan se buruto ni orile-ede Sudan, Ajo Agbaye fun Oro Ounje ati Ise Ogbin (United Nations Food and Agricultural Organisation (FAO), so ninu iroyin kan laipe yi wipe ogun ati ogbele ti ge
awon eniyan to fere to milionu meji kuro ninu eto ideran ati pe iku lati owo ebi ti bere si sele.
Iroyin na so bayi: "Ogbele na eyiti ilosoke ninu rogbodiyan tun mu buru si ti si opolopo ebi nipo pada. Ija na tun ti se idarudapo si ise ogbin ati ikowole iranwo aanu fun awon to nilo re julo. Ilosoke iwa-ipa ti se idinku
ninu ipin funni awon nkan iranwo anu, awon iku to jemo ebi ni a si ti nroyin re."
Iroyin na ni a gbejade ati owo Eka Ajo FAO fun Ifitonileti ati Itetekinini lo ni Agbaye. Ogbeni Miwita Rukandema to je Amoye Agba nipa oro Aje ti Ile ise na so wipe. "Akopo awon ikolu ogbele, rogbodiyan
olodun gbooro, isipopada awon olugbe ati awon kokoro ire-oko ti a ko dekun won ti mu ki ipaya wa fun awon olugbe Somalia lori oro ounje. 5
5 Page 6 7
Vol II No. 15 February 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
6
Ni awon ibomiran ni ila-oorun Afrika, ogbele ati ojo ti ko ro deede ti din ikore oka ku ni orile-ede Kenya, Uganda ati Ethiopia, eyi si mu ki opolopo eniyan ma woke fun iranlowo ounje. Ni orile-ede Eritrea, oke
medogbon eniyan ti o sipo pada latari ogun pelu orile-ede Ethiopia ni o dojuko owongogo ounje. Ni orile-ede Sudan ewe, bi ireti pe nkan yo dara ti wa to, milionu meji eniyan ni iha gusu lo gbarale iranlowo onije ti
pajairiri latari ogun abele to nlo lowolowo.
Iroyin na tun woye wipe ekun awon Adagun Nla ti aringbungbun ila-oorun Afirika si dojuko igara ounje latari
rogbodiyan to wo lowolowo ni opolopo agbegbe ni ekun na. Fun apeere, isoro ounje to po si ni Burundi latari iloseke iwa -ipa ni awon agbegbe kan, eyiti o yorisi isipopada awon eniyan lotun ti o si fi agbara da eto

iranlowo aanu duro lati ile okeere si awon bi milionu kan eniyan to wani awon ibudo asasala.
Gegebi iroyi na so so: "Igbe aye ninu awon ibudo wonyi ko dara rara; ko si omi mimo ati eto imototo" O si wa
so tele wipe owongogo ounje yio buru si ni awon osu to mbo niwaju.

Ni orile-ede Democratic Republic of Congo, iroyin na so wipe regbodiyan ti so awon eniyan bi milionu mewa di eyiti ko ni idaniloju atije onije miran; nigbati rogbodiyan to doju ise ogbin ati itaja ru ni orile-ede Republic of
Congo to je amulegbe won. Biotilejepe Rwanda ni alekun ikore ounje laarin odun na; yio si nilo iranlowo
ounje lati le bo awon asasala to npadobo bi oke marundinladota. Ni orile-ede Angola ati Madagascar, wahala ipese ounje ni o buru si latari ogun abele ati iyabo esu. Ni awon ibomiran ni iha gusu Afirika ati opo

ninu iha iwo-oorun Afirika, ipese ounje wa ni deede.
Gegebi Ajo FAO se so ni Iwo oorin Afirica awon agbegbe ogbele sahel ti ni ikore ire oko to po ni awon orile-ede
bi melo kan bietilejepe omiyaleya-ona to buru pupo wa mi awon agbegbe kan ni orile-ede Gambia, Senegal, Mauritania, Mali, Niger ati Chad. Orile-ede Guinea-Bissau, Liberia ati Sierra-Leone nikan ni o si

nni isoro ounje latari rogbodiyan to ti wa tele.
Iroyin na so bayi: "Sugbon nkan ti ndara si i ni orile-ede Sierra-Leone ati paapa ni Liberia nibiti awon ilowosi
orisirisi ninu ise-ogbin ti mu alekun to dara wa ninu ipese ounje. FAO

Abule kan ni orile ede Ghana tewogba Ise Ogbin to ba Ayika mu 5mins 34secs. Ni ododun, igbo ma njo laulau, a si ma pa ohun ini ati eweko run ni awon ekun meteta to wa ni ariwa orile-ede
Ghana. Sugbon ni abule kan, Nwodua, to wa ni ibuso mewa si Tamale to je olu-ilu ekun naa, igbo kii jo, o si duro gegebi apere to wunilori iru nkan ti iwa rere nipa ti ayika le se.

Gegebi Issahaku Abubakar Sadiq omo odun mokanlelegoji se so: "Fun odun mesan, ko si isele igbo sisun kokan ni Nivodua."
Nigbati won gbo, lati enu oluko won ninu ile-eko agba ni odun 1988 nipa awon ibaje ti igbo sisun nmu ba ile, eweko ati ohun ini, awon eniyan na pinnu lati ina fi aye gba igbo sisun ni agbegbe won biotilojepe ododun ni
won nse odun ina jakejado ekun na.
Lododun, awon eniyan a moomo dana si igbo lati se kabo si akoko ipese ile fun akoko-ogbin lati bere.
Laisi idena kokan, ina na ti ba ohun ini ti isiro kan lati owo Ajo Panapana ti orile-ede (National Fire Service) pe owo re ni bilionu (milionu lona ogorun) kan owo Cedi je ni odun 1997 (bi oke metadinlogun abo owo dola
Amerika). 6
6 Page 7 8
Vol II No. 15 February 2000 CHANGE Radio (Yoruba)
7
Ni awon ekun ariwa meteta na, igbo sisun nigbagbegbo ti din ora ile ku o si de ibi ti opolopo awon agbe ti gbagbo wipe kadara awon ni.
Sugbon Issahaku ti woye alekun to han gedegbe ninu ire oko lati igbati abule re ti dawo igbo sisun duro ti won si fi aye gba iseda aye lati tun fi eroja sinu ile na.
O se iranti wipe: "ni igba atijo nigbati a ti fere so igbo sisun di ilana esin olododun, ise ogbin soro nibi pupo.
Nigbati mo ba se afiwe ile nigbati mo wa ni omode si bi o se wa nisisiyi, mo mo wipe dajudaju dida igbo sisun duro ti mu anfani ba abule yi. Teletele, ile na ma nle, o si se haunhaun. Ile na soro lati ro, pelu bi ategun ati

iwolo ogbara ti buru to ni agbegbe latari ile iyanrin ti ko dipo ati oke ile to nse agbero fun eweko.
Nisis si yi ti a ti fi aye gba eweko lati dagba laisi igbo sisun ni akoko eerun iwolo ile ti dinku, eyi si se alekun to
po ninu eroja to wa ninu ile. Lododun ni ile na nlora sii."

Pelu oko agbado to kun to si ni awo kikun, ko si eniti o le jiyan wipe ile na ko lora.
Ni Nwodua ko si eniti o nlo ajile ti ki ise ti iseda aye. "A gbarale iseda aye lati se idapada ohun ti a ti mu kuro
ninu ile nipa yiyera fun igbo sisun. A nse idapada sinu ile nigbati a ba nse ipese ila na fun ogbin. A tun nlo ajile ti ijera eweko ati igbe eranko."

Awon agbe na tun nlo awon ohun itoju miran bi ogbin saarin poro ebe ati iyi ohun ogbin pada lati odun kan si ekeji. Eleyi si mu abajade to dara wa.
"Lati odun 1992, a ko ni idi lati na owo wa ti ko to lori ajile onikemikali. Nipa bayi a ni owo sii lati na sori ise ogbin gangan."
Eyi ti se okunfa opolopo awon odo sinu ise-ogbin, sisa lo si Tamale tabi Accra lati wa ise ti ko si si ti dinku.
Agbe miran, Paul Alhassan so wipe biotilejepe ire oko lati sare kan nisisiyi je bi apo iresi mewa si mejila, eyi ko iti to bi o se wa tele ni bi ogun apo ni nkan bi odun 1970.

O so pe: "ki o to di odun 1992 ire-oko lo sile gan an, mo si fere jawo ninu ise ogbin."
Ohun ifanimora miran ni Nwodua ni alekun to ti de ba awon igi won, ninu awon igi ibile bi sheanut ati dawadawa ati awon igi eleso bi kaju, goba, mongoro ati ibepe. Awon miran ni neem ati acacia.

Pelu iranlowo lati owo Eto Imudarasi Ayika ni Afirika ni odun 2000 ti Ajo Agbaye fun Eto Idagbasoke
(United Nations Development Programme.) Nwodua ni ibudo itoju awon ojele igi nibiti awon abule to ba fe se awokose re ti ma ngba awon irugbin won.

Alhassan so wipe awon igi ti awon gbin lo se iwuri fun awon lati ma jo igbo won "nitori igi ni o ma nfaragba ju ninu ina-igbo."
Ni odun 1993 Ise "Agbese ti Nwodua lori Igbo lo gba aami eye ti agbegbe Kumbungu fun "ilowosi to dayato" si idagbagba soke ise-ogbin lati owo Eka Ile-ise Ijoba fun Ounje ati Ise Ogbin. 7
7 Page 8 9
Vol II No. 15 February 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
8
Ni odun ti o tele, o tun gba aami eye ti ekun na fun ise agbese igbo-dapo mo-ogbin, ati ni odun 1997 won gba
aami eye miran eyi ti won se alekun re pelu ebun ti won gba lati owo Ajo fun Ipolongo Idena Igbo Sisun ni odun to koja. Ise ogbin to dara pelu ilo awon iseda aye ti yorisi awon omode to ri ounje to dara je, opo owo

sii fun awon abule na ati idinku idaamu lori owo ile-iwe.
Pelu olugbe ti ko ju edegberin odin medogbon eniyan, Nwodu ni ile-eko akobere, ile eko Girama Kekere ati
ibudo ekose nibiti won ti ngba eko lori ise gbenagbena, ikole and itewe fun awon akeko bi okoodinirinwo.

Laisi ani ani, abule to ye lati fi se arikogbon ni. Edward Ameyi bor.
Orile-ede Niger Republic wa ona lati se imupadabo awon ti ko kawe won yori 3mins 18secs
Bawo ni o se le koju isoro awon odo to je wipe leyin ti won ti kuna lati kawe yori, won ko ri ipo won ninu awujo, tabi ni igberi ko won, larin agboole won tabi laarin ilu nibi ise won?

Ni orile-ede Niger Republic, awon odo to ti yo sonu kuro ni ile -eko ndapo mo ogoro awon ti ko ni ise ni aarin-ilu, won ko si fe pada lo si awon abule won ni itiju. Awon to pada lo si igberiko ko ni ikosemose kokan
ti won le fi ri ise se.
Awon obi woye wipe ko rorun fun awon omo ile-eko to ti tete fi ile-eko sile lati ri ipo dimu laarin awujo. Nigbati awon obi won ri wipe ilana ile-eko ko ni ipa rere lori ilana ebi ati agbegbe, ara bere si fun won si ilana
ile-eko, won ko si fe ran omo won lo si ile-eko mo.
Lati koju isoro yi, Eka Ile-ise Ijoba fun Eko ati ajo orile-ede Faranse kan ti ko lowo ijoba ninu ti a pe ni 'Aide
et Action', bere ise agbese kan ti a pe ni "Awon Alabasise po Eko" eyiti a doju re ko awon odo igberiko lati odun medogun si medogbon to ti kawe de aaye kan.

Awon odo ti won yan gegebi "Awon Alabasise po Eko" yi ni won fun ni idanileko iranileti ki won to ko won gegebi akeko ise oluko. Nigba kanna won gba eko ninu isakoso ise okowo kereje kereje. Eni kokan ni o
yan ise tire ti won si fun ni iranlowo owo die lati fi bere ise okowo kekere kan. Won le ra irin ise, ero igbeoko-ojuomi rin tabi era iranso.

Ni pasiparo fun iranlowo yi, awon odo " Alabasisepo Eko" yi nko awon omode lati ile-eko akobere agbegbe ni irole irole. Awon Alabasisepo yi nran won lowo pelu ise agbelese won, lati mo ati lati ko awon eko won ati
lati se aseyori ninu eko won.
Leyin akoko asewo die, iyorisi rere farahan. Idarasi to farahan waye ninu ise ile-eko awon odo akeko ti awon alabasisepo yi nko leko.

Ni die ninu awon abule ti ise agbese ti koko bere, iyege ninu idanwo ga lo si ogorun ninu ogorun. Eyi se igbelaruge fun awon odo oluko na, o si se iwuri fun won ninu ise won titun ati lati duro sinu ebi ati agbegbe won
dipo ki won ko lo si arin-ilu.
Ise na se afihan isepataki ilowosi abegbe ati iwuri awon obi ninu eko, paapa ni ifokansi lati se aseyori "Eko fun
Gbogbo Eniyan" (Education for All (EFA). 8
8 Page 9 10
Vol II No. 15 February 2000 CHANGE Radio (Yoruba)
9
"Laarin abule awon obi faramo ile-eko sii nitori won mo wipe bi awon omo awon tile fi ile-eko sile, won o wulo fun agbegbe," Eyi ni oro ti Hamissou Oumarou to je Alakoso EFA 2000 Eka Ile-ise Ijoba fun Eko ni
orile-ede Niger Republic so. Latari iwuri to jade ninu agbeyewo iriri yi, a lero wipe eto na yo tan lo si awon ekun miran ni orile-ede na.
Africa News Online
Idanileko Oniifioro wero si aso loju awon ofin orile-ede
Naijiria to se atileyin fun lilu iyawo 3 mins 12secs.
Iwa-ipa abeile si awon obirin ki ise iwa odaran ni orile-ede Naijiria. Oga olopa tele, Sunday Aghedo lo so

eleyi ninu idanileko oniifiorowero lori "Riroyin Iwa-ipa Abeile gegebi Iwa Odaran ni orile-ede Naijiria", o si da ebi na le ori awon ofin to wa nile to fi ase onidakonko si isoro yi . Oga awon olopa ni ipinle Eko nigbakan
ri yi se awuyewuye lori awon ofin to se idiwo fun olopa Naijiria lati dekun iwa-ipa abeile doju aami.
Ajo orile-ede Naijiria kan ti ko lowo ijoba ninu "Ise Ikegbajare lori Iwa-ipa si awon obirin (Project Alert on Violence Against Women)" lo se to idanileko na ni ifowo-sowopo pelu Akojo Owo Ajo Agbaye fun Awon
Obirin (United Nations Fund for women (UNFEM) lati le ru imo soke nipa isoro yi ki won si mu awon akoroyin, olopa ati awon ajo afenifere ti ko lowo ijoba ninu sise papo lati royin iwa-ipa abeile gegebi iwa
odaran ni orile-ede Naijiria.
Nigbati o nso oro isipade patako re ni idanileko na to waye ni ilu Eko, Ogbeni Agbedo tokasi wipe awon ese bi melo kan ninu Ofin lori Iwa Odaran (Criminal Code Law) ati Ofin Ijiya fun Irufin (Penal Code Law) fi ase
idakonko fun lilu iyawo. O so wipe atunse awon ofin mejeji yio jeko olapa le se eto to ye ninu oran iwa-ipa
abeile.

Ofin Ijiya fun Irufin, paapa ori karundin logota ese kini so wipe ko si ohun to je ese ti ko ba ti mu iselese to ga wa sori enikeni ati ti a ba se lati owo obi, alagbato, oluko ile-iwe tabi oga ekose, lati ba omo re, omo agbatoju
re, akekore tabi omo ekoso re ti ko ti ju omo odun mejidinlogun wifun itoni.
Ohun Kanna lo sele si iyawo ti a lu bole "lati owo oko re fun itosona iyawo na iru oko ati iyawo na ti won walabe ofin isedale ninu eyiti iru ito sona be ti ba ofii mu".

Ogbeni Aghedo so wipe ori kejidi legota Ofin Ijujafun Inifin tun so bayi "ko si ohun lo je ose nitori wipe o fa tabi a fe kio fa tabi o seese ko fa ipalara ki palara ti iru ipalara be ba kere tobe ti eniyan ologbou ati lokan to
wani deede ko ni se awuyewiuje lori ipalara na".
Sugbon a da awon akoroyin lebi fun aiki royin iwa-ipa abeile gegebi iwa odaran tabi pelu itenumo to ye. Awon olopa si jewo wipe ki ise gbogbo igba ni awon nse akosile iwa-ipa abeile ti won ba mu esun re wa.

Ninu oro ikinikabore, Iyaafin Regina Amadi-Njoku to je olugbaninimoran lori eya fun UNIFEM ni Iwo-oorun Afirika so bayi, "Iwa-ipa si awon obirin je iwa odaran ti a gbodo mu be, pelu eyi ti o ba sele
laarin ebi."
Gegebi oro Iya Afin Effah Chukwumah, Oludari Alase fun Ajo Ikegbajare. "Awon olukopa ninu idanileko na
pinnu lati fojusi awon koko oro bi melo kan ninu akitiyan ti yo tun waye lati koju ainiimo to buru pupo lori iwa-ipa abeile lati orile-ede Naijiria. Lara awon eleyi ni ati ri awon eto ifuniniimo, ifitonileti ti a le gbeyewo si ara

won laarin awon olopa, awon ajo afenifere ati awon akoroyin ati ipolongo fun atunse awon ofin to nse atileyin fun iwa-ipa abeile.
Project Alert

. 9
9 Page 10 11
Vol II No. 15 February 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
10
Awon Ayewo Titun se afihan opo Ewu to wa ninu Taba lilo 3mins 38secs.
Awon ti yio ku lati inu siga mimu yio po si ni ilopo meta tabi jube lo laarin odun medogbon to nbo. Awon iroyin to jade laipe yi lati odo Egbe orile-ede Amerika fun Okan (American Heart Asscociation (AHA) beru wipe
opolopo omo Amerika ni oro na yio kan nitori awon omo kekeke to nmu siga ni orile-ede Amerika to npo sii -o si ti to bi milionu merin ni odu yi. Awon bi milionu marun ninu awon omode yi ni yio ku iku to je mo siga
mimu laarin awon odun to nbo. Nibayi awon ogunna gbogbo to nse siga ni agbaye ti nsise takuntakun lati gbe owon ate ipolowo nlanla to fese mule gidigidi duro lati fa awon omo orile-ede Naijiria sinu siga mimu.

Awon akosile Ajo Agbaye fun Ilera (World Health Organisation (WHO) to wa ninu iroyin to ajo AHA gbe jade ntokasi wipe iku jakejado aye lati inu awon arun to ro mo siga mimu yio lo soke si milionu mewa ni odun
2025 lati milionu meta pere ni nkan bi odun 1995.
Gegebi oro Lynn Smaha to je aare ajo AHA: "O ye ki ominu ko enikeni to ba ri awon akosile yi. Owo ti won
nna lori itoju alaisan latari siga mimu ni orile-ede Amerika nikan ni a siro re si adoje bilionu (milionu lona egberun) owo dola Amerika lododun. Lara eyi ni a ti ri awon i nawo to je mo siga mimu awon alaboyun eyiti

a ti so wipe o nfa ki awon ikoko fuye pupo ni akoko ti a bi won."
Iroyin ajo AHA na tun se afihan awon ikolu buruku miran to ro mo siga mimu. Lara eyi ni ati ri ipaseje,
ipadanu ise osise, ailokun lara, iku aitojo ati ibaje ti ina to sele lati ara siga nfa.

Ireti wa fun awon to ba fe lati fi siga mimu sile. Gegebi bi ajo WHO se so, eniti o ti nmu siga tele le sun ara re seyin kuro lodo arun okan laarin odun kan to ba fi siga mimu sile. Eniti o ti nmu siga tele, to fi iwa na sile fun
odun medogun yio ti fe bo tan patapata lowo ewu iku lati inu awon arun to jemo siga to ti nmu tele.
Nibayi, awon oluwadi nfojusi awon ona to dara ju lati le se iwuri fun awon odo kekeke lati fi siga mimu sile patapata. Ona yi da lori iwadi to fihan wipe opo ninu awon agbalagba to nmu siga lo ti bere iwa na ki won to
di omo odun mejidinlogun. Iwadi kan ti won se laipe yi ni orile-ede Amerika tokasi wipe ilowosi ninu eto ti o ba nko awon odo kekeke lati ko siga mimu sile munadoko ju ki won ma da won leko lori awon ewu to wa
ninu siga mimu. Gegebi Rick Petosa to je olujumoko iroyin iwadi na se so, egbe kiko lo ni agbara pupo ju ogbon ori lo ninu mimu awon odo wonu iwa siga mimu.

Petosa ni "Dida awon odo leko leri ewu ilera ti siga nfa ko da won lekun lati mu siga. Ni idakeji ewe, awon eto awujo to nipalori eniyan fojusi awon ohun ti awon odo nkominu le lori. Awon eto to kesejari fojusi igara
awujo lori eniyan ati bi eniyan sele mo awon ona lati fi bo lowo awon igara na. O dara julo lati ko awon odo nipa awon nkan to nsele ni kiakia. Awon oluwadi miran ri wipe iru awon eto bayi lo din iye bi awon odo se
nbere si mu siga ku lati iko ogbon ninu ogorun si idaji.
Awon abajade iwadi na ni won gbejade ninu atejade aipe yi ti Iwe Iroyin atigbadegba ti Ilera Ile-eko. Awon
akosile si wa lati odo egbe pupo lara awon ti a ti ri ajo WHO, Ibudo fun Idena Arun (Centre for Disease Control) ati Ajo orile-ede fun Iwadi ojukoju lori Ilera (Nation Health Interview Survey).

ENN 10
10 Page 11 12
Vol II No. 15 February 2000 CHANGE Radio (Yoruba)
11
Ajo Agbaye so wipe Arun kogboogun Eedi nmu Irokeke ewu ba alafia ni ile Afirika 4mins 30secs.
Fun igba pipe ni awon ogun to nja ni ile Afirika ti wa lori awon oro agbeso laarin Igbimo Aabo ti Ajo Agbaye (United Nations Security Council). Sugbon ko si igba ti igbimo naa tii fi okan si Arun kogboogun Eedi gegebi
irokeke ewu si alafia lori ile na.
Ni osu to koja a fokansi wipe Igbimo eleni medogun na yio se ariyan jiyan lori oro ilera fun igba akoko ninu
eyiti Igbakeji Aare orile-ede Amerika, Al Gore iba ba ipade pataki na soro. Sugbon sa, orile-ede Russia ati China -meji ninu awon omo egbe igbimo na marun ti ipo won ko le ye -tako isele oto na.

Asoju orile-ede Amerika, Richard Holbrooke so fun awon oniroyin wipe ifokansi ipade na ni lati se afihan iye iparun ti arun na ti fa ni ile Afirika, itiraka lati se idinku si egan to ro mo arun na ati lati "beresi se atunto aabo
gegebi ohun to gbooro leyin ogun Igbaradi ju bi o ti wa tele ri lo." Ogun Igbaradi ni a nlo gegebi oro lati fi se apejuwe awon odun ti orile-ede Amerika ati awon ojulumo re ni Iwo-oorun Europe fi nko nkan ija ogun jo ni
igbaradi fun ogun agbaye pelu orile-ede Soviet Union to ti tuka ati awon ojulumo re ni Ila-oorun Europe.
Gegebi aare igbimo na fun osu ki ni odun yi, Holbrooke pe ipade gbogbo igbimo o si pe ogbeni Gore lati ka
apileko pataki lori ilana ise lori ikolu Arun Eedi. Gegebi Holbrooke se so, igbakeji Aare na yi tun se ifilo igbe owo ati awon ohun elo titun sile.

Ki ipade na to waye, Ogbeni Gore so awon ohun ti o wa nile. Gegebi oro to so lori igbesafefe ero amohunmaworan jakejado orile-ede: "Opo eniyan sii ni a lero wipe yio ku lati inu ajakale-arun kogboogun
Eedi laarin ewadun akoko ninu orundun titun yi ju gbogbo eniyan to ku gegebi jagunjagun ninu gbogbo ogun to sele ninu orundun ogun to koja lo."

Arun kogboogun Eedi ti se ibaje to ga si oro-aje ati awujo ile Afirika, o si nfi igara to ga sori ilana ilera ti ise nda laamu, o ndu awon orile-ede ni awon osise won to wulo julo o si fi awon omo orukan to ju milionu mewa
lo sile ni ile na.
Ni odun 1998, awon ogun ni ile Afirika pa oke mewa eniyan. Arun kogboogun Eedi ni ile Afirika pa milionu meji eniyan. Iha ila-oorun ati gusu ni oro na kan ju. Ibiti iko marun pere ninu ogorun awon olugbe aye gbe wa
ni o ni ju idaji lo ninu emi bi milionu merindinlogun o le oke medogun to ti sonu latari arun Eedi lati igba ti
ajakale-arun na ti bere gegebi awon akosile ajo Agbaye ti fihan.

Gegebi oro Akowe-Agba Ajo Agbaye ninu akosile re si igbimo na, isele iku lati owo Arun Eedi to po laarin awon gbajumo ile Afirika, ati awon osise ijoba, ni o ti nmu irokeke ewu ba ati se ijoba doju aami. Ikolu arun
na to po laarin awon olopa ati awon omo ogun ti so awon orile-ede Afirika di eyiti ko le koju irokeke ewu lati
ehin odi.

Anan tesiwaju bayi: "Ninu awon awujo ti ko fara ro teletele, iru akopo ajalu bayi ko le yori si ohun miran ju opo rogbodiyan si. Besi ni rogbodiyan lo ma nse ipese ile olora fun ikolu arun na siwaju. Iwopale ise ilera ati
ti eko, idilowo iranlowo aanu lati ile okeere, isinipo opolopo awon olugbe ati ikolu aarun na to ga laarin awon
omo ogun -gegebi o se wa laarin awon egbe miran to ba nlo soke sedo kakiri ile na -gbogbo iwonyi lo nmu ki arun naa tubo ma yara tan kale siwaju ati siwaju."

Ni osu to koja Anan pe awon asoju mejila mejila bi melo kan lati ile Afirika, awon eka ile-ise Ajo Agbaye, 11
11 Page 12 13
Vol II No. 15 February 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
12
awon ijoba oluranlowo, awon egbe afifeinusise ati awon ajo oloko-owo lati se agbekale ilana kan lati fi din iye bi ikolu se nwaye laarin awon omo ile Afirika ti ojo ori won bere lati odun medogunsi merinlelogun ku si bi
idamerin ki o to di odun 2005.
O kepe fun awon ipolongo ifitonileti ati idena siwaju, iyara-gbe-jade abere ajesara, itoju towo e mo niwon fun omo ile Afirika ati ifaramo awon orile-ede to lowo lati tubo gbe owo sile lati gbejako ajakale-arun na ni ile
Afirika.
Fred Eckhard to je agbenuso fun Ajo Agbaye so wipe: Annan ti lero wipe Igbimo Abo Ajo Agbaye yio di olubasisepo ninu akitiyan na lati se aridaju wipe rogbodiyan pelu awon ohun ija olowo ko tan arun Eedi kale
tabi ko dena awon ajo agbaye ati awori egbe miran ninu iti raka won lati se idena re. Deseretnews

Eto Fun Awon Omode
Ketekete ati Erinmi 4mins. 14secs.
Ni opolopo odun seyin Ketekete ati Erinmi je ore timo timo, won a si ma je oko papo ni bebe odo kanna. Ni ojo kan omi odo na lo sile, Ketekete gboju soke wo odi keji o si ri awon irugbin to tutu yoyo to si fanimora.

Ki Erinmi to de ni owuro ojo yen, Ketekete da omi ru lo si odi keji o si je eyi to te lorun ninu awon irugbin adidun na. Nigbati o pada ni asale ojo na Erinmi wo ikun re to tobi o si bere, "Nibo lo ti lo?".

"Ore mi, mo rekoja odo nibiti awon irugbin to dara ti nhu. Iwo na o se ba ni lo ni owuro ola?". "O di dandan,". Erinmi dahun, " mase lo laimu mi dani".
"Ni owuro, Ketekete ati Erinmi pade won si rekeja odo na. Bi won se nlo, Ketekete gba Erinmi ni imoran wipe oluso kan wa to nso awon irugbin na losan ati loru. Sugbon o fun ni idaniloju: "Iwo sa farabale, ore ni
Emi yio ma sona, ngo si ke ti mba ti ri oluso na to nbo. Bi o ba ti gbo ti mo ke, sa kuro ninu oko na ni kiakia." Erinmi dupe lowo Ketekete fun aanu re o si sare je ohun to ni je titi ti o gbo ti Ketekete nke. O si sare kuro
ninu oko na ni itopa eti odo na o si rekoja si odi keji lo sinu abo adagun kekere nibiti o gbe mookun sabe omi ti enikan ko le ri. Eyi tun sele ni ojo keji ati iketa, titi ti Erinmi fi woye wipe Ketekete ki isi ni waju tabi leyin on
nigbati on ba nsalo ni tori oluso ti o ni o wa nibe. Lojiji, o han si gbangba wipe ore on ndogbon lati fi eyi to ju
ninu ounje na sile funrare ni nipa jijeki Erinmi je die pere ki on si ke lati le kuro ninu oko na. Ko si oluso kokan besi ni Ketekete ko salo -o ti o -nse ni o duro seyin to njeun lo de ibi to fe.

Erinmi ko so nkankan nipa ifura re, won si nba a lo be titi ti ojo fi de ti odo tun ga soke pada.
Nisisiyi Ketekete ni lati duro si odikeji odo nitori odo na jin, isan re si lagbara, on ko si le we. O bere si tinrin si bi ebi se npa si i lojojumo nitori ko si eweko pupo leba odo na, won ko si dun lenu bi awon irugbin odikeji.

Ni akoko yi, Erinmi beresi tobi si bi oun se tesiwaju lati jeun ni awon oko irugbin ni ajeyo lojojumo.
O so fun Ketekete, "O ye ko pada wa si ibi awon irugbin yen. Wo ara re bi o se ntinrin si lojojumo, ti ounje to dara si wa ni irekoja odo."

Kekete dahun teduntedun. "O wu emi na, sugbon o mo wipe nko le we."
"Iyen o soro o," Erinmi dahun. "bi o se je ore mi ngo gbe o koja si odikeji." 12
12 Page 13 14
Vol II No. 15 February 2000 CHANGE Radio (Yoruba)
13
Bayi, ketekete gun eyin Erinmi won si bere si rekoja lo. Ohun gbogbo lo deede titi ti won fi de arin odo na nigbati Erinmi kigbe soke: "O jin nibiyi, ese mi o si le kanle mo." O ri lo si isale pelu Ketekete. Erinmi bere si
rin lo ni isale o si jade si odikeji sugbon Ketekete ti ko le we tabi se emi bi Erinmi, ri sinu odo na.
Titi di oni yi, ore laarin awon Ketekete ati Erinmi ko ti i tun waye. Shangani Folktales

Oro Itoju Iseda Aye ti Enikan so lori Awon Ajalu Iseda Aye 47secs. "Ile aye kansoso ni a jogun. Nigbati awon eniyan ba di molu si iseeda aye lati pa ibo igi run, tabi lati din omi
abeile ku, tabi lati doti afefe ayika wa debi ti iyipada fi nsele ninu afefe ile, nigbana ni awon abajade re ti a le ka gegebi ijiya eda eniyan yio le pupo. Ki a kan ma di ogbe ijiya eda eniyan lasan koto. A gbodo lo sibi gbongbo
awon ohun to nfa a ki a si se ayipada itesiwaju osi ati ibaje ayika to npo si ki o to pe ju. Ilolupo eda abemi ati
ibugbe won to se gbero ni a gbodo fokansi, ninu eyiti gbogbo ibatan aye le gbe ni ibamu pelu gbogbo iseda aye."

Alayeluwa Omoba Sadruddin Aga Khan (1985)
Idi Re ti Emo Apata kofi ni Iru 3mins 55secs. Nigba pipe seyin ni ibere iwa, siwaju ki eda eniyan to farahan, Kiniun ni oba gbogbo eranko. Siwaju si i, on

nikansoso na ni o ni iru.
Biotilejepe inu re dun o si nyangan nitori ola ti Eleda fun un, sibe o ro wipe o ye ki awon eniyan on na ni iru, nitori iru wulo pupo -ati paapa ki on Kiniun funrarare ma ba da yato laarin gbogbo won. O pinnu lati se awon
iru funrarare ki o si fun awon eniyan re.
Nitorina o bere ise o si se iru orisirisi iwo, titobi ati awo. Nigbati o se tan o pe Inaki lati pe gbogbo awon eranko jo. Ki olukuluku le wa yan tiwon. O ni ki Inaki mu gbogbo won wa si Gbogan Kiniun to wa ninu
Apata ki o si ri wipe on ko gbagbe enikeni.
Inaki gberaso lati pe gbogbo won nitosi ati lokere, nigbati yio si fi di irole, won ti bere si pejo si ibi Gbogan
Apata na. Gbogbo won, yato si Emo Apata ti a mo si Dassie. O ronu wipe o ti jinna ju fun on lati lo. Sugbon Dassie be awon obo kan to nkoja lo lati gba ebun toun fun on, ki won si se alaye fun oba wipe oju nti oun nitori

kikere ti on kere ti iwo on ko si wuni lori. Pelu ifokanbale wipe won yio ji se on, o yi wo inu iho re, o si tesiwaju ninu oorun re.

Oba Kiniun agbalagba na si beresi mu awon iru fun awon eranko to pese bi olukuluku se nnawo si eyiti o fe sugbon Kinun se opolopo asise nitori ko ri ran daada mo biotilejepe osupa kun o si tan rokoso. (Nitori idi eyi
ni Okere fi ni iru to gun ju ara re lo nigbati Erin si ni iru to tiririn to si tun kuru pupo.)
Nigbati o ti ko pupo ninu awon iru na fun won, Kiniun woye wipe Dassie ko si nibe. Awon eranbo ti beresi
ki ara won ku orire, won si nwo iru ara won sira won, nigbati awon Obo sese ranti lati jise Dassie. Inu bi oba si Dassie fun aiteriba fun ase on sugbon, nigbeyingbeyin inu re ro o si mu iru kekere kan to ni irun pupo fun

awon obo lati mu to Dassie lo. Oba lo sa fe ki gbogbo eranko ni iru.
Sugbon, nigbati won npada lo, awon obo pinnu lati ko Dassie logbon, nitori won ro wipe ko to fun ebun na.
Nitorina wo le iru Dassie si ipekun iru tiwon titun to gun. Inu won si dun pelu bi o se ri.

Nigbati won de ibugbe Dassie ninu apata lori oke, awon obo fi ebun won yangan won yan lo sihin ati sohun. Won so fun Dassie ole on ti won se lati fi ko logbon, won ni ni ojo iwaju Dassie gbodo teriba fun ase oba ki
o si jawo ninu iwa ole. 13
13 Page 14 15
Vol II No. 15 February 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
14
O mase o! okan Dassie baje, sugbon o ti yole ju ko ri nkankan se si oro na lo. Nitorina, idi re niyen ti o fi je wipe titi di oni yi, Emo apata ko ni iru.
When Hippo Was Hairy
Eranko Wo lo buru julo? 1min. 35 secs. Idahun si ibere yi yio ya o lenu. O tie le wipe: "Sugbon kilo se ti nko fi ronu debe?" Awa eniyan ni. Lati eyin
wa a ko mo bi iseda aye se nsise. A ro wipe a fi ohun gbogbo sinu aye fun wa lati lo bi a ti fe. A se awari wipe
a ni agbara lati yipada, lati lo ati lati parun ... ohun ti a si se na niyen ti awon eniyan miran si nse loni. Afenifere itoju iseda aye to gbajumo kan. Gerald Durrel, se apejuwe bi a se pa aye run bayi: Aye gbelege gegebi owu

alantakun. Ti o fowo kan fonran kan wa mu ki igbonriri deba awon fonran yoku. Ki ise wipe awa nfowokan owu na nikan, nse ni a nfa iho nlanla ya sinu re ." Die ninu awon ona ti a fi le gba da iparun na duro niwonyi
"Igbese akoko ti a gbodo gbe ni lati ko nipa iseda aye bi a ba ti le se to. Kiko ma nran wa lowo lati mo.
Nigbati a ba mo, yio se se fun wa lati se itoju ile aye wa ati eda abemi gbogbo to wa ninu re, ati awa tikara wa. O seese ko je awa ni yio se atunse owu alantakun ti a ti faya na."

Nje o ro pe a le se? A gbagbo wipe a le se. Chongololo

Awon Otito to wulo ni Arowoto.
Oko-owo Wiwo Awon Eye 1min. 47secs.
Nibo ni ni ile Afirika ni o le lo lati ri odindi ise oko-owo kan to o da lori wiwo awon eye? O wa ni orile-ede to kere ju ni Afirika -Gambia. Awon nkan wonyi lo so di paradise eye wiwo.

* Eya eye egbetadinladota ti a kopo sinu ile kekere bi odunrunlelegberun mokanla iwon ibuso kilomita ni igun mererin re.
* Agbekale fun irin-ajo igbafe to dara, pelu eto isinmi tiko nani lowo pupo ati oko-owo igbafe to didi nse itoju awon to fe wo eye.
* Ayika fun irinajo ti ko lewu ti ko si mu wahala dani. * Orile-ede kan soso ni Iwo-oorun Afirika nibiti eye wiwo ti dabi isinmi dipo irin-ajo pataki.
* Ibi ti o rorun ju lati ri awon eye to je eya ti agbegbe, ati wipe.
* O mo ibiti o le lo gangan fun awon eye na. O le lo si Egan Iyasoto ti Abuko fun awon eye igbo ninu igbo ti ko soro lati rin ninu re; tabi Tanji fun awon eya to po repete, nibiti o ti le ri odunrun

eya ni itopa ibuso kilomita marun leti okun, tabi si Ibudo Tendaba fun irin-ajo oko olopon lo si awon igbo igi egba ati opolopo awon eya inu igbo igi.

Sugbon ile Afirika nikan ko lo ni oko-owo fun Eye wiwo. Orile-ede Costa Rica kekere ni aringbungbun ile Amerika tobi to i lopo marun orile-ede Gambia, sugbon on na ni ohun gbogbo to ye lati fi je ibi aabo fun awon
to nwo eye. O ni eya eye to to adotale legberin, iselu to ko ni wahala, inawo igbe-aiye ti ko ga ati opolopo eweko. Arinrin ajo afe kan to lo si orile-ede na so wipe on ri eye eye ogotalenirinwo laarin ose meta pere.
Africa Birds and Birding

Asale to tobi ju laye 22 secs. Pelu ile to to milionu mejo o le irinwo egberin ibuso kilomita ni igun mererin re, Asale Sahara ni o tobi ju laye,
o si si ntobi si i. Titobi re yi je ti apopo gbogbo asale to ku laye; o si ju ile orile-ede Naijiria lona mejo lo. Arbovitae 14
14 Page 15 16
Vol II No. 15 February 2000 CHANGE Radio (Yoruba)
15
Orile-ede China gbesele ise gedu sugbon o se alekun ninu ikogedu wole lati ile okeere 25 secs.
Akosile ijoba fun ikowole gedu fere to ilopo meji si iye to ju milionu merin iwon mita ni igun mererin lo ni idaji odun 1999 leyin ti ijoba ti gbesele ise gedu ni odun to koja leyin omiyaleyaona to buru pupo. Ikowole igi ti
a sise lori re paapaa lo soke bi iko meta ninu merin. Awon afenifere itoju iseda aye mo daju wipe igbesele ise gedu ni orile-ede China ti yori si ilosoke gedu gige ni awon orile-ede to yii ka.
Aborvitae
Ipa ti Taba nko ninu Ipagborun 1min. 7 secs.
Isiro bi oke mewa sare hektari ile onigi ni a npadanu re lododun latari ise ogbiri taba, eyi to jasi bi iko meji ninu ogorun ipagborun ni agbaye, gegebi abajade iwadi titun kan ti a gbe jade ninu iwe iroyin kan ti a pe ni

Didari Taba. Ipadanu igbo yi ga pupo ni awon orile-ede to nsogbin taba, o si to bi iko marun ninu ogorun igbo orile-ede kokan. Won ma nlo igi lati fi gbe taba, paapaa ni awon orile-ede to seese ndagbasoke ni gusu
ile Afirika ati awon apakan ni Aringbungbun Ila-oorun, Gusu Ilu Amerika ati Asia. Laarin odun 1990 ati
1995, milionu merin ole irinwo egberun iwon tonnu igi ni won lo ninu sise taba, paapa fun gbigbe re.

Biotilejepe awon orile-ede die ti se iwuri fun awon agbe lati dako ogbin igi ti won o ma lo fun gbigbe taba, pupo ninu igi ti won nlo lo si nwa lati inu igbo adayeba.

Onkowe iwadi na, Helmut Geist, so wipe: "Igbagbo wipe ipagborun lati i nu taba sise ko ni ikolu to buru pupo ju ni a gbodo talaya."
Arborvitae
Olujodasile Ajo Ajatitafita fun Itoju Iseda Aye ti a mo 1min. 1sec
si Greenpeace ti di agbenuso fun awon Onise Gedu
Dokita Patrick Moore, to je olujodasile Ajo Ajafitafita fun Iseda Aye ti a mo si Greenpeace, ti ri ise miran pelu

awon egbe kan to dojuko teleri. O nsise nisisiyi fun Ajosepo Igbo ni British Columbia (British Columbia Forest Alliance) -ajosepo awon ogunna gbongbo ajo onise gedu lati orile-ede kan si ekeji ti a nfi esun kan
wipe o nse iwuri fun ise gedu lona ti ko ni agbero.
Aye ko rorun fun un ni idakeji ogba lohun. Ni apero awon oniroyin kan laipe yi nibiti o ti soro lori awon ayi pada ti won ngbero re ninu ilo ile, enikan so akara gbooro kan si i o si baa. Akara gbooro na ti ajo olounje
kan se ni won so si ni ifiehonuhan nipa dida to da awon egbe afenifere ayika. Ni tire, Moore gba eni to ju akara na lese, o si jade kuro ni gbongan pelu ibinu.
Agitrop
Opo Ibugbe si i fun awon Omokunrin ati Omobirin Agbaye to je alaini 26 secs.
Nje o mo wipe "E gba okan wa la" (Save our Souls (SOS) Abule Awon Omode ti o bere ni ilu Austria kekere
kan to nje Imst ni adota odun seyin lati owo Dokita Hermann Gmeiner ti gberu si Abule SOS irinwo-din-medogun ni orile-ede mokanleladoje ni agbaye?

SOS Nigeria
A nfe Ogba Ewon ti ko ganilara 1min 8 secs.
Pupo ninu awon elewon ni orile-ede Naijiria lo npada si ewon bi elese elekerin, elekarun tabi elekefa. Akosile ti a gbe jade ninu Awon Akosile Olododun (Annual Abstract of Statistics (AAS) fihan wipe okan ninu mewa

awon elewon laarin odun 1986 ati 1990 lo ti lo sewon ni igba meri miran. O ju ogota oke elewon lo ti won tun dajo ewon fun ninu awon odun yen. 15
15 Page 16
Vol II No. 15 February 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
16
Nigbati o nsoro lori akosile na eyiti o waye leyin bi odun meji to ye ko ti waye, egbe ajafuneto eniyan. kan -ajo Ise fun Imupadabosipo ati Alafia Awon Elewon (Prisoners Rehabilitation and Welfare Action
(PRAWA) fi esun kan ogba ewon Naijiria wipe ko doju aami Ajo Agbaye lori awon ofin fun itoju awon elewon. O wa ro ijoba lati se ayipada to to lati mu ki awon ogba ewon re kun oju osuwon. Lara awon aba
re ni a ti ri imudarasi aaye fun idaleko awon osise ogba ewon, iranlowo fun awon elewon to ti jade ati imo ara ilu lori yiye to ye lati gba awon elewon to ba ti jade pada sinu awujo.
PRAWA
Okun ti ile rogba yika to to bi ju laye 24 secs.
Nje o mo wipe okun Mediterranean ni okun ti ile rogba yika to tobi ju laye? Titobi re je milionu meji abo o le egberun mesan ati edegberun ibuso kilomita ni igun mererin re, awon ile aye meta lo si yi i ka -Afirika, Europe

ati Asia.
Eyi tumo si wipe o ni ilolupo eda abemi to dayato nipa mimu lara awon eya eda abemi egan to je ti isedale
awon ile to yika na. Arbovitae 16

Page Navigation Panel

1 2 3 4 5 6 7 8 9
10 11 12 13 14 15 16

 

© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw