Document Body Page Navigation Panel
1
OUNJE
Ajo Agbaye so orile-ede Madagacar ati Vietnam po
ninu Ise lori Ounje 1 min. 51 secs. 11 Won so orile-ede Madagascar ati
Vietnam po ninu ifowosowopo
iha gusu fun idagbasoke alagbero
Ajalu atowoda Eniyan: Idi pataki fun Ebi. 48 secs. 16 Awon otito
to jeyo lati odo Ajo Agbaye fun Ise Ogbin ati Ounje
Awon Obirin Ile Afirika tewogba ewa titun lati dojuko ebi 3 mins. 13 secs.
7 Awon obirin ni orile-ede Kenya bere ona ise-ogbin titun.
ILERA
Minisita orile-ede Naijiria Kan nigba atijo kepe fun itesiwaju igbogunti
Arun Kogboogun Eedi. 5 mins 4 secs. 8
Minisita Ilera nigba atijo gba Aare orile-ede Naijiria Olusegun
Obasanjo niyanju lati se agbedide igbogunti Arun Kogboogun Eedi
Atileyin Eledegberin Milionu owo Dola Amerika fun Igbogunti Arun awon
Omode. 2 mins 15 sces 3
Bill Gates gbe owo goboyi sile fun iwadi ati isakoso abere ajesara.
Awon Omode lowosi igbogunti Arun kogboogun Eedi 2 mins 18 secs 16 Awon
Omode wa ona kan lati fi aniyan won han lori Arun
Kogboogun Eedi
AWON ENIYAN
Awon Omo orukan npo sii ni ile Afirika 1 min. 4 secs. 16 Pupo awon
Omode ile Afirika lo ndi Omo orukan lode oni
ju ti ateyinwa lo
Ajo Agbaye se igbelaruge Eto awon alaabo-ara 42 secs. 16 Awon alaabo-ara
to wa laye je idaji bilionu (milionu
lona egberun) eniyan.
ISE
Orile-ede Kenya nseto lati siwo ijoba kuro lara ibudoko etikun kansoso to
ni. 1 min 2 secs 15
Ijoba orile-ede Kenya ngbero lati jawo kuro minu isakoso
ibudoko etikun kansoso to ni nitori iwa ibaje to ti gbile
ISOWO
Kofi Anan soro tako ibasepo lori owo ti ko se deede 1 min 58 secs 14 Awon
orile-ede to lowo ni o kilo fun wipe o seese ki awon
orile-ede talaka tapa si ilana isowo ni agbaye ti ko mu iderun ba won.
OKOWO
Ajo Oloko-owo ile geesi kan se idoko owo ninu Isoomidimimo ni orile-ede South
Africa. 2 mins 40 secs 6
Ajo Oloko-owo to je asaaju ninu ise isoomidimimo ra elegbe re ni 1
1 Page 2 3
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
2
ITOJU
Ibudo Ajogunba Aye Titun kan ni orile-ede South Africa 2 mins 37 secs. 11
Ogba Egan orile-ede South Africa kan ni agbegbe KwaZulu ni
o ti di ibudo ajogunba aye
Ofin titun ti won ndaba re nmu irokeke ewn ba Igbo Olojo-pupo to tobi
ju laye 1 min 48 secs. 4
Iparowa awon agbe ni orile-ede Brazil nse irokeke lati doju
aseyori lori ayika dele
AJALU
Iseda Aye kolu ipinle orile-ede India kan lona to le 44 sces. 15 Iji
buruku ja ni Orissa, ipinle etikun kan ni orile-ede India
IDOTI
Isakoso Egbin ni Agbegbe mu awon anfani pupo wa 8 mins 22 secs. 9 Iwadi
ni awon orile-ede mejo to sese ndagbasoke fihan wipe
ilowosi awon eniyan agbegbe ninu isakoso egbin mu opolopo anfani wa.
EDA ABEMI EGAN
Omo orile-ede Japan to wewon ni orile-ede Thailand se
iwuri fun isowo ninu Labalaba ni orile-ede Ghana. 1 min 43 secs 12 Awon
Omo orile-ede Ghana mo nipa owo elere-pupo to wa ninu labalaba
Arun mu irokeke ewu ba iye Kiniun to wa ni orile-ede South Africa 2 mins
21secs 3
Ogba Egan orile-ede Kruger ni orile ede South Africa dojuko ajakale
arun iko egbe.
Ikooko ile Afirika to ti wa labe ewu iparun ti pada bo sipo 1 min 19 secs.
6 O dabi enipo Ikooko orile-ede Ethiopia ti setan lati kuro ninu akosile
awon eranko to wa labe ewu iparun to ga.
Awon Ohun to dun moni lati se, lati ri ati lati mo 2 mins 16 secs. 16
Irinajo ranpe sinu ipinsiyeleyele emi ati awon akitiyan inu igbo
Eto Awon Omode
Ehoro ati Awon Omo Kiniun 7 mins 56 secs 13 Abo Kiniun onigberaga
gba itiju lati owo Ehoro kekere
Ko si Eja fun Erinmi 2 mins 1 secs 12 Erinmi se adehun lati le
ma gbe ni ibiti o feran -iyen inun odo
Bawo ni awon Ejo se ngun igi laini ese? 29 secs 12 Nigbamiran ipe
a ma sise bi ese
Oro ti Enikan so lori Itoju: Aye to lopin 36 secs. 12 Aye yio
fo ti eniyan ba poju ninu re.
Idi ti Amotekun fi ma nfi Ounje re pamo soke igi 1 mins 55 secs. 15 Ikoko
ki ifoni lomi lemeji
. 2
2 Page 3 4
CHANGE Radio
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba)
3
Iroyin
Atileyin Eledegberin Milionu Owo Dola
Amerika fun Igbogunti Arun Awon Omode 2 mins 15 secs Igbogunti awon arun
ti npa awon ikoko ni iha aye to sese ndagbasoke lati owo Ajo Alasepo ni Agbaye
fun
Abere Ajesara ati Ifunni ni Abere Ajesara (Global Alliance for Vaccines and
Immnisation (GAVI) ni yio lo soke lati ojo kokanlelogbon osu kini odun to nbo
latari igbowosile. Ajo Amuludun ti Ogbeni Bill Gates ati aya
re Melinda ti gbe adojo milionu owo dola Amerika sile lododun fun odun marun
eyiti akopo re je edegberin
milionu owo dola Amerika fun GAVI ni ojo kerinlelogun osu kokanla odun yi. Pelu
itanitete igbowosile yi, GAVI ngbero lati si aso loju eto awon akitiyan titun
onikiakia ni ojo kokanlelogbon osu kini odun ti nbo. Lara
koko eto na ni a tiri: * Awon itiraka onikiakia lati se agbejade awon abere
ajesara
titun pelu awon ohun to ro mo lati fi se imudarasi ilera awon
omode ni awon orile-ede to sese ndagbasoke; * Gbigbe abere ajesara jade ni kiakia;
* Lilo awon abere ajesara to munadoko ni ona to po si; * Imudarasi ona si
ise ifunniniabere ajesara alagbero; ati.
* Fifi ifunnini abere ajesara se ohun to se pataki julo fun agbeyewo
akitiyan lori idagbasoke kariaye.
Awon omo egbe GAVI je awon ti won ti faraji fun sise iwurr fun imupo si ati
ilo awon abere ajesara to ti wa tele ati awon titun ni awon orile-ede to sese
ndagbasoke. Lara awon omo egbe na ni ati ri Ajo akojo Owo ti
Agbaye fun Awon Omode (the United Nations Children's fund (UNICEF), Ajo Agbaye
fun oro Ilera (World
Health Organisation (WHO) Banki Agbaye (World Bank), Eto Abere Ajesara Awon
Omode ti Ogbeni Bill Gates ati aya re Melinda, Ajo Amuludun Rockefeller, okoowo
ti abere ajesara ati awon ajo miran.
Nigbati o nsalaye igbero GAVI fun ifunnini abere-ajesara in kiakia, ajo UNICEF
so wipe on ni ona to munadoko ti owo re si moniwon julo lati fi dena arun. Gegebi
ajo na se so, "Ki ise wipe o jeki a le yera fun awon inawo
ile iwosan ati itoju nikan, sugbon nigbati a ba paapo mo ounje to peye, ifunnini-abere-ajesara
ni ipile fun ilera ipilese to sekoko fun idagbakun-oju-won ni igba ewe." Lara
awon arun apani ti abere ajesara ndena re ni
iredodo ofun, iko fe, arun wayinlu, arun roserose, eyi ati iko egbe.
UNICEF so wipe "Pupo ninu inawo fun sise agbekale awon ohun elo fun ifunnini
abere-ajesara loorekoore ni
o ti wa nile. GAVI yio se atileyin fun akitiyan awon orile-ede to sese ndagbasoke
lati gbejako awon arun apani miran bi iba jedojedo ati iba ponju-ponto".
UNICEF
Arun mu irokeke ewu ba iye kiniun to wa ni orile-ede South Africa 2 mins
21 secs.
Gbogbo kiniun to wa in ogba Egan orile-ede ti Kruger ni orile-ede South
Africa lo wa labe ewu bi arun iko egbe ti nran larin awon eranko. Arun na wo
ogba na ni nkan bi odun 1960 lati odo awon maalu osin o si ti
kolu awon efon to wa ni ekun gusu ogba na nibiti eyiti o ju idaji lo ninu
awon kiniun ogba na to to bi egberun meji ngbe.
Iye awon kiniun ati awon eya eranko miran ti arun na ti kolu ni won ko iti
mo. Sugbon efon je eranko to ma nje papo, won si ntan arun na ni kiakia nipa
wiwuko si ara won loju. Eyi ni oro ti Dokita Michael Woodford
to je alaga egbe awon amoye nipa isegun eranko ti ajo Imuwalaaye awon Eya ti
Egbe Isokan Agbaye fun
Itoju Iseda Aye so. 3
3 Page 4 5
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
4
Gegebi afikun Dokita Woodford so wipe: "A ko ro wipe awon kiniun ma ntan arun
na si ara won sugbon nigbati o je pe won ma ndubule po won si ma njeun ni egbegbe,
o seese ki opolopo won ko arun na nipa
ajijoje efon kan to ni arun na". A fura si wipe ikolu laarin awon kiniun na
ga. Ayewo ti awo ara ti won se laipe yi lori ogbon kiniun to tinrin to si je
alaisan fihan wipe mesan ninu mewa won lo ni arun na.
Ko si iwosan ni arowoto fun arun na, beni ko si si abere ajesara lati dena
itankale. Awon osise ogba na ngbero lati ya awon eranko alaisan kuro lara awon
ti ara won da nipa sise ogba yi ekun gusu na ka.
Gbogbo awon efon to wa ni ekun ti won sogba yika na ni won o pa lati 'fo' agbegbe
na mo. Ti o ba ya won o lo awon efon ti ko ni arun lara lati fi ropo ni agbegbe
na. Won o tun se asewo lati fi mo bi yio se pe
to lati mu arun na kuro patapata ni ekun gusu na leyin ti won ba ti pa awon
efon na run. Ni idakeji, gbogbo efon to wa ninu ogba orile-ede Kruger ni won
o pa.
Nigbati o nkilo wipe ki won sora fun asise nitori ipaya, Ogbeni Mark R. Stanely
Price, Oludari ise ajo Amuludun ti ile Afirika fun Eda Abemi Egan (African Wildlife
Foundation (AWF) ni ile Afirika so wipe:
"Lakoko ti ko si wahala kokan o seese ki arun wa sugbon ona kansoso pere niyen
laarin opolopo ti eranko fi ngba ku. Sugbon pelu bi awon eranko ti npo sii ti
ko si si idalekun kokan mu ki ibesile arun buru
pupo". AWF
Ofin Titun ti won ndaba re nmu Irokeke ewu ba Igbo
Olojopupo to tobi ju laye. 1 min 48 secs Ijoba orile-ede Brazil ti gbe aba
ofin titun kan jade eyiti o le gba ipagborun to ga laaye ninu igbo olojo pupo
ti Amazon, gegebi awon afenifere ayika se so. Ofun titun na yio je ko sese
lati yi igbo adayeba pada si oko ogbin laisi ase ijoba kokan. Ni afikun yio
se iwuri fun ifiropo awon igbo ayebaye pelu igi 'eucalyptus' ati
awon eya igi miran to dara ni wiwo. Yio tun fi aye gba igbo gige ni awon egbe
oke ati awon agbegbe odo
eyiti a dabobo nisisiyi.
Awon alariwisi so wipe ofin yi yio fi eyi to ku ninu igbo okun Atlantic ti
Brazil sabe ewu to ga. Idameta igbo olojopupo to ku laye lo wa ni orileede Brazil.
Sugbon Brazil ti padanu eyito fere to idaji ninu re. Gbegebi
Robert Buschbacher to je Oludari fun Itoju ni ajo WWF ti Brazil se so. "Ti ofIn
yi ba gba ase, yio se
ayipada si gbogbo ilana ofin lori ayika. Ju gbogbo re lo, yio si gbogbo iyoku
igbo orile ede Brazil sile fun iparun to ga nitori se iwuri fun iyipada igbo
si ile ogbin".
Ofin ti a ndaba re na ni a so wipe o fe waye latari iparowa to po lati odo
Ajo orile-ede fun Ise-ogbin to je egbe awon agbe. Won see daradara tobe ti o
fi ba gbogbo eniyan lojiji, Ninu igbese na, won tile pa eka
ti Imo Ero ti Ajo Orile-ede fun Ayi ka, (Technical Chamber of the National Environment
Council (CONAMA) to ni agbara pupo ti segbe kan. Minista fun oro ayika paapa,
Jose Sarne y Filho, ko kopa
ninu idunadura aba ofin titun na, o si so wipe on ko faramo.
Awon afenifere ayika nparowa lati da ofin na duro sugbon ko dabi enipe yio seese
fun won. WWF.
Kofi Anan soro tako ibasepo lori owo ti ko se deede. 1 min. 58 secs. Akowe
agba fun Ajo Gbogbo Orile-ede Agbaye (United Nations) Kofi Anan ti be awon orile-ede
olowo
to nse opolopo nkan jade lati mu gbogbo idena owo kuro ki won si silekun oja
won sile fun awon oja lati
awon orile-ede to sese ndagbasoke, pelu ikilo wipe ilodisi awon orile-ede talaka
si isowo ti ko ni idena ko ni se koju. 4
4 Page 5 6
CHANGE Radio
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba)
5
Ninu oro kan ti o seto re fun kika ni Ipade Keta ti awon Minista Ajo fun Isowo
ni Agbaye (World Trade Organisation (WTO) to waye ni ilu Seattle ni osu kokanla
odun yi, Akowe-agba na so wipe on ni ireti wipe
ipade nla na yio je eyiti yio fi ipile ilana isowo ni agbaye to dara ti ko si
ni idena lele. Gegebi oro re: "Ayafi ti
a bale mu da awon orile-ede to sese ndagbasoke loju wipe sisi oja won sile yio
mu anfani wa fun won, bikose be ilodisi re ko ni se koju. Eyi yio je ajalu buruku
fun iha aye to sese ndagbasoke, ati paapa fun gbogbo aye
lapapo".
Anan, ti ko le ka oro re leyin ti awon elehonu ti fa ifagile ayeye isipade na,
fi esun kan awon orile-ede onimo
ero wipe won ntesiwaju lati dena awon ohun-elo lati iha aye ti ko ti dagbasoke
kuro ninu oja won. Gegebi Akowe-agba na se se itokasi, awon orile-ede onimo-ero
bi melo kan fi esun idaojasile kan awon orile-ede to
sese ndagbasoke sugbon otito ibe ni wipe awon gan an ni won nda apoju oja
won -ounje ti won ti se edinwo re pupopupo -sinu oja agbaye, ti won si ntipa
be fi ise oojo awon egbegberun lona egbegberun agbe talaka
sabe ewu.
Pelu iwoye wipe "Isowo ti ko ni idena dara ju iranlowo lo", Ogbeni Anan kepe
fun idinku to ga ninu owo ibode ati awon idena miran to wa lori ikojawole lati
awon orile-ede to sese ndgbasoke. O ni: "Fun ikojawole
lati awon orile-ede to reyin patapata, ki won fagile owo ibode ati ibufunni
oja".
Pelu ikilo lati ma da ebi lori isowo ni agbaye fun ikuna awon ilana amulo abeile,
Anan ro awon orile-ede onimo ero ki won mase gbidanwo lati wa ojuutu si isoro
tiwon laibikita fun awon talaka.
UNO
Awon Omode Lowosi Igbogunti Arun Kogboogun Eedi 2 mins 18 secs.
Iranti olododun ti Ojo Arun Kogboogun Eedi ni Agbaye, ikejila iru re, ni
o waye ni osu kejila odun yi pelu afihan ti o lagbara lati odo awon omode -awon
ti ajakale-arun buruku yi kan julo. Aworan fiimu kan ti a pe
ni Awon Iriri lati ile Agbegbe Sahel eyiti awon omode ko, to si je
akoko ninu iru re bi ogbon ni a gbe safefe ni awon orile-ede Afirika bi mewa
lara eyiti Naijiria wa. O so itan ibaje Arun Eedi ti a ba fi oju Omode wo
o. Aworan na ni itan meta nipa Arun Eedi to fun ni ni oye to si tun mu ogbon
dani, ti a ko lati owo awon meta
akoko to bori ninu idije to sile fun gbogbo omode jakejado aye.
Gegebi Ajo Igbekele Ero Imohunmaworan fun Ayika (Television Trust for the
Environment (TVE) to gbe aworan na jade se so: "Awon Iriri lati Agbegbe Sahel"
ni ifojusi ati efe to je ti ile Afirika. A gbe jade ni
awon ede ibile a si see ki a le tun won se ni awon ibomiran ni ibamu pelu asa
tiwon".
Idije na ni ajo TVE da sile lati se deede pelu koko oro fun ojo Arun Kogboogun
Eedi ni Odun yi: "Omode ati Odo: Fetisile, Keko, Walaaye". O ju egberun mejila
itan lo ti won rigba, eyiti o fihan gbangba ipa ti arun na
ni lori imoye awon omo ile Afirika. Awon ti o bori ni ogbon ekun ni won yan,
awon wonyi ni won o se itan won si aworan fiimu. Ajo TVE yio lo gbogbo egberun
mejila itan na lona kan tabi omiran.
Gegebi ajo na se so ninu oro akoso re si Awon Iriri Lati Agbegbe Sahel,
"Ko si eyiti yio sofo ninu won. Awon imo ti a ko balo ni a o toju lati je
akojopo ede, ifojusi, aniyan ati aba fun ojuutu si ati segun arun apani
yi lati odo awon odo." Gebebi oro TVE, ise agbese na ni ifojusi, ikopa ati atileyin
lati odo awon ogbontarigi osere ile Afirika. Gbogbo ogbon fiimu na ni won o
fi sori akopo agba fiimu pelu awon iwe eko ti won o si pin
won fun awon ajo to nsise fun idena ati iwosan Kokoro Arun HIV. TVE.
5
5 Page 6 7
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
6
Ajo Oloko-owo ile Geesi Kan se Idoko-owo ninu Oja Orile-ede South Africa
2 mins 40 secs.
Won ti ta ajo oloko-owo orile-ede South Africa kan to nso omi di mimo, ti
a mo si Envig Holdings fun ajo
oloko-owo Weir Westgarth ti ilu Glasgow ni Scotland fun milionu meta o le oke
marundinlogoji owo poun. Weir je ajo oloko-owo ile Geesi kan to mo nipa siso
omi iyo di mimo fun ilo ile ise ati ile gbigbe.
Egbe Weir so wipe rira ajo Envig Holdings to do si eti ilu Cape Town ti o
si ni ile ise ni ilu Johannesburg ati Botswana, ni yio yorisi idasile ajo oloko-owo
titun ti a o pe oruko re ni Weir Envig lati le pa imo ijinle awon
ajo mejeji po.
Agbenuso kan wipe "Labe adehun na, a o da ajo oloko owo titun kan sile ti olu
ile ise re yio wa ni Glasgow ti yio si ma se ipese awon ero fun siso omi di
mimo, eyiti yio dara fun awon to nlo omi to po bi awon ajo
onimonomono ati olomi, ati awon ilana ise imo ero miran. Lara awon Ilana na
ni a ti ri imo ero titun ti Envig
ti a mo si ero 'bio-reactors' ati awon ohun-elo awo tanna felefele ti won ti
gba iwe ase 'iwo-loni-won' lori won".
Paul Capell to je Oludari agba fun Weir Westgarth ti yio tun je alaga ajo
titun na so wipe: "Ajo oloko-owo na ti awon ra yio fun awon ni imo ero ti awon
nilo lati le koju ibere to nsare po si fun omi
fun awon ile ise ati fun fifo itujade ninu eyiti a lero lati kopa gidigidi.
Yio si tun je afikun awon imo nipa ise to wa ni Weir Westgarth ki o si mu anfani
kariaye wa fun Envig.
"Ilo awon ero bio-reactors oni awo tanna felefele ati iru imo ero be sese
bere ni, sugbon ilo re yio ga pupo ni ojo iwaju paapa ti a ba ro ti igbese kariaye
lati dabobo ayika ati lati se itoju omi ni ona to dara ti ko si tun
nani lowo ju bi o ti ye lo".
Weir so wipe ere miran ti yio yori lati inu adelun na ni wipe Envig ati Weir
Westgarth yio fowosowopo sise lati se ipese awon ero fun siso omi iyo di mimo
fun oja ile Afirika eyiti o nlo ona pataki ti Weir kan ti a mo
si imo ero ayi pada omi sise ati itanna waiwai onipele pupo (MSF).
Ajo Envig to ni iriri pupo nipa yiyanju isoro omi idoti ti o si tun nse awo
tanna felefele tire labe oruko Membratek ni o ti fekan sise po ri pelu ajo ile
Geesi to wa ra yi. Awon mejeji ti sise papo laarin odun meji
to koja, won si ta ero isoomidimimo kan laipe yi fun Ibudo Monomono Tukuta to
je ti Eskom, ajo orile-ede South Africa to ngbe ina monomono jade. Ero na ma
nse omi alalotunlo to to egberun mejila abo iwon
mita onigun mejo jade lojojumo. London Press Service.
Ikooko ile Afirika to ti wa labe ewu iparun ti pada bo sipo. 1 min 19 secs.
Ikooko orile-ede Ethiopia to je ikooko kansoso to je eya ti ile Afirika
lotito ni o dabi eni wipe o ti setan lati
pada bo sipo. Awari enu ojo meta yi lori awon eya eranko na ni opolopo agbegbe
ni ori apata Wollo ni iha
ariwa Ethiopia ti mu ayipada wa ninu iye won ti a ro pe o wa lati bi irinwo
si edegbeta si iye to to adota lelegbeta. Eyi si ti se igbelaruge lati se eto
itoju fun un.
Ikooko Ethiopia na ti awon onimo ijinle sayensi sapejuwe re bi eyiti o je
eya to sowon sugbon to je ojulowo ni a tun mo si Ijakumo Simien. A koko ri ni
iberepepe orundun kokandinlogun lori awon apata
Simien nibiti iye re to ku nisisiyi ko ju adota lo mo. Awon to po ju ninu eranko
na bi ogosan ni o wa ni awon ogba orile-ede ti Apata Bale ni iha ila-oorun gusu
Ethiopia. 6
6 Page 7 8
CHANGE Radio
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba)
7
Gegebi oro Dokita Claudio Silliero-Zubivi ti ile eko giga Yunifasiti Oxford
to saaju iko to se aridaju wiwa ti
awon ikooko na wa ni ibi merin ni Wollo: "Awari titun yi ti so Wollo di ekun
pataki keji fun itoju ikooko Bale. Eyi si se igbelaruge eto fun itoju awon eya
na".
AWF
Awon Apileko Oro
Awon Obirin Ile Afirika tewogba ewa titun lati dojuko ebi. 3 mins
13 secs. Egbe obirin kan ni orile-ede Kenya ti a mo ni agbegbe gegebi Ivuso
ya Mayatta, ti fi ara re han gegebi ona
to munadoko lati mu imo ero to darasi nipa eso ogbin wo awon agbegbe to talaka.
Ivuso ti itumo re je 'emi ifowosowopo' ti se aseyori lati se igbelaruge
orisi ewa (pigeon peas) kan ti o dara ju ti tele lati fi koju
aijeounje-to-darato.
Awon obirin Ivuso koko gbo nipa ewa na lati odo awon onimo ijinle sayensi to
nsise ni. Ajo Kariaye fun Iwadi
lori Irugbin fun awon Agbegbe Ologbele-die (International Crops Research Institute
for the Semi-Arid Tropics (ICRISAT) ati ni Ajo Iwadi lori Ise-Ogbin ti orile-ede
Kenya (Kenya Agricultural Research Institute (KARI)
ti won kopa ninu ise imudarasi ti ewa na fun iha ila-oorun ati gusu ile Afirika
eyiti Banki Idagbasoke Ile Afirika gbe owo sile fun. Nwon gbo wipe awon oka
na ni opolopo eroja afunaralokun, amuarawanidede, awon ora
ati eroja amuaradagba, ati wipe gbigbin won yio se ile gbigbe won loore.
Isiro bi meta ninu mewa awon omode to wa ni iha isale asale Sahara ni ko ni
iwon to latari aito eroja agbara ati asearalore ninu ounje won. Awon wonyi yio
ni anfani ninu jije ewa na eyiti o ni opolopo eroja afunaralokun
ati ora to to ilopo mewa eyi to wa ninu ewa miran, ati ilopo marun eroja amuarawanideede
(Vitamni A) ati ilopo meta ti Vitamin C. Awon ewa na ko na eniyan lowo rara
to eran sugbon bena ni o si fun je orisun to dara
fun eroja amuaradagba.
Pelu imo titun yi, Ivuso sise lati mu eroja ounje won dara si nipa sise alckun
minu iye ewa pigeonpea ti awon eniyan agbegbe nje. Awon obirin na ndin won si
nta awon akara ati akara felefele lile to ni pigeonpea to po
ninu pelu oka baba ati jero dipo oka wheat.
Oludasile Ivuso, Diana Nzomo ni: "A ti se imudarasi ounje ti a nje nibiyi".
ICRISAT to se agbekale eto idanileko ati ifuninimo fun awon onimo-ero nipa ounje,
awon to nse ounje ati awon agbe, paapa awon obirin
ni orile-ede India, Kenya, Malawi, Tanzania ati Uganda lati se iwuri fun ilo
irugbin na.
Ewa pigeonpea na yio tun je irugbin-owo, paapa bi imo nipa re ba ti nga si.
Ibere fun ikowole wa fun ni ile Asia, Ariwa Amerika ati Ile Europe, o si dabi
enipe ibere to wa to ilopo meji iye ti awon agbe ni orile-ede
Kenya ngbe jade nisisyi.
O fere je gbogbo eya ara ewa na lo wulo. Igi re nse ipese ohun idana ati igi
ogba. A le lo epo re bi ounje
ohun-osin ati ewe re bi ounje eran-osin. Ewa na tun ma ngba eefin nitrogen lati
inu afefe sara a si ma yii pada si eroja to nse ile loore.
Iwon sare hektari ewa na nmu anfani to to ti iwon ogoji kilo ajile wa. Itakun
re to ma nwonu ile lo gan an ma nse iranwo lati di ile mu ki a si dena isanlo
ile. Pataki ju gbogbo re lo ni wipe eweko na le wa omi toto ati eroja
lati so eso ninu odun oda paapa. Aseyori irugbin na dara tobe ti awon onimo
ijiule sayensi fi so wipe ko si irugbin miran to mu adalu anfani iru re wa fun
awon agbegbe ologbele-die nibiti ogbele ti ma nwaye nigbagbogbo.
CGIAR NEWS. 7
7 Page 8 9
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
8
Minisita Orile-ede Naijiria nigba atijo kepe fun itesiwaju igbogunti Arun
Kogboogun Eedi 5 mins 4 secs.
Ijoba orile-ede Naijiria ni enikan ti ro lati se afihan ifaramo re lati
se idaduro ati lati pa ajakale Arun Kogboogun Eedi run nipa iteramo igbeowosile,
ipolongo fun imo ati idinku aleebu to ro mo awon to ni arun
Eedi. Ojogbon Olikoye Ransome Kuti to ti figbakanri je Minisita fun Ilera ati
Oro Eda Eniyan lo kepe yi nigbati o nse idanileko ti Ojo Oludasile ni Ajo Orile-ede
Naijiria fun Oro Ile Okeere (Nigerian Institute of
International Affairs (NIIA) ni osu kejila odun yi.
Nigbati o nsoro nipa "Itesiwaju Isoro Ajakale Arun Kogboogun Eedi ni orile ede
Naijiria ati Ile Afirika," Ojogbon Ransome-Kuti se itopase itan eto idalekun
Arun Eedi ni orile-ede Naijiria, o so wipe igbeowo
sile lo soke lododun lati milionu kan Naira si milionu marun laarin odun 1986
ati 1992. O si wa lo sile lododun lati odun 1993 titi ti o fi di oke medogun
Naira pere ni odun 1999. Laarin akoko yi, iye eniyan to
ni arun Eedi ni orile-ede na lo soke lati bi eniyan meji ninu mewa iye eniyan
to wa lorile-ede na ni odun 1993 si bi eniyan mefa ninu mewa ni odun 1999.
Ni ifiwera orile-ede Senegal ni isele Eedi akoko tire na ni odun 1986, ni
odun kanna ti o sele ni Naijira, sugbon o din ni enikansoso ninu mewa omo orile-ede
na to ni arun na nisisiyi. Ransome-Kuti mu wa si
iranti wipe idasi lesekese lati owo Aare Senegal, Abdou Diouf ati gbajumo olori
elesin kan lo se iranwo lati dekun itankale arun na ni orile-ede na.
Laipe yi Aare Olusegun Obasanjo se isuna owo adota milionu Naira fun eto idekun
Eedi ni Naijiria. Ile Asofin apapo se alekun owo na lo si ogorun milionu gegebi
afihan atileyin girigiri fun eje Aare lati gbogun
ti arun oloro na ni orile-ede Naijiria.
Ransome-Kuti se alaye awon ohun ti won gbodo bojuto ni kiakia fun asoyeri igbogunti
arun Eedi. Lara eyi ni awon alaboyun to ti ni kokoro arun HIV ati 'Eedi', iwa
ibaje ninu rira ati ipinkiri oogun, ise asewo laarin
awon odomobirin, ati ainimo nipa awon ti arun Eedi ti kolu.
O fere je wipe gbogbo omo ti won nbi pelu arun Eedi lo je omo ile Afirika, besi
ni ke gbogbo iye omo ile Afirika ko ju idamefa gbogbo eniyan agbaye lo.. Iye
awon aboyun to ni arun Eedi ni Naijiria ti lo soke lati
bi meji ninu mewa ni odun 1992 si bi mefa ninu mewa ni odun 1999. Iye to ga
ju ni a ri ni Oturkpo ni ipinle Benue. Geidam ni Ipinle Yobe lo ni iye awon
alaboyun to ni Eedi to lo sile ju. Eyi jasi wipe opolopo omo
ni a nbi pelu Eedi. O fere je pe gbogbo awon omo na lo nku ki won to pe omo
odun marun. O seese ki iye na ju bayi lo nitori meta ninu merin awon alaboyun
ni ko ni anfani itoju ise isegun, gegebi oro Ransomu-Kuti.
Awon odo ti o ni arun na ti a ko bi mo won ni o seese ko ni ikolu arun na
lati inu ise asewo ati ajakale osi.
Gegebi Ransome Kuti se so, isoro kariaye ni eleyi. Awon omo asunta to to ogbon
milionu si adosan milionu ni o wa laye latari isoro awujo eda eniyan ati oro
aje. Mejo ninu mewa won lo nlo egbogi oloro.
Iwadi laarin awon omo asunta ni Eko fihan wipe okan ninu merin won lo ni kokoro
arun HIV ati Eedi. Eyi so won di igbakeji si iye ikolu arun na laarin awon asewo.
Isoro arun Eedi buru si latari iha ti awon ara ilu ko si awon to ni arun na.
Oju ma nti awon to ni arun na ti won ki ifi le jewo wipe awon ni arun na. Awon
ebi awon ti arun na pa ma nbe awon dokita ki won ma ko
iru iku to pa won sinu iwe oku won. Igba pupo ni awon eniyan ma nsa fun awon
to ni arun na ti won yio si fi ku lairi itoju, awon eniyan a si ma foju ifurasi
wo awon ebi won. Abuku to so mo arun na latari aini imo
na njeki awon to ni arun na dake nipa isoro won ki won si ku ninu irora ati
itiju. 8
8 Page 9 10
CHANGE Radio
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba)
9
Ninu oro na, Ransome Kuti bu enu ate lu awon ijoba ile Afirika fun kiko owo
to wa fun eto idalekun Arun Eedi je.
Ransome Kuti so wipe: "Inawo sona to to yio se pupo fun awon to ni arun Eedi
ni ile Afirika, pupo ninu awon to ni kokoro arun HIV ati Eedi ni a o si le gbala".
O toka si iwadi Ajo Agbaye kan to fihan wipe owo dola
Amerika mejila pere lo nde odo awon alaisan Eedi ni ile Afirika ninu ogorun
owo dola Amerika, ti won so wipe won nna lori egbogi.
Eto idekun Eedi ti ijoba to wa lori alefa ti bere ni orile-ede Naijiria pelu
awon ipolongo ori ero redio ati telifison to nkepe awom omo orile-ede Naijiria
lati mu igbe aye rorun si fun awon alaisan Eedi, die ninu awon
to je wipe won ni ikolu arun na laisi afowofa won nibe. Obasi Ogbonnaya.
Isakoso Egbin ni Agbegbe mu awon anfani pupo wa. 7 mins 53 secs. Iwadi
enu aipe yi lori isakoso egbin olodidi ni awon orile-ede to sese ndagbasoke
fihan wipe ilowosi awon
eniyan agbegbe ninu isakoso egbin mu opolopo anfani wa, lara eyiti a ti ri awon
anfani ilera ati ti awujo bi:
* Ikolejo sinu awon ikonkansi ti a pile se si iwaju ile.
* Idinku ninu awon idoti ti a nda sinu awon odo, soju titi tabi ti a ndana sun;
ati * Idir ku ninu oorun buruku to njade lati inu idalenu sibi to wu awon eniyan
agbegbe.
Awon anfani miran ni ifiagbara fun awon olugbe fun ikopa to peye ninu eto
ilu, ilosile to han ninu awon arun omode, alekun ninu ilo ile iyagbe ti ara
ilu ati ilosile ninu awon omode to nsagbe legbe awon ibudo idalenu.
Iwadi na lo da lori ise agbese mesan ti won da sile ni iwo oorun ile Afirika
ati ile Asia lati owo ajo Egbin (WASTE) -Eto Imose nipa Egbin Arin Ilu (Urban
Waste Expertise Programme (UWEP) to fikale si orile-ede
Netherlands ti ajo Oludari Iranlowo fun Idagbasoke ti orile-ede Netherlands
(Netherlands Directorate for Developemt Assistance (NEDA) ati Ile-Ise Ijoba
fun Oro Ile Okeere gbe owo sile fun. Ise na se akosile
awon isele ikopa awon agbegbe ati awon ile-ise aladani kekeke ninu imototo ati
idanu egbin olododi ti arin-ilu, o si nse iranwo lati se agbekale ki o si se
akojo awon to mose fun isakoso egbin ni awon orile-ede to sese
ndagbasoke.
Ilowosi agbegbe ninu idanu egbin arin-ilu jasi imulowosi awon ogunna gbongbo
olukopa ninu eto na bi awon
agbasese aladani eleniyan kokan ati eleniyan die (micro and small enterprises
(MSE), awon igbimo ekun jekun, awon egbe afenifere ti ko lowo ijoba ninu, awon
alase agbegbe ati awon egbe obirin oloja. Awon
miran ni oba alaye, awon olori ekun, awon olori elesin, awon oluko, awon oselu
ati awon odo.
Awon agbegbe ise agbese na ni awon ibugbe awon talaka to ni bi edegbejo si edegbaata
olugbe. Awon ni
ekun Djicoroni Para ni ilu Bamako, orile-ede Mali, ekun Gueule Tapee ni ilu
Dakar, orile-ede Senegal, ekun kan ni Ouagadougou ni orile-ede Burkina Faso,
ati ekun Siddharthapura ni ilu Colombo ni orile-ede Sri
Lanka. Awon ekun miran ni Nepal ni orile-ede Pakistan, orile-ede Philippines
ati India.
Agbekale isakoso egbin arun-ilu lati owo awon agbegbe mu ifowosowopo wa laarin
awon ajo afenifere ti ko
lowo ijoba ninu, awon ajo agbegbe, awon agbasese aladani kekeke ati awon alase
agbegbe. Awon ipolongo
imototo gba atileyin awon alase ijoba ilu lori eto imulo, atileyin imo ati ohunelo,
won si se agbekale awon ofin
imototo. 9
9 Page 10 11
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
10
Awon isoro imototo, isakoso egbin, ilosoke iye emiyan ilu ati aito awon osise
lo wa fun gbogbo awon agbegbe ki ajo WASTE to lowo si oro won. Awon alase agbegbe
ko ni irin-ise ati owona fun ifilele eto imulo, agbese
ati ayewo. Aisi ifokantanraeni larin awon ti oro na kan tun mu isoro na buru
si.
Gegebi iroyin WASTE se so: "Eyi mu ki awon eniyan ma da ile won si egbegbe titi,
aarin ogba ile ati inu odo. Titori eyi awon ibudo idalenu ti ko ni akoso beresi
po si. Awon eniyan na ko ni anfani pupo, ijoba ko kobiara
si won, won si papoju ni iye. Won ko ni oju ona, omi mimu, eto idaegbinnu ati
ipo gegebi olugbe arin ilu. O
to ogbon eniyan to wa ni ojule kan ni ekun Gueule ni ilu Dakar. Bena ni ni ilu
Karachi idaji awon olugbe ekun Ghousia ni won pe ni atipo tabi olugbe-laini-ase.
Isakoso egbin ni elekunjekun wa ni iha Iwo-oorun ile Afirika. Ilowosi awon
onise adani kekeke, awon egbe odo ati awon egbegbe agbegbe ninu kiko ile fun
awon alase ilu laaye lati dojuko awon ise miran to jemo
isakoso ilu. Ni ilu Dakar ati Bamako, o to igba awon onise adani kekeke to nipa
ninu ise kiko idoti, won si ti seto ara won si egbegbe lati dabobo anfani to
so won po. Ni ilu Bamako ati Cebu city awon obirin ma nfi
tifetife bere ise gbalegbata, imo lori imototo ati itoju ilera.
Iroyin WASTE na so pe: "Mimoye ise agbese kan ati ona ti a fi gbekale ma nse
iwuri fun ilowosi ninu re.
Ipolongo to jafafa ti a si teramo lo mu atileyin to ga wa fun eto imototo adanuse
ni ekun Ghousia colony. Ipolongo na salaye bi awon eniyan yio se kopa, o si
tun wa se iwuri fun awon eniyan lati jiroro lori eto na." Iru
ona be ni won lo pelu iyorisirere ni ilu Ouagadougou.
Bena ni a ri wipe agbekale to fun gbogbo eniyan laaye lati dasi oro ma ndara
fun isakoso egbin ilu to ni ilowosi
awon eniyan. Iroyin ajo WASTE woye wipe: "Ilowosi ninu ise kan ati ifiagbara
fun awon eniyan ilu ni o ma nwaye ti a ba fi aye gba ariyanjiyan laarin ara
ilu, ifikunlukun ati ona ajumosoropo fun ara ilu. Idaduro iselu ati
ayipada idibo ma nmu aifokantan wa fun ise agbegbe."
Osi ati aini agbegbe ile gidi ni o je awon okunfa to lagbaraja fun ilowosi.
Ko si awon idi miran to le mu awon
eniyan parapo ja fun anfani won ju irokeke ilekuro, ibere fun ile nini tabi
ifunni ipo ara ilu fun awon olugbe. Lara awon eko ti a ri ko ni wipe awon eniyan
ma nlowosi isakoso agbegbe fun egbin arin-ilu olodidi ti sise be
ba wa ni ibamu pelu ohun to je won lokan bi enikokan tabi bi egbe. Opolopo
eniyan lo fi ifeinu han nigbati o fi aye sile fun gbigba won sise gegebi agbale
tabi oluti omolanke. Ifeinu won lo sile leyin ti gbogbo ise to si sile
ti tan gegebi a se woye ni Ouagadougou, Patan City, Senegal ati Mali.
O seese ki ise akoso agbegbe fun egbin mehe ti awon olugbe ko bale sanwo awon
ise na. Awon isoro tun le waye bi awon ajo, ile-ise ati awon eniyan kokan ko
ba le: -*
bojuto ise isakoso egbin ti won da sile;
* mu ki awon olugbe lowosi ise na lati ibere; * se aridaju ipa ti olukuluku
omo egbe yio ko;
* pari ija laarin awon oluti omolanke ati awon osise alakoso; * ri aridaju
ibaraenisoro to peye pelu awon eniyan agbegbe; tabi
* se aridaju wipe ise ko poju fun awon oluti omolanke
ati agbale tabi ki owo ti won ngba kere pupoju.
Laiseaniani ona eleka pupo ni a nilo lati se ifesemule isakoso egbin alagbero
ni awon orile-ede to sese ndagba soke. Eto alagbero je eyiti o mu imototo wonu
awon ifokansi awujo, to se aridaju eto to mu ere wa, to se
aridaju ise to se gbarale to si se irusoke imo ara ilu lori isepataki re. Ni
afikun o gbodo: 10
10 Page 11 12
CHANGE Radio
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba)
11
* mu awon olukopa aladani, ti ilu ati ti agbegbe papo ki o si fun olukuluku
ni ise to han gedegbe ni orisirisi eka lati idoti kiko si atunlo awon aloku
ohun idoti;
* se agbekale imo ero titun lati pese ise ati owona; ati * fa ilowosi awon agbegbe
to talika ju, ti isakoso ilu ati ipese awon anfani ilu ko de odo won.
UWEP
Ibudo Ajogunba Aye Titun Kan ni orile-ede South Africa 2 mins 37 secs.
Ogba Egan ile olomi ti Greater St. Lucia ni ekun KwaZulu-Natal ni orile-ede
South Africa ni won ti fi ase si
gegebi Ibudo Ajogunba Aye, eyi si fa ayeye ni Ile ise Itoju Iseda Aye ti KwaZulu-Natal
(KwaZulu-Natal Nature Conservation Service (NSC). Eyi ni yio je ibudo ajogunba
aye akoko iru re ni orile-ede South Africa.
Ogba na ni yio gba idabobo to ga julo, a si ni ireti wipe yio fa opolopo awon
arinrin-ajo-afe nitori ipo re titun ni agbaye.
Gebebi oro Dokita Hans Grobler to je Igbakeji Oludari NCS: "Ikede na dun wa
ninu o si wu wa lori. Opolopo awon omo orile-ede South Africa ati awon eniyan
lati orile-ede miran lo ni ife to ga si ogba ile olomi
ti Greater St Lucia to si ti se atileyin fun wa ninu akitiyan wa lati ri wipe
ogba na ati awon ilana adayeba inu re ni a dabobo nigbagbogbo".
Minisita fun Ise-ogbin ati Oro Ayika fun KwaZulu-Natal, Ogbeni Narend Singh
fi idunnu re han lori ikede wa. O ni yio mu iwuri pupo wa fun irin-ajo-afe fun
ekun na lapapo ati wipe KwaZulu-Natal yio ni anfani pupo
latari awon ise titun to ma si sile lati inu idagbasoke ise irinajo-afe alagbero.
O se afikun wipe: "Italaya wa fun ojo iwaju ni lati se agbekale awon ohun elo
ti yio mu ki awon alejo le je igbadun awon ohun na to mu ki St.
Lucia je ibi pataki -sugbon lati dagbasoke ni ona ti ko ni kolu awon ilana adayeba
re oniyebiye tabi ko se idojuru ewa agbegbe na."
Lara ogba ile olomi St. Lucia na to to adotalelugba egberun sare hektari ni
ati ri gbogbo Adagun St. Lucia, Ile Olomi Iyasoto ti St. Lucia ati Maputaland,
Ile Iyasoto Etikun ati Ile Iyasoto ti Etikun Kosi. O se akojopo
orisirisi ibugbe lara eyiti a ti ri awon oke alasopo awon eda abemi bi iyun
labe okun ati awon etikun, awon igbo etikun, ile ira olomi iyo ati olomi mimo,
omi Adagun St. Lucia funrarare, ile gbalasa etikun ati awon
agbegbe oko igi.
Agbegbe ti a dabobo na je ile fun awon erinmi iha gusu julo to tobi pupo, egberun
ooni ati opolopo awon eranko ati eye. Lara awon akitiyan awon arinrinajo-afe
ninu ogba na ni ipeja, iwako-olopon, eye-siso,
imokun ninu omi jijin pelu awon ohunelo ode oni, irinse ati ipago. Gbogbo akitiyan
yi lo fi aye sile fun
iyaworan. Ramsar
Ajo Agbaye so orile-ede Madagascar ati Vietnan po ninu Ise Lori Ounje.
1 mins 51 secs
Ninu emi ifowosowopo ti iha gusu eyiti oloogbe Aare orile-ede Tanzania nigbakanri,
Julius Nyerere bere re,
awon ijoba orile-ede Madagascar ati Victnam ti gba lati sise papo lati se idagbasoke
eka ise-ogbin ninu oro
aje Madagascar. Laipe yi ni awon orile-ede mejeji fowo siwe adehun kan pelu
Ajo Agbaye fun Ounje ati Ise
Ogbin (UN Food and Agricultural Organisation (FAO) lati ran awon amoye lati
orile-ede Vietnam lati se
iranwo fun eka ise-ogbin ni Madagascar. 11
11 Page 12 13
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
12
Gegebi adelun na se lo, Vietnam yio ran Madagascar lowo fun odun meta lati se
idamo, lati se agbekale ati lati se awon orisirisi ise agbese igberiko kekeke
to wa ni ibamu pelu inilo Madagascar Erongba awon ise agbese
na ni lati se imukuro gbogbo idena to wa fun ipese ounje alagbero fun orile-ede
erekusu na. Awon ijoba orile-ede mejeji ati ajo FAO yio si se atileyin.
Akojade kan fun awon oniroyin lati odo ajo FAO salaye wipe ifowosowopo iha
gusu iru eyi npese anfani fun imulagbarasi ifowosowopo laarin awon orile-ede
to sese ndagbasoke ti o wa ni ipele idagbasoke to yato si
ara won, pelu atileyin awon orile-ede olugbeowosile ati ajo FAO. Ise na nse
labe asia Eto Pataki ti ajo FAO fun Ifokanbale lori Ounje (FAO's Special Programme
for Food Security (SPFS), eyiti o nran awon orile-ede
lowo lati je anfani iriri ati imose awon orile ede to ti dagba pupo. Dokita
Jacques Diouf to je Oludari-agba fun ajo FAO lo se ifilole eto na ni ibere odun
1997. Eto pataki fun Ifokanbale Ounje na nlo lowolowo ni orile-ede
mokanleladota, mokanleogbon ni Afirika, mejila ni Asia ati Ila-oorun ti tosi,
mefa ni Latin Amerika, meji ni Europe ati okan ni Oceania eyiti o duro fun iye
to ga ju iko ogota ninu ogorun awon orile-ede to talika ju laye
lo. FAO. Org
Omo orile-ede Japan to wewon ni orile-ede Thailand se iwuri fun isowo ninu
Labalaba ni orile-ede Ghana. 1 min. 43 secs.
Eka ile-ise ti Eda Abemi Egan ni orile-ede Ghana ti bere ipolongo kan lati
se igbelaruge owo ninu awon
labalaba ti a mu lati inu igbo ti a se itoju won ti a si wa to won sori pako
tabi ohun miran. Awon eya labalaba bi ogun ni won ti damo ni orile-ede Ghana.
Lara awon eleyi ni a ti ri awon eya to je ti agbegbe na nikan bi
Diopetes kakumi, Mylothris atewa, Epitola asibeyi ati labalaba ti iha
iwo-oorun Afirika Papilo Antimachus to niiye apa to fe to iwon sentimita
medogbon. A le ri Papilo antimachus kokan ta fun iye owo to to ogorun
owo dola Amerika (USD100). Opo minu awon eya to ku ni a le ri okokan won ta
fun owo dola Amerika
meji (USD2.00) eyiti o je owo to joju ti a ba se si owo Ghana -cedi.
Owo kariaye ninu atopo labalaba to ogorun milionu owo dola Amerika (USD 100
Million). Eka Ile-ise Eda Abemi Egan Ghana si gbagbo wipe on le ri owo to to
adojo egberun owo dola Amerika (USD 150,000) pa
lododun lati inu ise-osin labalaba. Akitiyan titun yi bere leyin ti ile ise
asoromagbesi aladani kan royin mimu ti
awon osise eda abemi egan ni Thailand mu omo orile-ede Japan kan ti o nji labalaba
pa ni Thailand. Won fi si itimole ni ogba ewon ki o to di wipe eka ti imo nipa
eranko ti ile eko giga Yunifasiti kan ni Thailand se idamo
awon labalaba na. Iroyin na di oro yeye ni orile-ede Ghana, sugbon o tun pese
anfani fun adele oga agba awon osise eda abemi egan ni Ghana, Ogbemi Nick Ankudey,
lati da awon omo orile-ede re leko lori awon
Eto Fun Awon Omode
Ko Si Eja Fun Erinmi 2mins. 1 Sec. (Itan yi nso Idi Ti Erinmi
fi ma ntu igbe re kakiri. Itan na wopo laarin opolopo awon eya ile Afirika,
biotilejepe odo awon eya Bushman lo ti bere).
Nigbati a nfun eranko kokan ni aye ni aye, ako ati abo erinmi kan bebe wipe
ki won fun won laaye lati ma gbe inu omi tutu ti won feran pupo. Opolopo ikominu
lo wa nipa gbigba won laaye lati gbe ninu omi. Enu won tobi
pupo, eyin won gun o si mu, irisi won ati ijeun won tobi tobe ti eru fi nba
awon eranko yoku wipe won yio je gbogbo eja to wa ninu odo tan. Yato si eyi,
won ti fi ibe fun eranko miran lati ma gbe -iyen ooni. Ko dabi
enipe o mu ogbon wa lati jeki orisi eranko nlanla meji ti eb i ma npa gan an
gbe ninu awon odo. Nitori idi eyi won ko ibere awon erinmi won si ni ki won
ma gbe ori ile gbalasa ati ile onikoriko. 12
12 Page 13 14
CHANGE Radio
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba)
13
Nigbati won gbo iroyin yi, awon erinmi mejeji beresi sunkun won si nke, ariwo
ti won si npa buru pupo. Won bebe titi ti won fi ri ibere won gba. Sugbon ni
idakeji, won mu ki awon erinmi na jeje wipe ti won ba ti ngbe
ninu awon odo, won ki yio pa ejakeja lara. Koriko ni won gbodo ma je dipo. Awon
erinmi na jeje tokan tokan, won si sure sinu omi won nkun pelu idunnu. Bena
lo si se ri wipe titi di oni oloni ni awon erinmi ma
ntu igbe won ka si bebe odo, ki gbogbo eranko le ri wipe ko si eegun eja ninu
re. O si si le gbo bi won se nrerin pelu ayo wipe won gba won laaye lati gbe
ninu odo nigbeyingbeyin.
When Hippo was Hairy.
Bawo ni Ejo se ngun igi laini ese ? 29 Secs. Ejo ti o ba ngun igi
ni awon ipe to lagbara labe inu re. Awon eleyi ni a npe ni ipe ikun. Awon ipe
yi a ma
farako si ara epo igi ti ko jolo ki ejo na le fa ara re lo soke. Gbogbo ejo
lo ni awon isan alagbara to so mo
egbe won. Bi awon isan na se nti egbe won. lo siwaju beni awon ipe wuruwuru
aya won nfarako ibikibi ti ko ba ti jolo lati ran ejo na lowo lati lo siwaju.
Chongololo
Oro ti enikan so lori Itoju: Aye to lopin 36 Secs. "Aye rubutu ti a ngbenu
re yi dabi oko inu ofurufu nla........ Sugbon agbara ati ohun elo inu re lopin.
Ki a tun
so ni ona miran, oko na ko le tobi si, besi ni awon oro inu re niwon. Bi a
ko ba fi idiwon si bi eda eniyan se
npo si i, bi a ba si fi awon ohun agbara, oro ati ile aye sofo, oko inu orun
yi ati gbogbo atuko ati ero inu re yio fo yio si segbe sinu afefe, eyi si jasi
iparun gbogbo eda eniyan.
Ryoidu Sasakawa, Alaanu omo orile-ede Japan kan
Ehoro ati awon omo Kiniun Abo kiniun ni awon ikoko marun. Nigbati o si
ti di igba ti won nilo eran sugbon ti won si kere ju lati ba lo sode,
o pinnu lati wa olutoju fun won. Ni owuro ojo kan o nyan lo lona ti awon eranko
ma ngba o foju sona lati ri
eranko to le se ise na. O koja lara ijapa laitile dase duro. Ijapa ti rindin
ju yio si tan eniyan ni suru. Akata sare kuro lona fun un, bi o se nki tiberutiberu
lona ojo tire sugbon kiniun ko wo odo re. Eniyan o le fokan tan
akata pelu ise to kere julo, ki a ma wa so titoju omo re.
Pelu ikanju, Kiniun wa igbo na pelu oju to mu, nitori o nfe gbona re lo lati
sode. Lojiji, owu rubutu onirun kan
fo koja niwaju re .......... kini yen, Ah-Ehoro!
"Duro! Kiniun pase "Se oju nkan e tobe lenu ojo meta yi ti o tie fi nki mi
mo?"
"E karo iya agba," Ehoro ki towotowo. " Se alafia ni e wa ati awon omo yin arewa
mararun?"
"Nipa won na ni mo fe soro", Kiniun so fun. "Enikan ma ni ola ati oore-ofe lati
toju won nigbati mo ba lo sode."
"Ola gidi ni yio je fun eni na", Ehoro soro laigbohunsoke.
"Beni, iwo lo ma se e", Kiniun dahun. "Ko mura lati kun oju iwon igbekele ti
mo ni ninu re bikojebe ki o sora gidigidi. Ngo ma mu eran wa lojojumo, wa si
ma pin wa si ma fi bo awon omo na ni dogbandogba. Ngo ma
wa wo won loorekoore, nitorina ki o bojuto won daradara. Paapa, ise re ti bere
ni bi mo se nsoro yi ko si si eniti o nso won nisisiyi, nitorina ki o yara lo."
Bi o se so be tan Kiniun yipada o si pare sinu igbo -o ti ri ojuutu
si isoro re. 13
13 Page 14 15
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
14
Awon isoro ehoro sese bere ni. O fese janle ni ibinu. "Ola nitoto!" o bara e
soro pelu ibinu. Iyen ni wipe ko si ounje aaro fun oun niyen. Ki oun ya wa ibiti
o pamo fi awon omokomo na si. Bo se nyara rin lo, Ehoro ko
fi akoko jafara. Opolo e to mu yanyan ti beresi sise lori bawo ni oun se le
jere ninu ohun to sele. Tani Kiniun to ma fi on sise lasan? Ehoro ri iho nla
kan to sofo o si ko awon omo Kiniun sinu re nibiti won o wa ni alafia.
Lojojumo ni Kiniun nmu eran wa to si nbere: "Bawo ni awon omo mi se wa? Jeki
nri won." "Won ti ndagba, won tobi, won si lagbara," Ehoro a dahun. A na owo
re sinu iho a si fa omo Kiniun kan pelu eti e fun iya e lati
ri. A da iyen pada a si tun fa omiran soke ati bebelo.
Sugbon ni gbogbo igba yen, Ehoro funrarare lo nje eran yen to si nfi kekere
ninu re bo awon ono Kiniun. Ni
okokan awon omo Kiniun ku o si ku okansoso. Nigbati Kiniun ba de lati wo awon
omo re Ehoro a fa omo kansoso to ku soke a si yara fihan ki o ma ba ri bi o
si tirin to, a da pada a si dibon bi enipe o nwa omiran.
Sugbon omo Kiniun kanna ni yio fa jade lemarun. Laipe omo yi na ku. Ehoro
mo pe ti Kiniun ba mo, ojo aye on pin niyen, nitorina o ronu gan an. Laipe Ehoro
sare lo si ibi igbo elegun kan o si rapala gba inu re koja ni
bi emelo kan titi ti awo ara re fi di wuruwuru ti o si faya, o si ni awon ogbe
ti o buru pupo. Lehinna o wa pada
lo si iho ibiti awon omo Kiniun wa o wa na gbalaja dubu e. Nigbati o gbo ti
Kiniun nbo, o beresi sokun o si nkerora bi eniti o wa ninu irora ati ibanuje.
"Kilo sele?" Kiniun kigbe. "Nibo ni awon omo mi wa?"
"O mase o, o mase o!" Ehoro kigbe. "Mo nso awon omo yin nigbati egbe awon
obo kan de ti won pa awon omo na won si je won. Mo gbiyanju lati le dabobo won
sugbon kini mo le se, emi nikan laarin gbogbo awon
obo yen? Mo gbiyanju sa asala sugbon eyin na ri bi mo se ri.
Kiniun ti fere gba wipe ooto ni Ehoro nso. O dabi enipe awon obo ti lu bole
-sugbon o nfe aridaju. Ehoro ni, "A o se igbo suru kan nibiti e o fi ara pamo
si. Nigbana ma da epa kakiri ayi ka lati le fa awon obo na wa,
e o si gbo nigbati won ba nfi enu ara won jewo. Nigbati e ba ti dara yin loju
ese won ki e be le won mole -sugbon
e gbodo ge iru won lati le fun mi ni idaniloju melo lepa ninu won." Kiniun gba,
laipe o si fi ara pamo sinu ibi ipamo na. Ko pe lehin naa ni awon obo de nitori
epa ti Ehoro fun kakiri ile. Ehoro joko kehin si igi kan
o si sebi enipe on ko ri awon obo na. O he epa kan o yiri e wo laarin awon
ika e, o nkorin lohun pele: "Fun awon omo ti a ti je, ko si ohun to sele si
wa."
Awon obo je alafarawe to ga. Ako nla to je olori won wo Ehoro o si fetisi
orin e. On na he epa kan o nju kiri laarin awon ika re titi ti o fi nyi, on
na si nkorin pelu Ehoro.
"Fun awon omo ti a je ......." beni gbogbo egbe joko ni ileele ti won si se
afarawe olori won, won nyi epa won si nkorin na pelu bi ohun won wuruwuru ti
ga to.
"Ko si ohun to sele si wa."
Kiniun ko gbo ohun pele ti Ehoro sugbon o gbo ti awon obo. O beresi hu pelu
ibinu iru re si nju lati egbe kan si ikeji bi o se ngbaradi lati be. Awon obo
ko gbohun re laarin gbogbo orin ti won nko, nitorina o ba won labo
nigbati o be saarin won to si pa opolopo won to si ge iru won kuro. Ehoro wa
leyin re o si nsa awon iru na bi o se nge won sile. Nigbati o ti pa gbogbo obo
ti ko raaye salo tan, Kiniun joko o nmi hele lati sinmi. Ehoro
yan de lati eyin re, o si ko awon iru soke.
"E wo iye obo ti mo pa lati fi gbesan awon omo yin. Melo ni e pa?"
Sugbon kiniun ko ri iru kokan lati fihan. Shangani Folktales 14
14 Page 15 16
CHANGE Radio
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba)
15
Idi ti Amotekun fi ma nfi Ounje re pamo soke igi 1 min. 55 Secs. Awon
omo ile Afirika ma nso itan yi fun awon omo won wipe nigba pipe seyin, awon
ore meta wa, amotekun
arewa, ijakumo ati akata. Won ma njijo lo sibi gbogbo ni. Nigbakugba ti amotekun
ba pa eran yio fi ninu re sile fun awon ore re ki awon na le jeun to dara.
Ni ojo kan o sele wipe ara Amotekun ko da, nitorina ko le sode. "Ijakumo"
o pe ore re, "Jowo pa eran die fun mi, ara mi ko da." Sugbon Ijakumo ole dahun.
"O ti o, o ti re mi, so fun Akata." Nitorina Amotekun ni
"Akata," jowo pa eran fun wa loni, nitori ara mi o ya to lati se." Sugbon Akata
na tun wa awawi. "O ti o, mo ni ogbe ni ese mi."
Bi o se so bayi, Amotekun kigbe ni ibinu: "Mo ro wipe ore mi ni yin sugbon
eyin mejeji ole buruku ni yin. Lailai mi o ni fi eran sile fun yin mo ti nba
ti pa eran mi. Lati oni lo ma se aridaju e. Ti nba ti je eyiti mo fe ninu
eran mi ngo fi iyoku ko soke igi. Nigbana ko si eyiti yio le debi to wa ninu
yin.
Amotekun sebi o se wi. Lati ojo na lo ni ko ti fi eran kokan sile fun awon ore
re amotaraeninikan. Oke igi lo ma ngbee lo nibiti owo awon ijakumo ati akata
ko le to. Won ti di asaleje nibayi, won a ma je ajeku ti awon
eranko miran ba fi sile. Ojo ibanuje ni fun won nigbati won padanu Amotekun
gegebi ore. When Hippo was Hairy
Awon Otito to Wulo ni Arowoto
Iseda Aye Kolu Ipinle orile-ede India Kan lona to le 44 Secs
O fere to egberun mejo emi to segbe laipe yi ninu iji nla meji ti a npe
ni iji lile alajayika (cyclone) eyiti o ba abule to ju egberun mejidinlogun
lo je ni awon ekun etikun ipinle Orissa ni orile-ede India. Gegebi isiro UNICEF
agbole milionu meta ni oro na kan, o si ju milionu mewa eniyan to ti si nipo
kuro ni ibugbe won. Gbogbo irugbin lo baje patapata ni itopa etikun na to lo
bi ogoje ibuso kilomita.
UNICEF ati awon ajo miran kakiri aye ti fi ohun elo iderun ranse si awon ti
oro na kan. Ajo na ngbero lati wa ni Orissa titi di odun 2002 nigbati won o
ti tun Orissa ko, ti yio si ti pada bo si po patapata.
UNICEF
Orile-ede Kenya ngbero lati siwo Ijoba kuro lara ibudoko etikun kansoso
ti o ni. 1 min. 2 Secs.
Ijoba orile-ede Kenya ngbero lati jawo kuro lara ibudoko etikun kansoso to
ni, iyen Ibudoko Kilindini, eyiti
gbogbo eniyan mo si Ibudoko Mombasa latari iwa ibaje to ga ninu Ajo Alase Ibudoko
Etikun ti orile-ede Kenya (Kenya Ports Authority). Eto ti wa nile tipe gege
bi ohun asegbeyin ti ko ba sese fun won lati pa iwa
ibaje to ti jinle ninu Ajo Alase Ibudoko Etikun orile-ede na run.
Gegebi iwe iroyin, ti ro laipe yi, won ti bu enu ate lu Ajo Alase Ibudoko Etikun
fun aisekokari awon eru nlanla
daada, o njeki awon eru koja laisanwo ibode, ki eru di awati lona tabi ki won
ti ji won ni ale ko to di ojo ti won o lu awon eru ti won ko gba ni gbanjo.
Sugbon awon ti oro na kan gbongbon ti tapasi igbero lati yowo ijoba kuro ni
ibudoko na. Awon oselu lati ekun etikun, awon egberun mejo omo egbe osise Ibudoko
ati awon eniyan agbegbe ti fi ehonu won lori oro na
han bi won se ngbaradi lati gba iwe idaduro lenu ise eyiti yio lo pelu iyowo
ijoba kuro. News Link Africa 15
15 Page 16 17
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba) CHANGE Radio
16
Awon omo orukan npo si ni ile Afirika 1 min. 4 Secs. Iye awon omode to
di omo orukan lati owo Arun kogboogun Eedi ti ga lo soke fiofio, nigbati yio
ba si fi di
opin odun ti nbo, awon milionu metala omo jakejado aye ni yio padanu okan ninu
awon obi won latari arun na, gegebi iroyin titun kan lati odo Ajo Agbaye eyiti
won gbe jade ninu ayeye ojo Arun kogboogun Eedi lagbaye
ni osu kejila odun yi.
Iroyin na "Awon omo ti Arun Eedi so di orukan: Idahunsi lati owo iwaju lati
iha Ila-oorun ati Gusu Afirika" ni ajo UNICEF ati Eto Alajosepo Ajo Agbaye lori
kokorun arun HIV ati Eedi jijo se akopo re. Nigbati yio ba
fi di opin odun yi, aye yio ti ri awon omo to ju milionu mokanla lo ti Arun
Eedi ti so di orukan ti iko
marundinlogorun ninu ogorun won si wa ni iha isale asale Sahara ni Afirika.
Gegebi oro Carol Bellamy to je Oludari Alase ti ajo UNICEF, "Bi isoro ti awon
omo orukan na se ga to koja siso. Ki arun Eedi to waye omo die ni awon orile-ede
to sese ndagbasoke lo je orukan. Sugbon nisisiyi, o ju
okan ninu mewa lo to je omo orukan. UN News.
Ajo Agbaye se Igbelaruge Eto Awon Alaabo-Ara 42 Secs. Nje o mo wipe
o ju edegbeta milionu awon alaabo-ara lo to wa laye lode oni? Eyi fi won si
aarin awon orile-ede
marun ti iye eniyan won poju lori ile aye. Ajo Agbaye (The United Nations (UN)
ti titorina kepe fun eto
imulo ti a moomo se lati se aridaju ona ni dogbandoga fun awon alaabo ara si
awon eko ilu, ti oselu, ti awujo ati ti asa jakejado aye.
Pelu apejuwe awon eto fun awon alaabo-ara gegebi okan ninu awon oro to nipon
to dojuko eda eniyan lode oni, ajo UN ro awon orile-ede lati fun won ni ona
si eko, ise ati igbe aye awujo eyiti o ti nfo won ru titi di isisiyi.
UN News
Awon Otito lati odo Ajo FAO 48 Secs. * Awon iroyin meji to jade laipe
yi lati odo Ajo Agbaye fun Oro Ounje ati Ise-ogbin (UN Food and
Agricultural Organisation -FAO) ti tokasi wi pe idagiri ounje nibi gbogbo ni
aye nwaye lati owo eda
eniyan yato si iseda aye. Awon iroyin na wipe: "Fun igba akoko, ajalu ti awon
eniyan da sile bi ija igboro ati idaamu oro aje ni ikolu to poju lori awon ounje
ju idaamu ti iseda aye da sile lo."
* O fere to milionu mewa eniyan ni iha isale asale Sahara to nilo iranlowo
ounje ni pajawiri nisisiyi. Ni orile-ede Somalia nikan milionu kan eniyan lo
ni idojuko owon ounje to le
nigbati awon to le ni ogun oke eniyan wa labe ewu airiounjeje rara.
* Won ti yan Dokita Jacques Diouf ti orile-ede Senegal lati lo akoko odun mefa
keji gegebi oludari agba fun Ajo Agbaye fun Oro Ounje ati Ise ogbin (UN Food
and Agricultural
Organisation) lati osu kinni odun 2000. FAO-Org.
Awon Ohun to dunmoni lati se, lati ri, ati lati mo 2mins. 16Secs. *
Isode Alafia (Green Hunting): Eyi je okan ninu awon ere idaraya to titun
ju laye, o si je abula laarin
ere idaraya to nmu ni sa agbara to po ati irinajo-afe to wa ni ibamu pelu itoju.
O le sanwo lati ta awon ofa keekeeke lu awon eranko dipo ki o pa won. Awon ode
alafia jeki o seese fun awon afenifere iseda aye lati
ko awon eranko lo si ibi ti ko lewu lati fi awosorun oniredio sorun won ki won
si toju ogbe won. Ere idaraya
na nse akojo owo fun itoju iseda aye. Sugbon o seese ki a si ere na se debi
ti o fi le fa ewu ba eran-ode ati ode paapa. 16
16 Page 17
CHANGE Radio
Vol II No. 14
January 2000 (Yoruba)
17
* Igbo Bwindi ti ko se wo: Igbo na ti a mo daradara fun awon inaki ori
apata to wa ni be ni o je ile fun die ninu awon akojopo eweko ati eranko to
kun daradara -igba eya igi, irinwo-din-ladota eya eye ati ogorun
eya eranko. Awon olugbe ibe ti eniyan nri ju ni awon labalaba -irinwo-dinladota
eya -awon ti a si ngbohun won ju ni awon eye ati obo. Awon to soro lati ri ni
awon erin igbo ti won npare mo inu igbo, beni awon ti
eniyan si nwa ju ni awon inaki. Awon inaki Bwindi ni ifanimora to yato, boya
latari apapo titobi ti won tobi pupo, wiwa ti won wa labe ewu iparun ati ifanimora
lati ri eda to jo eniyan pupo tobe ni
ifojukoju.
* Awon Adan to banileru sugbon to tun yanilenu: Pelu bibu ti awon eniyan
nbu won fun irisi won to
burewa ati isopo won mo awon oku to nji dide lati mu eje eniyan loru ni aye
atijo, adan je eranko ti a ko mo daadaa. Iwoye awon adan finnifinni, awon to
nje eso ati awon to nje kokoro fihan wipe.
* Laisi awon adan yi to nmu ibisi ba awon itanna to si ntan eso kakiri, ipinsiyeleyele
awon eweko igbo ile olooru iba dinku gidigidi;
* Laisi awon adan, idapada awon igbo ile olooru ko ni waye;
* Laisi awon adan eleso to nje ounje aladun itanna igi afon ti o si ntipa be
mu ibisi ba igi na, omiran igbo yi iba ti ku akurun;
* Egbaata adan ti eniyan ba ri laarin iseju mewa ni irole ojo kan yio ti je
iwon kilo kokoro metalelogun -ona to peye lati fi pa awon kokoro laisi ewu fun
eda eniyan tabi ayika.
Africa Environment and Wild Life
CHANGE Radio (ISSN 1119-6211) je akojade fun ero asoromagbesi olososu eyiti
a nte jade ni ede Geesi,
Hausa, Igbo, Faranse ati Yoruba lati owo Communicating for Change (ti a mo tele
si WWF Africa Communications Network) 5A, Adeyemo Alakija Street, Victoria Island,
P. O. Box 56283, Falomo, Ikoyi,
Lagos, Nigeria. Ero Ibanisoro: (234)-1-262-0602, Ero Ifa eda iwe ranse: (234)-1-262-0603,
E-mail cfc@ fordwa. linkserve. org. Gbogbo itan ni a le tun lo pelu ijewo to
ye. E fi gbogbo iwe ranse si: Olootu,
CHANGE Radio. Aworan Eyin Iwe: Eye Ako Demoiselle ti a nri ni ipinle Borno ni
orile-ede Naijiria. Olootu
Alakoso: Sandra Mbanefo Obiago, Olootu/ Onkowe: Obasi Ogbonnaya. 17
© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw