Document Body Page Navigation Panel
Eyo kansoso ninu milionu ajesara alatenuje lo nyorisi irose ti o je mo ti
ajesara. Sugbon biotile je ajalu fun eniyan kokan to, ewu ati ni ikolu roserose
omode lati inu ajesara ko to anfani ti o wa ninu didena egbegberun
arun na titun lododun. Ajo Agbaye fun Ilera ti yan Ajesara Alatenuje fun Idawole
Iparun Arun Roserose Omode ni Agbaye nitoripe o ma ndena ikolu daradara ju Abere
Ajesara re lo. O ju bilionu (milionu lona
egberun) kan ajesara Alatenuje ti a nfun awon omode lododun jakejado aye.
Bi mo se nkowe yi leyin odun mokanlelogbon, ko ti si iwosan fun Arun Roserose
omode. Sugbon idena wa fun arun na, bena si ni ipolongo jakejado aye lati pa
arun na run nigbati yio ba fi de opin odun yi.
Loni, arun polio ti a tun npe ni Roserose awon Ewe ni a ti parun ni opolopo
agbegbe aye. Awon ibi itoju kokoro arun na to le ran eniyan wa ni iha isale
asale Sahara ni ile Afirika ati Gusu ile Asia.
Neema Bhandari Moving Pictures Catalogue.
Asa ibile se iranwo lati dekun Isodiasale 4 mins. 22 Secs. Won ti
se iwadi kan lati se akosile awon ona ti ibile lati fi se akoso oro adayeba
eyiti awon agbe ati darandaran
to ngbe ni awon eteti iha isale asale Sahara ni ile Afirika. Iwadi na ni a se
lati se igbelaruge anito ounje ati idinku osi nipa sise iwuri fun iwadi lori
isakoso ile gbigbe lona titun.
Iwadi na eyiti Eto Eteti Asale ti Egbe olubanidamoran lori Iwadi lori Ise
Ogbin ni kariaye (Consultative Group on International Agricultural Research
(CGIAR) se ni o se akosile awon ogbon ibile to si wa fun igbelaruge
itoju, sugbon o tun se awari wipe awon ogbon awon olugbe asale ti nsare di ohun
igbagbe.
Ni ipari re, iwadi na so wipe: "Awon ofin ati ilana to ti figbakanri ran awon
eniyan ti emi won yi to ngbe egbegbe asale lowo eyiti o jeki won le gbe ni ibamu
pelu iseda aye ninu ilana ilolupo eda abemi ati agbegbe to
gbelege ni a ko tele mo, ki ise wipe amoomose sugbon nitori ko si awon ona miran."
A gbe Eto Etiti Asale na dide lati se itoju awon ogbon na.
Awon olugbe asale ni orile-ede Kenya ati Burkina Fasso wa lara awon ti won
se iwadi lodo won ti a si koo sile.
Awon eniyan agbegbe Turkana ni iha iwo-oorun ariwa Kenya a ma fi iya to le je
enikeni to ba ge igi ninu Moru Anayeche to je igbo mimo eyiti won gbagbo wipe
o je ibi isedale won. Awon agbegbe na a tun ma dabobo
awon igbo ti o ba je mo ti alujonnu awon oku, o si tun ni awon ofin ayebaye
to se iranwo lati toju awon eweko ati igi to ba wa leti awon igbo na, sugbon
itoju re je ise gbogbo agbegbe.
Bena ni ni orile-ede Burkina Fasso, awon eniyan agbegbe asale die ma ngbin
awon igi bi awon igi elegun Acacia Albida sinu oko won nitori won woye
wipe wiwa ni be awon igi na ma nfun won ni ire oko to posi.
Won tun ma nse iwuri fun fifi awon iseku irugbin sile laarin oko ti a ba ti
fi itule tu won. Awon agbegbe na ki igba ki won lo awon eya igi kan bi Paricum
Lactum ati Cenchrus bilflorus (ti a mo ni agbegbe gegebi
cramcram) lati fi dana nitoripe won ma nje awon oka won nigba eerun "akoko ebi"
nigbati ko ba si jero tabi oka baba mo ninu ile. Titi di enu ojo meta yi, awon
darandaran agbegbe Sahel ati awon ohun osin won ma
ntele ojo lo si iha ariwa nigba ojo, won a si tun pada lo si awon papa oko tutu
ni iha gusu ni akoko eerun. Won na ngbin irugbin sugbon won tun ma nje ki ile
wa ni ailo lati jeki o tun ara re se. Sugbon nisisiyi, pelu olugbe
to npo si, ko si ile gbalasa mo bena si ni ko si ile-oko ti a le fi sile lailo.
Nitorina o ti di dandan fun awon olugbe asale lati fi igbe aye isikiri won sile
fun eyiti o joko loju kanna, eyi si ti yorisi isogbin-ju, ijekoju ati ipagborun
lati le ru la ninu awon ekun to sofo yi.
Iwadi na so wipe: "Iwontunwonsi igbe aye ni awon eteti asale ti nbaje nibi
gbogbo eyi si nfa isodiasale ati irokeke iyan, ipadanu ati ibaje igbe aye eniyan
ati ti ayika." 1
1 Page 2 3
10
Vol II No. 15 (Yoruba) CHANGE Radio March 2000
Awon isoro wonyi lo buru si nigbati akoko ogbele gigun kan waye ni ile Afirika
lati odun 1968 si 1973. Awon oko ogbin di asale, egbegberun awon eniyan ati
maalu lo si ku latari airiounjeje. Awon logaloga onimo-sayensi
ati alase gbagbo tokantokan wipe ti a ba se akoso awon oro adayeba lona alagbero,
a le da ibaje ile duro ki a si din ikolu buruku ti ogbele ku.
Wiwa ona lati se eleyi lo yorisi idasile Eto Eteti Asale pelu ifowosi awon
agbajo ajo pupo. Lara awon wonyi ni Banki Agbaye, Akojo owo fun Ilolupo-Emi
ni Ekunjekun, Ajo orile-ede Amerika fun Idagbasoke ni kariaye
(USAID), Ajo Agbaye fun Ipese Ayika (Globa Environment Facility (GEF), ati Ibudo
kariaye fun Iwadi lori Idagbasoke (International Development Research Centre
(IDRC).
Eto na nlo lowolowo ni awon orile-ede Afirika mesan; Botswana, Burkina Fasso,
Kenya, Mali, Namibia, Niger, Senegal, SouthAfrica ati Zimbabwe.
CGIAR News
Nigbakanri a nge gedu, nisisiyi a nse itoju igbo na. 3 mins. 58 Secs.
Ona to lo lati ibudo oko ofurufu Redding si Hayfork, ilu kekere kan elegbaa
eniyan, eyiti o wa ninu Igbo orile-ede
ti Trinity ni igun iha iwo-oorun ariwa California, lo lo yi ona ori apata kan
to kun fun eweko. Ona yi ni Lynn Jungwirth se afihan ipa pataki to ko. O ti
se idasile ona moto eyiti o mu itan agbegbe re to jinna rere wa
si aye ode gbangba to si mu aye ode gbangba lo si agbegbe re.
Ile to je ti ijoba apapo lo bo oju ile to je iko marunleladorin ninu ogorun
gbogbo ile to wa ni ibile Trinity (eyi je iye kanna pelu agbegbe ijoba ibile
kan), a si mo awon abule ibe bi eyiti o gbara le gedu julo ni ipinle California.
Ninu awon ariyanjiyan lori ojo iwaju awon igbo orile-ede ti Amerika, Jungwirth
ti fi ara re han gegebi agbenuso to lagbara fun awon agbegbe igberiko to ti
fi igba pipe gbarale ohun oro yi ti won si nwa ipa ti won o ko ninu
bi a se nse akoso awon igbo na. Ninu awon odun to bere lati bi 1980 koja 1990,
edekoyede lori ile awon igbo orile-ede ti Amerika le si bi awon afenifere ayika
se nja fun idena sii lori ise gedu ti awon to si ro wipe ise-oojo
awon ni oro na kan ja pada. O ju awon milionu mewa eniyan lo to ngbe ni awon
ilu nibiti ise to jemo igbo ti je orisun owo to nwole fun won.
Bi a tile nfi igbakugba soro na bi ti ise to dojuko ayika, Jungwirth omo odun
mokanledota, to wa lati inu ebi onigedu ati alapako gbagbo wipe ona to dara
wa lati fi se itoju awon igbo ti yio si tun mu awon anfani oro aje
ba awon ilu agbegbe. Awon ajafitafita to npo si yika orile-ede Amerika ti beresi
dan awon ona wo lati fi ko awon onise gedu ati pako ti ko ri ise se mo ni awon
ise miran ti yio se imubosipo ati itoju awon igi, odo ati bebe
odo lati fi se agbero ilana ilolupo igbo to dara.
Ise yi je lara igbese to gbooro eyiti a pe ni ise igbo to da lori agbegbe eyiti
o mu ilowosi awon agbegbe ibile wa ninu isakoso igbo to darasi. Fun awon abule
onigedu bi Hayfork, eyiti o njijakadi lati ruula, igbese yi je
itansan ireti.
Ni odun 1993, Jungwirth bere Ibudo Idanileko lori Iwadi lori Ile Ayika Odo lati
gbiyanju lati je ki ona titun fun ise akoso igbo sise fun ilu re. Ni odun 1996,
gegebi iyorisi ise re ni Hayfork, a pee lati darapo mo igbimo to
se eto fun Ipade Nla keje ti orile-ede Amerika lori Igbo, eyiti Ajo Amuludun
Ford wa lara awon to se atileyin re.
Jungwirth se iranti bayi: "Won nsoro lori igbimo kan lori iwadi, okan lori
ilana imulo, omiran lori eko imo. Mo wa so wipe kilo de ti a ko ni igbimo lori
awon agbegbe? Nitoripe ohunkohun yio wu to le je iwadi tabi eto eko
re ti o ko ba ni atileyin awujo lati se won, ko le sise."
Loni, igbimo awon agbegbe, ti Jungwirth je alaga re ti di itankale orile-ede
fun awon ajo bi odunrun, to si je ero pataki fun igbese awon agbegbe lori igbo
ni orile-ede Amerika. Awon osise igbo lati ona jijin bi orile-ede
India, Mozambique ati China ti wa si Hayfork lati keko nipa ise ibudo na ati
lati se pasiparo imo. Ninu awon eto olona-titun ti ibudo na ni won ti ndanwo
ni awon abule ati ilu miran.
Jungwirth mo wipe isakoso oro to da lori agbegbe ni a gbodo papo pelu awon
akitiyan miran ki awon ilu bi Hayfork le se idasile opolopo ona oro aje eyiti
o se pataki pupo fun iruula won. Ni opolopo ojo a ma so wipe
ohun gbogbo yio dara sugbon on na mo wipe ona si gun siwaju. Iroyin Ajo Amuludun
Ford. 2
2 Page 3 4
11
Vol II No. 15 (Yoruba) CHANGE Radio March 2000
Eto Awon Omode
Itan Arigbungbun Ile Afiirika Kan lori Ketekete Abila akoko 4 mins.
49 Secs. Ni atetekose nigbati ohun gbogbo je otun ni ori ile aye, gbogbo
eranko lo ri bakanna, ko si eyi to ni iwo to
dayato tabi aso alarabara. Sugbon ninu iho apata kan to sunmo eti bebe adagun
omi nla na ni awon iwo orisirisi ni titobi ati iriri ati aso wiwo oniruru ati
awo orisirisi wa.
Gbogbo eranko to ngbe ni awon geregere onikoriko gbalasa ni won pe papo ti
won si so fun lati lo si iho apata na ni owuro ojo keji lati lo yan awon iwo
ati aso wiwo ti won ro wipe yio dara ju fun won. Eyi fa irusoke
ariwo ati ifojusona, gbogbo awon eranko lo si ni itara lati ri iru awon aso
ati iwo to wa fun won.
Gbogbo won lo ni ifojusona yi, yato si Ketekete Abila, eyiti o je wipe on kansoso
to je logun laiye e ni ounje. Lotito gbogbo eranko yoku lo mo wipe alajebanu
ni Ketekete Abila. Nigbati gbogbo eranko gbera lati lo si
ibi adagun ma bi ile ojo keji ti nmo, Ketekete Abila ko darapo mo won. Bi yio
ba rin irin to jin to yen, o gbodo koko je koriko tutu daradara fun ounje owuro,
ko si le ri idi ti gbogbo eranko toku ti nkan oun loju lati
wasibi iho apata na. Ketekete Abila fimu soro wipe on yio tele won laipe, leyin
ti on ba ti pari ounje aro oun. Pelu ekunnu koriko lo fi soro jade, nitorina
gbogbo awon eranko yoku fi Ketekete Abile oniwa abuku yii sile
ni ibinu.
Leyin wakati die leyin eyi, Ketekete Abila pinnu wipe on ti jeun to to, o wa
rora nyan lo si ibi adagun, na ni itopase ona fife ti awon eranko yoku ti la
sile. Bi Ketekete Abila ti sunmo adagun na, die ninu awon eranko
na ti npada lo si papa, enu si ya Ketekete Abila lati ri iyipada to wa ninu
iriri won. Erin ti yan aso alawo resuresu kan ti ko wuyi loju sugbon o wa buyi
kun eleyi pelu ehin nlanla meji. Kiniun to yan aso didan alawo
eruku pelu iru nla to ni iru dudu to gun. Eranko kan ti a npe ni Sable ni
aso dudu to ndan pelu awon iwo tite to buru ni wiwo.
Lokokan Ketekete Abila koja lara gbogbo awon eranko ninu awon ohun eso won.
Nigbeyingbeyin, bi o ti fe wo iho apata na, Ketekete Abila koja lara Agbanrere.
Ohun to seni lanu ni wipe Agbanrere ko riran daada
nitorina aso to yan tobi pupo ju fun o wa ri gburugburu lara e. Bakanna o ti
yan iwo meji ti ko tobi bakanna o si le won mo imu re. Ju gbogbo re lo, iriri
Agbanrere ko dara sugbon o dabi enipe inu re dun.
Nigbati Ketekete Abila wonu iho apata na, aso kansoso to ku ni okan to ni
ila dudu ati funfun nlanla, ko si ri iwo kokan rara. Leyin to rin irin-ajo gigun
na, ebi tun ti npa Ketekete Abila o si yara dan aso kansoso to ku
wo. Aso ajeji onidudu ati funfun na ba mu daradara, sugbon nitoripe inu re ti
npariwo ko bikita wipe won ko fi iwo kokan sile fun on. Nibayi awon eranko yoku
to ti pada de ori papa ti beresi ye ara won wo pelu idunnu
ninu awon ohun oso won titun. Nigbati Ketekete Abila pada de papa ko tile bikita
fun awon eranko yioku, nse lo gbori lo sile to si beresi jeun osan re lo. Awon
eranko yoku ri aso onidudu ati funfun re to dayato, won
si beresi rerin eleya. "Wo Ketekete Abila okanjuwa ninu aso e titun to panilerin
ti ko si ni iwo kokan," Gidigidi pariwo pelu efe. Laipe gbogbo eranko to ku
beresi gbe oro na so.
Ketekete Abila ko bikita. Kini eniyan nfi iwo se nigbati o je wipe on to kanpa
ni opolopo koriko ojele lati je nigbakugba ti eniyan ba fe? Titi di oni yi,
Ketekete Abila ko nilo iwo sugbon nigbagbogbo lo ma nsanra ti aso
re onidudu ati funfun to dayato si ma ndan. When Hippo Was Hairy
Nje Awon Oga (Alagemo) ma nbimo nipa pipa ara won? 2 mins. 11 Secs. Itan
aye atijo kan wa ni ila-oorun ile Afirika wipe lati bimo nse ni oga ma npon
igi lo soke ti yio si wa moomo
jabo ti yio si fo si wewe lati bimo. Biotilejepe eyi ki ise otito, itan na wopo.
Kini idi re ti itan na fi bere rara? Nje o seese ko je abajade ijamba? Boya
enikan ri abo oga to jabo lati ori igi to fo si wewe ti awon omo inu
re si jade.
Bawo ni awon oga se nbimo? Awon eya oga kan ma nbimo lori igi. Awon eya miran
ma nye eyin si ileele nibiti ooru ati ogeneten akoko ojo ma nse iranwo lati
pa won.
Opolopo eniyan lo beru oga ti won si npa won. Eyi le je nitoripe oga ma nse
awon ohun to sajeji. Won le yi awo pada nigbakugba ti o ba fe; won le yi oju
mejeji pada gba ona ibomiran lekanna, won si le rin pelu irin
eleyokokan ti ko yara to si sajeji. Gbogbo nkan yi lo ma nderuba awon eniyan.
Sugbon won ma nse iranwo lati dabobo oga kuro lowo awon aperanje, won si nran
oga lowo lati mu awon kokoro to je ounje tiwon na. 3
3 Page 4
12
Vol II No. 15 (Yoruba) CHANGE Radio March 2000
Awon oga le gbe orisirisi awo jade. Won le yipada lati awo kofi, si awo
eweko, awo pupa foo, awo osan pipon tabi awo dudu. Won le jeki awon awo yi ki
tabi fuye, o si le fi ila tabi tototo kun fun idanilojuru nigbati
ayika won ba yi pada. Nitoripe won nse gbogbo nkan wonyi, awon eniyan ro wipe
won loro. Sugbon won ko ni.
Won ki ipa eniyan lara. Ni iyato si nkan ti opo eniyan ro, o ko ni ku tabi
pa awo da ti oga ba bu o je. Eranko na tile nran wa lowo nipa jije awon tata
ati kokoro miran to nje awon eweko ati irugbin inu ogba wa. Awon
idi daradara niyi lati jeki won gbe aye. Chongololo.
Kini Idi ti awon Aayan fi wa nigbati won ki ise iranwo ni ona kokan? 58
Secs. Ibere to dara niyi, beni idahun re gbodo je wipe ohun gbogbo lo ni
ipa tire lati ko ninu iseda aye. Ati aayan ati
esinsin lo je lara ona iseda aye fun idaegbinnu. Ninu igbo won a ma je oku eranko.
Awon esinsin ma nmu oje aladun lati ara awon itanna, won a si tipa be fun won
ni agbara ibisi nipa gbigbe ereku ako itanna lati ara okan
si ekeji.
Opolopo awon kokoro lo ti ri ibugbe mira n nipa gbigbe pelu eniyan. Awon esinsin
ati aaya feran lati maje iyagbe eniyan ati egbin. Ohun to se ni lanu ni wipe
nigbamiran won ma ngbe kokoro arun lati inu egbin sinu
ounje wa. Awon kororo arun yi a ma mu wa saisan, nitorina a gbodo ranti lati
bo awon ounje wa ki a si jeki ile wa ati agbegbe wa wa ni imototo. Bi a ba se
eleyi, awon esinsin ati aayan ko ni da wa laamu pupo.
Chongololo.
Oro ti Enikan so lori Idagbasoke 30 Secs. "Iha gusu Afirika ni awon
oro, okuta iyebiye ati ohun imusagbara ju iha ila-oorun gusu Asia lo. Nibiti
ti igbeyin
yi ti ni igbegbaoroke ni oro eda eniyan. Pelu bi orile-ede South Africa ti bo
sode nisisiyi, a ti beresi dojuko aisedeede wa ninu oro eda eniyan. O da mi
loju wipe nigbati yio ba fi di idaji orundun kokanlelogun, a le bere
si soro nipa awon Kiniun Gusu Afirika ni ifegbekanegbe awon ekun Asia." Christian
Tembo, Igbakeji Aare Zambia/ Courier.
Awon Omo Oore 5 mins. 43 Secs. Oore feran ebi re kekere to je awon
ikoko oore onipe, nigbati o si pada dele ni ojo kan ti o ri wipe won ti lo,
o baraje. Pelu aniyan, o wo kakiri fun aami lati so fun on to sele. Awon ipase
to ri je ti Goya, ologbo ehanna. "Ole yen!" Oore binu. "Ngo mu!" o si topase
na de idi igi giga kan. Nitoto o beresi gbo ti awon omo re nhan
ganran ti won si nkigbe ni oke lori awon eka igi na.
Nigbana ni okunrin arugbo kekere kan rin to ona na wa. O ri idaamu Oore o wa
bi leere oun to sele "Ologbo Ehanna ti ji awon omo migbe o si ti fi won pamo
loke igi yi," Oore salaye pelu ibanuje.
"Fokanle, ngo gba won pada fun o." Okunrin agbalagba na so fun. O si bere
si ge igi na titi ti o fi wo lule. Oore sare lati yo awon omo re, bi Ologbo
Ehanna ti be kuro lori igi na botise subu ti o si sa wo inu igbo lo ti
okunrin arugbo na si nle lo.
Bo se nfo lo ninu koriko Ologbo Ehanna sare kolu Ehoro awon mejeji si subu yakata
sinu igbo ewedo kan. Okunrin arugbo yi ko ri ikolura won o si nsare lo pelu
ero wipe on si nle Ologbo Ehanna lo.
"Oju ma kuku nkan e o," Ehoro kigbe nigbati o ti dide kuro labe Ologbo Ehanna.
"Kilo de?"
"Okunrin Arugbo yen nle mi nitori mo ji awon omo Oore gbe. "Ologbo Ehanna salaye."
"Ma wo ntire, Ologbo Ehanna, nitoripe ore mi ni e, ma ran e lowo." Ehoro dahun.
Ni owuro ojo keji, Ehoro wa Oore lo o si beresi baa soro. Eku araya o, Nhungu.
Mo gbo wipe won ji awon omo re gbe lana. Ohun
to nilo ni ibi to pamo daada lati fi won si. O sele wipe mo ni iho asiri kan
ti elomiran ko mo nipa re, ngo si fi awon re pamo sibe ti o ba fe."
"O seun pupo, Ehoro." Oore ni okan imore pupo fun ifeinu yi, inu re si dun
bi o se nse iranwo lati gbe ebi re kekere lo sinu iho to si fi won sile nibe
labe aabo. Sugbon bi o ti nrin lo si apakan ati Ehoro ni ikojusi re ni o
gbo ti Ehoro npe "Kiakia, Ologbo Ehanna, ma bo kiakia." 4
© 2002 Communicating for Change. All Rights Reserved
Developed by George Mbuagbaw